You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Ẹ dẹkun ikede ayederu esi ibo - INEC sekilọ

    Ajọ eleto idibo ilẹ wa ti n fewe ọmọ mọ awọn araalu leti, paapa awọn eeyan to n kede esi ibo to jẹ ayeder, lori awọn oju opo ikansira ẹni lori ayelujara pe ki wọn so ewe gbejẹ mọwọ.

    Ajọ eleto idibo naa ni, ajọ naa nikan lo ni agbara lati kede ẹni to jawe olubori ninu awọn ibo ta di lana.

    Ajọ Inec wa rọ awn eeyan to ti n dawọ idunnu pe ki wọn ni suuru si igba ti oun yoo kede ẹni to ba moke ninu awọn esi ibo naa.

  2. Ibo kika gberasọ lawọn ipinlẹ

    Akojọpọ awọn esi ibo ti n gberasọ bayii jakejado awọn ipinlẹ to wa nilẹ Naijiria, to fi mọ olu ilu ilẹ wa, Abuja.

    Lawọn ipinlẹ kan, awọn osisẹ ajọ eleto idibo lawọn ijọba ibilẹ kan, ti n kede esi ibo awọn eeyan to moke fun ibo ile asofin ipinlẹ, ti eto si ti n lọ lati se iyoku akojọpọ awọn esi ibo naa loni.

    Awọn akọroyin BBC to wa yika awọn ipinlẹ gbogbo nilẹ yii, ti fi ohun ransẹ pe, deede aago mẹsan owurọ yi ni wọn yoo bẹrẹ akojọpọ awọn esi ibo gbogbo to waye lana.

    Ẹmaa ba wa bọ lori ikanni yii lati mọ bo se n lọ nidi ikede awọn esi ibo naa.

  3. E ku ojumọ. Ẹ si kaabọ sori ikanni yii ni aarọ oni.

    Bo se n lọ lori ikede awọn esi ibo ile asofin ipinlẹ ati ibo gomina la maa mu wa fun yin loni.

    Ẹ ku oju lọna.

  4. Ikú dóró! Temitọpẹ Ọlatoye ‘Sugar’ jáde láyé

    Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni, awọn eeyan kan ti yinbọn Hon. Temitọpẹ Ọlatoye, ti gbogbo eeyan mọ si Sugar. A gbọ̀ pe oju ni wọn ti ta ni ibọn. Hon Ọlatoye ni aṣojú ṣofin tó ń ṣojú ẹkùn ìdìbò Akinyẹle/Lagelu nipinlẹ Ọyọ. A gbọ́ pé wọ́n ti gbé Hon Ọlatoye lọ sílé ìwòsàn UCH fún ìtọ́jú, sugbọn ẹpa ko boro mọ.

  5. Àkójọpọ̀ èsì ìdìbò ń lọ lọ́wọ́ ní ìpínlẹ̀ Ekiti

    Ajọ INEC ni ipinlẹ Ekiti ti bẹrẹ si ni se akojọpọ esi idibo kaakiri ipinlẹ naa ninu idibo sipo asofin ni ipinlẹ naa.

  6. Ibùdọ ìkóbojọ ní ìpínlẹ̀ Eko ti tò ní ìmúrasílẹ̀ fun ìbò kíkà

    Ibùdọ ìkóbojọ ní Eko àti Ondo ni wọn ti setàn fun ètò ìbò kíkà

  7. Seyi Makinde fẹyin awọn alatako rẹ janlẹ ni wọọdu rẹ

  8. Wahala bẹ silẹ ni agọ idibo Adebayọ Adelabu n‘Ibadan

    Awọn janduku ti da ibo ijọba ibilẹ ward 9, unit 10 of Ibadan South East LGA ru.

    Ibudo idibo yii ni oludije si ipo gomine ipinlẹ Ọyọ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Adebayo Adelabu ti dibo lowuro oni.

    Iwa ipanle awọn janduku naa si ti mu ki o nira fun ajọ eleto idibo lati kede abajade esi idibo ni ibudo naa.

    Kọmisana ajọ eleto idibo, Mutiu Agboke ṣe alaye fun BBC Yoruba wi pe, kele ofin ti gbe meji ninu awọn janduku naa.

    Bo tilẹ jẹ wi pe "wọn lu melo kan lara awọn oṣiṣẹ ajọ eleto idibo, wọn gbe igba ibo, bẹẹ sini wọn tun ti awọn oṣiṣẹ ajọ naa mọle ki awọn agbofinro to yoju sibẹ lati doola emi awọn oṣiṣẹ ajọ INEC.

    Titi di asiko yii, a ko tii mọ esi ibo ni ibudo ti Adebayọ Adelabu ti tẹka.

  9. Ènìyàn méjì sọ ẹmí nù ní ìpínlẹ̀ Rivers

    Ènìyàn méjì ti pàdánù ẹmí wọn níbi wàhálà tó bẹ́ silẹ̀ ní àgbègbè Akinima ní ìjọba ìbílẹ̀ iwọ-òòrun Ahoada ní ìpínlẹ̀ Rivers.

    Ọkàn nínú àwọn tí ọ̀rọ̀ náà soju rẹ̀ sọ fun BBC pé àwọn jànduku kan ló gún obinrin kan nígo láyà ti ó sì kú lójú ẹsẹ̀ nígbà ti ẹnikejì tí wọn yìn ní ìbọ̀n lẹ́sẹ̀ dé ilé ìwòsàn, sùgbọ́n ó padà jẹ́ Ọlọ́run nípè.

    Iwọ-òòrun Ahoada jẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ tí ìdìbò ààrẹ àti ilé ìgbìmọ Asofin àgbà kò fẹnukò lọ́sẹ̀ méjì sẹ́yìn, nítolri ìwà jàgídíjàgan tí ó sẹlẹ̀ níbẹ̀, tó sì yẹ kí ìdìbò míràn ó wáyé lónìí.

    Bákan náà ní àwọn jandukú pa alága fìdíhẹ ìjọba ìbílẹ̀ nígbà kan rí Emilia Nte níjọba ìbílẹ̀ Andoni.

    Ọkan nínú àwọn ti ọ̀rọ̀ náà soju rẹ̀ Hannah Innocent sàlàyé pé àná ní wọn páa ní ààlà Asarama àti Egendem bí ewọn se lọ si abúlé rẹ̀ ní Unyandaní ìjọba ìbílẹ̀ Andoni náà.

  10. Awọn janduku ji apoti ibo gbe ni Umuolo Omagwa, nipinlẹ Rivers

  11. Ojo nla rọ ni Ilọrin lasiko ibo

  12. Adelabu fọwọ gbaya pe oun yoo bori ibo gomina Ọyọ

  13. Ẹni tó ní ìpèníjà étí pàrọwà sí àwọn olósèlú láti se ìlú

    Lórí ọ̀rọ́ owó tí wọn ń pin ni ìpérú, ọkunrin kan to ni ìpèníjà etí sàlàyé pé kìí ṣe kí a máa pín owó ni ó ṣe pàtàkì fún ìdàgbàsókè ìlú. Ó tako àṣà owó pínpín.

  14. Àwọn ará ìpínlẹ̀ Ogun ń jà lórí owó tí wọ́n fi ra ìbò wọn, Àwọn ará ìpínlẹ̀ Ogun ń jà lórí owó tí wọ́n fi ra ìbò wọn

    Ìjà be sílè laarin awọn odò Iperu Remo lórí owó tí Dapo yà fún wọn.

    Àwọn ará ìpínlẹ̀ Ogun ń jà lórí owó tí wọ́n fi ra ìbò, Bí wọn ṣe ń lági mọ àrá wọn lóri ní wọn bu ara wọn lásọ, ẹ̀yìn ò rẹyìn ọngọ́rún márun náírà ló kan elò míran.

  15. Oludije fun ipo Gomina APC ni Kwara dibo

  16. Atiku Abubakar ti dibo nilu Yola

  17. Àwọn gbájúgbajá olórin àti òṣèré to dìbò lọ́nìí

  18. Ní ìpínlẹ̀ Kwara APC jáwé olúbori ní ibùdó ìdìbò Lai Mohammed

    Èsì ìdìbò ibudo idibo Lai Mohammed to jẹ minista fún ọrọ iroyin ati ifitonileti ni Naijiria ti jade.

    APC jawe olubori pẹlu: 186

    PDP: 048

    Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, nipinlẹ Eko, Babatunde Ọlalere Gbadamosi, padanu ni ibudo idibo rẹ, wọọdu kinni, ibudo idibo kẹrinla, Ikorodu.

    Oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Babajide Sanwo-Olu lo bori nibẹ.

    Ní ìpínlẹ̀ Oyo, Ajimobi pàdánù wọ́ọ́dù rẹ̀ ní àgọ́ ìdìbò ogún, ní àdúgbò Olúyòlé nílú Ibàdàn

  19. Ó tó gẹ́ jẹ́ ti Kwara, ó tọ́pẹ́ ni tiwa l'Eko

    Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Ahmed Tinubu ti sọrọ pé, ko le si ó tó gẹ́ ni Eko bii ti Kwara

    O to gẹ ti yi eto idibo pada ni ọsẹ to kọja ni Kwara.

  20. Bukọla Saraki ati aburo rẹ, Gbemi tako ara wọn lori idibo