You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Kókó ohun méje tóo ní láti mọ̀ tóo bá ń wá iṣẹ́ tó léè fún ọ ní “visa” ní UK

  2. Ó ṣe! Ìyáwó jáde láyé lọ́jọ́ ìgbéyàwó rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oyo

  3. Ẹ gbà wá o, àwọn Daran-daran yìí ń pa ni lẹ́kún jayé, wọ́n tún jó wa mọ́lé! - Àwọn èèyàn Yewa North

  4. Àlàyé lórí bí ayẹyẹ ọdún Ọlọ́runbọrùn Udiroko ṣe lọ lónìí rèé nílùú Ado-Ekiti

  5. Mnangagwa borí ìbò ààrẹ Zimbababwe fún sáà kejì

  6. A ó ṣe ìwádìí ẹ̀dà àrùn Covid-19 tuntun ní ìpínlẹ̀ mẹ́rin – NCDC

  7. 'Owó iná ni mo lọ bèèrè lọ́wọ́ òṣìṣẹ́ DSS kó tó gún mi ní ọ̀bẹ'

  8. Irú èpè wo ni Aláàfin Aole ṣẹ́ fún ìran Yorùbá tí wọn ló ń jà di àkókò yìí?

  9. Fásitì Ibadan pohùndà lórí àdíkùn tí wọ́n mú bá iye ọjọ́ tí àwon òṣìṣẹ́ yóò máa fi lọ ibi isẹ́

  10. A kò ní gbà kí Niger lo àwọn ajaguntà ilẹ̀ míì láti kojú àwọn ọmọ ogun wa – ECOWAS

    Ajọ ECOWAS ti sọ pe oun ko tii mu ọjọ pato ti yoo kogun lọ si orilẹ-ede Niger.

    Amọ o ti kilọ fun awọn ologun to ditẹgbajọba nibẹ ki wọn ṣọra fun lilo awọn ajagunta lati ilẹ mii nitori yoo lẹyin.

    Aarẹ ECOWAS Commission, Omar Touray, sọ pe bo tilẹ jẹ pe awọn ko tii mu ọjọ ti awọn yoo ko ija wọ Niger ajọ naa ti fofin de Niger, yoo si kogun wọ ilẹ naa amọ yoo jẹ lọna to ba ofin mu.

    O ni oun gbagbọ pe oniruru ijiroro ti awọnṣe pẹlu awọn aditẹgbajọba naa yoo so eso rere laipẹ amọ ṣa awọn ọmọ ogun ECOWAS yoo wa ni ṣẹpe lati kọlu orilẹ-ede naa ti gbogbo igbiyanju awọn ko ba so eso rere.

    Lori ọrọ awọn ajagunta Wagner, ECOWAS sọ pe oun ko ni gba ki Niger lo ajagunta kankan lati ilẹ mii.

    Touray tun ke si awọn aditẹgbajọba Niger lati ri daju pe alaafia ni Aarẹ Mohamed Bazoum atawọn mọlẹbi rẹ, ki nnkankan ma si ṣe wọn.

    Wayi o, olori awọn aditẹgbajọba naa, Abdourahmane Tchiani, ti sọ fun ECOWAS pe awọn koni da Bazoum pada sori alefa.

    Gbogbo orilẹ-ede to jẹ ọmọ ẹgbẹ ECOWAS lo ti ṣeleri lati fi ọmọ ogun ranṣẹ ti akoko ba to lati kọlu Niger.

  11. Tinubu rán àwọn olórí ẹ̀sìn Islam sí orílẹ̀-èdè Niger fún ìjíròrò àláfíà

    Aarẹ Bola Tinubu ti ran awọn adari ẹsin Islam kan, Ulama, lọ si orilẹ-ede Niger fun itẹsiwaju ijiroro alaafia lẹyin iditẹgbajọba to waye nibẹ.

    Tinubu lo gbe igbesẹ yii lẹyin ipade kan pẹlu awọn adari ẹsin Islam naa, eyii ti Sheikh Dahiru Bauchi, n dari.

    Ṣaaju ni awọn adari Musulumi ọhun ti kọkọ lọ siluu Niamey, to jẹ olu ilu orilẹ-ede naa ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin fun ijiroro.

    Aṣẹ tuntun yi ni Tinubu pa gẹgẹ bii alaga ajọ ECOWAS.

    Lati igba ti awọn ologun ti gbajọba lọwọ Aarẹ Mohamed Bazouma loṣu to kọja ni Niger ni ECOWAS ti fofin de orilẹ-ede naa, eyii to mu ko maa padani awọn anfani kan to n jẹ tẹlẹ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ ECOWAS.

    Ni bayii, ECOWAS ti fontẹ lu ikọ ọmọ ogun ti yoo kọlu Niger lati gba ijọba naa pada, amọ awọn ọmọ ogun ọhun ṣi wa ni ṣepẹ titi di igba ti iṣẹ yoo kan wọn lẹyin oniruru ijiroro atawọn ipade alaafia to n lọ lọwọ.

    Lara awọn to ti n gbiyanju lati yanju aawọ Niger naa pẹlu suuru ni aṣoju ECOWAS si Niger, to tun jẹ ajagunfẹyinti ati adari ologun Naijiria nigba kan ri, Abdusalami Abubakar.

    Ẹwẹ, Abubakar ti sọ fun ilẹeṣẹ ioryin BBC pe gbogbo ọna ti ECOWAS mọ ni yoo gba lati yanju ọrọ naa kaka ki wọn lọ kogun ja orilẹ-ede Niger.

    Wayi o, awọn ologun to ditẹgbajọba lorilẹ-ede naa ti sọ pe yoo gba awọn to ọdun mẹta ki awọn to le gbe ijọba ọhun kalẹ fun oloṣelu.

  12. Ìdí tí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Eko ṣe kọ̀ láti fi òǹtẹẹ̀ lu Akin Abayomi, Omotsho àtàwọn 15 míràn fún ipò Kọmisọna

  13. Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ kí ọlọ́pàá mú ẹni tó ni ilé alájà méjì tó dàwó l’Abuja

  14. Ẹbí ‘Tani Ọlọhun’ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn Shehu àti àgbàgbà ẹ̀sìn ní Ilorin láti dáríjin èèkàn Oníṣẹ̀ṣe náà

  15. Wọ́n bá òkú olùbádámọ̀ràn Sẹ́nétọ̀ lẹ́gbẹ́ títì, ẹbí pè fún ìdájọ́ òdodo

  16. Ilé ẹjọ́ fún Ààrẹ Central African Republic lágbára láti wà lórí oyè títí láí

    Ile ẹjọ to ga julọ ni Central African Republic ti fọntẹ lu abọ ipade apero awọn eeyan orilẹ-ede naa, eyii to fun Aarẹ lanfani lati lo ọdun meje lori alefa fun saa kan, to tun fun Aarẹ naa laafani lati dije du ipo ni iye igba to ba wu lai ni gbedeke.

    Ile ẹjọ ọhun ni ida 95% awọn to dibo nibi apero naa lo sọ pe awọn faramọ igbesẹ ọhun ninu ida 57% awọn eeyan orilẹ-ede naa to kopa ninu rẹ.

    Ofin tuntun orilẹ-ede naa faye gba Aarẹ lati yan igbakeji rẹ.

    Bẹẹ naa lo tun fofin de awọn oloṣelu to jẹ ọmọ orilẹ-ede naa pẹlu orilẹ-de mii lati maṣe lafani lati dije du ipo Aarẹ, o si sun iye adajọ ile ẹjọ to ga julọ siwaju lati mẹsan an si mọkanla.

    Wayi o, awọn ọmọ ẹgbẹ alatako ti koro oju si ofin tuntun ọhun, wọn si sọ pe o jẹ ọna eburu lati fi Aarẹ Faustin-Archange Touadéra sori oye titi lai.

    Awọn ẹgbẹ alatako naa tun sọ pe aṣẹ Russia ni awọn ọmọ igbimọ to ṣatunṣe ofin naa tẹle.

    Ẹwẹ, awọn ajagunta Wagner n ṣatilẹyin fun Aarẹ Touadéra, koda, awọn ajagunta naa ti de si orilẹ-ede naa bayii lati pese abo.

    Ọdun 1960 ni Central African Republic gba ominira lọwọ orilẹ-ede France, lati ọdun naa lo si ti n bọ sinu isọro kan lati omiran.

  17. Tani ‘Tani Ọlọhun’tó ń dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ fún àwọn Alfaa ìlú Ilorin?

  18. Ìpínlẹ̀ Oyo pàdánù rẹfirí méjì láàrín ọjọ́ méjì

  19. Aláìsàn 620 jáde láyé lẹ́yìn tí àwọn òṣìṣẹ́ ètò ìlera da iṣẹ́ sílẹ̀ ní Mozambique

    O kere tan, ẹgbẹta ati ogun eeyan lo ti jade kaye bayii ni Mozambique latari bi awọn oṣiṣẹ eto ilera ṣe da iṣẹ silẹ nibẹ.

    Eyii lo n waye lẹyin ti awọn oṣiṣẹ eto ilera naa da iṣẹ silẹ fun ogoji ọjọ o le, nile iwosan Maputo Central Hospital.

    Igba akọkọ ree ti awọn oṣiṣẹ eto ile ilera yoo da iṣe silẹ lorilẹ-ede naa, awọn dokita si ti sọ pe awọn yoo fi ọjọ mọkanlelogun le iyanṣelodi awọn bo tilẹ jẹ awọn eeyan kan n dunkoko mọ wọn.

    Awọn dokita naa ni awọn yoo ṣi maa da awọn eeyan kọọkan lohun botilẹ jẹ pe iyanṣelodi ọhun n tẹsiwaju.

    Gẹgẹ bii ohun ti awọn oṣiṣẹ eto ilera naa sọ, eredi iyanṣẹlodi awọn ko ṣẹyin bi ijọba ṣe kuna ati pese oogun atawọn irinṣẹ mii fun lilo.

    Wọn sọ siwaju si pe owo ara awọn lawọn fi n ra awọn ohun elo to yẹ ko wa ninu ọkọ ‘ambulance” awọn ko si ni ọna abayọ mii mọ ju ki wọn da iṣẹ silẹ lọ.

    Ẹwẹ, ijọba ilẹ naa ti sọ pe inu oun ko dun si igbesẹ awọn oṣiṣẹ eto ilera naa lati da iṣẹ silẹ nitori oun ti bẹrẹ igbesẹ lati pese awọn ohun ti wọn n bere fun.

  20. Olga Carmona gbọ́ ìròyìn ikú bàbá rẹ̀ lẹ́yìn tó gba ife ẹ̀yẹ World cup àwọn obìnrin fún Spain