You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Mímu omi ẹ̀rọ lé fa ààrùn òní igbá méjì, Cholera

    Ajọ eleto ìlera lorilẹede South Africa ni aarun oni igba meji ti ṣekupa eeyan mẹwaa ni Gauteng.

    Bakan naa ni eeyan to to marundínlọgọrun si ti dero ile wosan lẹyin ti wọn lugbadi aarun ni Pretoria.

    Awọn ọmọde naa o gbẹyin ninu awọn eeyan to ti lugbadi aarun naa. Olori ajọ eleto ìlera, Nomantu Nkomo- Ralehoko ni awọn eeyan ni lati sọra pẹlu omi tí wọn mu.

    Ní ilu Tshwane, ajọ eleto ìlera ti rọ awọn araalu lati dẹkun mimu omi ẹrọ nítorí oun lo sokupa aarun naa

  2. Buhari yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ afárá Niger lónìí

    Aarẹ Muhammad Buhari yoo ṣe ifilọlẹ afara Niger kejì laarin ọdun mẹjọ isejọba rẹ.

    Agbẹnusọ Aarẹ, Femi Adeshina lo kede ọrọ naa síta pe Aarẹ Buhari yoo si afara naa fun awọn arin irinajo.

    Ileeṣẹ Aarẹ ni lati ọdun 2005 ni wọn ti lero lati parí afara naa sugbọn saa Aarẹ Buhari lo parí afara naa.

    Bakan naa ni Aarẹ yoo tun ṣe ifilọlẹ awọn isẹ akanse ti isejọba ṣe laarin ọdun mẹjọ.

    Igbagbọ wa pe Aarẹ yoo lọ ipinlẹ Zamfara, Benue, Nasarawa, Cross River ati Ipinlẹ Kano lati se ifilọlẹ ise akanse naa

  3. Ìdajì àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ló ti sá kúrò láti ìgbà tí Taliban ti gbàjọba

    Iwadi ileeṣẹ BBC fihan pe awọn olukọ ni fasiti lorilẹede Afghanistan lo ti kuro lọ si orilẹede miiran lati igba ti ijọba Taliban ti gba isakoso ijọba orilẹede naa.

    Ẹka BBC ni Afghanistan ni o to ẹgbẹrun kan Ọjọgbọn ni Fasiti Kabul ni tẹlẹ sugbọn ti wọn sa kuro lọ si oke okun.

    Ọpọ awọn Ọjọgbọn naa lo ni bi wọn ṣe dunkoko mọ ẹmi wọn lo jẹ ki wọn ba ẹsẹ wọn sọrọ lọ si orilẹede mii.

    Bakan naa ni ijọba Taliban ti fofin de awọn obinrin lati ma le ni anfani lati lọ fasiti ati awọn ofin miiran eyi to dena de ki awọn obinrin kopa ninu ọpọ nnkan.

    Ọpọ awọn araalu lo ti kọminu lori igbasẹ ijọba Taliban.

  4. Wo bí ìwádìí ṣé ṣàwárí nọ́ọ̀sì mẹ́rin tó yọ ojú, ẹyà ará ọmọ tuntun méjì

    Awọn alaṣẹ ni Tanzania sọ pe awọn nọọsi mẹrin kan lagbegbe Tabora yoo foju ba ile ẹjọ lori ẹsun pe wọn ge ẹya ara awọn ikoko meji kan to ṣalaisi.

    Igbimọ iwadii kan ti wọn gbe kalẹ fidi rẹ mulẹ pe niṣe ni wọn ba ti wọn ge ẹya ara awọn ikoko meji yi ti wọn ko pe ọjọ.

    Iya awọn ọmọ meji yi ba ti wọn ti yọ oju wọn ti wọn si fi ọbẹ ge awọ kuro niwaju ori wọn.

    Kọmiṣana lagbegbe naa Batilda Buriani sọ pe awọn nọọsi ti wọn mu yi ni wọn ti ni ki wọn lọ fidimọle fun igba diẹ naa lẹnu iṣẹ.

    O ni awọn fura si pe wọn fẹ lo awọn ẹya ara yi lati ṣe ohun aburu ni.

    Bẹẹ lo ni awọn nọọsi yi parọ tan awọn igbimọ pe inu wọọdu mataniti ni wọn gbe awọn ọmọ yi si dipo inu iyara awọn nọọsi ti wọn gbe wọn si.

    Iwadii wọn tun fihan pe aisi ipese itọju to peye naa wa lara nkan to kọkọ ṣokunfa iku awọn ọmọ yi ki awọn alaburu to ge ẹya ara wọn.

  5. Àìsàn onígbáméjí pa ènìyàn mẹ́wàá, ènìyàn 39 ń gba ìwòsàn lọ́wọ́

    Aisan onigbameji ti bẹ silẹ ni orilẹede South Africa to si ti pa eniyan mẹwaa ni agbegbe Gauteg.

    Awọn eleto ilera ni orilẹede South Africa to kede rẹ ni eniyan marundinlọgọrun lo ti di ero ile iwosan laarin ọsẹ kan, ti awọn eniyan agbegbe Hammanskraal ni Pretoria si ti n fi ami han.

    Iwadii fihan pe eniyan mọkandinlogun lo ti lugbadi aarun naa ni ẹka ileewosan Gauteg

    Ti wọn si fikun un pe eniyan mẹtadinlogoji ni wọn n gba iṭju pajawiri lọwọ.

    Lara awọn to padanu ẹmi wọn ni ọmọ ọdunmẹta kan ati agbalagba mẹsan an.

    Ijọba war ọ awọn araalu lati bojuto eto ilera ara wọn, ki wọn si ri pe wọn gba imọtoto laaye.

    Bakan naa ni ijọba rọ awọn ara agbegbe Tshwane lati mase mu omi to wa ni agbegbe wọn.

    Ijọba fikun un pe awọn yoo maa gbe omi wa fun awọn araalu lasiko fun ida abobo wọn lọwọ aarun onigbameji to n ja ranyin ni South-Africa.

  6. Ìgbìmọ̀ olùgbẹ̀jọ́ ìbò ààrẹ wọ́gilé ṣiṣe àfihàn ìgbẹ́jọ́ lórí amóhunmáwòrán

    Igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye lori esi idibo aarẹ ni Naijiria ti fọwọ rọ ibeere alatako ijaweolubori Bola Tinubu to fẹ ki wọn ṣe afihan bi igbẹjọ naa ṣe n lọ lori amohunmaworan.

    Awọn agbẹjọro oludije ipo aarẹ Atiku Abubakar ati Peter Obi sọ awijare pe ṣiṣe afihan igbẹjọ yi yoo ṣe anfaani faraalu.

    Ṣugbọn awọn adajọ agba marun un to n gbẹjọ naa fariga.

    Adajọ Haruna Tsammani gẹgẹ bi ileeṣẹ iwe iroyin Daily Trust ti jabọ sọ pe ''Irori ti ko fẹsẹ mulẹ ni wi pe afihan igbẹjọ lori amohunmaworan yoo ṣe araalu lanfaani''

    Idajọ kekere yi jẹ bi aṣeyọri fun ikọ Tinubu ati ajọ eleto idibo ti wọn tako ibeere yi lati ọdọ awọn agbẹjọro Atiku ati Obi.

    Obi ati Atiku fẹ ki ile ẹjọ wọgile aṣeyọri Tinubu lori awijare pe magomago pọ ninu idibo naa.

    Bẹẹ ni Tinubu ati ajọ eleto idibo INEC naa n sọ ti wọn pe esi idibo yi ko ni abawọn tohun ti pe wọn ko ribi gbe esi idibo lawọn aaye idibo soju opo INEC gẹgẹ bi INEC ṣe ṣeleri.

    Ọgbẹni Tinubu ni wọn kede pe Tinubu jaweolubori pẹlu ida 37%,Atiku ni ida 29% ti Ọgbẹni Obi si ni ida 25%.

  7. Ọ̀rẹ́ àti kékeré ni èmi àti Chioma, a ti mọra fún ogún ọdún – Davido

    Gbajugbaja olorin takasufe, David Adeleke ti ọpọ mọ si Davido ti tu kẹkẹ ọrọ sita lori bi o ṣe ṣalabapade iyawo rẹ, Chioma.

    Davido ninu ifọrọwerọ kan to ṣe, o ni o ti to ogun ọdun ti oun ti mọ iyawo oun yii, to si n mu inu oun dun gbogbo igba.

    O ni fifẹ Chioma lo jẹ igbesẹ kan ti inu oun dun si pupọ.

    "Emi ati iyawo mi, lati ile ẹkọ ni a ti mọra.

    "Ẹnikeji mi ni, a si mọwọ ara wa pupọ gan.”

    "O ṣe koko ki eeyan wa ẹni ti ọrọ ara wọn ṣe yera wọn, emi ati iyawo mi, Ọlọrun da wa fun ara wa ni.

    "A ti mọra fun ogun ọdun, inu mi dun pe mo fẹ gẹgẹ bii iyawo, o tun wa mọ ounjẹ ṣe daadaa."

    Davido ati Chioma ni wọn bẹrẹ ere ifẹ lọdun 2015 lasiko ti wọn jẹ akẹkọọ ni fasiti Babcock, nipinlẹ Ogun.

    Amọ lẹyin iku ọmọ wọn, Ifeanyi, ni wọn ṣe igbeyawo bonkẹlẹ.

  8. Buhari gbọdọ̀ ṣàlàyé bí ìjọba àpapọ̀ ṣe ná $460m tó yá lọ́wọ́ China láti fi pèsè CCTV sílùú Abuja - Ilé ẹjọ́

  9. Àwọn agbébọn jí pásítọ̀ gbé ní Imo

    Awọn afurasi agbebọn ni wọn ti palẹmọ Olusọ aguntan Jude Maduka ti ile ìjọsin Christ the King Parish nipinlẹ Imo.

    Ikọlu yii n waye lẹyin ti awọn agbébọn ṣekupa Ọlọpaa meji laipẹ yii.

    Olusọ Maduka ni o mura lati lọ si ile ìjọsin lasiko ti awọn agbébọn ọhun yabo ile rẹ, ti wọn si ji gbe lọ.

    Igbakeji ree ti awọn agbébọn yoo jí Olusọ aguntan gbe nipinlẹ Imo.

    Awọn ọmọ ìjọ to ba awọn akọroyin sọrọ ni ninu ibẹru ni pupọ awọn ọmọ ìjọ wa bayii.

    Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Imo, ASP Henry Oloye ni iwadii ti bẹrẹ lori ijinigbe naa

  10. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ láti jẹun bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn

    Ajọ kan to n ja fẹtọ ọmọniyan lorilẹede Iran ti ni awọn ẹlẹwọn kan ni ọgba ẹwọn Ghazalhasar ni wọn ti bẹrẹ si ni wo oúnjẹ niran lati fi se ìwọde lori bi isekupani ati idajọ iku fun awọn ẹlẹwọn ṣe wọpọ lorilẹede naa.

    Awọn ẹlẹwọn ọhun lo bẹrẹ ìwọde lọjọ Aiku ti wọn si kọ lati fi oúnjẹ ti awọn ẹsọ gbe wa kan ẹnu wọn.

    Laipẹ yii, idajọ iku fun awọn ẹlẹwọn ti jẹ ohun to n waye lemọlemọ fun awọn ẹlẹwọn to jẹ oloselu ati awọn araalu to sẹ so ofin ìlu naa.

    Igbesẹ yii ni ko dun pupọ awọn ẹlẹwọn naa ninu, eyi to fa ti wọn fi bẹrẹ si wo oúnjẹ wọn niran.

  11. Kò sí òtítọ́ nínú ìròyìn pé Russia tún ti gba ìlú Bakhmut - Ààrẹ Zelensky

    Ààrẹ orílẹ̀ èdè Ukraine, Volodymyr Zelensky tí ni kò sí òtítọ́ nínú ìròyìn pé orílẹ̀ èdè Russia tí gba ìlú Bakhmut.

    Èyí kò sẹ́yìn ìròyìn tó gbòde kan pé àwọn ikọ Russia.

    Ààrẹ Zelensky ni àwọn ikọ ọmọ ogún wọn wá ní ìlú náà láti ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan.

    Ààrẹ náà ni òun kò ní leè sọ ju báyìí lọ, àmọ́ òun ti oun mọ ni pé ìlú náà kò sì lọwọ Russia.

    Ọpọlọpọ ìṣẹ́ ni orílẹ̀èdè Russia àti Ukraine ń ṣe láti gba ìlú Bakhmut nínú ogún tó ń wáyé láàárín orílẹ̀ èdè méjèèjì.

    Ó ti lè ní ọdún kan tí ogun tí n waye láàárín orílẹ̀ èdè Ukraine àti Russia.

  12. Àwọn ènìyàn burúkú kan fẹ́ bá àjọṣepọ̀ gómìnà Ganduje àti Tinubu jẹ́ - Ìjọba Kano

    Ijọba ìpínlẹ Kano ti bu ẹnu àte lu bí àwọn kan ṣe fẹ́ bá ibasepo tó wà láàárín gomina ìpínlẹ Kano àti Ààrẹ ti wọn dibo yàn, Bola Ahmed Tinubu.

    Ijọba Kano ni awọn eniyan ti ko ni ìtẹ́lọ́rùn ni wọn fẹ bá ìjọba tuntun náà jẹ.

    Wọn ni awọn ti wọn fi ẹ̀sùn kan náà ń pín ọrọ ti wọn sọ lórí fóònù laarin gomina Umar Ganduje àti Ibrahim Masari.

    Gomina náà ni ayédèrú ni ohun náà, tí kò sì òtítọ́ nínú ìròyìn tó ń káàkiri lórí ẹ̀rọ ayélujára.

    Nínú ayédèrú ìròyìn náà ni àwọn méjèèjì tí ń sọ̀rọ̀ nípa ìjíròrò tó wáyé láàárín Tinubu àti adari egbe oselu NNPP, Rabiu Kwankwaso.

    Ijọba ìpínlẹ Kano ni awọn eniyan to ti gba owó láti bá nkan jẹ́ lọ ń pín àwọn ọrọ náà lórí ẹ̀rọ ayélujára.

    Wọn ni awọn kò ní gbà àwọn ènìyàn yìí láàyè láti bá ìjọba tó ń bọ̀ yìí jẹ.

    Ní May 29 ni iburawọle yóò wáyé fún Bola Ahmed Tinubu gẹgẹbi Ààrẹ Kẹrindínlógún tí wọn dibo yàn ni Naijiria

  13. 'Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé ìyàwó mi tún lóyún lẹ́yìn tí mo gé ọ̀pá tó n gbé àtọ̀ jáde'

  14. 'Ìdí tí mo fí ṣe ìgbéyàwó pẹ̀lú àrà mí rèé'

    Omobinrin kan ti orukọ n jẹ Dorothy Fedeli ni o ṣe igbeyawo pẹlu ara rẹ lẹyin aadọta ọdun to kọkọ ṣe igbeyawo.

    Dorothy Fedeli, ẹni ọdun mẹtadinlọgọrun lo ṣe ayẹyẹ igbeyawo ọhun ti gbogbo mọlẹbi si wa ni bi ayẹyẹ ọhun ni Ohio lorilẹede Amẹrika.

    "Mo ti gbiyanju gan-an, pabo lo jasi fun idi eyi, kílode ti n ko le fi fẹ ara mi."

    Fedeli ni o ti kọkọ ṣe igbeyawo ni aadọta ọdun sẹyin, ti igbeyawo ọhun si fi ori san pọn eyi to mu pinnu lati ma ṣe igbeyawo miran mọ.

    Ọmọ mẹta ni Dorothy bi, to si tun ni ọmọ ọmọ kan. O ni ero yii to oun mu wa si imusẹ yii lo sọ si oun lọkan lasiko to wa ni ile ijọsin kan.

    "Mo ti ń dagbe lati ibi ogoji ọdun sugbọn mo pinnu lati se ohun pataki si oun

  15. Ẹ fún mi lọ́sẹ̀ méje láti pèsè àwọn ẹlẹ́rìí mi- Peter Obi

    Oludije sipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi ti bẹrẹ fun ọsẹ meje lọwọ ileęjọ lati se afihan awọn ẹlẹri rẹ lori ẹjọ to pe fi tako idibo to gbe Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan wọle.

    Obi ni oun ẹlẹri to to aadọta ni ye lati sọ ohun ti oju wọn ri lasiko eto idibo to waye ninu osu kẹta ọdun yii.

    Obi, ẹni ti agbẹjọro rẹ, Ọjọgbọn. Awa Kalu gba ẹnu rẹ sọrọ ni awọn nilo asiko naa ti fi gbaradi koju ajọ eleto idibo ilẹ Naijiria lori bi wọn ṣe dan wọn duro.

    "A n duro de awọn iwe kan ti a bere lati owo Ajọ INEC."

    Agbẹjọro ni awọn yoo nilo Ọgbọn isẹju fun awọn ẹlẹrin naa lati sọrọ ẹnu wọn tan.

    Ṣugbọn Agbẹjọro INEC, Abubakar Mahmood ni oun fẹnu ko pẹlu ẹnikẹni lori akoko ti awọn ẹlẹrin yoo fi sọrọ wọn tan.

    Bakan naa lo ni oun ko mọ pe ajọ INEC ṣe ida duro kan kan fun awọn akẹgbẹ wọn.

    Ninu ọrọ ti rẹ, INEC ni oun yoo nilo ọjọ mẹta làti pese awọn siwaju ile ẹjọ. Agbẹjọro fun Aarẹ ti ilu sẹsẹ dibo yan, Roland Otaru ni oun yoo nilo ọjọ mẹ́san lati fi pe apapọ ẹlẹri to to mọkanlelogun.

    Niyi Akintola, Agbẹjọro fun ẹgbẹ oselu APC ni oun yoo ọjọ mẹsan lati pe ẹlẹri meje wa si ileęjọ.

  16. Ǹjẹ́ o mọ àwọn òṣèré bí Oyin Adejọbi, Funmi Martins àtàwọn míì tó ti dágbére fáyé?

  17. Wo ìdí tí àwọn arákùnrin mẹ́ta yìí fí gbà ìdájọ ikú lọ́wọ́ ìjọba Iran

    Awọn alaṣẹ lorileede Iran ti yẹgi fun awọn arakunrin mẹta kan ti wọn ni wọn lọwọ ninu ifẹhonuhan tako ijọba to waye lọdun to kọja.

    Ile ẹjọ ilẹ naa da awọn mẹtẹẹta lẹbi pe wọn lọwọ ninu iṣẹlẹ iyinbọnpaniyan eleyi to mu ẹmi awọn agbofinro mẹta lọ ni Isfahan loṣu Kọkọnla.

    Ajọ ajafẹtmọniyan Amnesty International sọ pe idajọ yi ko bojumu ati pe o ṣeeṣe pe wọn fiya jẹ awọn ọkunrin naa lahamọ

    Awọn oluwọde mẹrin mii ni wọn ti yẹgi fun lẹyin awọn wọnyi lati oṣu kejila ọdun.

    Ọpọ lo gba idajọ iku ti wọn si fẹsun iditẹmọjọba kan aimọye.

    Iwọde taa n wi yi waye jakejado Iran lẹyin iku arabinrin Mahsa Amini ẹni ọdun mejilelogun ẹya Kurd ti awọn ọlọpaa Sharia mu lori ẹsun pe ko wọ Hijab rẹ bo ṣe tọ ni Oṣu Kẹsan.

    Lọjọ Ẹti ni wọn ṣeku pa awọn mẹta taa n wi yi-Majid Kazemi, ẹni ọgbọn ọdun,Saheed Yaqoubi,ẹni ọdun mẹtadinlogoji ati Saleh Mirhashemi ẹni ọdun mẹrindinlogoji.

    Wọn mu wọn lẹyin iwọde to waye ni ilu Isfahan lọjọ Kẹrindinlogun oṣu Kọkanla nibi iṣẹlẹ ti ọmọ ogun meji ati ọlọpaa kan kagbako iku lọwọ ọtta ibọn.

    Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn s fun Amnesty International pe wọn fi tipa gbe awọn arakunrin naa pamọ,ti wọn si fiya jẹ wọn titi ti wọn fi jẹwọ ọrọ ti wọn fi ka ẹsun siwọn lọrun.

    A gbọ pe niṣe lawọn to n wadii ọrọ lẹnu wọn da ori arakunrin Kazemi kodo ti wọn si fi fọnran fidio bi wọn ṣe n fi iya jẹ ọmọ iya rẹ.

    Koda wọn a tun ṣebi igba pe wọn fẹ gba ẹmi rẹ ti wọn a si tun dẹru ba pe awọn yoo pa awọn ọmọ iya rẹ lọkunrin.

  18. Afurasí ajínigbé mẹ́rin kó sí gbaga ọlọ́pàá ní Ekiti

    Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Dare Ogundare ti fojú àwọn afurasí mẹ́rìndínlógún hàn fún ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn lọ́kan-ò-jọ̀kan.

    Mẹ́rin nínú àwọn afurasí yìí ni wọ́n ní àwọn nawọ́ gán ní agbègbè Òkè Ako ní ìpínlẹ̀ Ekiti àti àwọn apá ibì kan ní ìpínlẹ̀ Kwara.

    Ogundare tó sọ àrídájú rẹ̀ pé iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ekiti kò ní fi ààyè gba ìwà ọ̀daràn ní kété tí àwọn bá ti parí ìwádìí ni àwọn máa gbé àwọn afurasí ọ̀hún lọ sí ilé ẹjọ́.

    Ó ní àwọn ọlọ́pàá Ekiti pẹ̀lú àjọṣepọ̀ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi nawọ́ gán àwọn afurasí meji tí orúkọ won ń jẹ́ Abu Hassan tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Danger àti Abubakar Sodiq.

    Ó ní àwọn afurasí méjéèjì yìí ló jẹ́ ògbóǹtarigì ajínigbé tí wọ́n ń ṣọṣẹ́ ní agbègbè Iyemero/Oke-Ako/Irele/Ipao-Ekiti.

    Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá náà ni àwọn tó ti kó sí páḿpẹ́ àwọn afurasí yìí ló dá wọn mọ̀ tí wọ́n sì nawọ́ sí wọn pé àwọn ló jí àwọn gbé.

    Ó ní ìbọn tiwa-n-tiwa kan, àti ọta ni àwọn bá lọ́wọ́ wọn lásìkò tí ọwọ́ tẹ̀ wọ́n. Bákan náà ló ní ìwádìí ń tẹ̀síwájú láti ṣe àwárí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ wọn mìíràn tó ti sá lọ.

    Ó fi kun pé ọwọ́ òfin tún tẹ àwọn afurasí mìíràn, Umar Hassan àti Yusuf Lawal fẹ́sùn wí pé wọ́n yawọ agbègbè Ayenco ní Eda-Ile Ekiti tí wọ́n sì jí obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mary Olajumoke gbé.

    Ó ní lẹ́yìn tí àwọn afurasí náà gba owó ìtúsílẹ̀ ni wọ́n tó tú ọmọbìnrin náà sílẹ̀.

    Ó ṣàlàyé pé ada méjì àti ₦82,200 tó jẹ́ owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n ná kù ni àwọn bá ní ọwọ́ wọn nígbà tí ọwọ́ òfin bà wọ́n. Ó fi kun pé àwọn afurasí yòókù ni ọwọ́ bà fún ìwà ṣíṣe ẹgbẹ́ òkùnkùn àti olè jíjà.

  19. ‘’Ìkọlù àwọn agbébon ti kọja ala, niise ni oku sun lọ ni agbegbe wa’’

    O kere tan ilu mẹjo ni agbegbe Dan-Kurmi ni ijọba ibilẹ Maru ni Zamfara ni awọn agbebọn ti sekọlu ni ipinlẹ Zamfara.

    Ikọlu to waye ti pa eniyan mẹrindinlaadọta, ti wọn si dana sun awọn ilu naa ati ohun ini wọn.

    Bakan naa ni wọn n koju awọn ipenija lọgọọrọ pẹlu awọn agbebọn to n sekọlu si wọn.

    Ninu ọrọ rẹ, Kaunsẹlọ Iliyasu Salisu Daraga ni awọn ara agbegbe naa ni ibanujẹ ati ifoya ni awọn fi n gbe.

    Wọn ni laaarin osu yii, awọn agbegbọn ti sekọlu si wọn ni igba mẹtadinlogun.

    ‘’Ni ikọlu akọkọ , awọn eniyan 51 lo ku , ni ikọju keji, awọn eniyan 17 ni wọn sekọlu si, ni agbegbe Hayin Getso ati Fari Ruwa.’’

    Ikọlu miran to waye, eniyan 54 lo tun ku, ti awọn mẹrindinlaadọta miran tun ku.

    Bakan naa ni wọn kesi ijọba ko jọwọ saanu wọn, ki wọn pese eto aabo to muna doko fun wọn ni ipinlẹ Zamfara.

    Nibayii, ijọba ti ko awọn ẹsọ alaabo sibẹ, amọ ibẹru bojo si gba ọkan wọn, ti wọn si ni igbiyanju si n lọ lọwọ.

  20. Iléẹjọ́ wọ́gilé èsì ìdìbò tó gbé ẹgbẹ́ òsèlú Labour Party wọlé ní Abia

    Adajọ ileẹjọ nipinlẹ Kano, Mohammed Yunusa ti gbekile esi idibo to gbe gomina ti wọn ṣẹsẹ dibo yan ni Abia, Dr Alex Otti wọle.

    Bakan naa ni adajọ gbekile esi idibo ẹgbẹ oselu Labour Party ni ipinlẹ Kano ati Abia.

    Adajọ ni bi wọn se de ori iwe idibo ko tẹle ofin eto idibo ti ọdun 2022.

    Ojọ Ẹti ni wọn fi idajọ naa ṣowọ si awọn oniroyin.

    Ninu ẹjọ ti Arakunrin Ibrahim Haruna Inrahim pe tako ẹgbẹ oselu Labour ati INEC lo ti ni ẹgbẹ oselu Labour party ko se iforukọ silẹ ni ọdọ INEC laarin ọgbọnjọ ti ofin sọ ki wọn to se idibo abẹle.

    O ni nitori wọn ko tẹlẹ ofin naa, idibo to gbe wọn wọle ko ni ẹsẹ nilẹ.

    O ni Labour party ko lee sọ pe oun ni oludije ninu idibo naa, nitori naa wọn ko lee jawe olubori.

    Adajọ ni eyi fihan pe awọn ibo ti ko kẹsẹjari lo gbe Alex Otti wọle gẹgẹ bi gomina ti wọn dibo yan ni ilu Abia.