You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ṣé òótọ́ ni pé ayédèrú ìwé ẹjọ́ ni wọ́n fi rán ‘Tani Ọlọ́hun’ lọ s’áhámọ́ fún ẹ̀sùn bíba àwọn Alfa Ilorin lórúkọjẹ́

  2. Àwọn àwòrán tó jojú ń gbèsè nípa àjọ̀dún ìṣẹ̀ṣe tọdún 2023 rèé

  3. ‘Àwa oníṣẹ̀ṣe kìí ṣe oníṣẹ́ ibi’

  4. 'Àwọn Ọba ilẹ̀ Yorùbá nílò láti múra kí ìṣẹ̀ṣe má ti ọwọ́ wọn parun'

  5. Àwọn agbófinró dúró wámúwámú lódò Yemoja n'llọrin, ọdún Ìṣẹ̀ṣe kò wáyé níbẹ̀

  6. Àjọ WHO ṣàwárí ẹ̀dà àrun polio tuntun lára èèyàn mọ́kànléláàdọ́ta ní Naijria

    Ajọ WHO ti sọ pe eeyan mọkanlelaadọta ọtọtọ lo lugbadi ẹda “cVPV2” to jẹ ti arun polio laarin oṣu kinni si oṣu Kẹjọ ọdun yii.

    WHO ni ijọba ibilẹ marundinlogun ni iha Ariwa Naijiria ni arun naa ti milẹ titi julọ, o si ti n kọ awọn eleto ilera agbegbe naa lominu bayii.

    Aṣoju ajọ WHO si Naijiria, Walter Mulombo, lo fi ọrọ ọhun lede nibi ipade apero kan to waye niluu Kaduna.

    Lara awọn to wa nibi ipade naa ni awọn aṣoju agbegbe to jina rere lawọn ipinlẹ bii Kaduna, Kebbi, Sokoto, Zamfara, Katsina, ati Kano.

    Eredi ipade apero naa ni lati wa ojutu si awọn ipenija to n waye lẹka eto ilera lawọn ipinlẹ ọhun.

    Mulombo sọ pe eeyan mẹtadinlaadọta ninu awọn mọkanlelaadọta to ni arun cVPV2 ọhun lo wa agbegbe iha iwọ oorun ariwa.

    O ni awọn agbegbe to ku ti arun naa tun ti ṣọṣẹ jẹ ibi ti ipenija eto abo wa.

    Mulombo fi kun pe eto abo to dagẹgẹ ariwa Naijiria wa lara ohun to mu ki eto ilera awọn eeyan agbegbe naa buru jai.

  7. Ilé ẹjọ́ fẹ́sùn ìpànìyàn kan nọ́ọ̀sì tó pa ọmọdé jòjòló mẹ́wàá

  8. Àwọn tálákà ló gbọ́dọ̀ jẹ àǹfàní ₦5bn tí ìjọba àpapọ̀ fẹ́ fún àwọn gómìnà jùlọ - àwọn onímọ̀

  9. Ìdí tí Gómìnà Adeleke ṣe yan olùdámọ̀ràn fún 'government house pool' ní ìpínlẹ̀ Osun - Ìjọba ìpínlẹ̀ Osun

  10. Ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi : Ẹ̀gbọ́n mí kú fún ìrètí gbogbo wa

    Aburo ọkan lara awọn eeyan to padanu ẹmi rẹ ninu Ijamba ọkọ oju omi to waye lorilẹede Cape Verde sọ fun BBC pe o un gbinyanju lati de si orilẹede Spain.

    O to ọgọta eeyan to ku ninu ijamba ọkọ oju omi, to ti wa lori fun oṣu kan. Pupọ awọn eeyan lo wa lati orilẹede Senegal. "Gbogbo wa lo yalẹnu. Ọkan lara opo idile wa ni,"

    Mamour Ba sọrọ nipa ẹgbọn rẹ Cheikhouna. Sugbọn, Ba, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni oun yoo si tun gbinyanju lati kuro lorilẹede Senegal nitori o nira lati se orire lorilẹede Senegal to wa.

    Mẹta ninu awọn ọmọ iya rẹ ọkunrin ati ọmọ ẹgbọn baba rẹ lo kan agbako iku ojiji ninu ijamba ọkọ oju omi oni pako to gbera lati abule Fass Boye pẹlu eeyan kan le ni ọgọrun un lọ si ilẹ Europe.

    "Wọn fẹ lọ si orilẹede Spain. Wọn sọ fun mi pe awọn fẹ lọ, n ko si le sọ fun pe ki wọn ma lọ nitori wọn ti ipinnu lọkan wọn.

    O ro pe gbogbo wọn ti ku, ko to wa gba ipe lati Cape Verde lọjọru pe wọn ri awọn kan dola. Wọn wa lara eeyan mejidinlogoji, pẹlu ọmọde ti yi yọ sita ninu omi Ba ni oun ko ti le sọ nipa ilera awọn mọlẹbi rẹ,

    "Wọn ko ni okun lati salaye nnkan to sẹlẹ , wọn kan ni awọn wa laaye.

    " Sugbọn ifọrọwerọ naa fihan pe ki se gbogbo wọn lo moriyọ ninu ijamba naa laye.

    "Ọkan lara awọn ẹgbọn mi, Ibrahima fi foonu dokita pe mi lati Cape Verde.

    "O sọ fun wa wipe Cheikhouna sọnu ninu omi. Mo ba mi lọkan jẹ. A sumọ ara wa gan, jagunjagun ni.

    O ti ni iyawo pẹlu ọmọ meji. "Ijo to kuro ni ile, o di ọwọ mi mejeeji mu, O ni Aburo mi, mo ni lati lọ. "Ẹgbọn mi, ọrẹ mi si tun ni."

  11. Tani Olohun dèrò àhámọ́ ọjọ́ 50 fún bíba Alfa lórúkọ jẹ́ ní Ilọrin

  12. Ìjọba ti ilé ọmọ aláìní ìyá pa fẹ́sùn títa àwọn ọmọ

  13. Emefiele tún farahàn nílé ẹjọ́ ṣùgbọ́n ilé ẹjọ́ ní ẹjọ́ rẹ̀ kò tíì sí lójú ọpọ́n

  14. Ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi gbẹ̀mí arìnrìnàjo 60

    O to eeyan ọgọta to n rin irinajo lori ọkọ oju omi lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ akero oju omi doju bolẹ.

    Eeyan mẹrindinlogoji, pẹlu awọn ọmọde ni wọn ri dola ni ẹgbẹ omi lorilẹede Cape Verde.

    Gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ oju omi akero lo ti wa ni lori fun oṣu kan, ti igbagbọ si wa pe ọmọ orilẹede Senegal ni wọn.

    Ijọba orilẹede Cape Verde ti kesi ajọ agbaye lati wa nnkan se lati bi wọn eeayn se gbiyanju lati wọ orilẹede kan tabi omiran ni ọna aitọ, ki sisọ ẹmi nu le dikun.

    Agbẹnusọ ajọ agbeye lori irinajo IOM ni awọn eeyan ti wọn ko ba isẹlẹ naa lọ ni ọmọde mẹrin, ti wọn wa ni ọmọ ọdun mejila si mẹrindilogun.

    Ajọ to n oke okun lorilẹede Senegal ni ọkọ oju omi akero naa lo gbera kuro ni abule pajepaje lorilẹede Senegal, Fasse Boye lọjọ kẹwaa oṣu keje pẹlu eeyan kan le ni ọgọrun un.

    Moda Samb, oloselu ni abule naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe pupọ awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi naa lo jẹ agbalagba, ti pupọ awọn idile si n reti iroyin boya awọn eeyan wa laye.

    Ajọ ọhun ni awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu orilẹede Cape Verde lori bi awọn to ye isẹlẹ naa yoo se pada wale.

    Awọn arin irinajo yooku lo wa lati orilẹede Sierra Leone ati eeyan kan lati Guinea-Bissau \

    Jose Moreira, osisẹ ilera ni Sal ni awọn to farapa nibi ijamba naa ti n gba itọju, ti wọn si n se itọju wọn nipa ti ounjẹ.

    Minisita fun eto ilera, Filomena Goncalves ni: "A mọ isoro to wa ni gbogbo agbaye ti wọn eeyan fẹ kuro nibi kan lọ si ibi kan, a ti lati fọwọ sowọpọ gbogun ti isoro yii ni"

  15. Ìjàmbá ọkọ̀ ojú omi gbẹ̀mí arìn ìrìnàjo 60

    O to eeyan ọgọta to n rin irinajo lori ọkọ oju omi lo ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ akero oju omi doju bolẹ.

    Eeyan mẹrindinlogoji, pẹlu awọn ọmọde ni wọn ri dola ni ẹgbẹ omi lorilẹede Cape Verde.

    Gbogbo eeyan to wa ninu ọkọ oju omi akero lo ti wa ni lori fun oṣu kan, ti igbagbọ si wa pe ọmọ orilẹede Senegal ni wọn.

    Ijọba orilẹede Cape Verde ti kesi ajọ agbaye lati wa nnkan se lati bi wọn eeayn se gbiyanju lati wọ orilẹede kan tabi omiran ni ọna aitọ, ki sisọ ẹmi nu le dikun.

    Agbẹnusọ ajọ agbeye lori irinajo IOM ni awọn eeyan ti wọn ko ba isẹlẹ naa lọ ni ọmọde mẹrin, ti wọn wa ni ọmọ ọdun mejila si mẹrindilogun.

    Ajọ to n oke okun lorilẹede Senegal ni ọkọ oju omi akero naa lo gbera kuro ni abule pajepaje lorilẹede Senegal, Fasse Boye lọjọ kẹwaa oṣu keje pẹlu eeyan kan le ni ọgọrun un.

    Moda Samb, oloselu ni abule naa sọ fun ileeṣẹ iroyin AFP pe pupọ awọn eeyan to wa ninu ọkọ oju omi naa lo jẹ agbalagba, ti pupọ awọn idile si n reti iroyin boya awọn eeyan wa laye.

    Ajọ ọhun ni awọn ti bẹrẹ ijiroro pẹlu orilẹede Cape Verde lori bi awọn to ye isẹlẹ naa yoo se pada wale.

    Awọn arin irinajo yooku lo wa lati orilẹede Sierra Leone ati eeyan kan lati Guinea-Bissau \

    Jose Moreira, osisẹ ilera ni Sal ni awọn to farapa nibi ijamba naa ti n gba itọju, ti wọn si n se itọju wọn nipa ti ounjẹ.

    Minisita fun eto ilera, Filomena Goncalves ni: "A mọ isoro to wa ni gbogbo agbaye ti wọn eeyan fẹ kuro nibi kan lọ si ibi kan, a ti lati fọwọ sowọpọ gbogun ti isoro yii ni"

  16. Aráàlú dáná sun ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́rin ati ọ̀pọ̀ dúkìá ní Pakistan lórí ẹ̀sùn sísọ ọ̀rọ̀ òdì sí Islam

    Ogunlọgọ awọn Musulumi ni Pakistan lo ti dana sun awọn ile ijọsin bayii, ti wọn si tun kọlu ile awọn Kristẹni lori ẹsun pe awọn ọkunrin meji kan ṣe Quran ni iṣekuṣe.

    Agbegbe Jaranwala, ni Punjab ni ikọlu naa ti waye.

    Ọlọpaa ni ko din ni ile ijọsin mẹrin ti awọn eeyan naa dana sun, nigba ti awọn ile mii bii mejila ti ko jina pupọ si awọn ṣọọṣi naa jona.

    Idajọ iku lo wa fun ẹnikẹni to ba sọrọ odi nipa ẹsin Musulumi ni Pakistan.

    Bo tilẹ jẹ ijọba ilẹ naa ko tii yẹgi fun ẹnikẹni lori ẹsun ọrọ odi naa, ọpọ araalu lo ti ṣekupa awọn ti wọn ba fura si pe wọn sọrọ odi si Islam.

    Ileeṣẹ iroyin Reuters jabọ pe awọn meji ti ọlọpaa fẹsun ọrọ naa kan kọ ọrọ kobakungbe si awọn oju kan ninu ewe Quran.

    Yassir Bhatti, ẹni ọdun mọkanlelọgbọn, to tun jẹ Kristẹni wa lara awọn to sa kuro nile wọn bayii latari ikọlu to tẹlẹ iṣẹlẹ ọhun.

    Bhatti sọ fun ileṣẹ iroyin AFP pe “Wọn fọ ferese wọle, wọn ko aga, erọ amounjẹ tutu atawọn nnkan mii ti a n lo ninu ile lọ siwaju ṣọọṣi, wọn si dana sun gbogbo rẹ.”

    “Bẹẹ naa ni wọn fa bibeli ya, ti wọn si tun jo awọn bibeli mii.”

    Olori ijọba fidihẹ Pakistan, Anwar ul Haq Kakar, ti ke si ileeṣẹ ọlọpaa lati pana rogbodiyan naa, ki wọn si fi ṣikun ofin mu awọn to n da ilu ru.

  17. Ẹ máa múra ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé ní Eti-Osa, Ojo, Badagry, Ikeja àti Ikoyi – Ìjọba ìpínlẹ Eko

    Ijọba ipinlẹ Eko ti kede pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ omiyale waye lawọn agbegbe kan nipinlẹ naa lẹnu lọọlọ yii.

    Ninu atẹjade kan ti akọwe agba ileeṣẹ ijọba ipinlẹ naa to n ri si ọrọ omi, Lekan Shodeinde fi lede, o ni ṣeeṣe ki ojo arọrọda naa waye laarin ọjọ kẹrinla si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹjọ.

    Ijọba ipinlẹ naa ni ki awọn olugbe agbegbe Apapa, Badagry, Eti Osa, Ikeja, Ikorodu, Ikoyi, Lagos Island ati Ojo maa mura ojo arọrọda, eyii to le ṣokunfa iṣẹlẹ omiyale laarin ọsẹ yii siwaju.

    Gẹgẹ bii iroyin to n jade lati inu ẹrọ Flood Emergency Warning System, FEWS, ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ ayika, Shodeinde kede pe ki awọn eeyan agbegbe to darukọ ṣaaju maa murasilẹ.

    O tun ke si awọn olugbe agbegbe to sun mọ eti omi ki wọn yago fun akoko diẹ.

    Bẹẹ naa lo tun kilọ fun awọn awakọ lati ṣọra fun wiwa ọkọ wọn ninu agbara ojo ki omi ma baa gbe wọn lọ.

    Gẹgẹ bii ohun to sọ, ikilọ yii ṣe pataki lọna ati dena ofo ẹmi ati dukia nipinlẹ naa.

  18. Oyetola di Mínísítà fétò ìrìnnà, Wike ni Mínísítà fún FCT bí Tinubu ṣe kéde ipò àwọn mínísítà tuntun

  19. A ti ya owó bílíọ̀nù mẹ́ta Dollar torí ṣégeṣège owó bẹntiróò, kó lè dáa - NNPCL

    Ileeṣẹ ipọnpo orilẹede Naijiria (NNPC) ti ya owo pajawiri biliọnu mẹta Dollar latọdọ Banki to n ri si iwọle-wọde ọja l’Afirika (AFREXIM).

    Ninu atẹjade kan ti ajọ NNPC fi soju opo Twitter, ileeṣẹ naa ni iwe adehun naa ni awọn tọwọ bọ ni olu ileeṣẹ banki AFREXIM to wa ni Cairo lorilẹede Egypt ni Ọjọru ọsẹ.

    Atẹjade naa ṣalaye pe adehun yii yoo jẹ ki wọn le ṣeranwọ fun ijọba apapọ Naijiria ninu akitiyan to n ṣe lọwọ fun atunto ẹka inawo ati lati fopin si ṣegeṣege ti pasiparọ owo ilẹ okere n ṣe.

    Atẹjade naa ka wipe: “Ileeṣẹ NNPC ati AFREXIMBANK ti pawọpọ tọwọ bọ iwe fun owoya pajawiri biliọnu mẹta kan lati san gbese to wa nilẹ.

    “Itọwọbọwe naa to waye ni olu ileeṣẹ banki naa ni Cairo, Egypt ni yoo pese iranwọ kiakia ti yoo le jẹ ki ileeṣẹ NNPC nawọ iranwọ si ijọba apapọ ninu akitiyan rẹ to n lọ lọwọ fun atunto ẹka inawo ati ki iduro dede le wa fun pasiparọ owo ilẹ okere.”

  20. Ẹ lọ fọkànbalẹ̀, kò lè sí ẹ̀kúnwó epo bentírò- Ìjọba Àpapọ̀