INEC ni àwọn yoo parí ìkéde ipinlẹ Kano laipẹ kí ọkan àwọn èèyàn lè balẹ̀
Ajọ eleto idibo ipinlẹ Kano ti kéde lati ri aridaju pe wọn pari ikede esi idibo Kano.
Wọn ni kete ti awọn ba ti fẹnu kò lórí ohun ti wọn n jiroro lé lori ni wọn yoo bẹrẹ ikede pade.
Nkan bii aago meji ni iroyin ni awọn agbofinro gbe Yusuf Gawuna to jẹ igbakeji gomina Kano ati Sule Garo to jẹ kọmiṣọna.
Wọn ṣi wa ni gbaga awọn ọlọpaa titi di asiko ti a n kọ iroyin yii.
Awọn ile iwe ati ile ifowopamọ gbogbo ni wọn ti ti pa ti awọn eniyan wa ni inú fú lori ohun to le ṣẹlẹ ni Kano bayii.
Awọn agbofinro kun gbogbo oju opopona fọfọ ni.