Gomina Ibikunle Amosun tipinlẹ Ogun ti dibo
Ibikunle Amosun n ṣatilẹyin fun Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM dipo APC ti oun ba jade
You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín
Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo
Ibikunle Amosun n ṣatilẹyin fun Akinlade ti ẹgbẹ oṣelu APM dipo APC ti oun ba jade
Oludije ZLP tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ, Sharafadeen Alli ti dibo bayii.
Ṣegun Adewale ti Aeroland gbá akọroyin BBC léti nitoripe o n ká fidio bi o ṣe n pín ẹgbẹrun kan naira fun awọn oludibo ni Pleasure bus stop nipinlẹ Eko.
Ademola Adeleke to dije dupo gomina nipinlẹ Osun ni oun yoo bori nile ẹjọ laipẹ
Awọn eniyan ibudo idibo wọọdu yii ko pọ to
Ajọ EFCC, sọ pe niṣe ni awọn janduku kọlu awọn oṣiṣẹ ajọ naa to n gbiyanju lati fi panpẹ mu ẹni to fẹ ẹ pin owo naa, ti wọn si tun ba ọkọ ajọ naa jẹ.
Agbegbe North Bank nilu Makurdi ni ọwọ ti tẹ ẹ.
Gomina Ambode to jẹ ọkan lara awọn gomina ti ko ni pada wa fun saa keji ni o ti dibo bayii ni ilu epe ni ipinlẹ Eko
Babajide Sanwo Olu lo n dije dupo gomina ipinle Eko lẹgbe oṣelu APC
Minisita fún ètò ìròyìn àti Ásà, Alhaji Lai Muhammed dibò ní Polling unit 006, Oro ward 2, Irepodun LG, Kwara.
Ọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ni Naijiria, EFCC, tẹ arakunrin kan Abdulkareem Abdulsalem, to n pin owo fun awọn oludibo nilu Ilọrin.
Ninu iroyin kan ti ajọ naa fi sita loju opo Twitter rẹ, EFCC sọ pe ni ẹka ibudo idibo keje ni ileewe awọn olukọni, Kwara State College of Education, ni ọwọ ti tẹ ọkunrin naa
Gomina nigba kan fun ipinlẹ Ọyọ, to tun jẹ oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party, ADP, ko to o di pe o wọgile ipinnu rẹ naa tibo nilu Ogbomọṣọ pẹlu aya rẹ, Kẹmi Alao-Akala.
Iṣẹ igbọnsẹ, a kii fi ran ọmọ. Funra kọmisana ọlọpaa nipinlẹ Edo, Danmallam Mohammed, lo bọ si oju ọna lati gbe nkan di ojupopo.
Botilẹjẹ wi pe ko yẹ ko si igboke-gbodo kankan nitori idibo, niṣe ni awọn olugbe ilu Benin n ṣe ohun to kan kaluku wọn bi ẹni pe ko si idibo.
Awọn ọlọkọ eero ati aladani n lọ, ti wọn si n bọ lojupopo. Eyi lo mu ki inu bi kọmisana ọlọpaa naa, to si bọ si oju ọna lati gbofinro funra rẹ.
Oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ oṣelu Action Alliance, AA, Uche Nwosu ti pariwo sita pe irọ ni irpyin kan to sọ pe oun ti yọwọ ninu idije fun ipo gomina ipinlẹ Imo.
Nwosu to jẹ ọkọ ọmọ gomina ipinlẹ naa lọwọlọwọ, Rochas Okorocha, sọ pe awọn alatako oun lo wa nidi iroyin naa.