You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìjìyà tí àjọ ECOWAS n fún Niger tí bẹ̀rẹ̀ sí fa ọ̀wọ́n gógó owó ọjà

    Ìjìyà tí àjọ ECOWAS n fún Niger tí bẹ̀rẹ̀ sí fa ọ̀wọ́n gógó owó ọjà

    Awọn olùgbé ni àwọn agbegbe kan ni orile-ede Niger ti bẹrẹ si ké ìrora nitori owó gege to gun ori ọjà lẹyin ti ìjọba ológun ti ẹnubodè.

    Diẹ lara awọn ọmọ orile-ede naa, paapa awọn oniṣowo, lo ti fi owo kún owó ọjà, pẹlu awawi pe igbesẹ wọn ko ṣẹyin awọn ijiya tó bá orile-ede naa nitori iditẹgbajọba to waye ni Ọjọ́rú ọ̀sẹ̀ to kọja.

    Eyi n waye lasiko ti awọn orile-ede to wa ninu àjọ ECOWAS (akojọpọ àwọn orile-ede to n ṣe ọrọ̀ ajé pọ̀ ni Ìwọ-oòrùn Africa) ti ti n fi opin si karakata pẹlu Niger.

    Orile-ede Benin to pààlà pẹlu Niger ni Ariwa, ti ti ibodè rẹ pa.

    Yatọ si ijiya yii, Ecowas tun fun awọn ológun naa labẹ ìṣàkóso Ọgagun Abdourahmane Tchiani ni gbedeke ọ̀sẹ̀ kan lati da Basoum pada sipo

    Bakan naa ni awọn ológun to gba ijọba lọwọ Aarẹ Mohamed Bazoum, kede pe àwọn ti ti ibode orile-ede naa lori òkun, ofurufu, ati ori ilẹ̀.

    Akọroyin BBC Hausa, Tchima Ila Issoufou, jábọ̀ pé owó ọjà rírà ti wọn gan-an niluu Yamai, olu ilu orile-ede Niger.

  2. Ọkọ̀ òfurufú já lulẹ̀ ní Eko, àwọn ènìyàn farapa

  3. Gbogbo atótónu ti parí, ọjọ́ tí a máa gbé ìdájọ́ kalẹ̀ rèé - ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò Ààrẹ

  4. Binta Ayo Mogaji, Fathia Balogun, Sola Kosoko ṣèdárò 'Bufallo', àgbà òṣèré tó jáde láyé

  5. Kazeem Dosunmu, Alfa tó fi owó ilé ẹ̀kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ kọ́ afára fún ìlú rẹ̀

  6. Russia ju àdó olóró sí ìlú Ààrẹ Ukrain, èèyàn mẹ́fà jáde láyé

    O kere tan, eeyan mẹfa lo ti jae laye lẹyin ti ado oloro orilẹ-ede Russia kan balẹ si ilu Kryvyi Rih.

    Ọmọdebinrin ọdun mẹwaa kan ati iya rẹ wa lara awọn to ba ado oloro naa lọ.

    Minisita fun ọrọ abẹle Ukraine sọ pe yatọ si awọn to ku, eeyan mọ́kàndínláàdọ́rin mii tun farapa ninu ikọlu ọhun.

    Gomina agbegbe ibi ti ado oloro naa ti ṣọṣẹ, Serhiy Lysak ti kede ọjọ ọfọ kaakiri agbegbe ọhun.

    Kii ṣe igba akọkọ ree ti Russia yoo ju ado oloro siluu naa to jẹ ibi ti wọn ti bi Aarẹ Volodymyr Zelensky.

    Ninu oṣu Kẹfa, eeyan mọkanla lo ku, nigba ti awọn mejidinlọgbọn mii jade laye lẹyin ti Russia ju ado oloro siluu naa.

    Aarẹ Zelensky sọ pe ile alaja pupọ kan ati ọgba ile ẹkọ fasiti kan ni ado oloro naa kọlu, nibi to ti ba ọpọ dukia jẹ yatọ si awọn to jade laye.

    Nnkan bii aago meje aarọ ni ikọlu ọhun waye.

  7. Ẹ lọ fọkàn balẹ̀, a ó ṣe àfikún owó oṣù yín láìpẹ́ – Tinubu sí àwọn òṣìṣẹ́

    Aarẹ Bola Tinubu ti sọ pe ijọba apapọ yoo ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ ijọba laipe, ti wọn yoo si kede iye owo oṣu tuntun awọn oṣiṣẹ to lkere julọ.

    Tinubu lo fi ọrọ yii lede lasiko to n ba awọn ọmọ Naijiria sọrọ lọjọ Aje nibi to ti sọ ọpọ ọrọ nipa ọrọ aje Naijiria.

    Gẹgẹ bii ohun to sọ, igbesẹ naa jẹ ọkan lara awọn ọna lati maye dẹrun fawọn araalu lẹyin ti ijọba rẹ yọ owo iranwọ ori epo bẹntiro.

    O ni “bakan naa, a ti n ṣiṣẹ ni ifọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ fun iye owo oṣu oṣiṣẹ to kere julọ.”

    “Nnkan ti mo fẹ sọ fun awọn oṣiṣẹ ree: ẹ lọ fọkan balẹ, owo oṣu tuntun n bọ fun yin laipẹ.”

    “Ni kete ti a ba ti fẹnuko lori iye owo oṣu tuntun naa, a o ṣe alakalẹ eto iṣuna lati bẹrẹ si n san owo ọhun.”

    Tinubu tun kan sara si awọn ileeṣẹ aladani to ti ṣe afikun owo oṣu awọn oṣiṣẹ latiri bi nnkan ṣe le koko laarin ilu nitori igbesẹ ti ijọba rẹ gbe lori afikun owo epo.

  8. Wo kókó márùn-ún tó wà nínú ọ̀rọ̀ tí Tinubu bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ

  9. Lásìkò tí Nàìjíríà ń pariwo àfikún owó oṣù, ńṣe nìjọba Oyo tún ń dín wa lówó àjẹmọ́nú - NLC Oyo

  10. Kò sí bí ológun tún ṣe lè rí ìjọba gbà mọ́ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà - Ọ̀gágun Adisa Raji, gómìnà ológun nígbàkanrí

  11. Àgbàrá òjò gbé ilé 100, ewúré 15 lọ ní Gombe

    Ko din ni ọgọrun ile ti agbara omiyale ti gbe lọ bayii ni ipinlẹ Gombe, eyii to sọ nnkan bii ẹẹdẹgbẹta eeyan di alairilegbe.

    Ilu Dogon Ruwa, ni ijọba ibilẹ Kaltungo, ni iṣẹlẹ naa ti waye.

    Adari ilu ọhun, Aliyu Isah ṣalaye fun awọn akọroyin pe lara awọn ẹranko ti agbara ojo naa gbe lọ ni ewurẹ ati agutan wa.

    Isah, to tun jẹ Sa’in ilu Dogon Ruwa ilu naa sọ pe awọn alaṣẹ ijọba ibilẹ naa mọ ohun ti awọn n dojukọ amọ ijọba ko ṣe iranlọwọ kankan fun awọn.

    O ti wa ke si ijọba ipinlẹ naa bayii lati wa nnkan ṣe si ọrọ omiyale naa.

    Oni “awa olugbe Dogon Ruwa fi akoko yii ke si ijọba lati ran wa lọwọ.”

    “A nilo ile gbigbe ati ounjẹ… a ti fi ọrọ naa to alaga ijọba ibilẹ wa leti.”

    “Nnkan bii ewurẹ ati agutan marundinlogun la padanu, ọgọrun ile lo si baiṣẹlẹ naa lọ, nigba ti ẹẹdẹgbẹta eeyan ko ni ile lori mọ.”

  12. Ìyanṣẹ́lódì wa yóò tẹ̀síwájú títí tí ìjọba yóò fi ṣe àwọn ohun tí à ń fẹ́ – Ẹgbẹ́ àwọn dókítà, NARD

    Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NARD, ti sọ fpe iyanṣẹlodi awọn yoo maa tẹsiwaju titi ti ijọba apapọ yoo fi ṣe awọn ohun ti awọn n bere fun.

    Ọrọ yii lo n jade nibi ipade kan ti ẹgbẹ ọhun ṣe ni bayii ti iyanṣẹlodi naa ti wọ ọjọ kẹrin.

    Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita naa, dokita Emeka Oji sọ pe, titi di akoko ti ipade wọn naa n waye, ijọba apapọ ko tii da si ohun ti awọn n bere fun.

    Oji ni awọn yoo tẹsiwaju ninu iyanṣẹlodi ọhun “titi di igba ti ijọba yoo ṣe awọn ohun ti a bere fun ninu gbedeke ti a fun un lọjọ karundinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023.”

    Dokita Oji rọ ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi ṣada lori ọrọ ọhun ki gbogbo nnkan to dojuru ni ẹka eto ilera kaakiri Naijiria.

    Nnkan bii ẹgbẹrun marundinlogun dokita lo jẹ ọmọ ẹgbẹ NARD yii ninu nnkan bii ẹgbẹrun lọna ogoji dokita ni Naijiria.

    Bo tilẹ jẹ iyanṣẹlodi NARD yii fẹsẹ mulẹ, igun keji ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NMA, ko darapọ mọ wọn.

    Lori ibaṣepọ to wa laarin ẹgbẹ awọn mejeji, Oji sọ pe “a ṣi n ba NMA sọrọ lọwọ, a o si tẹsiwaju ninu ijiroro wa pẹlu wọn.”

    “A ke si gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ wa lawọn ipinlẹ ki wọn ni ijiroro pẹlu awọn aṣoju NMA ipinlẹ wọn, nitori a ko le da ija yii ja nikan.”

  13. NLC yóò bẹ̀rẹ̀ ìyanṣẹ́lódì ní Aug. 2, àwọn nǹkan tó yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀ nìyí

  14. Ìjọba kéde ìséde òní wákàtí mẹ́rìnlélógún ní Adamawa, O ní ikede yi waye lọna ati dẹkùn iwa janduku to n waye ni ipinlẹ ọhun.

    Gomina ipinlẹ Adamawa Ahmadu Umar Fintiri ti kede isede oni wakati mẹrinlelogun bẹrẹ lati ọjọ Aiku tii ṣe ọgbọn ọjọ oṣu Keje.

    O ní ikede yi waye lọna ati dẹkùn iwa janduku to n waye ni ipinlẹ ọhun.

    Gẹgẹ bo ṣe wi awọn janduku yi ti n se ikọlu sí àwọn aráàlú pẹlu nkan ija oloro bẹẹ lọ sí ní wọn a máa fọ ṣọọbu ko ẹrù lọ níbẹ.

    O ni ẹnikẹni tó ba tapa si ofin yi yóò foju wina ofin.

    Jakejado ipinlẹ ni ko ti ni ṣi lilọ bibọ ayafi awọn to ba n ṣe iṣẹ tó pọndandan nikan lo le wà níta.

  15. Ọkọ lé ìyàwó rẹ̀ kúrò nílé nítorí pé ọkùnrin ni dókítà tó gbẹ̀bí rẹ̀ lásìkò tó bímọ

    Ọkunrin kan nipinlẹ Katsina ti kọ iyawo rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹrinla silẹ nitori pe ọkunrin ni dokita to gbẹbi rẹ lasiko to n bimọ.

    Ajafẹtọ ọmọniyan kan, to tun jẹ adari ajọ Nana Women and Girls Initiative, Fatima Adamu lo fi ọrọ naa lede nibi ipade kan to waye niluu Abuja.

    Gẹgẹ bii ohun ti Adamu sọ, nnkan fẹ yiwọ lasiko ti iyawo ọkunrin naa n rọbi lọwọ eyii to mu ki wọn gbe digbadigba lọ sile iwosan.

    Amọ nigba ti wọn yoo fi gbe de ile iwosan, ko si dokita to jẹ obunrin nilẹ ayafi ọkunrin.

    Bo tilẹ jẹ pe a gbọ pe ọmọ naa bi ọmọ inu rẹ layọ ati alaafia, ọkọ rẹ fari ga nitori pe ọkunrin ni dokiya to gbẹbi rẹ, eyii to tu igbeyawo naa ka.

    Adamu ti wa rọ ijọba, paapaa awọn ijọba ipinlẹ lati dẹkun idẹyẹsi awọn obinrin ti wọn ba ti n gba awọn eeyan siṣẹ lawọn igberiko.

    Bakan naa lo tun kọminu lori bi awọn oṣiṣẹ eto ilera Naijiria ṣe n salọ soke okun latari bi nnkan ṣe ri ni Naijiria.

    O fi kun pe awọn ijọba ipinlẹ gbọdọ ṣe ojuṣe wọn lati ri daju pe awọn oṣiṣẹ eto ilera to dantọ wa lawọn ile iwosan kaakiri ipinlẹ wọn.

  16. Ìbúgbàmù inú ọjà mú ẹ̀mí èèyàn mẹ́sàn án lọ ní Thailand, 115 míì farapa yánayàna

    O kere tan, eeyan mẹsan an lo ti jade laye, ninu eyii ti ọmọ wẹwẹ mẹta wa, lẹyin ibugbamu to waye ninu ọja kan lorilẹ-ede Thailand.

    Inu ọja kan ti wọn ti n ta ina ti awọn eeyan fi n ṣere ‘fireworks’ ni iṣẹlẹ laabi naa ti waye lagbagbe Sungai Kolok, to jẹ ala ilẹ Thailand ati Malaysia.

    Yatọ si eeyan mẹsan an to ba iṣẹlẹ yii lọ, ọgunrun eeyan ati marundinlogun mii tun farapa nibẹ.

    Awọn olugbe agbegbe ibi ti ibugbamu ọhun ti waye ṣalaye pe o milẹ titi, o si yọ orule ati ferese awọn ile to wa layika kuro.

    Iroyin ni ina to sẹyọ lasiko ti awọn oṣiṣẹ kan n jo irin mọ irin ninu ọja nalo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun.

    Seksan Taesen, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe inu ile ni oun wa ti oun ti gbọ ibugbamu naa.

    O ni “mo ri orule ile mi to pin si meji, mo si ri ile to ti dawo ati ọpọ oku ti wọn sun nilẹ.

    Wayii o, kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ bayii yoo waye lagbagbe naa.

  17. Mo ṣèsì lo ATM oníbàárà gba owó ni ẹ màrún-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ - Òṣìṣẹ́ Banki tẹ́lẹ̀rí

  18. Inú bàbá mi kò dùn bí mo ṣe bọ́ aṣọ lórí pápá - Asisat Oshoala

  19. Wo àwọn orílẹ̀ èdè tí ológun ti gbàjọba láìpẹ́ yìí

  20. 'Mo pàdánù ọmọ mẹ́ta sọ́wọ́ ogun ní Sudan'