You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Asòfin tí wọ́n sẹ̀sẹ̀ búrawọlé fún kú lójijì

    Asofin Garba Madami to n soju ẹkun idibo Kaduna ni Ile Igbimọ asofin nipinlẹ Kaduna ti fi aye silẹ.

    Arakunrin naa lo n soju agbegbe Chikun lo ku ni Ọjọ Satide, leyin to pe ọjọ mẹrin ti wọn burawọle fun gẹgẹ bi aṣofin.

    Ki o to doloogbe lo ti di ipo alaga ijọba ibilẹ Chikun mu, ni ipinlẹ Kaduna.

    Bakan naa lo ti di ipo kọmisọnna tẹlẹri fun ọrọ eto ati isuna ni ijọba ipinlẹ Kaduna.

    Ko tan sibẹ, o ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi olubadamọran fun gomina tẹlẹri nipinlẹ Kaduna to ti doloogbe, Patrick Yakowa.

    Ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ Kaduna, Sẹnetọ Uba Sani ti ni iṣẹlẹ iku naa ya oun lẹnu kọja ala.

    Gomina naa ninu atẹjade to fi sita ba ẹbi, ara ati ọrẹ oloogbe naa kẹdun, to si sapejuwe oloogbe naa gẹgẹ bi eniyan tutu ti wọn mọ fun alaafia.

    Gomina naa wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ oloogbe naa si afẹfẹ rere, ko si fun awọn mọlẹbi ni ore- ofẹ lati la asiko yii kọja.

  2. Mo ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn olùdásílẹ̀ Boko Haram, wọ́n sì sọ ìdí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ fún mi - Obasanjo

  3. Kò sí ọba kankan nílẹ̀ Yorùbá tó le fọwọ́ sọ̀yà pé Ifá ló yan òun – Oluwo

  4. Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ lárìnlọọ̀dù tó jẹ́ agbódegbà fáwọn adigunjalè tó pa bàbá, fipa bá ọmọ rẹ̀ méjì lòpọ̀

  5. Àwọn ọmọ Naijiria fún Ààrẹ Bola Tinubu lórúkọ tuntun nítorí àwọn ìgbésẹ̀ tó ń gbé

  6. Àdó olóró bú bí àwọn olórí orílẹ̀-èdè láti Africa ṣe dé Ukriane láti pẹ̀tú sí ogun

    Olori orilẹ-ede meje lati Africa lo ti rinrinajo lọ si Ukraine lati pẹtu si ogun to n waye laarin Ukraine ati Russia.

    Awọn olori naa lati South Africa, Egypt, Senegal, Congo-Brazzaville, Comoros, Zambia, ati Uganda, yoo kọkọ ṣe ipade pẹlu Aarẹ Volodymyr Zelensky lọjọ Ẹti, ati Aarẹ Vladimir Putin lọjọ Satide.

    Aarẹ Cyril Ramaphosa ti South Africa lo ṣe olori ikọ olubẹwo naa.

    Ṣugbọn o dabi ẹni pe abẹwo wọn yii waye lasiko ti ko yẹ. Idi ni pe o n waye lasiko ti Kyiv bẹrẹ jiju awọn ado oloro si Ukraine.

    Lati igba ti ogun ti bẹrẹ laarin orilẹ-ede mejeeji ni ọwọn gogo ti ba awọn ounjẹ onikoro to n wọle si Africa alti Ukraine, ati ajilẹ (fertiliser) lati Russia – eyi to ti fa ọwọn ounjẹ.

    Amọ, ko pẹ ti awọn olori orilẹ-ede Africa ọhun gunlẹ si ilu Kyiv, olu ilu Ukraine, ti Russia ju ado oloro si afẹfẹ.

    Olori ilu Kyiv, vitali Klitschko sọ pe ni agbegbe Podilsky ni ibugbamu naa ti waye, pẹlu alaye pe ọpọlọpọ ado oloro lo ṣi wa loju ọna.

    Ṣaaju ni ijọba Ukraine fi ikilọ sita pe ibugbamu yoo waye. Ikilọ naa waye lẹyin ti ileeṣẹ ologun ofurufu Ukraine sọ pe ọpọ ado oloro Kalibr to jẹ ti russia ni wọn ti pese si oju ofurufu lati Black Sea, ti wọn si ti n lọ si ariwa Kyiv lati bu gbamu.

    Iru abẹwo pipẹtu si ija yii ko waye ri lati ọdọ awọn olori ni Africa.

    Oludari ajọ International Crisis Group (ICG), Murithi Mutiga sọ pe iru idasi yii lati ilẹ mii yatọ si Europe jẹ nnkan to ni apẹẹrẹ.

    Minisita fun eto aabo ni Ukraine, Dmytro Kuleba ti kọ ọrọ kan si ori ayelujara Twitter rẹni ede Gẹẹsi pe "owe ni Russia fi awọn ado oloro to ju si Kyiv pa fun awọn olori orilẹ-ede Africa to wá, pe ogun ni oun fẹ, kii ṣe alaafia."

  7. Ọ̀sẹ̀ kan péré lẹ ní láti fi gbé ìjábọ̀ yín lórí dídènà omíyalé agbára ya ṣọ́ọ̀bù kalẹ̀ - ìjọba àpapọ̀ sáwọn gómìnà

    Ìjọba àpapọ̀ ti fún àwọn gómìnà tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù le se àkóbá fún ní ọ̀sẹ̀ kan láti fi àbọ̀ ìwádìí wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ránṣẹ́.

    Fífún àwọn gómìnà ní gbèdéke ọ̀sẹ̀ kan yìí kò ṣẹ̀yìn láti wá ojútùú sí bí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ṣe máa ń ṣọṣẹ́ ní àwọn ìpínlẹ̀ kan ní ọdọọdún.

    Lásìkò ìpàdé ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà tó wáyé lọ́jọ́bọ̀ ni ìjọba gbé ìdarí yìí kalẹ̀.

    Ìpàdé ọ̀hún, èyí tí igbákejì Ààrẹ, Kashim Shettima darí rẹ̀ ní ó pọn dandan fún ìjọba láti tètè mọ ọ̀nà tí wọn yóò gbà láti fi kojú ẹ̀kúnwọ́ omi kó tó di wí pé ó wáyé rárá.

    Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dógún péré ló ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ìjábọ̀ wọn ṣọwọ́ sí ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni márùn-ún tí ìjọba àná gbé kalẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

    Bello ní wí pé àwọn ènìyàn tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ti ṣàkóbá fún sẹ́yìn tí kò ì tíì rí nǹkan ìdẹ̀kùn gbà kò ṣẹ̀yìn bí àwọn ìpínlẹ̀ ṣe kọ̀ láti fi ìjábọ̀ wọn ránṣẹ́.

    Ó ṣàlàyé pé ìjọba àpapọ̀ le dènà ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù tí àwọn tí ọ̀rọ̀ ọ̀hún kan bá tètè dìde sí ojúṣe wọn.

    Bákan náà ló tẹ̀síwájú pé àwọn àjọ tó máa ń wòye ojú ọjọ́ ti ṣe ojúṣe ti wọn, tí wọ́n sì ti ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ìpínlẹ̀ tí ọ̀rọ̀ náà kan gidi.

    "Ó kù sọ́wọ́ àwọn ìpínlẹ̀ yìí láti tètè fi àbọ̀ ìwádìí wọn ṣọwọ́ sí ìjọba àpapọ̀ ní kíákíá kí wọ́n lè tètè bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti dènà ìṣẹ̀lẹ̀ yìí."

    "Ìgbìmọ̀ ti fẹnukò pé gbogbo ìpínlẹ̀ gbọ́dọ̀ fi ìjábọ̀ wọn ránṣẹ́ ní ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀ lójúnà à ti dènà ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ní Nàìjíríà lọ́dún yìí."

  8. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọ́kọ́ OAU tí wọ́n bá òkú rẹ̀ nílé àkọ́kù

    Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Osun ni àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ohun tó ṣe okùnfà ikú akẹ́kọ̀ọ́ onípele àkọ́kọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì Obafemi Awolowo University, Ile-Ife, Treasure Salako.

    Ní ọjọ́rú ni ìròyìn ní wọ́n bá òkú Treasure ní ilé àkọ́kù kan ní agbègbè Lagere, Ile Ife, ìpínlẹ̀ Osun.

    Bákan náà ni wọ́n ní wọ́n bá ìgò ogun apẹ̀fọn sniper ní ẹ̀gbẹ́ òkú ọmọbìnrin náà tí ọ̀pọ̀ sì ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

    Àmọ́ agbenusọ ọlọ́pàá Osun, Yemisi Opalola nígbà tó ń bá iléeṣẹ́ PUNCH sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú ọmọbìnrin náà.

    Opalola ní àwọn ti gbé òkú Treasure sí ilé ìgbókùúpamọ́sí tí ilé ìwòsàn olùkọ́ni OAUTH, Ile Ife.

    Ó ní nítorí àwọn nǹkan tí àwọn ènìyàn bá lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkú náà ni wọ́n fi ń rò wí pé bóyá ó pa ara rẹ̀ ni.

    Ó ṣàlàyé pé àwọn máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé wọ́n ṣe àyẹ̀wò òkú náà láti le fìdí ohun tó gba ẹ̀mí Treasure.

    Ó fi kun pé gbogbo àwọn nǹkan tó bá yẹ kí àwọn ṣe ni àwọn máa gbé ìgbésẹ̀ rẹ̀ láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀.

    Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, alukoro OAU, Abiodun Olanrewaju ní kìí ṣe inú ọgbà ilé ẹ̀kọ́ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wáyé tó sì bá àwọn òbí ọmọbìnrin náà kẹ́dùn lórí àdánù ńlá náà.

    Olanrewaju ní ikú Treasure kò dùn mọ́ àwọn aláṣẹ ilé ẹ̀kọ́ náà nínú rárá.

    Bákan náà ló rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù àti àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀ láti máa ṣe àmójútó ara wọn, kí wọ́n sì máa wòye ẹni tó bá wà ní ẹ̀gbẹ́ wọn dáradára.

    Ó fi kun pé nǹkan tí àwọn gbọ́ ni pé ọmọbìnrin náà ń la àwọn ìdojúkọ kan kọjá èyí tó fa ìporúru ọkàn fún un bóyá nítorí náà ló ṣe gba ẹ̀mí ara rẹ̀.

    Ó ní "a bá àwọn òbí Treasure kẹ́dùn, kò yẹ kí ẹnikẹ́ni gbé irú ìgbésẹ̀ yìí bí ó ti wù kí nǹkan tí onítọ̀hún bá ń là kọjá ṣe lè lágbára tó."

  9. "Ọkùnrin kan pàdánù ìyàwó rẹ̀ méjì àti ọmọ márùn ún sínú ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi Kwara"

  10. Abdulrasheed Bawa ti wà ní àhámọ́ wa fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò - DSS

    Alága àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu, EFCC, Abdulrasheed Bawa ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ ìyẹn DSS.

    Lẹ́yìn tí Ààrẹ Tinubu fọwọ́ òsì ilé júwe fún Bawa ni DSS ránṣẹ́ pè é láti wá wí tẹnu rẹ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n kà si lọ́rùn.

    Ìròyìn ní alẹ́ pátápátá lọ́jọ́rú ni Bawa balẹ̀ sí àgọ́ àwọn DSS náà.

    Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya, nínú àtẹ̀jáde kan fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Bawa ti wà ní àhámọ́ àjọ àwọn.

    Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àwọn ti ń ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún Bawa lórí àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

    "DSS ti ránṣẹ́ pé alága EFCC tí Ààrẹ ní kó lọ rọ́kún nílé."

    "Bawa ti wà ní àgọ́ wa báyìí, àwọn nnkan tí a torí rẹ̀ pe Bawa kò ṣẹ̀yìn àwọn ìwádìí tó ń lọ lọ́wọ́ nípa rẹ̀." Afunanya sọ nínú àtẹ̀jáde náà.

  11. Tinubu fọwọ́ òsì júwe ilé fún alága EFCC, Abdulrasheed Bawa

    Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fọwọ́ òsì júwe ilé fún ọ̀gá àgbà àjọ tó ń rí sí ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè yìí, ìyẹn EFCC, Abdulrasheed Bawa.

    Tinubu ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé fún àìní gbèdéke ọjọ́ bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

    Ààrẹ ní nítorí à ti fún àwọn tó ń ṣe ìwádìí Bawa láàyè láti ṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́ ni òun fi ní kí Bawa lọ rọ́kún nílé.

    Ìgbésẹ̀ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí wọ́n fẹ̀sùn lọ́kan-ò-jọ̀kan, èyí tó lágbára kan Bawa.

    Àtẹ̀jáde kan látọwọ́ agbenusọ akọ̀wé ìjọba orílẹ̀ èdè yìí, Willie Bassey ní Ààrẹ ní kí Bawa kó gbogbo àkóso àjọ náà lé adarí ètò gbogbo lọ́wọ́ títí tí wọ́n máa fi parí ìwádìí Bawa.

    Ta ni Abdulrasheed Bawa?

    Abdulrasheed Bawa ni ẹni tí ọjọ́ orí rẹ̀ kéré jùlọ tí wọ́n máa yàn gẹ́gẹ́ bí ọ̀gá àgbà àjọ EFCC láti ìgbà tí wọ́n ti dá àjọ náà sílẹ̀ lọ́dún 2003.

    Ọmọ ogójì ọdún ni Bawa wà nígbà tó fi máa gba ipò náà nínú oṣù Keje ọdún 2020 lẹ́yìn tí Ààrẹ àná, Muhammadu Buhari yọ Ibrahim Magu lórí ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu.

    Láti ọdún 2005 ni Bawa ti gba iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọ́físà ní EFCC.

    Òun ni ó ṣe ìwádìí ẹ̀sùn màkàrúrù owó tabua tí wọ́n fi kan Mínísítà tẹ́lẹ̀ rí fọ́rọ̀ epo rọ̀bì, Diezani Alison-Madueke.

    Ìmọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ló kẹ́kọ̀ọ́ gboyè rẹ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ gíga fásitì, kó tó tún kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè fún ẹ̀kọ́ onípò kejì.

  12. Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún tí kò bá sọ Nàíjíríà s‘ógun abẹ́lé kejì

  13. Ilé ẹjọ́ sọ ọkùnrin sẹ́wọ̀n gbére fẹ́sùn pé ó fipá bá àwọn ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọmọdé mẹ́ta lòpọ̀

    Ilé ẹjọ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ìfipábánilòpọ̀ àti àwọn ẹ̀sùn tó fara pẹ tó wà ní Ikeja, ìpínlẹ̀ Eko ti sọ oníṣòwò kan Emeka Orisakwe sí ẹ̀wọ̀n gbére mẹ́ta.

    Èyí kò ṣẹ̀yìn bí ilé ẹjọ́ ní ọkùnrin ọ̀hún jẹ̀bi ẹ̀sùn fífi ipá bá àwọn ọmọ bíbí inú rẹ̀ mẹ́ta,tó jẹ́ ọmọdé sùn.

    Ilé ẹjọ́ ní ọjọ́ orí àwọn ọmọ ni ọmọ ọdún méjì àti ọmọ ọdún mẹ́fà kan.

    Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn láti ilé iṣẹ́ ìròyìn News Agency of Nigeria (NAN) ṣe sọ, Adájọ́ Abiola Soladoye ní gbogbo ẹ̀rí tó wà níwájú àwọn fi hàn pé bàbá náà jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.

    Adájọ́ Soladoye ní ọ̀dájú ni Orisakwe, pé ìdí nìyí to fi ní kí ìyàwó dákẹ́, tó sì ń wá ẹ̀rí láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìyàwó òun ní ọdẹ orí.

    Ó ní ó jẹ́ òun ìbànújẹ́ pé ọkùnrin náà le hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ sí àwọn ọmọ tó bí fúnra rẹ̀.

    Bákan náà ni adájọ́ tún bu ẹnu àtẹ́ lu àbúrò ọkùnrin náà tó wà jẹ́rìí nílé ẹjọ́, tó sì mú ìwé ẹ̀rí ayédèrú wá sí ilé ẹjọ́ láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ìyàwó Orisakwe kò gbádùn.

    Ó fi kun pé gbogbo ẹ̀rí àbúrò Orisakwe bá gbé wá sílé ẹjọ́ ni kò ṣe é gbàgbọ́ nítorí ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti ìgbà tí ìgbẹ́jọ́ náà tí bẹ̀rẹ̀ pé kí wọ́n parọ́.

    Adájọ́ Soladoye tẹ̀síwájú pé ohun tí àwọn náà sọ fún àwọn ọlọ́pàá nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé yàtọ̀ gédégédé sí ohùn tí sọ nígbà tí wọ́n wá jẹ́rìí nílé ẹjọ́.

    Ó ní ìwádìí àwọn dókítà fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé wọ́n fipá bá àwọn náà lòpọ̀ láti ọwọ́ bàbá wọn.

    Ìdí nìyí tí adájọ́ fi ní gbogbo ẹ̀rí ṣàfihàn pé Orisakwe jẹ̀bi ẹ̀sùn mẹ́ta tí wọ́n kà si lọ́rùn.

    Ilé ẹjọ́ wá sọ ọkùnrin náà sí ẹ̀wọ̀n gbére fún ẹ̀ṣẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

    Adájọ́ tún ní kí wọ́n fi orúkọ ọkùnrin náà sínú ìwé orúkọ àwọn ènìyàn tó ti lòdì sí òfin ìbálòpọ̀ ní ìpínlẹ̀ Eko.

  14. Mo ti ṣetán láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn adarí ilé aṣòfin - Tinubu

    Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ní òun ní ìfarajìn láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣòfin tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ búra wọlé fún.

    Tinubu ní òun máa ṣe àrídájú rẹ̀ pé gbogbo nǹkan tí àwọn bá ṣe ni yóò jẹ́ ojútáyé, tí àwọn kò ní fi ọ̀kan bọ ọ̀kan nínú.

    Ààrẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ yìí nínú ọ̀rọ̀ ìkíni tó kọ ránṣẹ́ sí sẹ́nétọ̀ Godswill Akpabio àti Tajudeen Abbas lẹ́yìn tí wọ́n yàn wọ́n gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ ilé aṣòfin àgbà àti Abẹnugan ilé aṣojúṣòfin.

    Tinubu nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí àwọn ọmọ ilé ní iṣẹ́ ìsìn ìlú ni àwọn ọmọ Nàìjíríà gbé lé àwọn lọ́wọ́ nítorí náà kí wọ́n sin àwọn ènìyàn ẹkùn tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn ń ṣojú tọkàntọkàn.

    Ó fi kun pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ń retí kí àwọn aṣòfin náà ṣe àgbékalẹ̀ àwọn òfin tí yóò sèso ire fáwọn ọmọ orílẹ̀ èdè yìí.

    Ó ní òun mọ̀ wí pé àìgbọ́ra ẹni yé le wáyé láàárín àwọn àmọ́ òun mọ̀ wí pé fún ìlọsíwájú orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ni yóò jẹ́.

    Ààrẹ tẹ̀síwájú pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ń retí kí àwọn mú àyípadà ọ̀tun bá orílẹ̀ èdè yìí láàárín ọdún mẹ́rin tí àwọn yóò lò nípò.

  15. ASUU, ASUP kọminú lórí ètò ẹ̀yàwó fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù

    Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì, ASUU ti júwe òfin ẹ̀yàwó fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń ṣe ìpínyà láàárín ọmọ olówó àti tálákà ní orílẹ̀ èdè yìí.

    Ààrẹ ASUU, Emmanuel Osodeke nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹ̀lú ilé iṣẹ́ The PUNCH ní àwọn máa tó fi ìhà tí àwọn kọ sí òfin náà léde ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn ló ti ṣaájú mọ̀ pé àwọn kò fara mọ́ ìgbésẹ̀ náà.

    Osodeke ní ètò yìí yóò kàn dá fẹ́ máa dá gbèsè sí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó jẹ́ ọmọ tálákà lọ́rùn lẹ́yìn tí wọ́n bá ti parí ẹ̀kọ́ tán

    Ó ní òun gbàgbọ́ pé ìgbésẹ̀ yìí dàbí ẹlẹ́yàmẹ̀yà láàárín ọmọ olówó àti ọlọ́rọ̀ nítorí òfin náà ti làá kalẹ̀ pé ẹni tí bàbá rẹ̀ bá ti ń gbù ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta lọ lọ́dún kò ní àǹfàní sí ètò ẹ̀yàwó yìí.

    Nínú ọ̀rọ̀ tirẹ̀ náà, Ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe, Anderson Ezeibe ní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé òun kò ì tíì ṣe àyẹ̀wò òfin náà dáadáa, òun kò rò wí pé ọ̀nà tí ìjọba fẹ́ kí àwọn tó bá gba owó náà láti dá padà jẹ́ èyí tó máa ṣeéṣe.

    Ezeibe ní pẹ̀lú àgbékalẹ̀ pé ọdún méjì lẹ́yìn sínsin ìlú ni kí àwọn ènìyàn náà dá owó padà, ó ní ọ̀nà wo ni ẹni tí kò ì tíì máa ṣiṣẹ́ nígbà náà fẹ́ fi dá owó padà.

    Ó fi kun pé ṣé ìpèsè iṣẹ́ máa ti wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní kété tí wọ́n bá ti parí ẹ̀kọ́ wọn ni.

    Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ Nàìjíríà, NANS ti júwe àwọn ètò ẹ̀yàwó náà bí ọ̀nà láti tẹ ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà síwájú.

    Àtẹ̀jáde kan tí alákòóso ẹkùn Zone D, Adejuwon Emmanuel fi síta ní àwọn kò faramọ́ ọ̀nà tí ìjọba là kalẹ̀ láti fi san owó náà padà.

  16. Àwọn ọ̀nà tí o lè fi rí ẹ̀yáwó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tí Tinubu ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù gbà rèé

    Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kejìlá oṣù Kẹfà ọdún 2023 ni Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu buwọ́lu àbá ẹ̀yáwó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ dòfin.

    Òfin yìí ti fi ààyè gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tó bá wà nílé ẹ̀kọ́ gíga Yunifásitì, ilé ẹ̀kọ́ gbogbonìṣe (polytechnic) tàbí ilé ẹ̀kọ́ olùkọ́ni láti yá owó láì ní san èlé kankan lórí rẹ̀.

    Abẹnugan ilé aṣojúṣòfin, Femi Gbajabiamila ló tẹ pẹpẹ àbá náà síwájú ilé, tí ilé sì buwọ́lù ú nínú oṣù karùn-ún.

    Pẹ̀lú ìbuwọ́lù Ààrẹ, òfin yìí ti fàyè gba ìdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ ètò ẹ̀kọ́ Nàìjíríà.

    Ilé ìfowópamọ́ yìí ni yóò máa ṣe àmójútó bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yóò ṣe máa gba owó náà.

    Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá fẹ́ yá owó yìí máa lọ fún àyẹ̀wò láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó lẹ́tọ̀ọ́ láti yá owó náà.

    Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ tó bá wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga ní Nàìjíríà ló ní àǹfàní láti yá owó yìí láti fi san owó ilé ẹ̀kọ́, ra ìwé tàbí láti fi ṣe iṣẹ́ ìwádìí.

    Ọmọ Nàìjíríà tó bá fẹ́ lọ kẹ́kọ̀ọ́ nílẹ̀ òkèrè kò ní àǹfàní sí ètò yìí.

    Kí ènìyàn tó lè ní àǹfàní láti gba owó yìí, owó tó ń wọlé fún ẹbí ẹni náà gbọ́dọ̀ dín ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà.

    Ẹnikẹ́ni tó bá ti jẹ ilé ìfowópamọ́ náà lówó tẹ́lẹ̀ kò ní ní àǹfàní láti gba owó mìíràn àyàfi tó bá san tilẹ̀ tó bá gbà.

    Akẹ́kọ̀ọ́ tó bá tún ti lọ́wọ́ nínú ṣíṣe èrú ìdánwò kò ní ní àǹfàní sí owó yìí.

    Lẹ́yìn ọdún méjì tí ènìyàn bá ti sin ìjọba tán ni òfin là kalẹ̀ pé yóò san owó náà padà.

    Nínú owó oṣù tí ẹni náà bá ń gbà lẹ́yìn tó bá parí àgùnbánirọ̀ ni wọ́n yóò ti máa yọ ìdá mẹ́wàá títí tí owó ọ̀hún máa fi pé.

    Ẹni tó bá kọ̀ láti san owó rẹ̀ tó bá yá le fi ẹ̀wọ̀n ọdún méjì gbára tàbí kí ó san owó ìtanràn ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà tàbí kí ó ṣe méjéèjì.

  17. Olùdásílẹ̀ AC Milan, tó tún jẹ́ olóòtú ìjọba Italy tẹ́lẹ̀,Silvio Berlusconi jáde láyé

    Olootu ijọba orilẹ-ede Italy nigba kan, Silvio Berlusconi ti kú lẹni ọdun mẹrindinlaadọrun.

    Owurọ ọjọ Aje ni iroyin nipa iku rẹ jade sita lẹyin to ti ṣaisan fun asiko pipẹ.

    Igba mẹrin ni Ọgbẹni Berlusconi jẹ olootu ijọba Italy.

    Wọn bi i ni ọdun 1936 niluu Milan, to si bẹrẹ òwò sise ko to o di pe o da ileeṣẹ abanikọle silẹ.

    Berlusconio di ẹni to ni owo julọ ni orilẹ-ede Italy lẹyin asiko diẹ, lati ara awọn ileeṣẹ amohunmaworan to da silẹ.

    O di gbajumọ l’agbaye nigba to da ẹgbẹ agbabọọlu AC Milan silẹ ṣaaju ko to di oloṣelu.

    Ṣugbọn o ta ẹgbẹ agbabọọlu naa ni ọdun 2017. Lẹyin ọdun kan, o tun pada si agbo bọọlu pẹlu idasilẹ ẹgbẹ agbabọọlu rẹ tuntun, AC Monza.

    O da ẹgbẹ osẹlu ti ẹ, Forza Italia silẹlọdun 1993. O si jẹ olootu ijọba Italy laarin ọdun 1994 si 1996, 2001 si 2006, 2007 si 2011, ati 2011.

    O tun pada si ilem aṣofin Italy gẹgẹ bi sẹnetọ lọdun 2022.

    O ti pẹ diẹ ti Berlusconio ti ni aisan jẹjẹrẹ inu ẹ̀jẹ̀. Lati ọdun 2020 si ni oriṣiriṣi aisan ti n ṣe e lẹyin to ko aarun Covid-19.

  18. Wo kókó ohun mẹ́tàlá tí Bola Tinubu ṣe bií Ààrẹ Nàìjíríà

  19. Ìtàn ayé Kudirat Abiola, akọni obìnrin tó jẹ́ ọ̀wọ̀n ìrántí fún àyájọ́ ìjọba alágbádá

  20. Wo ohun tó mú kí àyájọ́ June 12 ṣe pàtàkì fún Nàíjíríà