You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Àwọn adarí ní Naijiria kò nílò láti lọ sí òkè òkun fún ìwòsàn- Aisha Buhari

    Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ni ko yẹ ki awọn adari ni Naijria maa lọ si oke okun fun ayẹwo ati itọju ara wọn.

    Aisha Buhari sọ eyi lasiko ti wọn n se ifilọlẹ ile iwosan ninu ileeṣẹ aarẹ ni ilu Abuja, ni Naijiria.

    Iyawo aarẹ Buhari naa ni ọdun mẹfa sẹyin ni oun ti gbero lati da ilewosan naa silẹ lati bii ọdun mẹfa sẹyin.

    O ni asiko naa ni ọkọ rẹ lo ọpọlọpọ igba ni oke okun fun ilera ara rẹ ti o ku diẹ kaato fun.

    Aisha ni nibayii ni wọn ti kọ ileewosan naa tan, awọn adari ni Naijiria ati mọlẹbi wọn ko nilo lati lọ si oke okun fun iwosan.

    Amọ o ni wọn nilo dokita to kunjuwọn ni awọn ileewosan naa ni Naijiria.

    Eyi n waye lasiko ti awọn dokita lorilẹede Naijiria gunle iyanṣẹlodi lati lori owo osu wọn ti ko gbe ppẹẹli rara si oke.

  2. Oluwatoyin Sakirat di olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà

    Ààrẹ Muhammadu Buhari ti buwọ́lu ìyànsípò, Oluwatoyin Sakirat Madein gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà fún ortílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

    Ìyànsípò náà ló jẹ jáde nínú lẹ́tà kan tí olórí òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, Dókítà Folasade Yemi-Esan fi léde.

    Ó ní ààrẹ Buahri ti buwọ́lu ìyànsípò náà.

    Ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹta ọdún 1965 ni wọ́n bí Oluwatoyin Sakirat ní Iperu Remo, ìjọba ìbílẹ̀ Ikenne ní ìpínlẹ̀ Ogun.

    Ṣaájú ìyànsípò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣirò owó àgbà Nàìjíríà, Sakirat ni adarí ẹ̀ka ìsúná ní ọ́fíìsì olórí òṣìṣẹ́ orílẹ̀ èdè yìí.

    Oluwatoyin Shakirat ló ń gba ipò yìí lọ́wọ́ Ahmed Idris tó jẹ́ olùṣirò owó tẹ́lẹ̀ tí ààrẹ Buhari ní kó lọ rọ́kún nílé fẹ́sùn wí pé ó kojú ẹ̀sùn wí pé ó lọ́wọ́ nínú ìwà àjẹbánu tí owó rẹ̀ tó bílíọ̀nù 109 náírà.

  3. Wo àlàkalẹ̀ àwọn ètò fún ayẹyẹ ìbúrawọlé Tinubu gẹ́gẹ́ bí ààrẹ Nàìjíríà

  4. Wo bí o ṣe lè lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, 'App' tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo gbé kalẹ̀ láti mójútó ètò kólẹ̀-kódọ́tí

  5. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ arákùnrin tí ọlọ́pàá la igi mọ́ lórí, gba ọ̀kadà rẹ̀ l’Eko, wọ́n ní ìjìyà tó tọ́ ti bẹ̀rẹ̀ fún wọn

  6. Àwọn nǹkan mẹ́wàá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Subomi Balogun tó dolóògbé nìyí

  7. Ìdí tí aáwọ̀ èmi àti Tunde Kelani ṣe dá "Part 2 Ti Oluwa Nile" dúró tí mi ò tún gba owó kankan lára fíìmù náà rèé- Baba Wande

  8. Òjò àrọ̀rọ̀dá pa ènìyàn 13 ní Italy

    Gomina agbegbe Raenna ni orilẹede Italy ti kede pe ojo arọrọda iru eleyii ti wọn ko ri iru rẹ ri ti ṣẹlẹ ni agbegbe wọn.

    Wọn ni awọn ko I tii ri iru iṣẹlẹ bẹẹ laarin ọgọrun ọdun.

    Gomina naa ti wọn pe ni Mayor Mishel Dafaskali ni ojo arọrọda naa bai le ati ohun ini awọn ọmọ Naijria.

    Bakan naa ni Mayor naa ni o kere tan eniyan mẹtala lo ti gbẹmi mi ninu iṣẹlẹ naa ni agbegbe Emilia Romagma, ti ẹgbẹgbẹrun si ti fi ile ati ọna wọn silẹ nitori iji lile naa

    O kere tan odo mejila lo ti kun akunfaya nibẹ

    Iwadii fihan pe ẹgbẹgbẹrun biliọnu dọla lo ti ṣofo ninu iṣẹlẹ naa, paapaa ni ẹka eto ọgbin.

  9. Mi ò ní ibòmíràn láti pè ní ilé yàtọ̀ sí Naijria- Ààrẹ Buhari

    Aarẹ orilẹede Naijiria, Muhammadu Buhari ti ni ko si ibomiran to jẹ ile fun oun yatọ si orilẹede Naijiria.

    Aarẹ Buhari sọ eyi lasiko to gbalejo Asoju Ilẹ Gẹẹsi, Richard Hugh Montgomeru ati Aṣoju ilẹ Sri Landa Velupillai Kananathan ni ileeṣẹ aarẹ ni ilu Abuja,

    Buhari ni awọn ọrọ ti oun sọ pẹlu Ọba Charles III ni asiko ti wọn sepade to si beere lọwọ rẹ pe se o ni ile si Ilẹ Gẹẹsi.

    Amo Buhari ni esi ti oun fun Ọba naa nipe oun ko ni ile kankan yatọ si Naijria.

    Bakan naa ni aarẹ gba asoju ilẹ Gẹẹsi naa ni imoran pe wọn gbọdọ tẹsiwaju nipa bibọwọ fun asa ati ise awọn miran, eleyii to mu idagbasoke de ba wọn.

    Aarẹ Buhari wa fi da wọn loju pe eto ibaraẹni ṣọrẹ laarin orilẹede mejeeji yoo tẹsiwaju, ti wọn yoo si maa mu eto ọrọ aje ati idagbasoke ni ọkunkundun.

    Ninu ọrọ tirẹ, aṣoju orilẹde Sri Lanka sọ fun aarẹ Buhari pe ijọba awọn yoo ṣiṣẹ papọ pẹlu ijọba Naijria lati gbogun tie to aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria.

  10. ‘Ẹ ṣe ìwádìí adarí àjọ EFCC, Abdulrasheed Bawa fún ẹ̀sùn jẹgúdújẹrá’

  11. 'Ọdún 500 sẹ́yìn ni ọmọ Ọba Aláàfin Oyo tẹ ìlú Ondo dó'

  12. Gómìnà àkọ́kọ́ rèé tó buwọ́lù òfin láti dènà lílo TikTok ní Amẹ́ríkà

    Ipinlẹ Montana ṣetan lati di ipinlẹ orilẹ-ède Amẹrika akọkọ ti yoo fofin de lilo oju opo TikTok lori ẹrọ alagbeka aladani.

    Gomina Greg Gianforte lọ buwọ́lù ofin to de lilo TikTok lọjọru.Yoo sí gbera sọ gẹgẹ bí ofin ni ọjọ kini oṣu kini.

    Oju opo yi sọ pé ìgbésẹ yi tako iwe ofin Amẹrika to de ẹtọ awọn eeyan ipinlẹ Montana.

    Kaakiri agbaye l'awọn alaṣẹ ti n foju sunukun wo TikTok lori ipaiya pe o le fi ìròyìn pataki nipa awọn eeyan ṣọwọ sí ìjọba China.

    Arakunrin Gianforte, to jẹ ọmọ ẹgbẹ Republican sọ fún àwọn aṣofin pe fifi ofin de lilo TikTok patapata yoo mu itẹsiwaju ba "ojúṣe ajumọṣe lati daabo bo awọn eeyan ipinlẹ Montana lọwọ ifimufinlẹ ẹgbẹ Communist China"

  13. Àwọn afurasí daran-daran kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú, èèyàn 87 papòdà

    Iye eeyan to ku nibi ikọlu Ọjọ Iṣẹgun ni ijọba ibilẹ Mangu, ipinlẹ Jos ti pọ sii, o ti di marunlelọgọrin ti wọn si tun n wa awọn to sọnu bayii ni awọn ilu to faragba.

    Aarẹ ẹgbẹ idagbasoke awọn ara Mwaghayul ni agbegbe naa, Joseph Gwankat sọ eyi di mimọ lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ lẹyin ipade kan ti wọn ṣe lori ọrọ abo ni Aafin olori ilu Mangu.

    Gwankat sọ pe ọpọlọpọ ilu ni awọn afurasi daran-daran ṣe ikọlu si lẹẹkan naa eyi to fa iku ọpọ eniyan nigba ti wọn tun dana sun awọn ile ti wọn si ba oko awọn eniyan jẹ.

    Awọn obinrin ni agbegbe naa ti ṣe iwọde ifẹhonuhan lọ si Aafin Ọba wọn nibi ti wọn ti n ṣe ipade pẹlu awọn ẹṣọ alaabo, awọn adari ẹkun atawọn oṣiṣẹ ijọba eyi ti igbakeji gomina, Ọjọgbọn Sonni Tyoden dari wa sibẹ lati lee boju to ipenija abo ni ijọba ibilẹ naa.

    Ni bayii, lẹẹkan naa ni wọn n sin oku awọn to dagbere faye nibi ikọlu naa.

  14. Màá gbé ààrẹ Buhari lọ sí iléẹjọ́ tó bá tún yá $800 million – Sẹnétọ̀ Ali Ndume

    Senetọ Ali Ndume ti ni oun yoo gbe aarẹ Muhammadu Buhari lọ si ileẹjọ to ba tun ya $800 million, owo ti o ni oun fẹ ya naa.

    Ni Ibẹrẹ Osu Karun un ni aarẹ Buhari fi dọcumẹnti ranṣẹ si ile igbimọ aṣofin wi pe ki wọn gba oun laaye lati ya owo lọwọ banki agbaye lati jẹki opin de ma iya ati iṣẹ ti yoo ba awọn ọmọ Naijiria finra ti wọn bayọ owo iranwọ epo bẹntirol ti wọn n pe ni subsidy.

    Osu Kẹrin, odun yii ni ijọba kede pe awọn nilo owo ẹyawọ 800 milion dollar lọwọ Banki Agbaye fun awọn ọmọ Naijiria miliọnu aadọta ti iya ati iṣẹ n ba finra.

    Ọrọ yii ti da aigbọraeniye silẹ ni Ile Igbimọ Aṣofin, ti ṣẹnetọ Ali Ndume si pẹlu awọn to sọrọ tako yiya owo naa.

    Awọn asofin kan ni ẹyawo naa gbọdọ se anfaani fun awọn araalu, amọ awọn ti ko faramọ ni ko lee se ohunkọhun fun awọn araalu, wọn kan fẹ ko owo naa jẹ ni.

    Ninu ọrọ rẹ sẹnetọ Ali Ndume ni awọn kan ni ijọba aarẹ Buhari ni yoo jẹ anfaani owo naa, ti awọn araalu yoo si jẹ iya rẹ lasiko ti ijọba ba n da owo naa pada.

    O ni ti alaye oun ko ba tẹ ti aarẹ Buhari lọrun lori igbese naa, o le gba ileẹjọ lọ

    Bakan naa lo ni ti aarẹ Buhari bag be igbesẹ lati ya owo naa, awọn yoo pada ni ileẹjọ nitori inira ni yoo jẹ dun araalu.

  15. ‘’Ààrẹ Buhari yára gbé ìjọba sílẹ̀ kóo gbe fún mi’’

    Minisita fun eto ẹkọ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Obiageli Ezekwesili ti ni ki aarẹ Buhari gbe ijọba silẹ, ki wọn gbe ijọba fun oun nitori gbogbo ikuna isejọba rẹ.

    Ezekwesili lo sọ bẹ̣ẹ ninu atẹjade to fi si oju opo ikansiraẹni, Twitter rẹ

    O bu ẹnu atẹ lu ijọba aarẹ Buhari lori eto aabo to dẹnukọlẹ ni Naijiria, ati bi o se kuna lati pese aabo to peye fun awọn araalu.

    O ṣapejuwe Buhari gẹgẹ bi ọgagun ti ko lee gbera nilẹ ni oju ogun.

    Bakan naa lo kesi awọn ololufẹ aarẹ Buhari lati wa se atilẹyin fun oun ti Buhari bag be ijọba kalẹ fun oun.

    O fikun un pe igbẹkẹle oun ninu isejọba aarẹ Buhari ti jasi asan, ti oun ko si reti oun didara kankan mọ ni isejọba naa.

    Minisita fun eto eko naa ni ijọba Buhari kuna patapata lati pese eto aabo to peye fun awọn araalu.

    Laipẹ yii ni ikọlu waye ni Anambra to si gbẹmi awọn eniyan.

    Bakan naa ni ikọ Boko Haram si n sọsẹ ni iha Ariwa Naijiria pẹlu awọn agbebọn to n ji awọn eniyan gbe kaakiri orilẹde Naijiria lai si ọna abayọ.

  16. Ó bàmí lọ́kàn jẹ́ nítorí kò tọ́sí ìjọba US láti pe Bola Tinubu lórí fóònú rẹ̀ – Atiku

    Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oselu PDP, Abubakar Atiku tib u ẹnu atẹ lu bi ijọba orilẹede Amẹika se pe Bola Tinubu lori aago lati jọ jiroro papọ.

    Ọpọlọpọ awuyewuye loti tẹlẹ bi minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Amẹrika to jẹ akọwe ijọba, Anthony Blicken se pe Tinubu lori aago lati fi aduroti wọn han fun saaju iburawọle gẹgẹ bi aarẹ orilẹede Naijiria.

    Atiku ni itiju lo jẹ fun awọn ọmọ Naijiria nitori orilẹede Amẹrika buwọlu idibo to gbe aarẹ ti wọn dibo yan wọle, ti ọpọ si Gbagbo pe ayederu ibo lo gbe oludije ẹgbẹ oselu APC naa wọle.

    O ni ko yẹ ki ijọba Amerika pe Bola Ahmed Tinubu lati se atilẹyin fun.

    Ẹwẹ, ọjọru ni Blinken gbe Tinubu lori aago lati fi idunnu wọn han lati ṣiṣẹ pẹlu ijọba tuntun naa, ki ibasepọ to dan mọnran le wa laarin orilẹede mejeeji.

    Bakan naa ni Tinubu fesi pe awọn yoo tesiwaju lati ri pe ibasepọ to lamilaaka wa laarin orilẹede Naijiria ati ilẹ Amerika lasiko isejọba tirẹ.

    Saaju ni orilẹede Amerika ti ni awọn yoo gbegile iwe irina awọn ti wọn doju eto idibo gbogboogbo ni Naijiria bolẹ ni ọdun 2023, ti wọn si ni wọn ko ni lee wọ orilẹede Amerika.

  17. Àwọn dókítà ní Naijiria fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wọn

  18. Ta ni yóò ṣojú ẹgbẹ́ Labour Party níwájú ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ dá wàhálà sílẹ̀ nílé ẹjọ́

  19. Orí kó Ọmọọba Harry àti Meghan yọ́ nínú ìjàmbá ọkọ̀

    Ọmọọba Harry ti United Kigdom, ìyàwó rẹ̀ àti ìyá ìyàwó rẹ̀ ni orí kó yọ nínú ìjàmbá ọkọ̀ kan nígbà tí àwọn ayàwòrán ń téle wọn.

    Agbẹnusọ ọmọọba náà nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé nígbà tí Ọmọọba àti [yàwó rẹ̀ ń kúrò níbi ayẹyẹ kan ní New York lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.

    Agbẹnusọ ọmọọba náà ní ó lé ní wákàtí méjì tí tí àwọn ẹni náà fi lé wọn.

    Ó ní èyí ṣokùnfà tí ọkọ̀ ọmọọba náà fẹ́ lọ forí sọ àwọn ọks mìíràn àti àwọn ènìyàn, tó fi mọ́ àwọn ọlọ́pàá lórí títì.

  20. Ẹ pàdé Manuella, ọmọ ọdún méje tó ń ṣe àkàrà òyìnbó 'cake'