You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Bi Ganduje n tẹsiwaju ni ipinlẹ Kano tabi bẹẹkọ? Esi idibo naa ni wọn ti n ka yii

    Esi idibo Kano lo ti n lọ lọwọ yii

  2. Wo èsì idibo ipinlẹ Enugu bo ṣe n lọ bayii

    Wọ ti n ka esi idibo Enugu

  3. Esi idibo ipinlẹ Anambra ni wọn n ka yii

    Awka ni wọn n ka lọwọ yii

  4. E wo esi idibo gomina ipinlẹ Ebonyi

    Abakaliki ni wọn ti n kaa bayii

  5. Ẹyin ti ipinlẹ Oyo, èsì idibo yin rèé!

    Ajọ INEC ti n ka esi idibo ipinle Oyo bayii.

  6. Wọn ti n ka esi idibo ẹni ti yoo jawe olubori ni ipinlẹ Eko

    Se Sanwo Olu lo maa gori aleefa abi Agbaje ni abi Gbadamosi ni abi ẹlomii ninu awọn oludije to dantọ ti wọn jọ du ipinlẹ Eko?

    Esi naa n lọ lọwọ bayii

  7. Esi idibo gomina ipinlẹ Abia ni wọn ti n ka bayii lati Umuahia

    Esi idibo gomina ipinlẹ Abia ni wọn ti n ka bayii lati Umuahia

  8. Mudashiru Obasa, olórí ilé ìgbimọ aṣofin ni ipinlẹ Eko ti jawe olubori, Ojọgbọn Olufẹmi Saibu to dari eto idibo naa lo ṣe ikede ọhun

    Mudashiru Obasa ni yoo tun ṣoju Agege nipinlẹ Eko lẹẹkan sii.

  9. Wo ẹni to maa wọle gẹgẹ bii gomina ni ipinlẹ Delta

    Wọn ti n ka esi idibo ipinlẹ gomina ni Delta.

  10. Eyi ni èsì ìdìbò gomina fún ìpínlẹ̀ Kwara ṣe n lọ

    Bi o to gẹ́ ni Kwara bí kò tò gẹ́? Esi idibo yii lo maa fihan.

    Ilorin ni ibudo ti wọn ti n kaa bayii.

  11. Wo bi o ṣe n lọ nibudo ti wọ́n ti n kéde èsì ìbò ipinlẹ Ogun ni Abẹokuta

    Wo ẹkunrẹrẹ ohun gbogbo to ṣẹlẹ ninu idibo gomina ipinlẹ ni:

    https://bbc.com.im/yoruba/live/afrika-47494187%3C/p%3E%3C/div%3E%3C/div%3E%3C/article%3E%3C/li%3E%3Cli class="css-xxlek1">

    Ta ni Olatoye Temitope 'Sugar' tó di olóògbé?

    Ọmọ agboole Efungade-Onigbodogi, Alafara Oje ni ijọba ibilẹ Ibadan North East ni ipinlẹ Ọyọ, ni Ọlatoye Temitọpẹ ti ọpọ mọ si Sugar.

    Onigbodogi ati Alape ni ọlọkọ to wa Temitọpẹ wa sile aye lọdun 1973, ṣe wọn ni ọmọ Ibadan ti ko ba ni agboole ati oko kii ṣe ojulowo ọmọ Ibadan.

    Ileewe alakọbẹẹrẹ St Michael Primary School, Yemetu ati I.M.G Primary School, Beyerunka, Alafara Oje ni Temitọpẹ lọ.

    Lẹyin naa lo gba ileewe girama Ikolaba Grammar School, St Luke's College, Molete ati Alugbo Comprehensive High School, Egbeda lọ, ti gbogbo rẹ ni ilu Ibadan.

    Sugar gba iwe ẹri olukọni onipo kini ni ileewe ẹkọṣẹ olukọni NCE Federal College of Education, to wa ni Osiẹlẹ nilu Abeokuta, ipinlẹ Ogun, ki o to lọ si ileewe giga fasiti Ibadan lati gba iwe ẹri imọ ijinlẹ akọkọ, B.Sc, ati iwe ẹri imọ ijinlẹ keji.

    Kansilọ ni ijọba ibilẹ Ọdẹda lo fi bẹrẹ irinajo oṣelu rẹ. Wọn yan an gẹgẹ bii amugbalẹgbẹ fun ijọba ipinlẹ Ogun lasiko iṣejọba Ọtunba Gbenga Daniel.

    Lẹyin to ti jẹ olori ẹka ọdọ fun ẹgbẹ oṣelu PDP ni ẹkun idibo apapọ aringbungbun ipinlẹ Ogun, lo wa lọ du ipo alaga ijọba ibilẹ Lagelu ni ipinlẹ Ọyọ ni ọdun 2007.

    Ni ọdun 2011, ni wọn fi ibo yan an si ile aṣofin ipinlẹ Ọyọ labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Accord, ki o to wọle gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to n soju ẹkun idibo Lagelu/Akinyele, labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC. Ni ọdun 2018 lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu ADP lati du ipo Sẹnetọ ki o to fidirẹmi.

  12. Èyí ni èsì ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Delta

  13. Desmond Elliot mókè, ó padà sílé asòfin fún ìgbà kejì

    Gbajúgbajà òṣèré lédè Gẹ̀ẹ́sì, Desmond Eliot, ni àwọn èèyàn ẹkùn ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ Surulere ní Ìpínlẹ̀ Eko, tún ti dìbo yàn gẹ́gẹ́ bíi àṣòfin ìpínlẹ̀ Eko.

    Ìgbà kejì rèé ti Elliot yóò dìbò wọlé sílé asòfin ìpínlẹ̀ Eko.

    Elliot to n soju ẹgbẹ oselu APC ni ibo 15,357, nigbati Benjamin Olasunkanmi, latinu ẹgbẹ (PDP) se ipo keji pẹlu ibo 3,628.

  14. Ìgbákéjì olórí ilé aṣòfin Ondo tẹ́lẹ̀ pàdánù sáà kẹta

    Fatai Olotu to fi igba kan jẹ igbakeji olori ile aṣofin ipinlẹ Ondo, fidirẹmi ninu eto idibo ile aṣofin to waye ni ipinlẹ Ondo.

    Oludije ẹgbẹ PDP, Rasheed Ẹlẹgbẹlẹyẹ lo gba ipo naa mọ Olotu to jẹ oludije ẹgbẹ APC.

    Oun ni yoo si ṣoju ẹkun idibo Akoko North-West nile aṣofin ipinlẹ Ondo.

  15. Ìjọba Ondo kéde kónílé ó gbélé nílùú Ọ̀bà-Akoko

    Ijọba ipinlẹ Ondo ti kede konile o gbele ni ilu Ọ̀bà-Akoko, ni ijọba ibilẹ Akoko South-West.

    Eyi waye lẹyin rogbodiyan to waye nibẹ lasiko idibo gomina ati ile aṣofin.

    Iroyin fidirẹmulẹ pe awọn janduku oloṣelu ba awọn apoti idibo jẹ, to fi mọ ile, ọkọ̀ ati awọn dukia miran.

    Ati pe ẹnikan padanu ẹmi rẹ sinu rogbodiyan naa.

    Pẹlu ikede naa, ko ni i si lilọ-bibọ fun eniyan ati ọkọ ninu ilu naa.

    Ọna to gba inu ilu na kọja so ọpọlọpọ ilu to wa ni agbegbe Akoko nipinlẹ Ondo.

  16. Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní í ka èsì ìbò ìpínlẹ̀ Kwara

  17. UCH ṣàlàyé bí Sugar ṣe jáde láyé

    Alukoro fun ile iwosan ẹkọsẹ isegun fasiti Ibadan, UCH, Ọgbẹni Toye Akinriọla, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori bi asoju sofin kan nipinlẹ Ọyọ́, Temitọpẹ Ọlatoye se jade laye nile iwosan naa.

    Akinrinọla sọ pe awọn eeyan kan lo yin asofin to n soju ẹkun idibo Akinyẹle/Lagelu nipinlẹ Ọyọ ni ibọn loju wọ agbari ni ọjọ ibo.

    O fikun pe, digbadigba ni wọn gbe asofin naa, ti ọpọ eeyan mọ si Sugar wa sile iwosan naa nirọlẹ Ọjọ Satide, ti awọn akọsẹmọsẹ osisẹ UCH si setọju rẹ, amọ aisan lo se wo, a ko ri ti ọlọjọ se.

  18. Seyi Makinde fọkàn olólùfẹ́ rẹ̀ balẹ̀ pé dídùn lọsàn yóò so

    Oludije fun ibo gomina fẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ọyọ, Onimọ ẹrọ Seyi Makinde ti fi ọkan awọn ololufẹ rẹ balẹ pe, ko sewu loko nipa abajade esi ibo ti ajọ Inec yoo kede.

    Fọnran aworan kan ti Makinde fi sita lori awọn oju opo ayelujara, lo tun dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ nipinlẹ Ọyọ fun atilẹyin wọn.

    Bakan naa lo rọ awọn ololufẹ rẹ lati fọkan balẹ, paapa nipa iroyin kan to ni awọn eeyan kan fẹ́ se makaruru awọn esi ibo naa, o ni oun nigbagbọ pe ko ni si ewu fun oun.

  19. Dogara daro iku Temitọpẹ Ọlatoye Sugar

    Olori ile asoju sofin, Hon Yakubu Dogara ti daro iku ọkan lara awọn ọmọ ile asofin apapọ ilẹ wa, Hon Temitọpẹ Ọlatoye, ti gbogbo eeyan mọ si Sugar.

    Sugar ni awọn agbebọn kan yinbọn fun loju lasiko ibo gomina ati tile asofin ipinlẹ to waye lana.

    Ninu ikede kan to fi soju opo Twitter rẹ, Dogara ni iroyin iku asofin naa ba oun ninu jẹ pupọ, to si ba oun lojiji.

    O wa se apejuwe bi wọn se dẹmi Sugar legbodo naa gẹgẹ bii eyi to jẹ iwa ika, ailaanu ati iwa ailaju, eyi to yẹ ki gbogbo ọmọ orilẹede yii koro oju si.