You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Tí kò bá sí màgò-mágó, èmi ni màá di gómìnà Eko

    Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko ninu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Jimi Agbaje ti sọ pe màgò-mágó nìkan lo le mu ki oun ma di gomina ipinlẹ Eko.

    O fi igbagbọ yii han lasiko to ba akọroyin BBC sọrọ nibi to ti dibo.

  2. Ibo didi ti pari, ibo kika ti bẹrẹ lawọn agọ idibo

  3. Idarudapọ waye ni agọ idibo nilu Ire Ekiti

  4. Aje ko bu igba jẹ fawọn oṣiṣẹ INEC yii ni Ekiti

  5. Ọkùnrin yíì n laago fi pe àwọn èèyàn láti jáde dìbò

    Awọn araalu ko fi bẹ ẹ jade dibo ni adugbo Dọpẹmu l'Eko.

    Eyi lo mu ki Ọgbẹni Ọladele Iyẹwu fi ara a rẹ ji lati laago kiri adugbo naa pe ki awọn eniyan 'dakun' jade dibo.

  6. Fídíò bí wọ́n ṣe kátà-kárà ìbò ní Bayelsa

    Akọroyin BBC sẹ alabapade awọn to n ṣe kata-kara ibo ni ibudo idibo keji, wọọdu krin, ni abule Igbogbene nilu Yenogoa, ipinlẹ Bayelsa.

    Ibo ile aṣofin ipinlẹ nikan lo n waye nipinlẹ naa.

  7. Awọn eeyan ko jade lati dibo nile aarẹ l‘Abuja

    Awọn oludibo ko jade lati dibo ni ibudo idibo tile aarẹ.

    Koda, ko si eeyan kankan lori ila to fẹ dibo titi aago mejila aabọ ọsan.

    Ṣe lawọn osisẹ eleto idibo kan n takurọsọ laarin ara wọn, ti wọn si n fi ẹrọ ibaraẹnisrọ wọn sere.

    Awọn miran ninu wọn tiẹ ti n toogbe tori airi nkan se.

    12:40pm Nigba ti akroyin BBC de ibudo idibo to wa ni ileewe alakọbẹrẹ St. Paul, Omu-Aran ni nkan bi aago kan ọsan ku ogun iṣẹju, oorun ni awọm oṣiṣẹ INEC n sun.

  8. Gomina Kayọde Fayẹmi ti Ekiti ti dibo

  9. Oludije fun ipo gomina nipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu dibo ni Ikoyi

  10. Akinlade ni àwọn ologun n ṣiṣẹ fawọn oloṣelu kan

    Oludije sipo gomina nipinle Ogun labẹ oselu APM, Adekunle Akinlade, ti fi esun kan awọn omoogun Naijiria wipe, wọn sise fun oludije kan nipinlẹ̀ Ogun.

    Akinlade fikun wi pe, awọn ti fi ọrọ naa to awọn adari awọn ologun leti, ti wọn si fi da won loju wi pe, awon yoo se iwadii lori ẹsun naa.

  11. Gómìnà Amosun ní ó dájú pé olùdíje òun ní yóò wọlé

      • Author, Abdulwasiu Hassan
      • Role, BBC Hausa, Abuja

    Botilẹjẹ wi pe ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ni Amosun, oludije ẹgbẹ oṣelu, APM, Adekunle Akinlade l'oun ṣatilẹyin fun ninu idibo gomina.

    .

  12. Gboyega Oyetọla dibo nipinlẹ Ọsun

  13. Olufẹmi Lanlẹyin, oludije ADC tẹlẹ nipinlẹ Ọyọ dibo

  14. Sẹ́nétọ̀ Ladọja àti aya rẹ nàá ti dìbò

  15. Bukọla Saraki dibo ni Ilọrin

  16. Tinubu dìbò nípínlẹ̀ Eko

      • Author, Olubunmi Okunnu
      • Role, BBC Pidgin, Lagos

    Aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, Bọla Tinubu naa ti dibo ni nkan bi aago mejila ku iṣẹju maarun.

    Idibo ko tete bẹrẹ ni ibudo idibo rẹ, nitori pe awọn oṣiṣẹ INEC ko tete de.

    Nigba ti Tinubu de si ibi idibo, niṣe lo fi awọn to wa lori ìlà silẹ, to si lọ siwaju lati dibo lai to sori ìlà.

  17. Babatunde Gbadamọsi, oludije fun ẹgbẹ oselu ADP ti dibo

  18. Buruji Kasahamu ti dibo

  19. Wọ́n fi ǹkan fọ́ orí aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú yìí ní Kwara

    Iṣẹlẹ yii waye ni ibudo idibo keje, ni adugbo Oju-Ẹkun Zarumi nijọba ibilẹ Ilorin West.

    Bakan naa ni iroyin sọ pe awọn ọmọ ogun gbe arakunrin Yunus Ataragba, t'oun ti ẹjẹ lori, kuro nibudo idibo naa, nitori aṣẹ ti oloye ẹgbẹ oṣelu APC pa fun wọn.