Ilé aṣòfin àgbà ṣe ìpàdé pàjáwìrì lọ́jọ́ Àbámẹ́ta
Ààrẹ ile aṣòfin àgbà Naijiria , ti salaye idi ti wọn fi ṣe ipade pajawiri lọjọ Abamẹta.
Ninu atẹjade to fi si ori ayelujara Twitter, Sẹnetọ Ahmad Lawan sọ pe awọn gbé igbesẹ naa lati le fi ontẹ lu afikun owo isuna ti ìjọba gbe wa siwaju wọn.
Gẹgẹ bo se sọ, o ni "bayii kọ ni a ṣe ma n ṣe ipade wa, sugbọn o jẹ dandan fun wa lati buwọlu eto owo isuna tuntun nitori pe yoo ti pẹ ju ti yoo ba fi di oṣù Kẹfà.
Àwọn Sẹnetọ tuntun ni yoo wa nile aṣòfin lasiko naa.
Sẹnetọ Lawan salaye pe awọn owo ti wọn o fi ṣe àtúnṣe awọn afárá ati oju ọna ti àgbàrá òjò ba jẹ lọdun to kọja, lo wa ninu iwe isuna naa.
"Tí a ba kọ ta o fi ontẹ luu bayii, yoo ti pẹ ju ninu osu kẹfà nigba ti òjò yoo ti ma a rọ̀ púpọ̀.
Igba keji rèé ti ile aṣòfin ṣe agbeyẹwo isuna naa, wọn si ti fà á le igbimọ ti yoo mojuto o lọwọ.