You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Oorun l'àwọn òṣìṣẹ́ INEC yìí sùn láàgo mẹ́sàn án ààbọ òwúrọ̀ ní Ikorodu

    Laago mẹsan aabọ owurọ, oorun ni awọn oṣiṣẹ ti ajọ INEc gba nitori idibo n sun nibudo ti wọn yoo ti pin awọn nkan idibo.

    Ṣaaju ni awọn agunbanirọ ati awọn oṣiṣẹ ti sọ pe awọn ko ni i ṣiṣẹ idibo ti wọn ko ba san owo iṣẹ awọn.

  2. Buhari àti aya rẹ̀ dìbò ní Daura

  3. Ademola Ogunbanjọ oludije ẹgbẹ oṣelu ANN fun ipinlẹ Ogun ti dibo

    Oludije Ademola Ogunbanjo ti dibo ni Ijẹbu Igbo.

    O ni oun gbogbo lọ bo ṣe yẹ nibudo idibo oun ni ipinlẹ Ogun

  4. Bí àwọn kan ṣe n dìbò, ni igbe ọmọ tuntun dún nílé Aláàfin

    Ọkan lara awọn olori Alaafin ilu Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, Olori Mariam Ọmọbọlanle Adeyẹmi bi ọmọkunrin lanti-lanti.

  5. Àwọn òṣìṣẹ́ INEC kò tí ì dé sí ibi ìdìbò Ọṣinbajo láàgo mẹ́sàn án

      • Author, Kunle Falayi
      • Role, BBC Yoruba, Lagos

    Ni aago mẹsan ku diẹ, awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo ko tii de ibudo idibo igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo ni VGC, nilu Eko.

    Niṣe ni awọn oludibo duro tabi joko ti wọn n woye.

  6. Kò s'ówó, kò sí ìdìbò - Àwọn kọ́pà yarí ní Ikorodu

      • Author, Foluke Ogunbayo
      • Role, Broadcast Journalist

    Idibo ko tii bẹrẹ rara ni ilu Ikorodu, nitori awọn agunbanirọ yari pe awọn ko ni lọ si ibudo idibo ti wọn ko ba san owo iṣẹ awọn.

    Asoju ajọ INEC, Ọgbeni Habeeb sọ fun BBC Yoruba pe oun ko ni ohunkohun lati sọ si bi wọn ko se san owo awọn agunbanirọ naa ati awọn oṣiṣẹ yooku ti INEC gba fun idibo.

    Titi di asiko yii, iforukosilẹ tabi idibo ko tii bẹrẹ ni ilu Ikorodu.

  7. Ohun gbogbo ti ṣetan ni adugbo Ipata / Oloje nilu Ilorin

    Awọn oṣiṣẹ elto idibo ti wa ni sẹpẹ ni ile iwe Government Day School, Ubandawaki

  8. Owó ni kẹ̀ẹ̀kẹ́ ìhìnrere

      • Author, Yetunde Olugbenga

    Awọn oṣiṣẹ alaabo n pin owo ṣaaju ki idibo to o bẹrẹ, lati fi ṣe awọn eto to yẹ lati mu ki idibo rọrun.

    Ipinlẹ Ogun ni akọroyin wa ti ba wọn pade.

  9. Àwọn olóúnjẹ kò gbẹ́yìn níbùdó ìdìbò

    Okun inu la fi n gbe tita, bi awọn eniyan ṣe n gbaradi lati dibo gomina ati awọn aṣofin ipinlẹ, ni awọn iya to n ta ounjẹ naa wa ni arọwoto lati ta ounjẹ fun wọn.

    Aworan irẹsi atẹwa ta a ba pade re e ni ilu Ijẹbu-Igbo.

  10. Eto gbogbo ti bẹrẹ ni wọọdu kẹta ni Uyo

    Awọn eleto idibo ti wa ni Cross River ti o ti ṣe ohun gbogbo tan

  11. Wo ibudo idibo ti Senetọ Adeleke Ademola Nurudeen yoo ti dibo loni

    Awọn ajọ eleto idibo ko tii maa de sawọn ibudo idibo kọọkan bii ti eleyi ni edẹ nipinlẹ Oṣun

  12. Gbogbo ètò ti tò loni fun iwọ oludibo lati wa ṣe ojuṣe rẹ- INEC, Ojogbọn Mahmood Yakubu ni ipinlẹ mọkandinlọgbọn nidibo gomina a ti waye loni

    Ajọ eleto idibo ni ohun gbogbo ti ṣetan ki eto idibo bẹrẹ kaakiri Naijiria lago mẹjọ oni ni.

  13. Àwọn kan rèé ni Ijẹbu Ode ti wọn n bọ lati ìṣọ́ òrú kí wọn to lọ dibo

      • Author, Yetunde Olugbenga

    Wọn ni àwọn gba pé adura lo yẹ ko ṣaaju idibo ki olorun le yan ẹni ti yoo dara fawọn eniyan ipinlẹ Ogun

  14. Hajara Sani, obinrin to pinnu lati ṣe ẹtọ rẹ yii lo ti jii de ibudo idibo

    Ṣé ẹ̀yin ti dé ibùdó ìdìbò yín, àbí ẹ ti wà lọ́nà?

    Aago mẹ́rin ni obìnrin yìí, Hajara Sani ti dé ibùdó ìdìbò rẹ̀ tó wà ní Jarawa, nílùú Jos, láti ríi dájú pé òun ni ẹni àkọ́kọ́ lórí ìlà

  15. Eyi ni fidio naa ti o n tàn kalẹ lasiko yii nipinlẹ Rivers

    Fidio yii lo ṣafihan awọn kan ti wọn wọ aṣọ ọmọ ogun ti wọn kọlu ile awọn oloṣelu ni Rivers

  16. Ko si ohun to kan ọmọ ologun ati oṣelu Naijiria- Awọn ọmọ ogun ori ilẹ, Awọn ọmọ ogun Naijiria bẹrẹ igbesẹ lati wa awọn oniṣẹ ìbi ni Rivers

    Lori ẹrọ ayelujara ni fidio kan ti jade to ṣafihan awọn kan ti wọn wọ aṣọ ọmọ ogun lọ sile Omowe Tamunosisi to jẹ kọmiṣọna eto ẹkọ nipinlẹ Rivers ati tawọn oloṣelu mii.

  17. Nigeria 2019: Kò sí ìdí kankan fún ọ̀dọ́ Naijiria láti pa ara ẹ lásìkò ìdìbò

    Nigeria Elections 2019: Àwọn ọmọ Naijiria ti wọ́n n gbé lókè òkun wá sílé wa gba àwọn olóṣelu nimọran pé kò yẹ kí idibo òní mú ẹ̀mí ẹnikẹni dan

  18. Ìpínlẹ̀ Kwara gba bílíọ̀nù kan náírà lọ́sẹ̀ kan sìbò ààrẹ- EFCC, Àjọ EFCC mú kọmísọ́nnà mẹ́fà lórí ẹ̀sùn pé ìpínlẹ̀ Kwara gba bílíọ̀nù kan náírà lọ́sẹ̀ kan sìbò ààrẹ

    Àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba kan àti àwọn kọmísọ́nnà mẹ́fà ni àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC ti mú lórí ẹ̀sùn pé ìpínlẹ̀ Kwara gba bílíọ̀nù kan náírà lọ́sẹ̀ kan sìbò ààrẹ

  19. Ìjàmbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ s'áwọn tó ń lọ dìbò ní ìpínlẹ̀ Kwara, Àwọn èèyàn kan ṣàgbákò ìjàmbá ọkọ̀ nínú ìrìn-àjò wọn lọ sí ibi tí wọn yóò ti dìbò ní ìpínlẹ̀ Kwara

    Ìjàmbá ọkọ̀ ṣẹlẹ̀ s'áwọn olùdìbò kan tí wọ́n ń rìnrìn àjò lọ sí ibi tí wọn yóò ti dìbò ní ìpínlẹ̀ Kwara

  20. Ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́jì nìjìyà fẹ́ni tó bá jí àpótí ìbò- INEC, Àjọ elétò ìdìbò INEC sọ pé ẹ̀wọ̀n ọdún méjì lẹni tó bá jí àpótí ìbò tàbí tó bá ba ohun èlò ìdìbò kankan jẹ́

    Àjọ elétò ìdìbò ní ẹni tó bá jí àpótí ìbò tàbí tó bá ba ohun èlò ìdìbò kankan jẹ́ yóò fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbára