You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Governorship Election Updates: Ẹni tí Tinubu bá padà lẹ́yìn rẹ̀, Ọlọ́run ti padà lẹ́yìn onítọ̀ún - Alátìlẹyìn Sanwo-Olu

Àáyá ti bẹ́ sílẹ̀, ó bẹ́ áré ni ọ́rọ́ ìdìbò tònìí. BBC Yorùbá yóò máa mú gbogbo ìròyìn bó ṣe ń lọ káàkiri orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ètò ìdìbò gómìnà àti àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ kọọkan wá fún un yín

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun and Yemisi Oyedepo

  1. Rasaq Atunwa ti PDP kí gomina tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ yàn kú oríire ní Kwara, AbdulRazaq Atunwa tó díje dupò lábẹ́ ẹgbẹ́ òsèlú PDP fìdírẹmi nínú ìdìbò sípò gomina nípínlẹ̀ Kwara

    Rasaq Atunwa dupẹ lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ oselu PDP to duro ti oun lasiko idibo ọdun 2019.

    O tun ki AbdulRahman ti ẹgbẹ oselu APC to jawe olubori ku oriire, o ni oun gbà pé ipinlẹ Kwara yoo ma tẹsiwaju.

  2. "Iya Taye Currency wa, kò kú, a ṣẹ̀ṣẹ̀ jọ jẹ àmàlà tán ni"

    Agbẹnusọ fun ilumọọka olorin fuji kan, Alhaji Taye Akande Currency ti kede pe irọ to jinna sootọ ni iroyin kan to gba igboro pe, wọn ti yinbọn pa iya olorin fuji naa.

    Tọpẹ Eluyẹfa, to sọrọ lorukọ Taye Currency ni, Amala ati Abula ni Alhaja Mojisola Aduke (Iya Taye Currency) ati Alhaji Taye Currency (Apesin) pẹlu oun dijọ jẹ lọsan oni.

    Eluyẹfa ni bi o tilẹ jẹ pe ọpọ idunkoko mọni ni Taye Currency n koju latọdọ awọn eeyan kan lati bii ọsẹ meji sẹyin, amọ koko lara mama Currency le, ti ko si sewu.

  3. Èrò ń wọ́ nile Dapo Abiọdun ni Ipẹru pẹlu ìrètí

    Èrò ń wọ́ nile Dapo Abiọdun ni Ipẹru pẹlu ìrètí

  4. Saraki ki Abdulrazaq to yege ibo gomina Kwara ku oriiire

    Aarẹ ile asofin agba, Dokita Bukọla Saraki ti ki awọn eeyan ipinlẹ Kwara, paapa awọn alatilẹyin ẹgbẹ oselu PDP, fun atilẹyin wọn lasiko eto idibo to kọja.

    Ọrọ idupẹ yii, ni Saraki kọ soju opo ikansiraẹni Twitter rẹ nirọlẹ ọjọ Aiku. wa ki oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Kwara fẹgbẹ oselu APC ku oriire pe o jawe olubori ninu ibo naa.

    O wa ki pe yoo se aseye ti alakan n sepo.

  5. 2019 Nigeria Election: Àgbùnbánirọ̀ pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbà ọkọ̀ ojú omi l'Ondo

    Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe agunbanirọ kan, Ibrahim Okanlawon to ṣiṣẹ pẹlu ajọ eleto idibo INEC ninu ibo gomina ati ile igbimọ aṣofin ipinlẹ lagbegbe Ewerebubou, wọọdu Arogbo ni ipinlẹ Ondo padanu ẹmi rẹ.

  6. Ta ni yoo bori laarin Abba ati Ganduje ninu ibo Kano?

  7. Ọ́ tọ́ gẹ́ la ó tún yá mọ́ lẹ̀! Olùdíje fún ìpò gómìnà fẹ́gbẹ́ APC wọ lé ní ìpínlẹ̀ Kwara, Abdulrahman Abdulrazaq Olùdíje fún ipò gómìnà fẹ́gbẹ́ APC fẹ̀yìn olùdíje PDP AbdulRazak Atunwa gbo lẹ̀

    Omi tuntun ti rú, ẹja tuntun ti wọ̀ ọ́ ní ìpínlẹ̀ Kwara lẹ́yìn tí Olùdíje fún ìpò gómìnà fẹ́gbẹ́ APC Abdulrahman Abdulrazaq wọ le ìbò gómìnà.

  8. Àwọn agbofinro gba ìjọba nibudo ikede ibo ni Rivers

      • Author, Karina Igonikan
      • Role, BBC Pidgin

    Gbogbo awọn oṣiṣẹ INEC ti kuro ọfiisi wọn àti ni ibudo idibo ti wọn ti n kede tẹlẹ ni opopona PH / Aba.

    Bẹrẹ lati orita Waterlines titi dé GRA ni awọn agbofinro ti di pa.

    Koda wọn ko jẹ ki awọn akọroyin kọja lagbegbe naa ni kete ti awọn agbofinro atawọn ọmọ ogun pade ara wọn.

  9. El Rufai jawe olubori ni ijọba ibilẹ Guusu Kudan nipinlẹ Kaduna

    El Rufa'i bori Isa Asylum ti ẹgbẹ PDP nijọba ibilẹ yii.

    APC: 28,624

    PDP: 22,022

  10. INEC gbẹ́sèlé ètò ìdìbò ipinlẹ Rivers

    Ajọ eleto idibo ni lataari gbogbo rogbodiyan to n ṣẹlẹ lasiko ati lẹyin idibo gomina to waye ni ipinlẹ Rivers, ni wọn ṣe gbẹsele eto idibo naa nitori ko kogoja tó.

    INEC gbẹ́sèlé ètò ìdìbò ipinlẹ Rivers

  11. Governorship Election Results: APC jáwé olúborí ẹkùn ìdìbò 25 nínú 26 nípínlẹ̀ Ekiti

    Ajọ INEC ti kede wi pe ẹgbẹ oselu APC lo jawe olubori ninu gbogbo idibo si Ile Igbimọ Asofin Ipinlẹ Ekiti.

    Agbẹnusọ fun Ajọ INEC ni ipinlẹ Ekiti, Alhaji Taiwo Gbadegesin sọ pe esi idibo marundinlọgbọn ninu mẹrindinlọgbọn lo ti jade.

  12. Abdulrazag Abdulrahman mókè nínú ìbò gómìnà Kwara

    Oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oselu APC, Abdulrahman Abdulrazaq ti moke ninu gbogbo ibo ti ajọ eleto idibo kede lọsan ọjọ Aiku.

    Abdulrahman lo fi ẹyin alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu PDP, Abdulrazaq Atunwa janlẹ ninu ibo gomina naa.

    Apapọ ibo ti ikọọkan oludije naa ni niwọnyi:

    APC:276,259

    PDP: 115,310

  13. Esi idibo n tẹsiwaju nipinlẹ Kwara

    Awọn ajọ INEC ti pada dé ni ipinlẹ Kwara

  14. Bawo ni aworan yii ti ye yin si?

  15. Iroyin tuntun ti fihan pe ọmọ Naijiria kan wa lara awọn to ku ninu baalu Ethiopia to ja, Boeing 737 to ja lulẹ loju ọna rẹ lati Addis Ababa si Nairobi.

    Baalu naa ko eero mọkandinlaadọjọ, to fi mọ awọn oṣiṣẹ baalu mẹjọ. Awọn alaṣẹ ileeṣẹ baalu naa ni iṣeju mẹta pere ti baalu naa gbera ni o ja lulẹ.

  16. Ẹ wo nkan ti àwọn eniyan Ibadan ti n sọ loju òpó BBC bayii

    Awọn eniyan Ibadan n sọ nipa ohun ti wọn mọ ti o n ṣẹlẹ ni Ibadan bayii

  17. Ọgá INEC n'ípínlẹ̀ Ondo kò gba àwọn akọ̀ròyin láti rí èsì ìdìbò

    Ọgá ajọ eleto idibo INEC ni Ipinlẹ Ondo, Ambassador Rufus Akeju ti kọ jalẹ lati jẹ ki awọn akọroyin ri esi idibo ile igbimọ aṣofin to waye ni ipinlẹ naa ni ọjọ Abamẹta.

    Olu ileesẹ INEC to wa ni Akure ni ikede idibo ti waye. Nigba ti Akọroyin BBC beere fun esi idibo naa pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ, Akeju ni ko ti iṣe tan, iyẹn ni bii aago kan ọsan.

    Akeju ko si sọ idi ti ko fi fẹ ki awọn oniroyin ri esi naa bo tilẹ jẹ pe ikede ti pari. Alukoro ajọ naa ni Ondo,Sodiq Bimbo sọ pe Akeju ko ti i bu ọwọ lu esi naa ni wọn ko fi le gbe sita

  18. Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé, nǹkan kò fara rọ ní Ìlú Ibadan báyìí.

    A gbọ́ pé àwọn ọkọ̀ ń padà lọ́nà.

    Ṣé ẹ wà ní Ibadan báyìí, ẹ jẹ́ ká mọ́ bó ṣe ń lọọ?

  19. Ethiopian Airlines crash: Èèyàn 157 dèrò ọ̀run nínú bàálú tó já

    Iroyin fi han wipe awọn eniyan to wa lati orilẹede mẹtalelọgbọn lo owa ninu baalu orilẹede Ethiopia kan, Boeing 737 to ja lulẹ loju ọna rẹ lati Addis Ababa si Nairobi.

  20. Esi idibo ipinlẹ Akwa Ibom ti n lọ lọwọ

    Uyo ni ibudo ti wọn fikalẹ si ti wọn ti n kéde esi idibo ipinlẹ Akwa Ibom