You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin pa èèyàn 288,bíi 850 farapa

    Ko din ni eeyan 288 to ti ku bayoi, ti 850 si farapa ninu ijamba ọkọ ojú'rin kan to waye nipinlẹ Odisha, ni orílẹ̀-èdè India.

    Ọkọ̀ ojú'rin kan to ko èrò ni igbagbọ wa pe o yẹ̀ kuro ni oju ọna rẹ, ko to di wi pe ọkọ ojú'rin miran to n kọja lọ ni òdì-kejì kọlu u, lalẹ́ ọjọ Ẹti.

    Ijamba yii ni ti ọkọ ojú'rin to tii buru ju ni India, lati bi ọgọrun ọdun.

    Àwọn aláṣẹ sọ pe o ṣeéṣe ki awọn to kú pọ̀ si.

    Akọwe ijọba ipinlẹ Odisha, Pradeep Jena sọ pe igba ọkọ ambulansi ni wọn ti ko lọ sibi iṣẹlẹ naa.

    Bakan naa lo sọ pe dokita to le ni ọgọrun-un ni wọn tun ti ko lọ síbẹ̀.

    Àwọn aláṣẹ ileeṣẹ ọkọ reluwe ni India sọ pe ọkọ ojú'rin Coromandel Express ati Howrah Superfast Express lo kagbako ninu ijamba naa.

    India wa lara awọn orile-ede ti eto irinna ojú'rin rẹ tobi julọ ni agbaye, ijamba reluwe si jẹ nnkan to wọ́pọ̀ níbẹ̀.

    Ọdun 1981 ni ijamba oko ojú'rin to tíì buru julọ ni India waye.

    Iji lile kan lo ti ọkọ ojú'rin kan kuro ni oju ọna rẹ ni ipinlẹ Bihar. Ko din ni eeyan 800 to ku.

  2. 'Irọ́ ni pé mo ní owó àti dúkìá tó tó N9Trillion'

    Gomina tuntun ni ipinlẹ Zamfara, Dauda Lawal, ti sọ pe irọ ni ìròyìn kan to n lọ lori ayelujara pe owo ti oun ni tó tiriliọnu mẹsan-an Naira.

    Suleiman Bala Idris, to jẹ agbẹnusọ fun gomina sọ pe awọn eeyan kan lo gbe iroyin èké naa jade lati fi doju ìjọba bolẹ̀.

    O ni ara irọ ti àwọn to padanu ninu idibo to kọja n pa saaju idibo, ni iroyin naa.

    Lati ọjọ díẹ̀ ṣeyin ni iroyin ti gba ori ayelujara pe gomina tuntun ni ipinlẹ Zamfara ni owo ati dukia to jẹ 9 trillion ($18billion).

    Eyi waye lẹyin ti gomina naa kede dukia rẹ fun àjọ Code of Conduct Bureau, gẹgẹ bi ofin Naijiria ṣe la a kalẹ fun awọn to di ipo oṣelu mu.

    Kiakia si ni iroyin naa gba gbogbo ori ayelujara, paapaa laarin awọn eniyan ti ko mọ gomina tuntun naa.

    Sugbọn Gomina Lawal sọ ninu Ifọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹlu ileeṣẹ Radio France International (RFI) Hausa, pe awọn eniyan ipinlẹ Zamfara ko ni ni ọpọ ipenija ti wọn ni, to ba jẹ wi pe oun ni iru owo bẹẹ.

    "Amin. Ireti ati adura mi si Ọlọ́run ni pe ko fun mi ni iru owo bẹẹ, ki n le fi ran awọn eniyan mi lọwọ.

    " Gbogbo ìṣòro ti awọn eniyan mi n doju kọ, ni ma a ti fi owo naa yanju, ti mo ba ní iru rẹ. "

    Gomina Lawal sọ pe aaye ati ilana wa fun ẹnikẹni to ba fẹ ẹ ṣe iwadii oun.

    "Nnkan to ṣe koko ni pe Dauda Lawal ti ṣe nnkan ti ofin ni ko ṣe."

  3. Irọ́ ni pé mo kọ̀wé fi ipò sílẹ̀ —Olórí ilé aṣòfin Ondo

  4. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Oyo ń wá Lamidi Mukaila 'Auxillary' báyìí fún ẹ̀sùn ìpànìyàn

  5. Ilé aṣòfin Oyo tún rọ alága Káńsú mìíràn lóyè

  6. Olórí ẹgbẹ́ alátakò ní Senegal rí ẹ̀wọ̀n he fún 'kíkọ́ àwọn ọ̀dọ́ ní ìwà búburú'

    Ile ẹjọ́ kan ni Senegal, ti ju olori ẹgbẹ́ alatako Ousmane Sonko si ẹ̀wọ̀n ọdun meji, fun ẹsun pe "o n kọ awọn ọdọ ni iwa ibajẹ",àmọ́ wọn da a láre fun ẹsun ìfipa bánilòpọ̀.

    Idajọ naa tumọ si pe o hu iwa ti ko tọ pẹlu ẹni ti ọjọ ori rẹ ko to ọdun mọkanlelogun.

    Wọ́n gbe Sonko lọ sile ẹjọ́, lẹyin ti ẹni kan to ma n wọ́ ara 'massage therapist' fi ẹsun kàn án.

    Wọ́n fi ẹsun kan Sonko pe o fi ọwọ́ kan awọn ibi ti ko yẹ lara arabinrin naa, tó si tun dúnkookò mọ lọdun 2021. Ẹni ogún ọdún ni obinrin ọhun lasiko naa.

    Sonko ni oun ko jẹbi. O ni ẹsun naa jẹ ọna lati di erongba oun fun ipo aarẹ lọwọ.

    O ni oun lọ si ibudo naa, lati wọ́ ara nitori ìrora ẹ̀yìn ti oun ni.

    Ni kete ti idajọ waye ni awọn alatilẹyin rẹ bẹrẹ iwọde, ti awọn ati awọn ọlọpaa si kọju ija si ara wọn.

    Sonko ko yọju sibi igbẹjọ naa, bẹẹ ni ko kuro nile rẹ to wa niluu naa.

    Ẹnikan lara awọn agbẹjọro rẹ, Abdy Nar Ndiaye sọ pe, o jẹ nnkan to mu ifura dání pe adajọ ko tii pàṣẹ ki wọn mu oloṣelu, ẹni ọdun mejidinlaadọta naa

    "Eyi tumọ si pe erongba wọn kii ṣe lati mu Sonko, sugbọn o jẹ ọna lati má jẹ̀ ẹ́ ki o kopa ninu idibo to n bọ.

    Sugbọn ijọba sọ pe ẹsun ti wọn fi kan olórí ẹgbẹ alatako naa, ati awọn ẹsun ti wọn ti fi kàn án tẹlẹ rí, ko ni ohunkóhun ṣe pẹlu ọrọ oṣelu

    Adajọ ju ẹni to ni ibudo naa, Ndeye Khady Ndiaye, si ẹ̀wọ̀n ọdun meji fún ẹ̀sùn kan naa - kikọ awọn ọdọ ni iwakiwa

    Oloṣelu to gbajumọ laarin àwọn ọ̀dọ́ ti ko ni iṣẹ́ lọ́wọ́ ni Sonko.

    O ti fi igba kan jẹ́ aṣòfin, gẹgẹ bi olori ìlú Ziguinchor

    Bakan naa lo díje fun ipo aarẹ lọdun 2019, àmọ́ ipo kẹta lo ṣe

    Sonko fi ẹ̀sùn kan Ààrẹ Macky Sall pe o n gbero lati ṣe saa kẹta ni ipo, eyi ti ko ba ofin mu .

  7. Ọlọ́pàá dóòlà aláboyún mẹ́fà kúrò ní 'baby factory'

    Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ti doola alaboyun mẹfa, lẹyin ti wọn yabo ile kan ti wọn ti n ta ọmọ tuntun, 'baby factory'nipinlẹ Rivers.

    Ọlọpaa ni ọwọ́ awọn tun tẹ obinrin, ẹni ọdun mọkandinlogoji to ni 'ileeṣẹ' naa.

    Wọ́n ni o ti jẹwọ pe lootọ ni oun jẹbi ẹ̀sùn tita ọmọ tuntun, ati pe ọjọ ti pẹ ti oun ti n ṣe okowo naa.

    Kọmisanna ọlọpaa nipinlẹ Rivers, Polycarp Emeka, sọ lasiko to ṣe afihan awọn obinrin ti wọn doola naa pe, obìnrin afurasi naa, ati oṣiṣẹ rẹ kan ti wa ni ahamọ ọlọpaa.

    Bakan naa lo sọ pe iwadii ti n lọ nipa bi ọwọ yoo se tẹ awọn alajọṣiṣẹ pọ rẹ tó kù.

    Igba akọkọ kọ niyii, ti aṣiri awọn ileeṣẹ ti wọn ti n pese, ti wọn si n ta ọmọ tuntun, tu ni Naijiria.

    Ni awọn ileeṣẹ naa, wọn ma n ji awọn obinrin gbe - wọn o fun wọn loyun, wọn o sì ta awọn ọmọ ti wọn ba bí.

    Ni ipinlẹ Eko lọdun 2019, obinrin alaboyun mọkandinlogun ni àwọn ọlọpaa doola, nínú àwọn ilé kan ti wọn ti n ṣe irú iṣẹ́ buruku naa.

    Ṣaaju asiko naa, 160 ni awọn ọmọde ti wọn doola kuro ni ile itọju awọn ọmọ ti ko ni òbí meji ti ko fi orúkọ sílẹ lọdọ ijọba.

  8. Àlàyé lórí bí ilé ẹjọ́ ṣe yí ìdájọ́ padà sí ọdún méjì fún òṣìṣẹ́ Rahman Adedoyin tí wọ́n dájọ́ ikú fún l’Osun

  9. China ṣèlérí láti tẹ̀síwájú nínú àjọṣepọ̀ pẹ̀lú Naijiria lórí ọrọ̀ ajé

    Aarẹ orile-ede China, Xi Jinping, ti ṣe ileri pe oun ko ni fi opin si ajọṣepọ pẹlu Naijiria, lori eto ọrọ̀ ajé.

    Aarẹ Jinping ní Naijiria ṣe pataki pupọ fun ilẹ̀ Africa ati gbogbo agbaye.

    O sọ ọ̀rọ̀ yii lati ẹnu aṣojú rẹ, Peng Qinghua, to ṣe ipade pẹlu aarẹ Naijiria tuntun, Bola Ahmed Tinubu, ni ile ijọba niluu Abuja.

    Tinubu lo kede àbọ̀ ipade naa ninu atẹjade kan to fi si ori Twitter rẹ̀ ni Ọjọru.

    Qinghua sọ pe ajọṣepọ rere lo wa laarin orile-ede mejeeji, paapaa lori ọrọ̀ ajé ati okowo.

    Bakan naa lo sọ pe awọn ileeṣẹ to jẹ ti China n ṣe daada lori kíkọ́ oju ọna reluwe ati awọn òpópónà.

    Aarẹ Tinubu ní ireti oun ni pe ajọṣepọ to dara lori ọrọ̀ ajé, yoo tubọ gbilẹ si laarin orile-ede mejeeji.

  10. Ìpàdé láàrin ìjọba àti ẹgbẹ́ NLC lórí subsidy kò so èso rere

    Ipade laarin ẹgbẹ́ oṣiṣẹ ati ijọba apapọ to waye lọjọru nitori subsidy epo ti ijọba yọ, ko so eso rere.

    Ipade naa waye lẹyin ti NNPC kede iye ti awọn ile epo rẹ yoo ma ta lita epo kan bayii

    Ile ijọba niluu Abuja ni ipade naa ti waye laarin awọn aṣojú ẹgbẹ́ oṣiṣẹ (NLC), ọga ileeṣẹ NNPC, Mele Kyari, ati agbẹnusọ fun Ààrẹ Bola Tinubu, Dele Alak

    Àwọn aṣojú ijọba to tun wa níbẹ̀ ni gomina CBN, Godwin Emefiele ati gomina ipinlẹ Edo nigba kan, Adams Oshiomole

    Alaga ẹgbẹ́ NLC Joe Ajaero ati alaga TUC, Festus Osifo lo ṣojú awọn oṣiṣẹ nibi ipade naa.

    Akọwe ẹgbẹ́ NLC, Nasir Kabiru, sọ fun BBC pe, ẹgbẹ́ naa ko faramọ́ bi ijọba ṣe dá sisan subsidy dúró.

    NLC ní, ko boju mu bi ijọba tuntun ko ṣe jiroro pẹlu ẹnikẹni, to fi kede pe oun ko san subsidy mọ.

    Ọgbẹni Kabiru ṣalaye pe nnkan ti awọn n fẹ́ ni pe ki ìjọba mu iyatọ ba eto irinna, ko si tun mu igbe aye rọrùn fun awọn oṣiṣẹ, ko to o gbe igbesẹ lati yọ subsidy epo.

  11. Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ti Tinubu lẹ́yìn lórí ọ̀rọ̀ subsidy

    Àwọn ọmọ ile igbimọ aṣòfin Naijiria ti gbóríyìn fun akitiyan Ààrẹ Bola Tinubu, lati fi òpin si owo iranwọ ori epo.

    Nibi eto ìbúrawọlé rẹ lọ̀jọ Ajé ni Ààrẹ Tinubu ti kede pe opin ti de ba sisan subsidy. O ni ko si ipese owo kankan fun ninu owo isuna ọdun 2023, kọjá oṣù Kẹfà.

    Lati igba naa si ni ọ̀wọ́n gógó epo ti bẹrẹ, ti ọpọ ilé epo si n ta lita epo ni owo gege.

    Àwọn aṣòfin ni awọn fi ara mọ ikede aarẹ, lẹyin ti Aṣòfin Abdulraheem Olajide da àbá rẹ.

    Lẹyin ifẹnuko wọn, ni awọn aṣòfin naa rọ àwọn ọmọ Naijiria, lati ṣe sùúrù, ki wọn si gba adura fun ijọba lori igbesẹ naa.

  12. Ààrẹ Tinubu pàṣẹ fún DSS láti fi ọ́físì EFCC sílẹ̀

    Ààrẹ Naijiria, Bola Tinubu, ti pàṣẹ fun awọn oṣiṣẹ àjọ DSS, lati fi ọ́físì EFCC to wa ni Ikoyi, nipinlẹ Eko silẹ.

    Ọjọ Iṣẹgun ni awọn oṣiṣẹ DSS yabo ọ́físì EFCC, ti wọn ko si jẹ ki awọn oṣiṣẹ wọlé.

    Ohun ti awọn oṣiṣẹ DSS sọ ni pe awọn lo ni ile ti EFCC fi ṣe ọ́físì.

    Àwọn ti iṣẹlẹ naa ṣojú wọn sọ pé àwọn gburo ìbọn ni agbegbe naa.

    Ìṣẹ̀lẹ̀ naa fa ariwisi pupọ lori ayelujara, ti ọpọ eeyan si koro oju si iwa ti àwọn oṣiṣẹ àjọ mejeeji hù.

    Ninu atẹjade ti oluranlọwọ fun aarẹ lori eto iroyin, Tunde Rahman fi síta, aarẹ ni, kiakia ni ki awọn oṣiṣẹ DSS kuro ni ọ́físì naa.

    "Aarẹ sọ pe ti wahala kankan ba wa laarin àjọ mejeeji, ní ṣe ni ki wọn o yanju rẹ ni pẹlẹ pẹlẹ.

    Àjọ DSS ti fèsì si iṣẹlẹ naa.

    Ninu atẹjade ti agbẹnusọ àjọ naa, Peter Afunnaya, fi si oju opo Twitter ajọ naa ni alẹ́ ọjọ Iṣẹgun, o ni irọ patapata ni pe awọn di ọ̀nà mọ awọn oṣiṣẹ EFC

    Afunnaya sọ pe ile to jẹ ti DSS ninu ọgba naa, ni àwọn oṣiṣẹ rẹ duro s

    "Ko si ariyanjiyan kankan lori ile naa to wa ni ojule 15A, Awolowo Road, bi àwọn iroyin kan ṣe s

    " Inu ile naa ni àjọ DSS/SSS ti bẹ̀rẹ̀, eyi ti ko jẹ ìtàn to f'ara pamọ fun ẹnikẹni

    O ni ko si orogún kankan laarin àjọ mejeeji," àmọ́ wọn jẹ alajọṣiṣẹ pọ fun rere Naijiria ."."

  13. Bí èèyàn fi màlúù ránṣẹ́ tí wọ́n bá sè é yóò kan, mọ́tò ni kí ẹ rà fún mi báyìí – Iya Gbonkan

  14. Auxilliary na pápá bora lásìkò tí ọlọ́pàá ṣèkọlù sí ilé rẹ̀!

  15. Gomina Dapo Abiodun tú ẹlẹ́wọ̀n mọ́kàndínláàdọ́ta sílẹ̀ l'Ogun, Gomina Dapo Abiodun yẹ ìdájọ́ ikú kúrò lórí àwọn mẹ́ta

    Gomina Abiọdun tu ẹlẹwọn mọkandinlaadọta silẹ l'Ogun,

    Bẹẹ lo foju aanu wo awọn mẹta ti wọn dajọ iku fun

    Ẹsẹ ko gbero ni papa iṣere MKO Abiọla to wa ladugbo Kutọ niluu Abẹokuta ipinlẹ Ogun, nibi ti wọn ti ṣe ayẹyẹ eto ibura fun Ọmọọba Dapọ Abiọdun ati igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele gege gomina ati igbakeji gomina ti wọn dibo yan nipinlẹ naa, lati tukọ iṣakoso fun ọdun mẹrin miiran.

    Nibi ayẹyẹ naa ti adajọ agba ati kọmiṣanna f'ọrọ eto idajọ n'ipinlẹ ọhun, Onidajọ Mosunmọla Dipẹolu ṣe ibura naa ni Gomina Abiọdun ti paṣẹ pe ki wọn tu ẹlẹwọn mọkandinlaadọta silẹ, ati awọn mẹta ti wọn ti gbagbe sẹwọn tipẹ, lati maa lọ layọ ati alaafia.

    "Iwe ofin Naijiria gba mi laaye lati lo anfaani ipo mi lati dariji ẹnikẹni ti o ba ṣẹ si ofin ipinle Ogun.

    Lẹyin ti mo ti gba itọni lọdọ awọn igbimọ ti a gbe kalẹ lati gba mi lamọran lori lilo agbara, mo ti buwọ lu iwe to yẹ lati tu awọn ẹlẹwọn mọkandinlaadọta ti wọn n ṣẹwọn lọwọ l'awọn ọgba ẹwọn kaakiri ipinlẹ Ogun silẹ.

    "Mo tun ti buwọ lu iwe miran lati yi idajọ iku fun awọn mẹta pada si ẹwọn gbere. Awọn ẹlẹwọn ti wọn jẹ anfaani yii lonii, l'awọn to ti wa lẹwọn tipẹtipẹ, paapaa julọ awọn to ti le logun ọdun lẹwọn.

    "O kere julọ, meji ninu wọn ni wọn n ṣaisan nla, eyi to jẹ ki wọn jẹ ipalara fun ọgba ẹwọn. Mẹta ninu awọn ẹlẹwọn yii ni wọn ti lọgọta ọdun, nigba ti ẹnikan ninu wọn jẹ ọdun mẹrinlelọgọrin.

    "Awọn yooku lo ku bii ọdun meji ki wọn lo lẹwọn. Gbogbo awọn ti wọn si dajọ fun yii ni wọn ti kabamọ iwa ọdaran wọn, ti wọn si ti kọ iṣẹ pẹlu iwe ẹri lẹwọn, bẹẹ ni wọn tun ti fi iwa rere han lati jẹ ẹni ayipada rere."

  16. Ọmọ ọdún 16 tó gba àmì ẹ̀yẹ Guinness World Records nílùú Akure sọ ìrírí rẹ̀ fún BBC

  17. A faramọ́ bí ìjọba ṣe yọ 'subsidy' lórí epo - NNPC

    Ileesẹ eporọbi ni Naijiria, NNPC, sọ pe oun faramọ bi ijọba ṣe yọ owo ìrànwọ́ ori epo, subsidy.

    Ọjọ Aje ni aarẹ tuntun, Bola Ahmed Tinubu, kede ninu ọrọ to kọkọ ba awọn ọmọ Naijiria sọ. Ààrẹ Tinubu sọ pe ko si ipese fun 'subsidy' ninu owo isuna ọdun 2023 - eyi to tumọ si pe, ìjọba ko ni san án mọ.

    O ni ijọba yoo fi owo to yẹ ko fi san subsidy gbọ bukaata àwọn nǹkan miran fun idagbasoke ìlú.

    Nigba to n ba àwọn akọroyin sọrọ, ọga agba NNPC, Mele Kyari, ṣalaye pe subsidy ti ijọba da duro, yoo mu ki owo wa daadaa fun ileeṣẹ naa lati ṣe iṣẹ rẹ bo ṣe yẹ.

    "Ẹrù to wúwo ni subsidy jẹ lori owo to n wọle fun NNPC."

    Ṣaaju ki ikede naa to waye, ni awọn ileepo kan ti n ti ilẹkun wọn, ti wọn si kọ̀ lati ta epo fun araalu.

    Nigba ti yoo si fi di ọsan ọjọ Ajé, iroyin ti n lọ, paapaa lori ayelujara pe ọpọ ileepo ti fi owo kun iye ti wọn n ta lita bẹtiro kan niluu Abuja ati ipinlẹ Eko.

    Lori eyi, ọga NNPC fi da àwọn ọmọ Naijiria loju pe epo wa nílẹ̀ rẹpẹtẹ, ati pe ileeṣẹ naa n tọ pinpin bi epo ṣe n lọ kaakiri, lati ri i daju pe àwọn alagbata tẹle ilana to yẹ.

    Lati nnkan bi ọdun 1970 ni ìjọba Naijiria ti n san subsidy lori bẹtiro, lati din iye ti araalu n ra a kù.

    Ìjọba si ti gbiyanju lati da a duro ni àwọn akoko kan ṣeyin, sugbọn o ba atako pade.

    Lọdun 2012 ti ìjọba ààrẹ Goodluck Jonathan gbiyanju rẹ, jakejado Naijiria ni iwọde ti waye.

    Eyi mu ki ìjọba tun dawọ duro.

    Ọpọlọpọ tiriliọnu Naira ni ìjọba n ná lori subsidy lọdọọdun.

  18. Davido, Kunle Afolayan, Osimhen, àti àwọn míì yoo gba àmì ẹ̀yẹ tó ga jù lọ ní Naijiria

    Wọ́n ti kede orúkọ akọrin tàkasúfèé, Davido, ati agba oludari ere, Kunle Afolayan, pẹlu àwọn eeyan míì, pe wọn yoo gba ami ẹyẹ to ga julọ ni Naijiria.

    Ọjọ Aiku, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ni ileeṣẹ ìjọba to n mojuto awọn àkànṣe iṣẹ, kede orúkọ eeyan 339, ti yoo gba ami ẹyẹ lọdun 2023.

    Ọdọọdún ni ijọba Naijiria ma n fi orisirisi ami ẹyẹ da awọn ọmọ Naijiria, to n ṣe gbe orúkọ orilẹ-ede ga nidii iṣẹ́ ti wọn n ṣe.

    David Adeleke (Davido) ati Kunle Afolayan, gba ami ẹyẹ Officer Of the Order of the Niger (OON).

    Bákan naa ni ogbóntarìgì agbabọọlu, Victor Osimhen, naa gba ami ẹyẹ Member of the Order of the Federal Republic (MFR), fun ipa to n ko lagbo bọọlu.

    Osimhen lo ran ẹgbẹ́ agbabọọlu Napoli lọwọ, lati gba ife Serie A, fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹtalelọgbọn.

    Lara àwọn ti orúkọ wọn tun jade fun ami ẹyẹ ni apanilẹ́ẹ̀rín, Ayo Makun (AY), Tiwa Savage, Jay Jay Okocha, OloyeBBisi Akande, Olubadan ilẹ̀ Ibadan, Oba Lekan Balogun, Rauf Aregbesola, àti àwọn èèkàn ìlú miran.

    Ìjọba ti kọ̀wé si àwọn to fẹ fi ami ẹyẹ da lọla, o si ti ni ki ẹni kọọkan wọn fi akọsilẹ nipa wọn ranṣẹ́, titi ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un.

    Gbogbo wọn si ni ireti wa pe wọn gbọdọ wá si ilu Abuja fún ayẹyẹ ti wọn o ti gba àmì ẹ̀yẹ wọn, ati iwe ẹri, lọjọ kini, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.

    Lọdun to kọja, aarẹ to ṣẹ̀ṣẹ̀ kuro nipo, Muhammadu Buhari, fi ami ẹyẹ da awọn akọrin bii Tuface Idibia, Teni, ati Burna Boy, lọla.

  19. ‘’Gbogbo aráàlú ní yóò gbádùn ní ìjọba mi’’

    Gomina ipinlẹ Rivers ti wọn ṣẹṣẹ sẹ iburawọle fun, Siminialayi Fubara ti ṣeleri pe oun yoo jẹ gomina fun gbogbo awọn araalu ni ipinlẹ Rivers.

    Fubara sọ eyi lasiko ti wọn n burawọle fun gẹgẹ bi gomina tuntun nipinlẹ naa.

    Gomina naa seleri lati sa ipa rẹ gẹ gẹ bi adari rere.

    Fubara fikun un pe awọn iriri ti oun ti ri gẹgẹ bi oṣiṣẹ ijọba yoo ran oun lọwọ lati dipo naa mu daradara.

    Bakan naa lo fikun un pe awọn ko ni kẹyin si awọn ọdọ, ti awọn yoo si fi wọn si ipo to yẹ.

    Gomina ipinlẹ Rivers naa ṣeleri ;ati ṣe opopona daradara, to fi mo ipese eto aabo to peye fun awọn araalu.

    Lara awọn to wa nibi iburawọle naa ni gomina ipinlẹ Bẹnue tẹlẹri, Samuel Ortom, gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹri, Peter Odili ati iyawo rẹ Mary Odili, pẹlu awọn miran lo wa nibẹ.

  20. Gbágéde ìbúrawọlé wó lulẹ̀ ní Kano

    Gbagede ti wọn ti burawọle fun gomina ipinlẹ Kano, Abba Kabir Yusuf wọ lulẹ lasiko ayẹyẹ iburawọle naa.

    Iṣẹlẹ naa waye nigba ti gomina tuntun naa ti wọn pe inagije rẹ ni Abba Gida-gida wa pẹlu igbakeji rẹ to fi mọ Olori eto idajọ nipinlẹ naa.

    Amọ, ko si ẹni to farapa ninu iṣẹlẹ naa

    Gomina naa n gbiyanju lati kuro ni abẹ atibaba naa ni lẹyin ti wọn burawọle fun, amọ ti atibaba naa wo lulẹ, ti awọn ẹṣọ rẹ si sare gbe.

    Bakan naa ni awọn ololufẹ gomina naa kun ibẹ fọfọ, eleyii to dena gomina naa lati ri awọn ikọ ọmọogun to yan fanda kọja niwaju gomina naa.

    Papa iṣere Sani Abacha ni wọn lo fun eto iburawọle naa, ti o si kun fọfọ.