INEC ìpinlẹ Ekiti láwọn ti fawọn ẹrọ amunawa yanju iṣorọ ki ẹrọ kaadi idbo gbéná lọ lọjọ idibo, INEC: Ohun gbogbo la ti pése silẹ ki eto idibo le lọ daadaa ni ọla
INEC: Ohun gbogbo la ti pése silẹ ki eto idibo Ekiti le lọ daadaa ni ọla
You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín
Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo
INEC: Ohun gbogbo la ti pése silẹ ki eto idibo Ekiti le lọ daadaa ni ọla
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní ní ìpínlẹ̀ Bauchi sọ pé irọ́ ni ìròyìn tó sọ pé àwọn mú ọmọ ẹgbẹ́ PDP bí ọ̀dúnrún ún
O ni Gbogbo ohun èlò lo tí wá nikalẹ fún ìdìbò woorowo tí wọn sì ti kó àwọn ohun elo náà lelekunjekun àti iye oludibo to forúkọ sílè lọ sí ibùdó idibo. Gbogbo ìwé itekasi, káàdì tí yóò ṣe aridaju oludibo.
O ni àwọn iwe ti wọn yoo ko esi ibo si àtàwọn ohun elo elege lo tí wa larowoto àwọn osise tí yóò lo wọn.
Ìpalẹ̀mọ́ ìdìbò gómìnà kò dí àwọn obìnrin lọ́wọ́ lẹ́yìn tí wọ́n jáde lọ́mọde lágbà nílùú Port Harcourt fún àyájọ́ ọjọ́ obìnrin lágbàáyé
INEC Edo ni ọwọ wọn ti tẹ ohun gbogbo ti wọn nilo lati ṣeto idibo alaṣeyọri bayii
Ọjọ́bọ̀ ọjọ́ kèje oṣù kẹ̀ta ni àwọn sọ́jà yabo ààfin ọba Ateke Tom Amanyanabo ti ìlú Okochiri.
Imam Nazifi Inuwa ni àsìkò ti to ki àwọn eniyan Kano yan ẹni to maa tun ipinlẹ náà ṣe.
2019 elections: Ganduje ní òun yóò gba èsì yóòwù tó bá jáde ní ìdìbò gómìnà Kano
Awara ti ẹgbẹ African Action Congress sọ fun BBC pe otitọ ni pe ẹgbẹ All Progressives Congress ti gba oun gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije dupo gpomina fun wọn lọla.
Ni mọṣalaṣi ni agbegbe Saw Mail ni Ilọrin ni o ti gbamọran yii
Ẹrọ to n ka kaadi ni onikaluku a lò fi dibo gomina
Ibudo idibo 4442 ni wọn ti maa dibo ni ipinlẹ Rivers, Usman Belel to jẹ adari awọn eleto aabo ni ko ni si ijade ati iwọle lati aago mejila oru ọjọ Eti si aago mẹfa irọle ọjọ Abamẹta
Garba ni INEC ipinlẹ Kano ti ṣetan lati ṣeto idibo to yaranti
Awọn ọkọ agbopfinro ni wọn fi n ko awọn eelo idibo naa lati ibikan lọ si ikeji
Arabinrin Asmau Sani Maikudi n ba àwọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu sọrọ alaafia ni Zamfara
Gomina ni òun pé ìpadé yii láti fàwọn oṣiṣẹ Edo lọkan balẹ̀ ṣaaju idibo
Wọn ti n pin ohun eelo idibo kaakiri ipinlẹ Bauchi ni ẹ̀ka banki Naijiria to wa ni Bauchi.
Awọn janduku ti dana sun ọọfisi ajọ INEC to wa ni ijọba ibilẹ Ibesikpo Asutan nipinlẹ Akwa Ibom.
Botilẹjẹ wi pe ko ti i si ẹni to mọ nkan to fa ijamba naa, alaga ajọ INEC nipinlẹ naa, Mike Igini ti ṣabẹwo si agbegbe naa lati wo bi ile naa ṣe jona si, tabi boya o jo awọn nkan idibo.
Ibẹru-bojo wa ni ipinlẹ Akwa Ibom ṣaaju ki eto idibo gomina to o waye.
Gomina Udom Emmanuel naa n dije fun saa keji.
Awọn apẹja ati awọn to n wa erupẹ nipinlẹ Benue sọ pe awọn ti gbaradi fun idibo ti yoo waye lọjọ Abamẹta.
Diẹ lara wọn to ba akọroyin BBC sọrọ sọ pe awọn fẹ ẹ dibo yan olori ti yoo pese iṣẹ fun awọn, ati ileewe f’awn ọmọ wọn.