You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Aarẹ àná, Muhammadu Buhari ti gbé ẹrù rẹ̀, Daura yá

    Bayii ni aarẹ ana, Muhammadu Buhari se gbe ẹrù rẹ to si pada si ilé rẹ̀ ni Daura ni ipinlẹ Katsina ni ariwa Naijiria.

  2. Ireti ti pada fun Naijiria – Aarẹ Bola Tinubu

  3. Babajide Sanwo-Olu ti búra fún sáà ọdún mẹ́rin míràn gẹ́gẹ́ bí gómìnà Eko

    Ninu ọrọ to sọ lẹyin ibura rẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu kede ayipada eto idagbasoke to jẹ opomulero iṣejọba rẹ ti o pe ni ‘THEME’ pada si ‘THEMEPLUS’.

  4. Orí, dákun fún èmí náà ní Olú ọmọ!

    Ìyá tó bí Gomina Dapo Abiodun àti àwon ọmọ pẹ̀lú àbúro rẹ̀ ni Papa Isere MKO Abiola ni Kuto ni Abeokuta ni ipinle Ogun lonii

  5. Ọ̀kan lára àwọn akọni agbábọ́ọ̀lú fún Nàìjíríà tẹ́lẹ̀rí: Daniel Amokachi náà wà sí Eagle Square Abuja láti wa kópa níbi ètò ìbúra wọlé Aàrẹ Bola Tinubu

  6. Adájọ́ Mosunmola Dipeolu ti búra fún Gómìnà Dapo Abiodun ní ìpínlẹ̀ Ogun

    Wọn búra fún Omoba Dapo Abiodun MFR gẹ́gẹ́ bí gomina ipinle ogún lekeji.

    Adajo Àgbà ní ìpínlè ogún, Mosunmola Dipeolu tí búra fún gomina ipinle ogún, Omoba Dapo Abiodun gẹ́gẹ́ bí gomina ipinle ogún fún isejoba sáà kejì. Ayẹyẹ eto ìbúra yìí ló wáyé lónìí ní pápá ìṣeré MKO tí ó wà ní kuto Abẹ́òkúta níbi tí opolopo awon eniyan wá.

  7. Dapo Abiodun ṣètò ìbúra fún sáà kejì

    Dapo Abiodun ṣètò ìbúra fún sáà kejì ni papa iṣire MKO Abiọla to wa ni Kutọ nilu Abẹokuta.

  8. Imam Muhammed Kabir ló gbàdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ètò ni ilànà Islam ní Abuja Imam gbàdúrà ọgbọ́n fún Bola Tinubu pẹ̀lú ìfọ̀kànbalẹ̀ fún gbogbo eeyan Naijiria.

  9. Bíṣọ́ọ̀bù Stephen Adegbite tó gbàdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ètò ìbúrà fún Bola Ahmed Tinubu ni Abuja lónìí;

    Bíṣọ́ọ̀bù Stephen Adegbite tó gbàdúrà ìbẹ̀rẹ̀ ètò ìbúrà fún Bola Ahmed Tinubu ni Abuja lónìí; Bíṣọ́ọ̀bù gbàdúrà ara líle àti àlááfíà fún gbogbo eniyan Naijiria ati aarẹ tuntun

  10. Gbogbo eto lo ti n to bayii ni gbagede Eagle Square.

  11. Báyìí ni ètò ìfinijoyè sípò Gómìnà Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ti ń lọ

    Gbogbo eto lo ti to Papa Isere Lekan Salami ni Ibadan nipinle Oyo nibi ti Gomina Seyi Makinde yoo ti ṣe ibura wolẹ gẹgẹ bii gomina Oyo lẹẹkan sii

  12. Àwọn ọba, ẹbí Gómìnà Dapo Abiodun dé fún ètò ìbúra l'Ogun

    Iya to bi Gomina Dapọ Abiọdun ati awọn ọmọ rẹ, fi mọ awọn aburo rẹ lo n wọle si gbagede papa iṣere MKO Abiọla to wa ni Kutọ niluu Abẹokuta, nibi ti eto ibura yoo ti waye.

    Awọn ọba ilu Ẹgba pẹlu ti de si gbagede yii. Aṣoju Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Agura tiluu Gbagura, Olowu tiluu Owu, ati Alake ilẹ Ẹgba.

  13. Ìgbáradì ìbúrawọlé fún sáà kejì gómìnà fun Dapọ Abiọdun l'Ogun ti fẹ bẹ̀rẹ̀

    Bi eto ayẹyẹ ibura fawọn gomina tuntun ati awọn gomina to ti wa lori ipo tẹlẹ ti wọn tun pada dibo yan ṣe n lọ kaakiri orileede Naijiria lonii, ọjọ Aje tii ṣe Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu karun-un, ọdun 2023, bẹẹ naa ni ti ipinlẹ Ogun ko gbẹyin.

    Gbogbo eto la gbọ pe o ti bẹrẹ lati bura fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun gẹgẹ bii gomina ti yoo tun tukọ ipinlẹ Ogun fun ọdun mẹrin miiran.

    Papa iṣere MKO Abiọla to wa ladugbo Kutọ ni eto ọhun ti n waye, eyi to bẹrẹ lati aago mẹjọ aabọ aarọ.

  14. Wo gbogbo ohun tó ti wà níkàlẹ̀ dé ìbúra Bola Tinubu lónìí ní Eagle Square Abuja

    Muhammadu Buhari yóò gbé ìjọba sílẹ̀ fún Bola Tinubu lónìí

  15. Gbogbo ètò ti tò ní Eagle Square ní Abuja níbi tí Tinubu yóò ti búra dí aàrẹ Nàìjíríà tuntun

    Fún ojú lóúnjẹ́ ayọ̀ wo ohun tó n ṣẹlẹ̀ báyìí ní Eagle Square níbi tí Buhari yóò ti gbé ìjọba sílẹ̀ fún Tinubu láìp

  16. Àsìkò rèé fún gbogbo wa láti gbà pé kádàrá wa farapa - Obi

    Oludije sipo aarẹ lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ oṣelu Labour Party, Peter Obi, ti sọ pe asiko lati ro arojinlẹ, ni asiko yii jẹ fun gbogbo ọmọ Naijiria.

    O si tun jẹ asiko lati fi ara balẹ̀ ṣe agbeyẹwo awọn nnkan to fa ijakulẹ ati awọn anfaani 'to bọ́ mọ wa lọwọ'.

    Ninu àtẹ̀jáde kan to fi síta lórí Twitter rẹ̀ lọjọ Àìkú, ni Ọgbẹni Obi, ti sọ pe iru asiko yii lo yẹ ki gbogbo eniyan fọwọsowọpọ lati gbà pe lootọ ni 'ìpalára ba ayanmọ wa, àti lati mọ ìdí ti ifarapa fi wa'.

    Àtẹ̀jáde naa waye bi igbaradi ṣe n lọ lati bura fun ààrẹ tuntun, Bola Ahmed Tinubu ati igbakeji rẹ, Kashim Shettima, niluu Abuja lọjọ Aje.

    Obi rọ awọn ọdọ Naijiria, lati jẹ ki alaafia jọba, bo ti wu ki ẹnikẹni tọ́ wọn tabi bi wọn ninu, paapaa nítorí eto ìbúrawọlé to n waye lonii.

    'Digbi ni mo wa, lati ṣiṣẹ́ pọ pẹlu awọn ọmọ Naijiria to ni ero rere bíi tèmi, lati fi òpin si ègún to n gba anfaani mọ wa lọwọ, to si tun n fi ireti wa ṣòfò.'

    O ni àṣírí bi awọn kan ṣe n gbero lati ba orúkọ oun jẹ láìpẹ́, ti tu si oun lọwọ, àmọ́ o daju pe ko si ibanilorukọ jẹ to le din ipinnu oun fun idagbasoke Naijiria kù.

    Peter Obi ati ẹgbẹ́ oṣelu rẹ, Labour Party, wa lara awọn ẹgbẹ́ alatako to pe ẹjọ́ tako esi idibo to gbe Tinubu wọlé.

  17. Ó yẹ kí àwọn ìyàwó ààrẹ tó kúrò nípò náà má a gba owó ìfẹ̀hìntì - Aisha Buhari

    Aya ààrẹ Naijiria to n fi ipo silẹ, Aisha Buhari, ti sọ pe nnkan ti àárò rẹ yoo sọ oun ju ni ile ààrẹ, ni bi oun ṣe ma n rin kiri ni oru.

    Hajia Aisha sọ pe oun ma n rin lati ọ́fíìsì ààrẹ titi de ẹnu ọ̀nà ile.

    Ninu àkànṣe ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC ní Aso Rock Villa, ni Aisha Buhari tun ti sọ pe o yẹ ki wọn o máa san owo ifẹhinti fun awọn iyawo ààrẹ to ti kuro ni ipo, bii ti awọn ọkọ wọn "Nitori àwọn ojúṣe ti ọkọ wọn ko le wọn lọwọ."

    Aya ààrẹ naa sọ pe oun yoo tẹle ọkọ oun lọ si ilu Daura, lati jọ máa gbé nibẹ, tako bi awọn eeyan kan ṣe n sọ pe ìlú Dubai ni oun fẹ́ pada si.

    Hajia Aisha sọ pe itọju awọn ọmọ ati ọmọ-ọmọ ni oun yoo gbájúmọ́ ju, nitori pe ipo ko jẹ ki òun le se bẹẹ fun ọdun mẹjọ.

    Bakan naa lo ni o ṣeéṣe ki oun ṣi ile ẹ̀kọ́ oun pada, nibi tó ti ma n kọ awọn eeyan ni oriṣiriṣi isẹ ọwọ́, saaju ki ọkọ rẹ to di aarẹ.

  18. Àwọn àwòrán tó jojú nígbèsè láti ibi ìsìn ìdúpẹ́ àyípadà ìṣèjọba ní Nàìjíríà

  19. Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ajìjàgbara ‘Yoruba Nation’ làwọn jàǹdùkú tó kọlú iléeṣẹ́ rédíò Amuludun n’Ibadan -Ọlọ́pàá

  20. Ààrẹ ẹgbẹ́ àgbẹ̀ ọlọ́sìn kàgbákò ikú òjìji lọ́wọ́ àwọn ọọ̀ni

    Ọkùnrin àgbẹ̀ kan to to jẹ ọlọ́sìn ọọ̀ni ti jáde láyé lẹyin ti awọn ọọ̀ni to to ogoji faa ya pẹrẹpẹpẹ ni orile-ede Cambodia.

    Ọjọ Ẹti ni iṣẹlẹ naa waye nitosi ilu Siem Reap.

    Luam Nam, ẹni ọdun mejilelaadọrin, ku lasiko to n gbiyanju lati fa ọkan lara awọn ọọ̀ni to ma n yé ẹyin fun un, kuro ninu kùkú tó wà.

    Iléèṣẹ́ ọlọpaa sọ pe nibi to ti n fa a, ni ọọ̀ni naa ti fi ẹnu fa ọ̀pá ti agbẹ naa fi n rin.

    Ọga agba ọlọpaa, Mey Savry, sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe "bi ọkùnrin naa ṣe ṣubú lulẹ̀, ni awọn ọọ̀ni yòókù yabo o, ti wọn si n bu jẹ titi to fi ku.

    O ni ọgbẹ́ eyin pọ̀ ni ara oku Ọgbẹni Nam, nigba ti wọn o fi ri, bakan naa si ni apá rẹ kan jẹ́ àwátì.

    Oloogbe Nam ni aarẹ ẹgbẹ́ awọn àgbẹ̀ to n sin ọọ̀ni.

    Wọn n sin àwọn ẹranko naa lati ma a ri ẹyin, awọ ati ẹran ara wọn.

    Iru iṣẹlẹ ti waye ri ni agbegbe naa lọdun 2019, nigba ti awọn ọọ̀ni pa ọmọbinrin kan to jẹ ọmọ ọdun meji, ti wọn si tun jẹ òkú rẹ nitosi gbajugbaja Angkor Wat Temble