You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Fásitì Ibadan mú àdínkù bá àkókò tí àwọn òṣìṣẹ́ yóò máa fi lọ ibi iṣẹ́, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fi èrò wọn hàn

  2. DSS fẹ́ yọwọ́ nínú ẹjọ́ ìbọn níní lọ́nà àìtọ́ tí wọ́n fi kan Emefiele, wọ́n ní Ó lẹ́jọ́ tuntun láti jẹ́

  3. Ohun tí a mọ̀ nípa ikú baba Bobrisky, gbajúmọ̀ ọkùnrin tó ń múra bí obìnrin

  4. Tí wọ́n bá tún fi kún owó epo, a ó da iṣẹ́ sílẹ̀ pátápátá – NLC

    Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ni Naijiria, NLC, ti sọ pe oun yoo gunle ieyanṣẹlodi ti ijọba ba tun fi owo le owo epo bẹntiro.

    Adari NLC, Joe Ajaero, lo fi ọrọ naa lede nibi ipade ẹgbẹ African Alliance of Trade Unions, to waye niluu Abuja.

    Lati ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023, ti ijọba tuntun ti gori alefa ni Naijria ni ajọ NNPC ti n fi kun owo epo lemọlemọ.

    Ti ẹ ko ba gbagbe, N185 ni owo epo naa tẹlẹ ko to fo lọ si N500, ko to di pe o bọ si N617 loṣu to kọja.

    NLC ni “Ni bayii, wọn tun ti n gbero lati fi kun owo epo bẹntiro.”

    “Ohun ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ oṣiṣẹ yoo si ṣe ni ko lọ gba aṣẹ ile ẹjọ, eyii ti yoo ka ẹgbẹ oṣiṣẹ lọwọ ko.”

    “Ṣugbọn ẹjẹ ki n sọ fun yin pe ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ni fun wọn ni gbedeke kankan ti a ko ba tii yanju rogbodiyan ti afikun meji to kọja da silẹ, ki a tun ji laarọ ọjọ kan ka wa gbọ pe wọn tun ti fi kun owo epo bẹntiroa.”

    Lara awọn to wa nibi ipade naa ni awọn adari ẹgbẹ oṣiṣẹ ni Ghana, Kenya, Senegal, ati South Africa, wọn si gba ajọ ECOWAS niyanju lati maṣe kogun ja orilẹ-ede Niger.

  5. Wo èrèdí tí JAMB ṣe gba èèyàn 300 síṣẹ́ láì kéde àwọn ipò náà fáráàlú

    Ọga agba ajọ JAMB, Ọjọgbọn Is-haq Oloyede, ti ṣalaye eredi ti ajọ naa fi gba ọọdunrun eeyan siṣẹ lai ṣe ipolongo rẹ.

    Oloyede ni awọn gba awọn eeyan naa siṣẹ lati di ipo awọn to n fẹyinti ninu ajọ naa.

    Ọrọ yii lo jade lasiko ti Oloyede yọju siwaju ile igbimọ aṣojuṣofin lati salaye eredi igbesẹ ọhun, ati ohun ti ko jẹ ki JAMB kede awọn ipo iṣẹ naa ki gbogbo araalu le kọwe lati gba awọn iṣẹ ọhun.

    Eredi ti ọrọ yii fi lu sita ko ṣẹyin igbesẹ ile igbimọ aṣojuṣofin lati ṣe iwadii bi awọn lọgalọga kan nileeṣẹ ijọba ṣe n ta iṣẹ fun awọn eeyan kan nigba ti ọpọ awọn mii n jiya ainiṣẹlọwọ laarin ilu.

    Ninu iwadii ile naa ẹwẹ, wọn ṣawari awọn eeyan mẹrinla kan ti wọn n gbowo oṣu ijọba lọwọ Federal Character Commission, nigba ti wọn ko si ṣiṣẹ kankan.

    Oniruru aṣiri lo ti tu sita lati igba ti ile igbimọ aṣojuṣofin ti bẹrẹ iwadii naa.

  6. Ọkọ̀ òfúrufú iléẹṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria, NAF MI-171 já lulẹ̀ ní Niger

    Ọkọ ofurufu kan to jẹ ti ileẹṣẹ ọmọ ogun ofurufu Naijiria, NAF MI-171, ti ja lulẹ nipinlẹ Niger.

    Alukoro ileeṣẹ naa, Edward Gabkwet, lo fidi iroyin naa mulẹ ninu atẹjade kan.

    Iroyin ni nnkan bii aago kan ọsan ọjọ Aje ni ọkọ ofurufu naa jabọ, amọ a ko le fidi iye ero ọkọ naa mulẹ lasiko ti a n ko iroyin yii jọ.

    Atẹjade naa ni “Ọkọ ofurufu ọhun kuro nile ẹkọ alakọbẹrẹ Zungeru lọ si Kaduna amọ o jabọ lẹba abule Chukuba to wa ni ijọba ipinlẹ Shiroro.”

    “A ti bẹrẹ iṣẹ lati doola awọn to wa ninu ọkọ ofurufu naa, bẹẹ naa ni a tun ti bẹrẹ iṣẹ lati mọ ohun to ṣokunfa bo ṣe jabọ.”

    Ti ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kejilelogun, oṣu Keji, ọdun 2021, awọn ọmọ ogun ofurufu meje lo ku lasiko ti ọkọ ofurufu wọn jabọ lasiko to n lọ lati Abuja si Kaduna.

  7. Bàálù hẹlikọ́pútà ọmọogun Nàìjíríà kan já nípínlẹ̀ Niger

  8. Nǹkan dé! Franklin fi agbárí èèyàn wẹ̀ nílùú Akure

  9. Mo kìlọ̀ títí fún àwọn ọmọ Naijiria nípa òṣèlú ‘Emilokan’ àmọ́... – Tunde Bakare

    Pasitọ ijọ Citadel Global Community Church, Tunde Bakare, ti sọ pe oun kilọ fun awọn ọmọ Naijiria nipa oṣelu “Emilokan” amọ wọn kọ eti ikun si ọrọ oun.

    Bakare lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn ọmọ ijọ rẹ sọrọ lọjọ Aiku, nibi to ti sọ pe oṣelu ‘Emilokan’ ko le so eso rere fun Naijiria.

    Ti ẹ ko ba gbagbe, Aarẹ Bola Tinubu lo mu ki ‘Emilokan’ yii di gbajumọ lasiko to bẹrẹ ipolongo ibo Aarẹ rẹ niluu Abeokuta lọdun to kọja.

    Bakare sọ pe “Mo ranti ikilọ mi fun awọn ọmọ Naijiria ninu oṣu Kinni ọdun 2023… mo kilọ fun wọn pe oṣelu Emilokan yoo pada yọri si eyii ti awọn adari yoo jẹ Baṣọrun Gaa le awọn araalu lori ni lai bikita fun wọn.”

    Bakare tun sọrọ nipa gomina CBN ana, Godwin Emefiele ati ohun ti oju awọn ọmọ Naijiria ri lasiko to ko owo naira pamọ.

    O ni ko ṣeeṣe ki Emefiele ko owo naa pamọ lai gba aṣẹ lọwọ ijọba ana, ko si yẹ ko jẹ pe Emefiele yii nikan ni ijọba yoo di ẹbi gbogbo ọrọ naa le lori bayii.

    O ni “Godwin Emefiele le ṣe aṣiṣe nipa ọwọ to fi mu ọrọ owo Naijiria amọ kii ṣe oun lo yẹ ko jiya ohun to ṣẹlẹ.”

  10. “Akeredolu kò tíì padà wálé, ó ṣì wà ní Germany níbi tó ti ń gba ìtọ́jú”

    Ijọba ipinlẹ Ondo ti sọ pe gomina ipinlẹ naa, Rotimi Akeredolu ṣi wa lorilẹ-ede Germany, nibi to ti n gba itọju.

    Agbẹnusọ Akeredolu, Richard Olatunde, lo fi ọrọ naa lede ninu Atẹjade kan ni esi si fidio kan to gba ori ayeluara pe Akeredolu ti pada wa si Naijiria.

    O ni “Bo tilẹ jẹ pe a mọ ọpọ eeyan nipinlẹ Ondo ati kaakiri Naijiria lo ti n reti ki gomina pada wale, amọ a fẹ ki gbogbo eeyan mọ pe gomina Akeredolu ṣi wa lorilẹ-ede Germany, nibi to ti n bojuto ilera ara rẹ.”

    “A ti ri fidio kan lori ayelujara, eyii to n sọ pe gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu, SAN, CON, ti pada de si Naijiria lati ibi to ti lọ gba itọju.”

    “Gomina Akeredolu dupẹ lọwọ awọn ọmọ ipinlẹ Ondo fun adura ati atilẹyin wọn.”

    Olatunde ṣalaye siwaju si pe atilẹyin awọn eeyan ipinlẹ Ondo wa lara iwuri Akeredolu, yoo si pada walẹ laipẹ.

    O ni “Fidio ti awọn eeyan n pin kiri jẹ eyii ti wọn ya lasiko ipolongo ibo Aarẹ ati ile igbimọ aṣfin to kọja.”

    “Iwuri nla ni atilẹyin awọn eeyan ipinlẹ Ondo jẹ fun gomina Akeredolu, yoo si pada wale laipẹ lati tẹwsiwaju iṣẹ reẹ lati mu idagbasoke ba ipinlẹ Ondo.”

  11. Ìdí tí mo fi ta ọmọ-ọmọ mi fún N700,000 rèé

  12. Ǹkan mẹ́jọ tó máa kọ́kọ́ ṣẹlẹ̀ kí olólùfẹ́ méjì tó pa ara wọn

  13. ‘’Irọ́ ni ìròyìn pé wọ́n ti jó ilé isẹ́ Naijiria tó wà ní Niger’’

    Ileeṣẹ ọmọogun Naijiria ti ni ko si otitọ ninu iroyin pe wọn ti da ina sun ileeṣẹ ijọba Naijiria to wa ni orilẹede Niger.

    Eyi ko ṣẹyin iroyin to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara pe awọn afẹhọnuhan to n ṣatilẹyin fun ijọba ologun ni Niger ti lọ jo ileeṣẹ ijọba Naijiria to wa ni Niger.

    Lati aarin ọṣẹ ni fidio naa ti n ja lori ẹrọ ayelujara pe awọn afẹhọnuhan ti dana sun ileeṣẹ ijọba Naijiria to wa ni Niger.

    Ilee’sẹ ọmọogun Naijiria ni bio tilẹ jẹpe lootọ ni awọn afẹhọnuhan naa gbiyanju lati yawọ ibẹ ni Ọjọgbọn osu to kọja amọ ikọ ọmọogun ati awọn ọlọpaa ko fun wọn laaye.

    Bakan naa ni wọn ni titi di asiko yii awọn ikọ ọmọogun Naijiria ati ọlọpaa wa nibẹ ni wọn n ṣọ ibẹ lọwọ lọwọ.

    Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Tinubu lo n dari ikọ ECOWAS ti wọn n gbiyanju lati da ijọba tiwantiwa pada si orilẹede Niger.

    Aarẹ orilẹede Niger ti wọn y ni ipo, Bazoum Mohammed wa ni panpẹ awọn ologun naa.

  14. Russia fí ìkìlọ ránṣẹ sí Ecowas pé kò má fí ọmọ ogún kojú Niger

    Orileede Russia ti kìlọ fun ajọ Ecowas lori fifi ọmọ ogun ranṣẹ lati koju awọn aditẹgbajọba ni Niger.

    O ní igbesẹ yi le da wahala ti ko ni pari bọrọ silẹ.

    Ninu atẹjade kan lati ileeṣẹ okere Russia ni ikilọ yi to jade lọjọ Ẹti wa eyi to ni ki wọn ma ṣe ko ọmọ ogún já Niger.

    Atẹjade naa sọ pe "A ni ìgbàgbọ pé riran ọmọ ogun lọ sí Niger kii se ọna abayọ kaka bẹẹ yoo da wahala ti ko Si ẹni tó lè sọ igba tí yoo wa s'opin.Yoo tubọ da kun iṣọrọ ti agbegbe Saheli n koju bayi ni"

    Awọn olori ileeṣẹ ologun orileede ECOWAS yoo ṣe ìpàdé lọjọ Àbámẹ́ta eyi ti yoo da lori bi wọn yóò ṣe seto awọn ọmọ ogun tí yoo koju Niger.

    Lọwọ báyìí Aarẹ Ivory Coast Alassane Outtara sọ pé òun yoo ko ọmọ ogun tó le ní ẹgbẹrun kan ranṣẹ lati koju awọn ologun Niger.

    America, France ati EU l'awọn wa lẹyìn ìpinnu tí yóò dá ijọba padà fún ààrẹ Mohammed Bazoum ti wọn yẹ àga nidi rẹ.

  15. Ivory Coast ṣetán láti kó 1,100 ọmọogun kalẹ̀ fún ECOWAS láti kó lọ sí Niger, Niger Coup: Ivory Coast ṣetán láti kó 1,100 ọmọogun kalẹ̀ fún ECOWAS

    Aarẹ orilẹede Ivory Coast, Alassane Ouattara ti kede pe orilẹede oun yoo fi ẹẹdẹgbẹfa ọmọ ogun sọwọ lati dara pọ awọn orilẹede miran to wa ninu ajọ ECOWAS.

    Quattara leri leka bẹẹ lasiko ipade ajọ ẸCOWAS to waye nilu Abuja ni Ọjọbọ nibi ti wọn ti fẹnu ko pe ajọ naa yoo ko ikọ ọmọ ogun sọwọ si Niger lati da ijọba pada fun alagbada.

    Ọjọ kẹrindinlọgbọn osu keje ọdun 2023 ni ikọ ologun Niger ditẹ gbajọba lọwọ ijọba aarẹ Mohammed Bazoum, ti ECOWAS si leri pe oun yoo fi tipa le wọn kuro nipo asẹ naa.

    Bakan naa ni awọn olori orilẹede Senegal ati Benin naa ti seleri lọsẹ to kọja pe awọn yoo ko ikọ ọmọ ogun kalẹ fun ECOWAS lati lọ le awọn ologun kuro ni Niger.

  16. Ivory Coast yóò fí ọmọ ogún 1,100 ránṣẹ fí kojú ológun Niger

    Aarẹ orileede Ivory Coast, Alassane Ouattara ti lóun yoo ṣe atilẹyin ọmọ ogun tó le ní ẹgbẹrun kan ti yoo pẹlu awọn ọmọ ogun Ecowas lati koju awọn ologun Niger to gbajọba níbẹ.

    Eyi waye lẹyìn tí ECOWAS buwọ́lù aṣẹ lati fi ọmọ ogun yọ awọn ologun to gbajọba lọwọ aare Mohammed Bazoum loṣu to kọja.

    LỌjọbọ aarẹ Outtara sọ pé "awọn adari ologun yoo sí ṣe'pade lati fẹnu ọrọ ko amọ wọn ni atilẹyin awọn aarẹ lati bẹrẹ eto lilo ọmọ ogun lati koju awọn to gbajọba ni ko pẹ"

    Lọsẹ to kọja, Senegal, Benin ati Ivory Coast seleri lati fi ọmọ ogun ranṣẹ kete to Ecowas ba láwọn ṣetan lati koju ọmọ ogun ni Niger.

    Kọmisana f'ọrọ eto oṣelu aabo ati alaafia Abdel -Fatau Musah sọ fun BBC pe ko ni pẹ ti awọn yóò fi ko ọmọ ogun sọnà.

    " Ijiroro ko ni titi láé.Kiko ọmọ ogun sọnà kó ni dawọ duro ayafi ti awọn ologun to gbajọba ba ṣetan lati jiroro nipa dídá aarẹ ti wọn yọ pada ki ijọba awarawa sí padà nilẹ Niger"

  17. Tí a kò bá fọhùn akin fún ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìjọba alágbádá ní Niger, kò sí ẹni tí yòó bá wá ṣe é - Tinubu

  18. LASEMA ṣàwárí òkú ọkùnrin tó bẹ́ sódò láti afárá Ikoyi - Lekki

    Ọkunrin kan ti a ko ti le sọ orukọ rẹ lo ti bẹ sodo nipinlẹ Eko.

    Ajọ to n risi isẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA gbogbo igbinyanju awọn lati doola ẹmi ọkunrin naa lo ja si pabo.

    Isẹlẹ naa lo waye lọjọ isẹgun ni ori afara Lekki-Ikoyi

    Agbẹnusọ ajọ LASEMA Damilola Oke-Osanyintolu ni kete ti awọn gbọ iroyin nipa isẹlẹ naa ni awọn gbera lọ sibẹ.

    "Gbogbo igbinyanju lati ma jẹ ki ọkunrinn naa bẹ sodo ni lo jasi pabo.

    "Bakan naa ni gbogbo igimyanju ti ajọ LASEMA lati dola ẹmi ọkunrin agbalagba naa ni ko wa si imusẹ

    "A ti gbe oku ọkunrin naa kuro nibi ti isẹlẹ naa ti waye.

    " Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamine Hundeyin naa fi di isẹlẹ naa mulẹ."

  19. Ológun Niger sọ pé France n gbèrò láti tù àwọn agbésùnmọ̀mí sílẹ làhámọ́

    Orileede Faransé ti takò ẹsun pe o n fi ọna eru wọ oju ofurufu Niger ni itako aṣẹ tàwọn ologun to gbajọba fi le'lẹ.

    Awọn ologun Niger ni o fi ẹsun yi kan ilẹ Faranse.

    Wọn ní ilẹ Faranse ati awọn alajọṣepọ wọn n gbìyànju láti tu awọn agbesunmọmi to wa ni àhámọ́ silẹ.

    Wọn lò ti to ọdun mẹjọ tàwọn wọnyi ti wa ni ahamọ lori ẹsun dídá omi alaafia ilu ru.

    Amadou Abdraman to gbẹnu sọ fawọn ọmọ ologun lo ka ọrọ yi sita lori ẹrọ amohunmaworan ṣugbọn ko fi ẹrí kankan gbe ọrọ rẹ lẹyìn.

    Ikede yi n waye lasiko tí àjọ ECOWAS n múra ipade ijiroro lori ọrọ Niger lỌjọru.

    Ipade yi yoo sagbeyẹwo igbesẹ to kan boya ki wọn fí ẹsọ pẹlẹ yanju ọrọ tabi kogun ja Niger.

    Orileede Faransé ti wa sọ pé àwọn ko ṣe ohun to jọ mọ wíwọ oju ofurufu Niger tabi titu awọn agbesunmọmi silẹ.

    Ọrọ yi n waye ni k'ọpẹ k'ọpẹ ti olori awọn alajangbila kan ṣe idasilẹ ikọ kan lọna ati da ààrẹ Bazoum ti wọn yọ kuro lori aleefa sipo rẹ pada.

    lỌjọru ọmọ aṣoju Niger sí orileede France,Idrissa Kané la gbọ pé awọn ologun to gba ijọba mu ti wọn sì fẹsun kan wí pé o lu owó ilu ni ponpo.

  20. A kò leè gbàlejọ̀ Àjọ Ecowas nítórí nítorí ètò ààbò ìlú- Ìjọba ológun

    Adari ikọ ọmọogun to fi ipa gbajọba ni Niger ti kọ lati gbalejo ikọ Ajọ Ecowas to fẹ sẹ abẹwo si orilẹede naa.

    Awọn adari ikọ naa ni awọn ko lee gba ki wọn wọle si orilẹede wọn nitori awọn ko lee pese aabo fun awọn alejo naa.

    Awọn igbimọ lati ikọ Ecowas, ikọ African Union to fi mọ ikọ United Nations ni o yẹ ki wọn balẹ si orilẹede Niger ni oni.

    Amọ ikọ ọmọogun to gbajọba ni Niger naa ni igbeṣẹ ajọ Ecowas to mu ki wọn gbegidina awọn eto ọrọ aje wọn, to fi mọ ina ijọba ti mu ki awọn araalu gbe ibinu yọ si ajọ naa.

    Wọn ni nitori naa awọn ko lee pese agbegbe alaafia fun awọn aṣoju ajọ naa to n bọ ni orilẹede wọn.

    Bakan naa ni wọn fikun un pe awọn ti ti awọn ibode wọn ni ilẹ ati ofurufu.

    Iroyin lati Niamey to jẹ olu ily orilẹede naa fihan pe ọpọlọpọ araalu lo faramọ iditẹ gbajọba naa, ati bi wọn se yuọ aarẹ Mohamed Bazoum kuro ni ipo.

    Amọ orilẹede Amẹrika ti fi ikilọ sita pe oṣeeṣe ki ikọ ọmọogun ilẹ Russia , ti igun Wagner wa ni idi iditẹgbajọba to waye ni Niger.