You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Òṣìṣẹ́bìnrin ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú òfurufú pokùnso, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

    Arábìnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú òfurufú kan ìyẹn Nigeria Air Force (NAF) ni wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú ilé níbi tó pokùnso sí.

    Arábìnrin náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní George gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀ sínú ilé ìgbé àjọ ọ̀hún ní block T5, Sam Ethnam Base tó wà ní agbègbè Ikeja ìpínlẹ̀ Eko.

    Ìròyìn ní àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn NAF ló lọ gbé òkú náà.

    Ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ búburú náà wáyé.

    Agbenusọ ẹ̀ṣọ́ ààbò òfurufú, Commodore Ayodele Famuyiwa tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní àwọn tí gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣèwádìí ikú rẹ̀.

    Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, ohun tó fà á tí obìnrin náà fi gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀ nípa pípokùnso kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni báyìí.

  2. Aṣòfin tó ń bú ẹnu àtẹ́ lu ọkọ̀ òfurufú Nàìjíríà ń bèèrè fún ìdá márùn-ún iléeṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àbẹ̀tẹ́lẹ̀ - Sirika

    Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fétò ìrìnnà òfurufú ní Nàìjíríà, Hadi Sirika ti ṣàlàyé àwọn ohun tó ta kókó lórí ìgbékalẹ̀ ọkọ̀ òfurufú Nàìjíríà.

    Níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan tí Sirika ṣe pẹ̀lú iléeṣẹ́ ìròyìn Arise TV lọ́jọ́ Àìkú ló ti ṣàlàyé pé ọmọ ilé aṣòfin tó ń sọ wí pé èrú ni àgbékalẹ̀ ọkọ̀ náà ti ṣáájú bèrè fún rìbá ìpín ìdókoòwò ìdá márùn-ún iléeṣẹ́ náà.

    Sirika ní aṣòfin Nnolim Nnaji bèrè fún ìdá márùn-ún náà lórúkọ ara rẹ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀.

    Ó ṣàlàyé pé èsì tí òun fun ní ọjọ́ náà lọ́hùn-ún ni pé àwọn kan ló gba iṣẹ́ náà, kó lọ báwọn tí wọ́n bá fún un.

    Bákan náà ló bù ẹnu àtẹ́ lu bí alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìrìnnà òfurufú ní ilé aṣojúṣòfin, Nnolim Nnaji ṣe fẹ̀sùn kàn pé bòńkẹ́lẹ́ ni ìjọba àpapọ̀ fi ètò náà ṣe.

    Nnaji ní èrú ni àgbékalẹ̀ iléeṣẹ́ náà jẹ́ àti pé ilé aṣojúṣòfin kò lọ́wọ́ nínú rẹ̀.

    Ó ní ìgbìmọ̀ òun kò lọ́wọ́ nínú gbogbo ètò tí Sirika ṣe lórí àgbékalẹ̀ iléeṣẹ́ náà.

    Sirika tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bílíọ̀nù márùn-ún ni ìjọba àpapọ̀ pèsè fún àkànṣe iṣẹ́ náà àti pé ìròyìn òfégè ni pé bílíọ̀nù mẹ́tàlélọ́gọ́rin náírà ni ìjọba ná sí iṣẹ́ náà.

    Ó fi kun pé òun ti àwọn ṣe ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ náà ní ó kù díẹ̀ tí sáà àwọn máa parí ní àwọn tó ni iléeṣẹ́ náà ló wù láti ṣe ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ tí wọ́n sì pe àwọn láti wà níbẹ̀.

    Ó ní ìjọba kò san kọ́bọ̀ láti gbé ọkọ̀ náà wọ orílẹ̀ èdè yìí wá.

    Ṣáájú ni àwọn ènìyàn bu ẹnu àtẹ́ lu ìjọba àpapọ̀ lábẹ́ ìdarí Muhammadu Buhari nígbà tí wọ́n ṣe ìfilọ́lẹ̀ ọkọ̀ òfurufú Nàìjíríà nígbà tó ku ọjọ́ díẹ̀ tí yóò gbé ìjọba sílẹ̀.

  3. Àwọn babaláwo ni yóò padà máa ṣe ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní Nàìjíríà - Mimiko

    Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ondo, Olusegun Mimiko ti ṣèkìlọ̀ pé pẹ̀lú bí àwọn onímọ̀ ìṣègùn òyìnbó ṣe ń fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ lọ ilẹ̀ òkèrè le padà ṣe àkóbá ńlá fún ẹ̀ka ètò ìlera orílẹ̀ èdè yìí.

    Mimiko tẹmpẹlẹmọ pé tí Nàìjíríà kò bá tètè wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ àwọn dókítà tó ń fi orílẹ̀ èdè yìí sílẹ̀ ní ojoojúmọ̀, ó ṣeéṣe kí ọ̀rọ̀ náà bọ́ sódì tó bá máa fi tó ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá sí asiko yìí.

    Ó ní ó ṣeni láàánú pé ìjọba ń fi owó kún owó ẹ̀kọ́ àwọn dókítà yìí, síbẹ̀ ní kété tí wọ́n bá ti gba ìwé ẹ̀rí wọn ni wọ́n ń mórílé ilẹ̀ òkèrè.

    Níbi ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́jáde àkọ́kọ́ àwọn dókítà ilé ẹ̀kọ́ giga University of Medical Sciences, UNIMED tó wà ní ìlú Ondo, ìpínlẹ̀ Ondo ni Mimiko ti sọ̀rọ̀ yìí.

    Ó ní òun ṣe àgbékalẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ náà nígbà tí òun wà nípò gẹ́gẹ́ bí gómìnà, lójúnà àti sàmójútó bí kò ṣe sí àwọn tó gbero iru ǹkan bẹẹ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

    Gomìnà tẹ́lẹ̀ rí náà wárọ ìjọba láti tètè dìde sí ọ̀rọ̀ yìí nítorí kìí ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n fọwọ́ yẹpẹrẹ mú rárá.

    Bákan náà ló fi kun pé ìjọba nílò láti máa ṣe kóríyá fún àwọn dókítà kí wọ́n yé fi orílẹ̀ èdè Nàìjíríà sílẹ̀ mọ́.

    Ó tẹ̀síwájú pé tí ìjọba bá ń pèsè àwọn ohun tó le fa kóríyá fún àwọn dókítà yìí, wọn ò ní máa wá ilẹ̀ ọlọ́ràá lọ sí ilẹ̀ òkèrè mọ́.

    Mimiko ní ìjáfàra léwu lórí ọ̀rọ̀ náà nítorí bí a kò bá ṣọ́ra, ó ṣeéṣe kó jẹ́ wí pé ọ̀dọ̀ àwọn babaláwo ni àwọn aláìsàn yóò máa wá ìtọ́jú lọ tó bá yá.

  4. Sítòfù, hìjáàbù, àwọn ọkọ̀ ni ìjọba wá jí kó ní ilé mi - Matawalle

    Gómìnà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbésẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Zamfara, Bello Matawalle ti fẹ̀sùn kan ìjọba tó ṣẹ̀ṣẹ̀ gbá ọ̀pá àṣẹ láti tukọ̀ ìpínlẹ̀ náà fún ọdún mẹ́rin pé wọ́n wá ja òun lólè.

    Ní ọjọ́ Ẹtì ni ìjọba Zamfara lábẹ́ àkóso gómìnà Dauda Lawal ti ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) fi ìròyìn síta pé àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ya wọ àwọn ilé Matawalle níGusau àti Maradun tí wọ́n sì kó ọkọ̀ tó tó ogójì nílé rẹ̀.

    Àmọ́ nígbà tó ń fèsì sí ìgbésẹ̀ ìjọba náà nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ kan pẹ̀lú BBC, Matawalle níìwà búburú ni ìgbésẹ̀ náà.

    Ó ní hìjáàbù ìyàwó òun wà lára àwọn ẹrù tí ìjọba wá kó ní ilé òun.

    "Báwo ni ènìyàn kàn lè já wọ ilé onílé láì gba àṣẹ láì ṣe wí pé ìlú tí kò ní òfin là wà."

    Ó ní òun wà ní ìlú Abuja nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé, tí kò sì sí ẹnikẹ́ni tó sọ fún òun pé àwọn gba àṣẹ láti ilé ẹjọ́ láti ránṣẹ́ pé òun ti òun kọ̀."

    "Èyí tó dùn mí níbẹ̀ jù ni pé gbogbo yàrá àwọn ìyàwó mi ní ilé mi tó wà ní Gusau ni wọ́n gbọ̀n yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́, kódà wọ́n kó àwọn hìjáàbù lọ."

    Matawalle fi kun pé dípò tó yẹ kí ìjọba gbájúmọ́ ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Zamfara, ní ṣe ni wọ́n fẹ́ dá wàhálà òṣèlú sílẹ̀ láàárín ìlú.

    Ó ṣàlàyé pé gbogbo ọkọ̀ tí àwọn ènìyàn fún òun lásìkò ìpolongo ìbò ni ìjọba kó lọ àmọ́ òun kò ní jà láti gba àwọn ọkọ̀ náà padà nítorí òun lè rà àwọn ọkọ̀ míì gẹ́gẹ́ bí oníṣòwò ọkọ̀ tí òun jẹ́ kí òun tó di gómìnà.

  5. Ẹlẹ́gbẹ́ òkùnkùn tó bá ṣe ohunkóhun pẹ̀lú òkú mi yóò dara pọ̀ mọ́ mí lájùlé ọ̀run - Olubara

  6. Ṣé ẹ lè ló páàdì aláṣọ tí arábìnrin yìí ń rán láti ran àwọn obìnrin tí kò lówó páàdì òyìnbó?

  7. Tinubu fẹ́ ká darapọ̀ mọ́ ìjọba rẹ̀ sùgbọ́n àsìkò kú díẹ̀

    Gomina tẹlẹ rí ní ipinlẹ Kano Rabiu Musa Kwankwanso ti sọ pé ijiroro n lọ lọwọ lori didarapọ mọ ìjọba ààrẹ Tinubu.

    Olori NNPP Senator Rabiu Musa Kwankwaso sọ pe aare Bola Ahmed Tinubu fi ipò lọ oun ninu ijoba rẹ amọ o ni oun ko ti pa ọkàn pọ lori gbigba ipo naa.

    O fìdí ọrọ yi múlẹ lasiko to n ba BBC sọrọ nipa ipade to ṣe laipẹ yi pẹlu ààrẹ Tinubu.

    Nnkan bi wakati meji ní ìpàdé yi fi waye ni ọjọ Ẹti.

    Ijiroro pẹlu ààrẹ yi n wáyé lasiko ti aawọ n wáyé laarin ijoba tuntun Kano ati Gomina tẹlẹ rí Umar Ganduje.

    Ijiroro yi ṣàfihàn iru ibaṣepọ to wa laarin aare Tinubu ati itọka sí bí NNPP ti ṣe lè pawọpọ pẹlu ìjọba ààrẹ Tinubu.

  8. Ká ní mo pàdé Kwankwaso ní Aso Rock Villa ni, ó ṣeéṣe kí n gbá ojú ẹ̀ - Ganduje

    Gomina ana ni ipinlẹ Kano, Abdullahi Umar Ganduje ti sọ pe kani oun ati ẹni to di ipo naa mu ṣaaju oun , iyẹn Abdullahi Ganduje ba pade ara wọn ni ileeṣẹ aarẹ Naijiria, lọjọ Ẹti ti awọn mejeeji lọ ko ẹjọ ba Aarẹ ni, o ṣeeṣe ki oun fọọ leti.

    Ganduje sọrọ yii lasiko to fi n ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade rẹ pẹlu aarẹ Tinubu lọjọ Ẹti.

    Ganduje n bu ẹnu atẹ lu Kwankwaso lori ohun to pe ni igbesẹ gomina to wa lode nipinlẹ naa lọwọ, Yusuf Abba to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Kwankwaso, n gbe lati wo awọn ile kan nipinlẹ naa.

    Kwankwaso ni oludije ẹgbẹ oṣelu NNPP fun ibo aarẹ to kọja, ẹgbẹ oṣelu rẹ lo si bori ibo gomina ni ipinlẹ Kano.

    Bakan naa ni Ganduje pẹlu ti fi igba kan ri jẹ igbakeji fun Kwankwaso nigba to di ipo gomina mu ni ipinlẹ Kano, ki tirela to gba aarin wọn kọja.

    “Mo mọ pe o wa ni agbegbe ile nla yii ṣugbọn a ko tii pade. Boya Ká ní a lọ pade ni pẹrẹn, bóyá ìgbájú olóòyì ni ǹbá kó fún un.”

    Ganduje ṣalaye pe, boya lo pe ọjọ mẹta lẹyin ti Abba Yusuf wọle gẹgẹ bii gomina tuntun ni ipinlẹ naa lo ti wo awọn ile mẹrin to jẹ ajumọni laarin ijọba at’awọn aladani kan ni Kano.

    O ni oun ti fi ọrọ naa to ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa leti. Bakan naa lo ni oun ti ṣe alaye gbogbo bi nnkan ṣe lọ lori rẹ fun aarẹ Bọla Tinubu.

  9. Ààrẹ Bola Tinubu yọ ṣọ́ọ̀kì lẹ́sẹ̀ Gómìnà Báǹkì àpapọ̀ Nàìjíríà, Godwin Emefiele, Ó ní kó lọ rọọ́kún nílé

    Aarẹ orilẹede Naijiria, Bọla Ahmed Tinubu ti paṣẹ fun Gomina banki apapọ Naijiria (CBN), Godwin Emefiele pe ko lọ rọọkun nile naa.

    Aṣẹ aarẹ Tinubu farahan ninu atẹjade kan ti ọfiisi akọwe ijọba apapọ Naijiria fi sita lalẹ ọjọ Ẹti.

    Atẹjade naa tẹsiwaju lati ṣalaye wi pe, aarẹ gbe igbesẹ naa lati nitori iwadi to n lọ lọwọ lori ọfisi gomina banki apapọ naa ati awọn atunto to fẹ waye lori ẹkan iṣuna lorilẹede Naijiria.

    “Aarẹ Bọla Tinubu ti paṣẹ fun gomina Banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele CFR pe ko lọ rọọkun nile lẹyẹ o ṣọka.

    “Eyi n waye nitori iwadii to n lọ lowo lori ọfiisi rẹ ati atunto ẹka iṣuna ti ijọba n gbero lati ṣe.”

  10. Makinde fi òpópónà Akobo-Olorunda sọrí Gómìnà tẹ́lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Rivers, Nyesom Wike

  11. Ooni, Sultan, àwọn lọ́balọ́ba ṣèpàdé pẹ̀lú Tinubu

  12. Trump tún fojú ba ilé ẹjọ́, ó le ojú koko láì le fọhùn

  13. Ifá ti sọ̀rọ̀ lórí "subsidy" àti ìgbésẹ̀ ìjọba Naijiria

  14. Ẹran jíjẹ ti dèéwọ̀ o! Mọ̀ nípa ààrùn Anthrax tó kógbá ẹran wọlé lọ́jà

  15. Ààrẹ Tinubu buwọ́lu ọjọ́ orí ìfẹ̀yìntì tuntun fáwọn adájọ́

    Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ti buwọlu ọjọ ori ifẹyinti tuntun fun awọn adajọ lorilẹede Naijiria kuro ni ọdun marundinlaadọrin si aadọrin.

    Aarẹ Tinubu buwọlu abadofin afikun ọjọ ori ifẹyinti tuntun yii lẹyin ti awọn aṣofin apapọ buwọlu a a naa gẹgẹ bi ara awọn atunṣe to waye si iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999.

    Lara awọn adajọ ti ọrọ kan ni awọn adajọ ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria, ile ẹjọ kotẹmilọrun, ile ẹjọ giga apapọ ati ile ẹjọ to n gbọ awuyewuye laarin awọn ọṣiṣẹ ati agbanisiṣẹ.

    Bakan naa lawọn adajọ ile ẹjọ giga olu ilu Naijiria, ile ẹjọ giga ipinlẹ, ile ẹjọ kotẹmilọrun Sharia lolu ilu Naijiria, ile ẹjọ kotẹmilọrun kọkọkọ lolu ilu Naijiria, ile ẹjọ kotẹmilọrun Sharia tipinkẹ ati ile ẹjọ kotẹmilọrun kọkọkọ pẹlu yoo janfani afinkun baa

    Atẹjade kan ti Abiọdun Ọladunjoye fi sita, Aarẹ Tinubu tun Kede ipinnu iṣejọba rẹ lati ro ẹka iṣedajọ lagbara sii, latibọwọ fun ofin ati riro awọn oṣiṣẹ eto idajọ lagbara lati ṣe ojuṣe wọn .

  16. Ọmọdé mẹ́rin di èrò iléèwòsàn lẹ́yìn tí ọkùnrin kan fi ọ̀bẹ gún wọn ní France

    Eeyan mẹfa - ọmọde mẹrin ati agba meji ti farapa lasiko ti ọkùnrin kan fi ọ̀bẹ gún wọn ni orile-ede France.

    Iroyin sọ pe ipo ti ilera awọn eeyan naa wá ni iléèwòsàn buru pupọ.

    Annecy, ìlú kekere kan ti ko jìnà sí ẹnu ibodè France pẹlu Italy ati Switzerland, ni ìkọlu naa ti waye ni nnkan bi aago mẹ́wàá àárọ̀ ku díẹ̀.

    Gbàgede ìṣeré ni awọn ọmọ naa wa pẹlu àwọn òbí ati alagbatọ wọn nigba ti ọkùnrin naa kọlu wọn.

    Àwọn ọmọdé ni ọkùnrin naa dojú ọ̀bẹ rẹ̀ kọ, kò to gún baba arugbo kan níbi to ti n sa lọ lẹyin to gún awọn ọmọde tán.

    Ṣùgbọ́n ṣá, awọn ọlọpaa to tete dé sibi iṣẹlẹ naa yin ìbọn mọ ni ẹsẹ, ọwọ́ si tun tẹ ẹ.

    Ileesẹ ọlọpaa sọ pe ọmọ orilẹ-ede Syria ni ọkùnrin naa, to si n wa ọna lati jẹ anfaani àtìpó ni France.

    Àwọn aláṣẹ ko tii le sọ boya ìkọlu naa ni ọwọ́ àwọn agbesunmọmi ninu.

    Aarẹ Emmanuel Macron ṣapejuwe ikọlu naa gẹgẹ bi ìwà ojo, ati pe o ba France ni òjijì.

  17. Ọkọ mi kò le fàyè gba gbogbo ìrégbè tó ń ṣẹlẹ̀ lásìkò yìí ká ló wà láyé - Maryam Abacha

  18. 'Ìbínú ló jẹ́ kí n da omi gbígbóná lé ìyá "láńlọọ̀dù" mi lórí, ẹ ṣàánú mi'

  19. Bí Tinubu bá gbé “Palliative” silẹ̀, yóò dàrú bí ìgbà Covid-19 ni o! Ohun tó yẹ k’íjọba ṣe rèé – Onímọ̀ nípa ọrọ̀ ajé

  20. Pásítọ̀ tó yan àwẹ àgbàdèrò ọ̀run fáwọn ọmọ ìjọ yóò jẹ́jọ́ ìpànìyàn

    Ijọba orilẹede Kenya ni oun ti ri ẹri to kun oju iwọn lati fi pe Pasitọ Paul Mackenzie lẹjọ lori ẹsun didẹmi ọgọrọ eeyan legbodo.

    Pasitọ Mackenzie lo sọ fun awọn ọmọ ijọ rẹ loṣu diẹ sẹyin pe kí wọn gbadura ati awẹ lati lee lọ ba Jesu.

    Ọpọlọpọ awọn ọmọ ijọ rẹ lo ku si ori awẹ ọlọjọ gbọrọ yii

    Ko din ni oku awọn ọtalelugba o din mẹwaa lara awọn ọmọ ijọ rẹ ti awọn alaṣẹ ti ri bayii, kaakiri awọn saree ti wọn sin wọn si ninu aginju Shakahola.

    Aginju Shakahola yii ni Pasitọ naa tọkasi fun awọn ọmọ ẹyin rẹ gẹgẹ bi aginju to ni ọwọ pupọ.

    Awọn ẹgbẹta o le mẹtala miran ni wọn ṣi n wa bayii, ti awọn eeyan agbegbe naa ṣi n ṣe ọfọ awọn to ku.

    Minisita fun ọrọ abẹle ni Kenya, Kithure Kindiki sọ pe awọn ẹrí to dantọ ti wa bayii lati fi pe pasitọ naa at’awọnti wọn jumọ lẹdi apo pọ jofin.

    Minisita naa sọ loju opo Twitter rẹ pe ẹsun to nii ṣe pẹlu ṣiṣeku pa ọgọrọ eeyan ni wọn fẹ fi kan an.