Ramadan àti ìsìn ìrékọjà àwọn Krìstẹ́nì dá wàhálà sílẹ̀ ní Jerusalem
Awọn fidio kan ti gba ori ayelujara kan to n ṣafihan bi awọn ọlọpaa ilẹ Israel ṣe n lo ibọn ati igi lati fi ṣe iya fun awọn ara Palestine to n jọsin ti wọn si pa ala si ibi ti wọn ti n kirun ninu mọsalasi Aqsa.
Awọn ọlọpaa Israel naa ti fi fọnran tiwọn sita eyi to n ṣafihan bi awọn ara ilẹ Palestine ṣe n ju ohun abugbamu si gbọngan adura naa.
Awọn aworan to jade lẹyin iṣẹlẹ ṣafihan bi awọn tabili, aga ati ẹni adura ṣe fọnka sori ilẹ.
Agbala Mosalasi Aqsa/Haram al-Sharif ni ibi kẹta to mọ julọ ninu ẹsin Islam. Wọn tun maa n pe ibẹ ni Temple Mount, ibi to jẹ mimọ julọ ninu ẹsin awọn Judaism.
Latẹyin wa, ọgba mọsalasi naa ti maa n foju ri ikọ̀lu laarin awọn ara Palestine atawọn ikọ ologun Israel eyi to si n fa ọpọlọpọ aisi ifọkanbalẹ.
Ninu oṣu Karun ọdun 2021, ikọlu awọn Israel kan da ikọlukọgba alagbara kan silẹ fun odidi ọjọ mọkanla laarin Irael ati Hamas eyi tii ṣe ẹgbẹ awọn alakatakiti ẹsin Islam to n jọba ni Gaza.
Bakan naa lọdun to kọja, igba akọkọ ti Osu alapọnle ti Ramadan ati awọn eto ti awọn ẹya Jew ti to silẹ fun odidi ọsẹ kan lati ṣaami isin irekọja ja papọ lu ara wọn, ọpọlọpọ ija lo bẹ silẹ fun ọjọ pupọ lera lera ti o si gba ki awọn ọlọpaa Israel mojuto agbegbe naa ki wọn to sin awn arinrinajo wọ inu ọgba naa.
Wọn ni ṣe ni wọn ju okuta si ara ogiri ibi mimọ yii ti awọn Jew ti maa n gbadura.
Ẹwẹ, lọdun yii naa bayii, lati Ọjọru ọsẹ, ati pe fun opin ọsẹ meji to mbọ, ajọdun ọdun Ajinde ni fun awọn kan.
Gbogbo asiko ayẹyẹ ọdun yii lo maa n fa oju awọn arinrinajo igbafẹ mọra si ilu nla naa.
Ọgọta ẹgbẹrun eeyan lo yẹ ko de si ilẹ Israel lọsẹ yii gẹgẹ bi akọsilẹ to wa.
Bi ọgọọrọ musulumi ṣe n farahan fun adura ọjọ Jimoh keji ninu aawẹ Ramadan bẹẹ naa ni ero n tu wọ Jerusalem to si jẹ pe wọn n da ọna pọ mọra lati wọle si ilu mimọ naa.
“Eyi dara amọ o jẹ nnkan to le da wahala silẹ paapaa eyi ti awọn oloṣelu le fa”.
Ara ilẹ Pallestine to n taja sọ bẹẹ bo ṣe n ta abẹla fun awọn Kristẹni to n lọ si ibi iboji mimọ eyi ti wọn kọ sibi ti awọn ẹlẹsin Kristẹni nigbagbọ pe wọn ti kan Jesu m igi, si in si ati to ti jinde.
Ṣaaju wahala to bẹ silẹ ni Ọjọru ọsẹ, ilu Hamas ti pe fun ki awọn olujọsin ti ara wọn mọ inu mọsalasi Aqsa ti wọn wa lati le dena ipinu awọn alakatakiti ẹsin Kristẹni kan to fẹ lọ rubọ ẹran ewurẹ fun isin irekọja lori oke, eyi ti wọn gbagbọ pe aṣa inu bibeli kan ni.
Wn bẹrẹ si ni kọlu ara wọn lẹyin ti awn Palestine ti ara wọn m inu mọsalasi lẹyin adura Ramadan.
Awọn ọlọpaa lo wa le gbogbo ero danu ṣugbọn ọpọ wọn lo ṣi duro sinu ile.
Ọlọpaa ṣalaye pe wahala naa waye latọwọ awọn arufin atawọn oni jagidijagan ti wọn ni wọn tabuku mọsalasi.
Awọn alaṣẹ ilẹ Israel ti fi ọrọ sita pe ki awọn eeyan gbiyanju lati pa ẹtọ fun ijọsin mọ lọna to ba wu ẹnikẹni.
Ilu mimọ yii ni awọn musulumi ri gẹgẹ bi ibi ti Anọbi Mohammed ti goke re ọrun, ibi yii kan naa ni awọn Kristẹni naa bọwọ fun gidi gan gẹgẹ bi ibi tẹmpili meji pataki to wa ninu Bibeli.