You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Messi dara pọ̀ mọ́ Inter Miami

    Gbajumọ ẹlẹsẹ ayo, Lionel Messi ti sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Inter Miami loun yoo ti maa gba bọọlu jẹun ni saa to n bọ.

    Messi n ko ẹru rẹ kuro ni ikọ PSG lorilede France nibi ti o ti n gba bọọ jẹun lati nnkan bii ọdun meji sẹyin.

    Ṣaaju ikede rẹ, ọpọ eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ ati ti ẹgbẹ agbabọọlu Barcelona lo ti n wo pe Barca ni Messi yoo lọ.

    Bakan naa lawọn miran n wo o pe boya liigi ilẹ Saudi Arabia ni yoo lọ pẹlu bi awọn eekan agbabọọlu bii Cristiano Ronaldo, Kareem Benzema ati beebeelọ ṣe n dari kọ ilẹ Saudi lẹnu akoko yii.

    Lionel Messi ni kii ṣe rori owo loun se gbe igbesẹ naa ari pe to ba jẹ bẹẹ ni, orilẹede Saudi loun iba gba lọ

    “Mo ri pinnu lati dara pọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Inter Miami” ni ọrọ ti Messi ba awọn akọroyin kan sọ

  2. ‘A ò tíì gbúròó Tinubu, ohun táa fẹ́ lọ́dọ́ rẹ̀ rèé bí àwa aráàlú ṣe ń jẹ pálí ìyà toríi subsidy’

  3. Pope Francis tó jẹ́ ẹni ọdún 86 yóò nílò iṣẹ́ abẹ inú

    Poopu Agba, Francis ni wọn ti ṣetan lati se iṣẹ abẹ fun ni ọsan Ọjọru ni ileewosan Rome Gemelli Hospital.

    Pope naa ni wọn lero pe yoo wa ni ileewosan fun ọjọ diẹ lati le sinmi, ko si gba iwosan to peye lẹyin iṣẹ abẹ inu ti wọn pe orukọ rẹ ni, hernia operation.

    Aisan isalẹ inu naa ni wọn ni ohun fa inira lọpọlọpọ fun Pope naa, ti ko si see fi mọ ara mọ.

    Agbẹnusọ fun Vatican, Matteo Bruni ni ọpọlọpọ ipenija ilera ni Pope naa n la kọja lati bii ọdun diẹ.

    Bruni fikun un pe nigba miran lori aga tabi ọpa ni Poopu naa fi n rin nitori erunkun ẹsẹ to n dun un.

    Bakan naa lo fikun un pe Pope Francis yoo lo ọjọ diẹ ni ileewosan naa lati wo bi ara rẹ yoo se ri lẹyin iṣẹ abẹ naa.

    Ni Ọjọ Iṣẹgun ni Poopu Francis lọ si ileewosan fun ayẹwo ni Rome Hospital naa, lẹyin to ti lo ọpọlọpọ osu ni ileewosan fun aisan ‘’Bronchitis’’.

    Bakan naa lo lo ọjọ mẹta ni ileewosan ni Osu Kẹta fun aisan ọna ọfun, ni osu naa lo se ayajọ ọ̀un kẹwaa to gori oye Pope.

    Osu to kọja ni Pope oun kuro nibi ẹsin Ọjọ Ẹti nitori ara rẹ to gbona kọja bi o se yẹ.

    Bio tilẹ jẹpe Pope Benedict XVI to kuro nibẹ ki oun to de ibẹ kọ iwe fi ipo silẹ ni, amọ Pope ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ ni ọrọ ti oun.

    Pope Gbagbo wi pe kii se orunkun ni eniyan fi n dari ẹsin bi ko se imọ, ọgbọn ati oye, eleyii to wa lati inu ọpọlọ.

  4. Ariwo gbòde pé Sweden tí sọ ìbálòpọ̀ dì eré ìdárayá; Èsì ìjọba rèé lórí European Championship in Sex

  5. Àjọ INEC kéde orúkọ̀ àwọn olùdíje fún ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kogi, Bayelsa àti Imo

    Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti gbe orukọ awọn oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Kogi, Bayelsa ati Imo jade.

    Alamojuto agba fun eto ilanilọyẹ fun awọn iludibo, Festus Okoye sọ pe nibi ipade igbimọ iṣakoso ajọ INEC to waye lọjọ Iṣẹgun ni wọn ti buwọlu orukọ awọn oludije naa.

    “Eyi wa ni ibamu pẹlu a ala ikejilelọgbọiwe ofin eto idibo ti ọdun 2022 eyi to laa kalẹ pe ki wọn kede orukọ awọn oludibo, o pẹ ju aadọjọ ọjọ si ọjọ idibo, eleyi to jẹ ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ ọdun 2023.”

    O ni oruko awọn oludije naa ti wa loju opo ayelujara ajọ naa bayii.

    Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun lo n kopa ni eto idibo gomina ni Kogi, ẹgbẹ oṣelu metadinlogun lo n kopa ni ti Bayelsa ti mẹrindinlogun yoo si kopa ni ti ipinlẹ Imo.

    Bakan naa lo tun fi han pe ẹgbẹ oṣelu meji lo n fa obinrin kalẹ gẹgẹ bi oludije ni Bayelsa ati Kogi, nigba ti ko si oludije obinrin kankan fun ti Imo.

    Ajọ wa ran awọn oloṣelu lawọn ipinlẹ yii leti pe ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa ni ilẹkun ipolongo ibo fun awọn oludije yoo to ṣi silẹ.

  6. Olórí méjì ń jà fún àkóso ilé aṣòfin Nasarawa

    Olori meji lo ti dide ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Nasarawa.

    Awọn aṣofin fun saa ile igbimọ aṣofin keje ni ipinlẹ Nasarawa yan awọn aṣiwaju lẹtin ti wọn bẹrẹ iṣẹ lọjọ Iṣẹgun.

    Ibrahim Balarabe ati Daniel Ogazi lati ẹkun iwọ oorun ipinlẹ naa lawọn meji to n pe ara wọn ni olori ile naa bayii.

    Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa lo yẹ ki wọn ṣe ifilọlẹ ile igbimọ aṣofin keje ni ipinlẹ naa, ṣugbọn akọwe agba ile aṣofin ni ipinlẹ Nasarawa kede isunsiwaju eto ifilọlẹ naa nitori ohun to pe ni ikayasoke lori abo.

    Awọn agbofinro di ile aṣofin naa pa eyi ro mu ki Ogazi at’awọn to gbe lẹyin rẹ o duro pa si inu gbagede ile igbimọ aṣofin naa titi di agogo mẹfa irọlẹ.

  7. Arúmọjẹ lásán ni ìfilọ́lẹ̀ Nigeria Air tí ìjọba Buhari ṣe kó tó kúrò nípò

    ile igbimọ aṣofinṣoju lorilẹede Naijiria ti tọka si eto ifilọlẹ ileeṣẹ baluu Nigeria Air lasiko ti ijọba ana labẹ Muhammadu Buhari n ko igba wọle gẹgẹ bi arumọjẹ lasan

    alaga igbimọ ti ile aṣofinṣoju gbe kalẹ lori irinna ofurufu, Nnolim Nnaji sọ laifọtape 0e bi ijọba ana ṣe ṣe kurukẹrẹ sare ṣe ifilọlẹ ileeṣẹ baluu Nigeria Air naa ni jibiti lasan ni eyi nitori pe awọn eekan to lọwọ ninu idasilẹ ileeṣẹ naa lati ibẹrẹ pẹpẹ, bii ijọba apapọ ati ileeṣẹ irinna ofurufu, Ethiopian Airlines ni wọn n sẹ.pe awọn ko mọ si ọrọ naa.

    Ileeṣẹ irinna ofurufu nijọba apapọ ti kọkọ sọ wi pe, wọn kan ṣi aṣọ kuro loju rẹ ni, wọn ko tii ṣe ifilọlẹ rẹ.

    Iyalẹnu lo jẹ fun igbimọ naa nigba ti ajọ ro n ri si igbokegbodo ọkọ ofurufu NAMA, pẹlu bọ sita ṣalaye eyi.

  8. Kókó, Ìgbìyànjú ń lọ lọ́wọ́ láti dóòlà ẹ̀mí àwon ènìyàn níbi adágún odò Ukraine tó ya lulè

    Awọn oṣiṣẹ pajawiri n gbiyanju lati doola ẹmi awọn eniyan nipa kiko wọn kuro ni agbegbe Kherson ni orilẹede Ukraine.

    Eyi waye lẹyin ti adagun odo ti wọn n pe ni Dam fay naa ya ni agbegbe Kherson, ti orilẹede Russia ti gba lọwọ Ukraine lasiko ogun to n lọ lọwọ nibẹ.

    Awọn ikọ ọmọgun Ukraine ti fi ẹsun kan Russia wi pe awọn lo sekọlu si adagun odo naa ni ilu Nova Kakhovka.

    Amọ ni idahun si ẹsun yii, orilẹede Russia ni awọn ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.

    Aarẹ orilẹede Ukraine, Volodymr ni awọn ilu kereje bii ọgọrin ni omiyale naa ti ṣọṣẹ si.

    Nibayii, Ileeṣ̣ẹ iroyin ilẹ Russia ni ijọba orilẹede Russia ti kede ilu ko fararọ ni agbegbe naa.

    Aarẹ ajọ iṣọkan ilẹ Yuroopu, Charles Michel da ẹbi iṣẹlẹ naa ru Russia, to si ni ikọlu ohun ini awọn araalu jasi iwa ọdaran ni agbegbe.

    Bakan ni adari ikọ Iṣọkan Agbaye, UN to n risi lilo ohun ija oloro ọlọgọọrọ ni aisi omi tutu le fa ifasẹyin fun igbiyanju wọn lati doola ẹmi awọn eniyan, amọ o ni igbiyanju n lọ lọwọ lati da omi naa duro.

    Amọ oṣiṣẹ orilẹede Russia to wa nibẹ ni ẹrọ amunawa to wa nibẹ ni ado oloro ti wọn ju bajẹ, amọ kii se adagun odo naa, nitori naa kii se awọn.

    Bakan naa ni Russia da ẹbi iṣẹlẹ naa ru Ukraine, pe Ukraine lo jẹbi iṣẹlẹ naa.

  9. Nínú ibojì òkú yìí làwa ti ń jẹun, sùn, ṣiṣẹ́, ẹ ṣàánú wa torí ...

  10. Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC ṣẹ́wé lé ìyanṣẹ́lódí tí wọ́n ń gbèrò

    Ni alẹ ọjọ Aje ni wọn ṣe ipinnu yii lẹyin ijiroro pẹl’awọn aṣoju ijọba apapọ nibi ipade kan ni ile Aarẹ, Aso Rock Villa lori owo iranwọ ‘subsidy’ori epo bentiroolu ti ijọba yọ.

    Olori ile aṣojuṣofin apapọ NaijiriaHọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila ṣalaye abajade ipade naa fun awọn akọroyin pe adehun ati ifẹnuko ti waye pẹlu NLC ati TUC lori awọn ọrọ to jẹyọ lori yiyọ owo iranwọ naa.

    Bakan naa lo ni peijọba apapọ, ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ati NLC ti gba lati gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe agbeyẹwo awọn aba to wa nilẹ lori owo oṣu to kere julọ fun oṣiṣẹ, ki wọn su tun ṣe agbekalẹ akoko ti yoo gba won lati bẹrẹ si nii san an.

    Bakan naa lo ni igun mejeeji yoo jọ mojuto pinpin owo ti ijọba apapọ fẹ ya lọwọ banki agbaye lati fi san owo iranwọ fun araalu ati atunṣe awọn ibudo ipọnpo gbogbo to di apati lorilẹede Naijiria at’awọnipinnu mii.

    Ọjọru lẹgbẹ oṣiṣẹ NLC n gbero lati gunle iyanṣẹlodi tẹlẹ

  11. Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tomiwa Omolewa, alága PMS tuntun nípìnlẹ̀ Oyo tó rọ́pò Auxilliary

  12. NLC kò kópa,TUC ìjọba ṣèpàdé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ

    Ìjọba àpapọ̀ ti ní àwọn yóò ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC gbé síwájú àwọn tó fi mọ́ owó oṣù tó kéré jùlọ.

    Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé láàárín ìjọba àpapọ̀ àti TUC èyí tó wáyé fún bíi wákàtí mẹ́ta, Agbẹnusọ ìjọba àpapọ̀, Dele Alake ní àwọn máa wò ó tó bá jẹ́ wí pé àwọn ìbéèrè jẹ́ ohun tí ìjọba le ṣe àmúṣẹ rẹ̀.

    Ó ní lára nǹkan tí ìjọba ń rò láti ṣe tẹ́lẹ̀ láti mú ìdẹ̀kùn báwọn lórí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí wọ́n yọ ni láti fi ojú fo owó orí fún wọn fún ìgbà kan ná.

    Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé náà.

    Alake ní ohun tó dájú ni pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò gbé ìgbìmọ̀ kan dìde èyí tí àwọn ìpínlẹ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò ní aṣojú níbẹ̀, tí wọn yóò sì jíròrò lórí owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ.

    Ó ṣàlàyé pé kò sí aáwọ̀ láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nigeria Labour Congress, NLC lórí ìbéèrè wọn pé kí ìjọba fowo kún owó òṣìṣẹ́.

    Bákan náà ló fi kun pé bí NLC kò ṣe sí níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe lọ́jọ́ Àìkú kò túmọ̀ sí pé wọ́n fojú kéré wọn.

    Agbẹnusọ Tinubu ní ìjọba àpapọ̀ tún ti ń gbìyànjú láti kàn sí wọn fún ìpàdé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

    Ẹ̀wẹ̀, TUC nínú ìbéèrè tí wọ́n gbé síwájú ìjọba àpapọ̀ ní kí ìjọba dá owó epo padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀ kí ìjíròrò fi wáyé láàárín wọn.

    Ààrẹ TUC, Festus Osifo ní àwọn ní ìrètí pé ìjọba àpapọ̀ yóò gbọ́ tàwọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe ìlérí pàápàá lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ tí òṣìṣẹ́ yóò máa gbà.

  13. Ọba ò lè pé méjì láàfin ni mo fi yọ Auxiliary nípò - Makinde

    Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣàlàyé ìdí tó fi ní kí alága tẹ́lẹ̀ rí fún gááràjì ní ìpínlẹ̀ náà, Alhaji Mukaila Lamidi tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Auxiliary lọ rọ́kún nílé.

    Makinde ní ọba kò lè pé méjì láàfin ni òun fi fọwọ́ òsì júwe ilé fún Auxiliary.

    Níbi ètò ìsìn ìdúpẹ́ fún ìbúrawọlé sáà kejì rẹ̀ ní ilé ìjọsìn Cathedral of St. Peter, Aremo, Ibadan lọ́jọ́ Àìkú ni Seyi Makinde ti sọ̀rọ̀ náà.

    Makinde sọ àrídájú rẹ̀ wí pé ìjọba yóò ṣe àfọ̀mọ́ àwọn gáréèjì àti pé gbogbo àwọn tó ń da ìlú láàmú ni àwọn máa fi òfin gbé.

    Ó ṣàlàyé pé kí ètò ìdìbò tó wáyé ni àwọn ti pe àwọn alókòóso gáréèjì sí ìpàdé láti ṣe ìkìlọ̀ fún wọn pé àwọn kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa fa wàhálà.

    "A ṣàlàyé fún wọn pé tí a bá wọlé fún sáà kejì, a ma ri dájú pé àláfíà jọba, tí a máa ri pé ìrẹ́pọ̀ wà láàárín wọn."

    "Ẹnìkan ló fárígá pé òun kò lè bá àwọn yòókù ṣe, èmi náà sì sọ wí pé ìjọba méjì kò lè máa ṣàkóso ìlú kan."

  14. Ìdí rèé tàwọn òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná láwọn náà yóò da iṣẹ́ sílẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà

    Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ mọnamọna ni Naijiria naa ti kede pe awọn yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ninu iyanṣẹlodi tori afikun ow epo bẹntiroo ni Naijiria.

    Wọn lawọn gbe igbesẹ naa nitori pe ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn n ṣe iyanṣẹlodi naa nitori bi ijọba ṣe yọ ẹkuwo epo taa mọ si subsidy eleyi to mu ki nkan wọn lọja ni Naijiria.

    Olori ẹka alamojuto ẹgbẹ naa Godfrey Aba to n ṣe akoso ilu Abuja ati Kogi fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC pe iyanṣẹlodi yi yoo bẹrẹ lọjọ Keje oṣu Kẹfaa titi di igba ti ijọba yoo fi yi ipinnu pada lori afikun owo epo bẹntiroo.

    Ninu atẹjade ti adele akọwe agba ẹgbẹ naa wọnDominic Agwebike fi sita o ni o kesi awọn ọmọ ẹgbẹ lati maa fọkan tẹle ikede ẹgbẹ lati gunle iyanṣẹlodi yi lọsẹ yi.

    Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria NLC ati TUC ti ṣaaju kede pe awọn yoo ṣe iyanṣẹlodi l'Ọjọru tako bi ijọba ṣe yọ subsidy lori epo bẹntiroo.

    Aarẹ tuntun Bola Ahmed Tinubu lo kede pe ko ni si ẹkunwo lori epo bẹntiroo mọ lasiko ayẹyẹ iburawọle sipo rẹ.

    Awọn ẹgbẹ akọroyin naa pẹlu awọn to ni awọn yoo darapọ mọ iyanṣẹlodi yi.

    Bi aarẹ tuntun ba ṣe yanju ọrọ yi si yoo jẹ atọna bi ijọba rẹ yoo ṣe ba awọn oṣiṣẹ ati araalu ṣepọ lori awọn igbesẹ to nipa ni igbesi aye wọn.

  15. Wo ìpéjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Èṣù àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ìjọ́sìn, ìgbéyàwó, àtàwọn ayẹyẹ wọn

  16. Dúkìá Ààrẹ Buhari kò lè síi nígbà tó wà lórí oyè - Garba Shehu

  17. Àwọn jàǹdùkú ṣe ìkọlù sí Yahaya Bello, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò farapa

    Àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí jàǹdùkú òṣèlú ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ṣe ìkọlù sí gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello.

    Ìkọlù yìí ṣokùnfà bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ń mójútó Yahaya ṣe farapa.

    Ní nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrin oṣù Kẹfà ni ìkọlù náà wáyé ní agbègbè Naval Base, kìlómítà díẹ̀ sí ìlú Lokoja tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀hún.

    Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn Kogi, Kingsley Fanwo nígbà tó ń fi ìròyìn náà léde ní bí àwọn jàǹdùkú náà ṣe rí ọkọ̀ gómìnà tó ń bọ̀ ni wọ́n sí á ìbọn bolẹ̀ fún un.

    Fanwo fẹ́sùn kàn pé àwọn alátakò ẹgbẹ́ àwọn ló wà nídìí ìkọlù yìí àmọ́ BBC Yoruba kò lè fìdí èyí múlẹ̀.

    O fi kun pé gómìnà Bello kò fi ara pa nínú ìkọlù ọ̀hún nítorí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò rẹ̀ tètè gbé e kúrò níbẹ̀ ṣùgbọ́n tí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò náà farapa.

    Kọmíṣọ́nà náà wá ké sí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣàwárí àwọn tó wà nídìí ìkọlù ọ̀hún kí wọ́n sì fojú wọn winá òfin.

    Bákan náà ló tún ní gómìnà Bello tí ṣèkìlọ̀ pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú kankan kò gbọdọ̀ dìde láti sọ wí pé òun fẹ́ gbẹ̀san ìkọlù ọ̀hún.

    Ìkọlù yìí ló ń wáyé bí ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tí yóò wáyé nínú oṣù Kọkànlá ṣe ń súnmọ́ etílé.

  18. Wo àwọn gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá tí ilé ẹjọ́ sọ sẹ́wọ̀n gbére tàbí dájọ́ ikú fún

  19. N kò ní èròńgbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Wike

    Gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ni oun ko ni erongba lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin to kopa ninu ipade alatilẹkunmọri pẹlu Aarẹ Bola Tinubu.

    Wike, pẹlu Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ati James Ibori lo se abẹwo si Aarẹ lati kede atilẹyin wọn fun un lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn se ibura fun Aarẹ orilẹede Naijiria.

    Wike, lasiko to n ba awọn akọroyin ile ijọba sọrọ lẹyin ipade naa ni ko si nnkan to jọ pe oun fẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu kan si kan.

    “Ko si nnkan to jọ bẹẹ. Asiko ti a wa yii ni pe ki a gbe ẹgbẹ oṣelu si ẹgbẹ kan, ki a si jiroro bi ilọsiwaju yoo se deba orilẹede Naijiria .

    “Ọmọ orilẹede Niajiria ni wa, a si wa lati kede atilẹyin fun Aarẹ wa.

    “Ko si nnkan to jọ pe mo fẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.”

  20. Ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìgbẹ́jọ́ láàárín Sanwoolu àti Rhodes-Vivour rèé

    Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Eko ti ní ọjọ́ kan náà ni òhun yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Babajide Sanwoolu àti igbákejì rẹ̀, Obafemi Hamzat pè.

    Bákan náà ni wọ́n ní ọjọ́ tí àwọn máa gbé ìdájọ́ kalẹ̀ yìí náà ni àwọn máa dájọ́ lórí ẹjọ́ tí àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa INEC pè.

    Níbi ìjókòó ìgbẹ́jọ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹta oṣù Kẹfà ọdún 2023, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta ọ̀hún tí Adájọ́ Arum Ashom ṣáájú rẹ̀ ní ọjọ́ kan ni àwọn máa gbé gbogbo ìdájọ́ kalẹ̀.

    Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwoolu àti igbákejì rẹ̀, Obafemi Hamzat ló pẹjọ́ pé kí ìgbìmọ̀ náà da ẹjọ́ tí olùdíje sípò gómìnà Eko lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ti kọ́kọ́ gbé síwájú wọn nù.

    Agbejọ́rò gómìnà Eko àti igbákejì rẹ̀, Wole Olanipekun níbi ìgbẹ́jọ́ níẹjọ́ tí Rhodes-Vivour pè láti tako ìjáwé olúborí Sanwoolu níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù Kẹta kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé kò ṣàlàyé ìdí tó fi lẹ́tọ̀ọ́ láti pe àwọn lẹ́jọ́.

    Olanipekun fi kun pé Rhodes-Vivour nìkan ló dá pe ẹjọ́ tí ẹgbẹ́ òṣèlú tó díje lábẹ́ rẹ̀ kò sí nínú àwọn tó ń pè ẹjọ́ láti tako bí Sanwoolu ṣe gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

    Ó ní ìgbésẹ̀ yìí tako òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 tó sì rọ ilé ẹjọ́ láti da ẹjọ́ náà nù pátápátá.

    Nígbà tó ń fèsì, Rhodes-Vivour gba tẹnu agbejọ́rò rẹ̀, Olumide Ayeni ní òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 náà ti fi ààyè gba olùdíje láti pé ẹjọ́ fúnra rẹ̀ láìsí àtìlẹyìn ẹgbẹ́ to bá gbe dìde.

    Rhodes-Vivour fi kun pé ẹjọ́ tí òun pè kò ní ẹja n bákàn nínú àti pé kí ilé ẹjọ́ má gba ẹjọ́ tí gómìnà àti igbákejì rẹ̀ pè láàyè.

    Lẹ́yìn gbogbo atótónu àwọn agbejọ́rò méjéèjì ni ìgbìmọ̀ ọ̀hún rọ̀ wọ́n láti ri pé wọ́n gbé àwọn ẹ̀rí wọn síwájú ìgbìmọ̀ kó tó di ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kẹfà.

    Adájọ́ Ashom tún sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Karùn-ún tí ìgbẹ́jọ́ yóò tún tẹ̀síwájú.