You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Bó o bá ń gba ẹnu ní ìbálòpọ̀, wo àìsàn tó o lè kó lójú ara rẹ

  2. Buhari fi àìdúnnú rẹ̀ hàn lóri ìfipá gbàjọba tó wáyé ní Niger

    Aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹ, Muhammadu Buhari ni iyalẹnu lo jẹ fun oun nigba ti awọn Ologun gbajọba ni Niger.

    Buhari ni eyi mu ki irọnu de bao un lori ọna isejọba tiwantiwa ti wọn ti doju rẹ bolẹ lorilẹede ọhun.

    Bakan naa lo ni ifoya lo jẹ fun oun lori ipo ti aarẹ Niger ti wọn yọ ni ipo, Mohammed Bazoum ati awọn mọlẹbi rẹ wa.

    Aarẹ Buhari ninu ọrọ rẹ ni gẹgẹ bi awọn ọmọ Naijiria miran se n kọminu lori iṣẹlẹ to n waye ni Niger, ‘’eyi ba mi ninu jẹ gidi.’’

    Aarẹ naa wa gbadura pe ki ohun gbogbo di ẹrọ ni ilu naa si bi wọn se wa tẹlẹ.

    Bakan naa lo gbadura pe ki aarẹ Bazoum ati idile rẹ w ani alaafia pipe ati ifọkanbalẹ.

    Buhari lo di ipo olori Naijria mu fun ọdun mẹjọ ki o to gbe ijọba kalẹ fun aarẹ Tinubu ni oṣu Karun un, ọdun yii.

  3. Ọ̀fẹ́ ni ètò ẹ̀kọ́ ní àwọn ilé ẹ̀kọ́ gíga - Ìjọba Nàìjíríà

  4. A tako ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu kúrò ní àhámọ́ – Ilé Aṣofin Àgbà

    Ile asofin agba ni Naijiria ti fi osi da ipero awọn sẹnatọ lati Ila oorun Naijiria wi pe ki wọn tu adari ikọ IPOB, Nnamdi Kanu silẹ ni ahamọ.

    Asofin lati ipinlẹ Imo, Osita Izunaso lo kede apero naa ni ile asofin agba.

    Ni ero rẹ, o ni ti wọn bat u Kanu silẹ, yoo fi opin si ki awọn eniyan maa joko sile tipatipa bii awọn agbẹbọn ni agbegbe naa se kan an nipa fun wọn.

    ‘’Awọn agbebọn yii sọ fun awọn araalu pe dandan ni wọn gbọdọ joko si ile, ki wọn si tun ti awọn ileesẹ wọn naa.’’

    ''Eyi n mu ifasẹyin ba ọrọ aje agbegbe naa, eleyii to n fa iya ati isẹ fun awọn araalu,ti ati gbe ilu si ti iṣoro fun wọn.''

    Amọ awọn asofin naa lẹyin ti wọn gbọ aroye rẹ , fi ọwo osi daa nu, pe awọn ko lee fi ọwọ si ki wọn da Kanu silẹ kuro ni ahamọ.

    Bakan naa ni wọn kesi awon ẹsọ ọtẹlẹmuyẹ lati ri pe ọwọ wọn tunbọ tẹ awọn ọbayejẹ ni awujọ.

    Awọn agbebọn naa ni wọn ti n kan nipa fun awọn araalu lati ripe wọn joko si ile wọn ni gbogbo ọjọ Aje lati fi apa jannu lori atimọlẹ Kanu.

    Osù Kẹ́fà, ọdún 2021 ni wọ́n ti fi Kanu sí àhámọ́ lórí ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ mọ̀ ìjọba àti idẹ́yẹsíni.

  5. Ààrẹ Biden ti kéde ọ̀nà àbáyọ sí ojú ọjọ́ tó gbóná jainjain

    Aarẹ orilẹede Amerika, Joe Biden ti kede awon igbese ti yoo gbe lati seranwọ fun awọn ara ilẹ Amerika lati koju oju ọjọ to gbona Jainjain.

    Laipẹ yii ni iroyin ti n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara pẹlu bi oju ọjọ to gbona se n ba awọn eniyan finra ni ilẹ Amẹrika.

    Lara awọn igbesẹ ti aarẹ Biden ni oun yoo gbe ni idaabobo awọn oṣiṣẹ lasiko ti oju ọjọ ba gbona jainjain.

    Bakan naa lo ni awọn yoo gbese iranwọ ni ẹka to n risi ọrọ oju ọjọ ki wọn ba le tete maa sọ saaju lai puro bi oju ọjọ yoo se ri ni igba de igba.

    Amọ o seese ki igbesẹ aarẹ yii ma dun mọ awọn araalu to se agbatẹru fun ki ijọba wa wọrọkọ fi sada lori ọrọ oju ọjọ to n se segesege.

    Lara awọn ilu ti igbesẹ yii yoo ti gberasọ ni Boston, Philadelphia ati Washington DC.

    Ijọba Biden tun kede pe awọn setan lati wa ọna abayọ si iṣoro ti awọn osisẹ n la kọja lasiko oju ọjọ to gbona jainjain yii, paapaa awọn to n ṣisẹ ninu oorun.

    Ilu Phoenix ni Arizona ni iwọn oju ọjọ to le ni mẹtalelogoji, ti ọpọlọpọ iṣẹlẹ si ti waye nibẹ nitori oju ọjọ to gbona naa.

    Aarẹ Biden fi da awọn eniyan loju pe oun yoo da abo bo awọn araalu ti wọn nilo idaabobo naa julọ.

  6. Iléeṣẹ́ ọlọ́páà fajúro,wọn ní ki Cute Abiola wa ṣálàyé ohun tó mu fi aṣọ àwọn ṣe ''skit''

    Toun ti bi ofin orileede Naijiria ṣe faye gba ẹtọ araalu,kii ṣe bi ti pe ki wọn wa maa fi ẹtọ wọn tabuku ileeṣẹ ọlọpaa.

    Gbolohun to ṣaaju ọrọ atẹjade ti alukoro agba ileeṣẹ ọlọpaa fi sita ree nipa bi adẹrinposonu nii Cute Abiola ṣe fi asọ ọlọpaa ṣawada lọna to tabuku ileeṣẹ wọn.

    Olumuyiwa Adejobi sọ pe fọnran awada kẹrikẹri to ṣe to sipin loju opo ayelujara tabuku ti ko si bọwọ fun aṣọ ọlọpaa.

    O ni iwa yi tapa sofin Naijiria to si ni iru iwa yi yoo maa '' tapo si aṣọ aala awọn ọkunrin ati obirin to n fi tọkan tọkan ṣe iṣẹ ọlọpaa''

    Ni bayii o wa sọ pe awọn yoo ṣe iwadii Cute Abiola ti orukọ rẹ gangan n jẹ Abdulgafar Abiola tos i ṣeeṣe li o foju wina ofin lori iwa to hu.

    Lẹnu ọjọ mẹta yi, ileeṣẹ ọlọpaa ti n koro oju si awọn adẹrinposonu loju opo ayelujara fawọn kudiẹkudiẹ kan ninu fidio ti wọn n gbe sita.

    Laipẹ yi ni arakunrin kan taa mọ si Trinity Guy naa wọ gau lori fọnran to gbe sita eleyi to tabuku ọmọ obinrin keklere kan.

    Igba akọkọ kọ ni yi ti Cute Abiola ati awọn alaṣẹ yoo maa gbena woju ara wọn lori awada rẹ.

    Nigba to ṣi jẹ oṣiṣẹ ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi Naijiria, awọn ọga rẹ fi si atimọle lori bo ṣe n fi aṣọ awọn agbofinro ati ibọn ṣe awada skit rẹ.

    Cute Abiola ko ti fesi sọrọ tawọn ọlọpaa sọ.

  7. Awakọ̀ ojú omi bẹ́ sínú omi lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi tó gbé ọkọ̀ tó lé ní 3,000 gbiná

    Ọkọ oju om ikan to gbe ọkọ ayọkẹlẹ to le ni ẹgḅrun mẹta ti gbina ni agbegbe Ameland.

    Awọn awakọ oju omi naa fi ara pa to fi mọ awọn to le ni mejilelogun.

    Lọna ati doola ẹmi ara won nigba ti ina naa bugbamu ninu ọkọ oju omi.

    Awakọ ọkọ oju omi naa ni ọkọ ti oun lọ ina ọba to wa ninu ọkọ naa, ni marundinlọgbọn, ti ọkọ naa n wa lọmo.

    Nibayii, igbiyanju n lọ lọwọ lati pa ina naa amọ awọn onimọ ni oseese ki ina naa jo fun ọpọlọpọ ọjo.

    Saaju ni awọn awakọ oju omi naa giyanju lati pa ina naa fun ara wọn, amọ ina naa ni agbara ju wọn lọ ti wọn si sa asala fun ẹmi wọn.

    Bakan naa ni wọn ko awon ero inu ọkọ oju omi naa kuro, ki wọn ba le yẹ ninu ijamba ina to sọ naa.

    Balogun ọkọ oju omi naa, Williard Molenaar ni awọn meje lo ḅẹ sinu agbami nla lọna ati doola ẹmi ara wọn.

    Ọkọ oju omi naa ni wọn lo gbera lati Germany to si n lọ si ibudoko to w ani Port Said ni Eypt.

  8. Igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC kọ ìwé fi ipò sílẹ̀

    Igbakeji Alaga gbogboogbo fun iwọ Ariwa-Ila oorun ni Naijiria, Malam Salihu Lukman ti kọ iwe fi ipo silẹ

    Lukman naa lo fi iwe mi o se mọ ranṣẹ si Adele Alaga ẹgbẹ patapata, Sẹnatọ Abubakar Kyari.

    Eyi n waye lẹyin ọṣẹ kan ti alaga ẹgbẹ oselu APC tẹlẹ, Sẹnatọ Abdullahi Adamu ati akọwe ẹgbẹ patapata, Sẹnatọ Iyiola Omisore kọ iwe fi ipo wọn silẹ.

    Lasiko ikede naa, Malam Salihu Lukman ni oun kọ iwe fi ipo silẹ nitori awọn ọbayejẹ kan ti wọn fẹ da ẹgbẹ naa ru.

    O ni awọn igbesẹ ti wọn n gbe naa lodi si awọn ohun amuyangan to jẹ ipinlẹsẹ ẹgbẹ naa, ti eyi ko si bojumu ni oju oun.

    Lukman ni eyi lo jẹ ki oun kọ iwe fi ipo oun silẹ, nitori oun ko fẹ w ani ibi rudurudu.

    Bakan naa lo ni oun fẹ ki wọn ri oun gẹgẹ bi ẹni to n dena itẹsiwaju ijọba tuntun to wa lode nitori bi ohun se se atako awọn ohun ti oun ko faramọ ninu ẹgbẹ naa.

  9. Davido ko nílò láti bẹ ẹnikẹ́ni nítorí fídíò orin tó bí àwọn mùsùlùmí nínú - Soyinka

    Agba onkọwe, Ọjọgbọn Wole Soyinka, ti kesi gbajumọ olorin, Davido, pe ko kọ eti ikun si awọn to n beere aforijin lọwọ rẹ nitori fidio orin kan to fi oju opo ayelujara rẹ.

    Ọjọ diẹ sẹyin ni Davido fi fidio orin kan, ‘Jaye lo’, eyi ti ọkan lara awọn akọrin nileeṣẹ rẹ, Olamilekan Taiwo ti inagijẹ rẹ n jẹ Logos Olori, gbe jade si oju opo Twitter rẹ.

    Bo ṣe fi fidio naa ti ko ju iṣẹju aaya marundinlaadọta sita, ni awọn eeyan kan to jẹ Musulumi ti koro oju si pe e fidio naa tabuku si ẹsin awọn, ti wọn si ni ki Davido yọ fidio naa kuro kiakia.

    Ninu fidio naa ni awọn eeyan kan to wọ asọ funfun ti n jo niwaju mọṣalaṣi.

    Ọjọ kẹta ni akọrin naa yọ fidio naa kuro loju opo Twitter rẹ. Ṣugbọn awọn musulumi kan ṣi n sọ pe dandan ni ko tọrọ aforiji lọwọ awọn.

    Amọ Ọjọgbọn Soyinka sọ ninu atẹjade kan to fi sita ni ọjọ Iṣẹgun pe, Davido ko jẹ awọn musulumi ni ẹ̀bẹ̀ kankan.

    O ni “gomina ipinlẹ Kaduna nigba kan, Mallam Nasir El-Rufai, sọ ọrọ kan to tako awọn kristiẹni ri, ti ko si si ẹnikẹni to ni ko tọrọ aforiji”.

    Soyinkan sọ pe ko si ohunkohun to nilo ẹ̀bẹ̀, boya lati ọdọ Davido tabi El Rufai. O ni nnkan ti awọn ti inu n bi lori fidio orin ti Davido fi sita le ṣe ni pe “ki wọn o ma gbọ́ orin rẹ mọ”.

  10. Iléẹjọ́ ní àwọn mẹ́jọ jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyan ní ìbúgbámú tó gbẹ̀mí ènìyàn 32

    Ileẹjọ ni Brussels ti dajọ wi pe awọn mẹjọ jẹbi ẹsun ipaniyan lẹyin ọdun meje ti wọn se ikọlu si papakọ ofurufu ti wọn si pa eniyan mejilelọgbọn.

    Awọn ti wọn pa naa ni wọn w ani papakọ ofurufu ni olu awọn papakọ ati papakọ miran.

    Ọdun 2016 ni iṣẹlẹ naa waye ni osu kẹta ọdun.

    Lẹyin ọjọ gigun lori igbẹjọ, ti awọn adajọ si dide ṣọrọ lori igbesẹ naa, ki ijọba ni Brussels to wa kede igbesẹ rẹ.

    Awọn meje ti wọn fi ẹsun ipaniyan naa kan ni ọwọ tit ẹ saaju lati bi ọdun kan sẹyin, ki ọwọ to tẹ wọn.

    Saaju ki ikọlu naa to waye ni wọn ti ri Salah Abdeslam mi nitori wọn ko ni imọ ijinlẹ to peye.

    Oun ni wọn ni o kopa ninu ikọlu to waye ni ọdun 2015, ati ikọlu to waye ni Faranse, to si gbẹmi eniyan 130.

    Lẹyin naa ni o sa kuro ni Paris lọ si Belgium ni ọdun 2015 to si fariga pe oun ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.

    Amọ bayii ileẹjọ ti ni o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan fun iwa ọdaran ni aarin ilu

  11. Ìjọba ti kéde àfikún owó èlé tí àwon tó bá yá owó ní Báńkì yóò máa san padà

    Banki apapọ ni Naijiria, CBN ti kede pe afikun tib a owo ele ti awọn to bay a owo ni banki yoo maa san pada bayii.

    Ijọba kede pe ida 0.2 ni wọn fẹ fikun un owo ele ti awon eniyan yoo maa san pada.

    Eyi tumọ si pe ẹnikẹni to ba ya owo lọwọ banki yoo san ida 18.75 gẹgẹ bi owo ele pada fun banki.

    Eyi jẹ laraigbesẹ banki apapọ Naijiria CBN lati mu adinku ba ọwọngogo to gbode .

    Wọn ni eyi yoo mu adinku ba bi awọn eniyan se n ya owo, ati bi awọn eniyan se n na owo si.

    Gomina Adele banki apapọ CBN, Fola Shonubi ninu ọrọ rẹ ni banki gbe igbesẹ yii lati mu adinku ba ipalara ti owo iranwọ bẹntiro ti ijọba yọ kuro.

    Bakan naa ni eyi yoo koju ipalara to de ba ọrọ aje lẹyin ti ijọba yọ gbedeke ori owo ilẹ okeere si Naira.

    Eyi yoo tun mu atunṣẹ ba bi ijọba se fẹ pin awọn owo iranwọ yii pada.

    Igbesẹ yii pẹlu awọn igbesẹ ti aarẹ Tinubu gbe lọna ati mu ayipada pa eto ọrọ aje to dẹnukọlẹ ni Naijiria.

    Ọpọlọpọ awọn igbesẹ ni aarẹ Tinubu ti de lati igba to ti gba ipo ni Oṣu Karun un, ọdun 2023 ti wọn burawọle fun.

  12. Olùkọ́ Poly Iree faraya lórí bí Gómìnà Adeleke ṣe yọ Olùdarí ilé ẹ̀kọ́ wọn

    Kii ṣe gbogbo igba lawọn Olukọ a maa fẹnu ko lori ọrọ lọgba ile ẹkọ ni paapa awọn ile ẹkọ giga ni Naijiria.

    Amọ o jọ pe ọkan wọn papọ lori titako Gomina ipinlẹ Osun lori igbesẹ to gbe wi pe ki adari ile ẹkọ gbogboniṣe Poly Ipinlẹ Osun to wa ni Iree lọ rọọkun nile.

    Niṣe lawọn olukọ ile ẹkọ naa ṣe iwọde niwaju ile ẹkọ ọhun ti wọn si gbe lẹkun oju ọna ile ẹkọ naa ti pa.

    Iwadii BBC Yoruba fihan pe akọwe agba ileeṣẹ ẹkọ nipinlẹ Osun M.A.K Jimoh lo buwọlu iwe idaniduro lẹnu iṣẹ lorukọ Gomina si adari ile ẹkọ naa Tajudeen Odetayo.

    Ẹsun ti wọn fi kan adari ile ẹkọ naa ni pe o ṣe owo ile ẹkọ naa kumọkumọ ati pe ko kaju oṣunwọn nidi iṣẹ rẹ.

    Ni esi ti wọn lori ẹsun wọnyii, awọn olukọ ilẹ ẹkọ ọhun sọ pe awọn ko faramọ idaduro ọga awọn lori ẹsun wọnyi.

    Alaga fẹgbẹ awọn olukọ ni Poly Iree Ọmọwe Fatai Afolabi kede pe awọn yoo yanṣẹ lodi ati pe awọn ti dawọ idanwo tawọn akẹkọọ n ṣe lọwọ tori yiyọ adari ile ẹkọ wọn.

  13. Àwọn ohun tí a fẹ́ se fún àwọn ará ìpínlẹ̀ Ogun rèé fun ìrànwọ́ lásìkò ọ̀wọ́ngógó tó gbòde

    Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti ni oun ti se awọn eto silẹ fun awọn araalu lati se iranwọ lasiko ọwọngogo epo bẹntirol yii.

    Ninu atẹjade ti gomina naa fi lede loju opo Twitter rẹ lo ti salaye awọn eto tuntun naa.

    O ni on mọ pe ayọkuro owo iranwọ epo bẹntiro mu ki nkan buru lati aye nira fun awọn araalu.

    Gomina ipinlẹ Ogun ni awọn nkan ti oun yoo pese fun awọn araalu ni;

    • Ijọba yoo maa fun awọn osiṣẹ ni afikun iye owo to to N10,000 bẹrẹ lati osu keje yii fun osu mẹta fun awọn araalu
    • Owo iranwọ pajawiri lasiko iṣẹ fun awọn oṣiṣẹ ni awọn ileewosan nipinlẹ naa.
    • Awọn owo ajẹmọnu fun awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ naa.
    • Lẹta iigbega ni kiakia fun awọn to tọsi lati ọdun 2021 ati ọdun 2022
    • Sisan owo ajẹmọnu Osu Kẹta ati osu kẹrin ọdun 2023 fun awọn oṣiṣẹ nipinlẹ Ogun.
    • Sisan owo ajẹmọnu fun awọn oṣiṣẹ fẹyinti.
    • Awọn ileeṣẹ ijọba gbọdọ ri pe ida ogun awọn oṣiṣẹ wọn ni wọn n sisẹ lati ile lọna ati mu aye rọrun fun awọn araalu.
    • Ipese ounjẹ bii irẹsi, garri, ẹwa, agbado fun awọn araalu ti iya ati iṣẹ n ba finra.
    • Bakan naa ni ijọba yoo pese eroja oko fun awọn agbẹ ni iye ti ko kan ni ni eegun ẹyin.
    • Awọn nkan miran ti ijọba yoo se ni ipese ọkọ fun eto irinna ni iye ti ko kanni ni egun ẹyin.
    • Bakan naa ni ijọba yoo pese eto irina to ja geere fun awọn araalu nipa sise pọ pẹlu awọn adari ileeṣẹ kekere ati nla lati pese iṣẹ fun awọn araalu.
  14. Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ti fi pańpẹ́ mú àwọn tó fẹ́ sekọlù sí Atiku Abubakar

    Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fi panp̣ẹ ọba mu awọn eniyan mẹrin lasiko ti wọn n gbiyanju ati se atako si ile igbakeji aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Atiku Abubakar.

    Abubakar ọun lo dije du ipọ aarẹ labẹ asia ẹgbẹ PDP, to si fi idi rẹmi amọ ẹjọ w ani ileẹjọ.

    Ọkan lara awọn ti ọwọ tẹ naa jẹwọ , to si sọ iru eniyan to jẹ fun awọn agbofinro.

    Ninu ọrọ rẹ, Jubrila Mohammed ni ọmọ ikọ Boko Haram ni oun, ti ọwọ ọlọpaa si tẹ awọn lasiko ti awọn fẹ lọ se ikọlu naa.

    Ninu atẹjade ti agbẹnusọ igbakeji aarẹ tẹlẹri naa sọ ni o ni ni awọn mẹta yoku ni ọwọ naa tẹ, ti wọn jọ n pinnu ati sekọlu naa.

    Atẹjade naa fikun un pe awọn ikọ Boko Haram na tun fẹ sekolu si awọn ileeṣẹ to jẹ ti Atiku Abubakar ni Yola ati ni awọn ibo miean.

    Igbesẹ yii ni wọn n gbw lọwọ, ki ọwọ palaba wọn to segi.

    Nibayii gbogbo awọn ti ọwọ tẹ naa ni wọn ti w ani panpẹ ikọ ọmọogun Naijiriafun ẹkunrẹrẹ iwadii.

  15. Òjò àrọ̀ọ̀rọ̀dá ṣoṣe ní Ibadan, Afárá já, lilọ bibọ di ìnira

    Ojo arọrọda to waye ni Ibadan lọjọ Aiku ni agbegbe Olodo Bank ti ko inira ba awọn araadugbo Monatan, Olodo,Eji Oku ati Lalupon.

    Idiwọ to mu wa ko jẹ ko rọrun fawọn ọlọkọ to fẹ gba agbegbe na koja lọ si Iwo nipinlẹ Ọsun.

    Ojo ọhun to rọ fun bi wakati mẹrin lọsan bẹrẹ ni nkan bi ago mejila ọsan ti afara si ja ni aago mẹta abọ ọsan ana.

    Bo tilẹ jẹ wi pe ko si ẹmi kankan to ba iṣẹlẹ na lọ,ọpọ dukia ati ile to wa ni agbegbe odo naa ni omi ọhun fọwọba.

    Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa to ba akọroyin ile iṣẹ BBC sọrọ ṣalaye wi pe pẹlu bi afara ohun ti yaa si meji,o nira fun awọn olugbe agbegbe naa lati wọ ile wọn lọ.

    Wọn rọ ijọba ipinlẹ Oyo lati ṣeto opopona miran ti awọn olugbe agbegbe naa ma gba kọja,wọn tun rọ Gomina ipinlẹ Oyo Seyi Makinde lati tete wa atunṣe si afara opopona naa to ja.

    Usman Imarole ninu ọrọ tirẹ ṣalaye wi pe awọn agbaṣẹṣe tí ijọba ipinlẹ Oyo gbe iṣe naa fun ko ṣe iṣẹ ọhun daada lo mu ki afara naa ja.

    Usman sọ pe ''bi wọn ba gbe iṣẹ oju ọna ipinlẹ wa fun awọn to n ran bata, wọn yoo ṣe daada ju bi awọnn onikọngila ṣe ṣe eleyi to wa nilẹ yi lọ.''

    O wa ra ọwọ ẹbẹ si ijọba apapọ ati gbogbo awọn ẹka ijọba to n risi ijamba omi yale lati dide iranlọwọ fun awọn ti o sọ dukia wọn nù ninu isẹlẹ naa.

  16. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù Saudi Al-Hilal ṣetán láti kó £259m lè Mbappe

    Bi o ba fi le bọ si, agbabọọlu ọmọ orileede France nii Kylian Mbappe ni yoo jẹ agbabọọlu ti yoo maa gba owo julọ lagbaye.

    Iroyin to tẹwa lọwọ bayii ni ẹgbẹ agbabọọlu Saudi Al Hilal ti fi erongba wọn lelẹ lati san ọ̀tàlénígba din kan miliọnu pọun fun PSG ki wọn fi le ta agbawaju yi fun wọn.

    Ọmọ ọdun mẹrinlelogun yi to tun jẹ balogun ikọ France ni ọdun kan to yi ṣẹku lklori adehun to ni pẹlu PSG to si kọ lati buwọlu alekun ọjọ lori adehun yi.

    Koda ko pẹlu awọn ọmọ ikọ agbabọọlu naa to ṣe irinajo lọ si Japan ṣaaju ibẹrẹ saa liigi tuntun.

    PSG lawọn fẹ ta Mbappe ni kiakia dipo ki wọn dajọ si tita agbabọọlou ọhun.

    Owo ti PSG san lori Neymar lọdun 2017,£200m ṣi ni owo to pọju lọ ti wn san lori agbabọọlu lagbaye.

  17. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ girama dá olùkọ́ lọ́nà, lù ú lálùbami ní Ogun

  18. A fẹ́ sin okù èèyàn 103 tó kú lásìkò Endsars, àmọ́ kò sí ẹnikẹ́ni láti Lekki Tollgate nínú wọn

  19. Ènìyàn 17 ni àìsàn Diphteria ti pa ní Kaduna báyìí

    Iye awọn eniyan ti wọn ti ku lẹyin ti wọn lugbadi arun Diphteria ni Kaduna ti da mẹtadinlogun.

    Bakan naa ni awọn mejidinlaadọrin miran si ti lugbadi arun naa ti wọn si n gba iwosan lọwọ.

    Ijọba ipinlẹ Kaduna lo fi iroyin naa lede lori itankalẹ aarun naa ni ipinlẹ Kaduna.

    Ninu awọn to doloogbe naa, eniyan mẹrinla ninu wọn ni wọn wa lati agbegbe Kafanchan ati ijọba ibilẹ Jema’a, ti awọn mẹta miran si tun gbẹmi mi ni ijọba ibilẹ Makarfi.

    Ileeṣẹ iroyin Channels TV jabọ pe wọn si n reti esi ayẹwo ti wọn se fun eniyan bii ofun ti wọn se ayẹwo fun.

    Ijoba ni eniyan mejidinlaadọta ni wọn n gba iwosan lọwọ, ti ara wọn ko si kọ eto ilera ti wọn n fun wọn.

    Agbẹnusọ ileeṣẹ eto ilera ti ijọba ipinlẹ Kaduna, Jeremiah Daikwo ni awọn alaisan bii mejila ni wọn w ani ilewosan Makarfi, nigba ti awọn eniyan marundinlogoji.

    Lori igbesẹ ti wọn n gbe lati dẹkun ajakalẹ arun naa ni ijọba ipinlẹ Kaduna ni awọn n gbiyanju lati sawari awọn to ti faragba ninu arun naa ki wọn si tete ko wọn lọ fun itọju to peye.

    Bakan naa lo fikun un pe awọn eleto ilera n tẹsiwaju lati maa sawari awọn eniyan to b ani aarun naa ni ijọba ibilẹ mẹtalelogun ni ipinlẹ naa.

    Ti wọn si ni awọn n sisẹ pọ pẹlu awọn olori ati awọn adari ẹlẹgbẹjẹgbẹ lati sawari awọn eniyan naa ati lati dẹkun itankalẹ arun naa.

  20. Ènìyàn 12 ló ti gbẹ́mí mì lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ilé alájà mẹ́rin tó dàwó

    Awọn ẹṣọ alaabo ati awọn panapana ti gbiyanju lati doola ẹmi awọn eniyan lẹyin ti iṣẹlẹ ile to dawo to waye ni Cameroon.

    Ajọ panapana ni o kere tan eniyan mejila lo tib a iṣẹlẹ naa lọ ni Ọjọ Aiku, ti eniyan to le ni mọkanlelogun si farapa ninu iṣẹlẹ naa.

    Agbegbe Douala ni iṣẹlẹ ọhun ti waye, ni agbegbe ti awọn eniyan ti n se karakata.

    Ile alaja mẹrin naa lo dawo lori ile miran ni nkan bii aago kan our ni ẹkun ariwa ilu naa.

    Ijọba ibilẹ ni agbegbe naa ni awọn adoola ẹmi ti n wa awọn ti wọn ha si inu ile naa

    Ilewosan Laquintinie ni Douala ni eniyan mẹtala ni wọn ko wa si ibẹ, amọ ọmọdebinrin ọdun mẹta ati ọdọ ẹni ọdun mọkandinlogun ku ni ileewosan.

    Wọn fikun un pe awọn ọmọde mẹta kan n gba itọju pajawiri lọwọ.