Akọ́nimọ̀ọ́gbá Adegboye Onigbinde di agbẹnusọ fún àwọn àgbàìlẹ̀ Yorùbá
Ẹgbẹ igbimọ awọn agba ilẹYoruba ti yan akọnimọọgba awọn agbabọọlu orilẹ-ede yii nigbakanri Oloye Adegboye Onigbinde gẹgẹ bi aṣoju igbimọ agba ilẹ Yoruba.
Dokita Victor Taiwo ẹni ti o pe ipade awọn agba Yoruba ni, asiko ti to fun iran Yoruba lati fohun kan sọrọ.
Ipade naa lo waye ninu gbagede awọn lọba lọba to waye ninu ọfiisi ipinlẹ Oyo.
Taiwo ni ija to wa laarin awọn agba to n ṣoju ilẹ Yoruba lọ fa idi ti olori tuntun fi gbọdọ wa.
Taiwo ninu ọrọ rẹ ṣalaye wi pe "ti wọn ba ni ki ẹgbẹ Yoruba mu aṣoju iran Yoruba kan wa ẹgbẹ wo ló fẹ ran eeyan lọ, ṣe ẹgbẹ afenifere ni, ṣe afenifere Ayo Adebanjo ni? abi ti Fasoranti, abi ti Ayo Fasanmi ewo nibẹ?
Idi niyi ti a fi nilo lati yan aṣoju tuntun fun ilẹ Yoruba ti kii ṣe oloṣelu to si jẹ oloootọ, to nifẹ iran Yoruba.
Taiwo ni pẹlu igbesẹ yii aaye wa fun awọn igun Yoruba miran lati darapọ mọ ẹgbẹ agba ilẹ Yoruba tuntun kí iran Yoruba le fi ohun kan sọrọ".
Ninu ọrọ rẹ oloye Adegboye Onigbinde ni iṣẹ tuntun ni iran Yoruba gbe le oun lọwọ gẹgẹ bi aṣoju agba ile Yoruba ti oun yoo fi gbogbo agbara ṣe.
Akọnimọọgba awọn agbabọọlu orilẹ-ede yii nigbakanri tẹ siwaju ninu ọrọ rẹ wi pe "ilẹ Yoruba ti jẹ ọpọlọpọ iya latẹyin wa, mi o fẹ ki awọn ọmọ mi ati awọn ọmọ rẹ jẹ iru iya bẹẹ.
Oun ti a o kọkọ ṣe ni wi pe a o wa ọna ti ẹnu wa yoo ṣe ko, to fi jẹ wipe ibi ti a ba nlọ ni ao maa wi pe a nlọ."
Onigbinde jẹjẹ wipe oun ko ni fi oṣelu ṣe iṣakoso ki idagbasoke le ba iran Yoruba, nitori ẹbun pọ lara awọn ọdọ Yoruba.
Lara awọn to peju sinu Ipade naa ni Erelu Abiola Dosunmu Yeye Oba ti Ile Ife ti wọn yan gẹgẹ bi igbakeji oloye Onigbinde, Ọba Micheal Odunayo Ajayi, Arowotawaya Ẹlerinmo ti Erinmo Ijesha, Aṣoju Olubadan ti ilẹ Ibadan Ọba Mamhood Olalekan Balogun, atawọn aṣoju ẹgbẹ ilẹ Yoruba.