You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìjọba ológun ní Niger yan olóòtú ìjọba tuntun fún orílẹ̀-èdè nàá

    Olori ijọba ologun to ditẹgbajọba ni Niger, Ọgagun Abdourahmane Tchiani , ti kede ẹni to ti fi igba kan jẹ minisita fun eto ẹnawo gẹgẹ bi olootu ijọba.

    Ali Mahaman Lamine Zeine n rọpo Mahamadou Ouhoumoudou, to wa nipo naa tẹlẹ. Ilẹ europe lo wa nigba ti iditẹgbajọba naa waye lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Keje.

    Ọgbẹni Zeine to ti le ni aadọta ọdun, jẹ minisita eto ẹnawo lati ọdun 2001 titi di igba ti awọn ologun gba ijọba lọwọ Aarẹ Mamadou Tandja to ti di oloogbe bayii lọdun 2010.

    Agbẹnusọ ijọba ologun kan lo kede iyansipo rẹ ninu atẹjade kan lori amohunmaworan ijọba orilẹ-ede naa, Téle Sahel, ni alẹ ọjọ Aje.

    Ṣaaju asiko yii, Ọgbẹni Zeine ti ṣiṣẹ ni African Development Bank ni Chad, Ivory coast ati Gabon, gẹgẹ bi akọsilẹ nipa rẹ loju opo ayelujara ActuNiger.

    Yatọ si iyansipo Zeine, ijọba ologun naa tun yan Brig.Gen Amadou Didili gẹgẹ bi olori ajọ High Authority for Peace Consolidation (HACP) ati Brig Gen Abou Tague Mahamadou gẹgẹ bi ọga agba ileeṣẹ ologun.

    O tun yan Col Ibro Amadou Bachirou gẹgẹ bi olori awọn oṣiṣẹ fun olori ijọba ologun naa, ati Lt Col Habibou Assoumane gẹgẹ bi olori awọn ẹṣọ alaabo fun aarẹ ologun.

  2. Ayẹyẹ Ìbọrí-adé wáyé níbi ọdún Osun-Osogbo

    Ayẹyẹ iboriade ti waye nibi ọdun Osun-Osogbo to n lọ lọwọ niluu Osogbo, nipinlẹ Osun.

    Ọjọ aje, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ, ni ayẹyẹ naa waye ni aafin Ataoja ilu Osogbo.

    Iboriade ni eto ti wọn ma n ṣe nibi ọdun naa lati ṣe iranti awọn ọba to ti jẹ ri niluu Osogbo.

    Nibi ayẹyẹ naa ni wọn ti ma n ko gbogbo ade ọba to wa ninu aafin Ataoja ilu Osogbo jade fun ayẹsi.

    Lara aṣa ilu Osogbo ni pe, ọba to ba wa lori oye gbọdọ maa ṣe iranti awọn ọba to ti jẹ ṣaaju rẹ, to si ti waja, nipa bibọ ori fun awọn ade ti awọn ọba naa de nigba aye wọn.

    Nigba to ba ku ọjọ marun-un ti Arugba Osun yoo ru igba ni ayẹyẹ Ibori ade ma n waye. Oriṣiriṣi awọn ounjẹ ibilẹ si ni wọn ma n lo lati fi ṣe adura nibi eto naa.

    Lara awọn ounjẹ ti wọn ma n lo ni ireke, ṣuga, ọgẹdẹ, obi, orogbo, ati bẹẹbẹẹ lọ.

    Ti eto ba ti n lọ ni wọn o ma a gbe awọn ounjẹ naa kaakiri awọn to wa nibẹ, ti kaluku yoo si ma a mu tirẹ jẹ.

    Ataoja ilu Osogbo, Ọba Jimoh Olanipekun Laaroye kejì, awọn ijoye rẹ ati awọn eekan ilu mii mii, to fi mọ awọn ara ilu Osogbo ati alejo lo peju sibi ayẹyẹ Ibori ti ọdun yii.

  3. "Ọmọ ìyá oníbúrẹ́dì ni mí, ilé pákó la gbé dàgbà kí ń tó di gbajúmọ̀ akọrin"

  4. Àyẹwò parí lórí orúkọ tí Ààrẹ fí ránṣẹ sípò Mínísítà, El-Rufai kò sí níbẹ̀

    Ile aṣofin agba Naijiria ti kede orukọ marundinlaadọta gẹgẹ bi orukọ awọn ti ile ṣe ayẹwọ fun sipo Minisita labẹ ijọba aarẹ Bola Tinubu.

    Titi di asiko taa n ṣe akojọ iroyin yi,orukọ Gomina tẹlẹ ri ni ipinlẹ Kaduna Nasir El Rufai ko si ninu awọn ti ile ṣayẹwo fun.

    Oun nikan kọ, awọn meji mii Sani Abubakar Danladi lati ipinlẹ Taraba ati Stella Okotete lati Delta.

    Aarẹ ile aṣofin agba Sẹnẹtọ Godswill Akpabio,sọ pe awọn n reti abọ iwadii awọn agbofinro lori awọn eeyan mẹta wọnyi ki wọn to le ṣayẹwọ wọn sipo minisita ni ibamu pẹlu ofin.

    Lati ọjọ Aje to kọja ti wọn ti bẹrẹ ayẹwo ni wọn ti forukọ wọn ranṣẹ amọ ko pada siwaju ile debi pe wọn yoo kede wọn pẹlu awọn marundinlaadọta yoku.

    Orukọ awọn ti ile ti ṣayẹwo fun ree gẹgẹ bi Sẹnẹtọ Godswill Akpabio ti ṣe ka wọn jade:

    • Abubakar Momoh - Edo
    • Betta Edu - Kuros Riba
    • Uche Nnaji - Enugu
    • Joseph Utsev - Benui
    • Hannatu Musawa - Katsina
    • Nkeiruka Chidubem Onyejocha - Abiya
    • Stella Okotete - Delta
    • Uju Kennedy-Ohanenye - Anambra
    • Ahmed Dangiwa - Katsina
    • Olawale Edun - Ogun
    • Imaan Suleman Ibrahim - Nasarawa
    • Bello Muhammad Goronyo - Sokoto
    • Nyesom Wike - Rivers
    • David Umahi - Ebonyi
    • Mohammad Badaru Abubakar - Jigawa
    • Lateef Fagbemi - Kwara
    • Doris Aniche Uzoka - Imo
    • Yusuf Maitama Tuggar - Bauchi
    • Professor Ali Pate - Bauchi
    • Ekerikpe Ekpo - Akwa Ibom
    • Mohammed Idris - Nigeria
    • Olubunmi Tunji Ojo - Ondo
    • Dele Alake - Ekiti
    • Waheed Adebayo Adelabu - Oyo
    • John Eno - Profit Cross
    • Abubakar Kyari - Borno
    • Abdullahi Tijjani Gwarzo - Kano
    • Dr Mariya Bunkure - Kano
    • Isaac Salako - Ogun
    • Bosun Tijjani - Ogun
    • Tunji Alausa - Lagos
    • Tanko Sununu - Kebbi
    • Adegboyega Oyetola - Osun
    • Atiku Bagudu - Kebbi
    • Bello Matawalle - Zamfara
    • Ibrahim Geidam - Yobe
    • Simon Lalong - Plato
    • Lola Adejo - Lagos
    • Shuaibu Abubakar - Kogi
    • Tahir Mamman - Adamawa
    • Aliyu Sabi Abdullahi - Nigeria
    • Judge Ahmed Saidu - Gombe
    • Heneken Lakpobiri - Bayelsa
    • Father Maigari - Taraba
    • Zephaniah Jissalo - Abuja
  5. Ọwọ́ pálábá òṣìṣẹ́ Ọlọ́pàá,Frsc àti Lastma tó n gbà àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ségi

    Ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko ti ṣe afihan awọn janduku agbero to n gba owo loju popo lọwọ awọn ọlọkọ nla ati awakọ mii lagbegbe Mile 2.

    Yatọ si awọn eeyan mẹẹdogun ti ọwọ wọn tẹ la tun ri awọn agbofinro ọlọpaa,oṣiṣẹ ajọ ẹsọ alaabo oju popo FRSC to n dari lilọ bibọ ọkọ nipinlẹ Eko Lastma.

    Ọlọpaa mẹta, oṣiṣẹ Lastma kan ati oṣiṣẹ Lastma ni wọn fihan pe wọn n lẹdi apo pọ pẹlu awọn agbero lati maa gba owo lọwọ awọn awakọ.

    Benjamin Hundeyin to jẹ alukoro ọlọpaa ni ipinlẹ Eko sọ pe kọmiṣana Eko Idowu Owohunwa lo paṣẹ kawọn ọlọpaa tọ pinpin awọn alaburu yi to n gba owo lọna aitọ lọna Mile 2.

  6. D'Tigress ṣíná ìyà fún Senegal gba ife nídíje bọ́ọ̀lù alápẹ̀rẹ̀, Igba kẹrin ree ti wọn yoo gba ife ẹyẹ nidije ọhun

    Ikọ agbabọọlu alapẹrẹ obinrin orileede Naijiria D Tigress ti gbaife ẹyẹ nidije awọn obinrin ilẹ adulawọ fun igba kẹrin.

    Lorileede Rwanda ni wọn ti da bi ẹdun rọ bi oowe lẹyin ti wọn foju Senegal gbolẹ ninu aṣekagba idije naa ni papa iṣere to wa ni Kigali.

    Aṣeyọri yi waye pẹlu mi ayo mẹrinlelọgọrin ti wọn ri gba fi lewaju mẹrinlelaadọrin ti Senegal gba.

    Ni bayii wọn ti forukọ silẹ ninu itan nipa gbigba ife idije yii pẹlu orileede Senegal to ti ṣaaju ṣe bẹ gba ife nidije yi lẹẹmẹẹrin lera laarin ọdun 1970 si ọdun 1981.

    Ifeanyi Okoro jẹwọ ọmọ ọkọ nipa gbigba ami ayo mẹrindinlogun sinu awọn eyi to mu ki olukọni ikọ naa Rena Wakama di akọnimọọgba obinrin akọkọ ti yoo gba ife ẹyẹ ninu idije AfroBasket Women.

    Naijiria bori gbogbo awọn alatako wọn mẹrẹẹrin ti wọn koju ninu idije yi lae fiirẹmi.

    Amy Okonkwo ni wọn gbade fun gẹgẹ bi oludije to fakọyọ julọ ninu idije bọọlu alapẹrẹ awọn obinrin nilẹ Africa.

  7. Ìjọba Ondo yóò bọ́ ìdílé mílíọ̀nù kan nítorí wàhálà ‘Subsidy’

  8. Ṣé lóòótọ́ ni ìyá arúgbó kan yípadà di ológbò nípínlẹ̀ Ondo?

  9. 'Ìtọ̀ la n mu lábẹ́ ọkọ̀ ojú omi táa sá pamọ́ sí láti Eko dé Brazil'

  10. Wo bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan ṣe pe Ògún, Ṣàǹgó, Ọ̀ṣun sọ̀kalẹ̀

  11. ‘’Lóòtọ́ ni a ti ti ibodè tó wọ Niger láti Naijiria’’

    Ileeṣẹ ton risi ọrọ wọle-wọde ni Naijiria, Basir Adewale ti fi idi rẹ mulẹ pe wọn ti ti ibode to wọ orilẹede Niger lati Naijiria.

    Adewale lo sọ bẹẹ lasiko to se abẹwo si ilu Kastina lati mu aṣẹ aarẹ Tinubu sẹ.

    O ni oun le fi idi rẹ mulẹ bayii pe aarẹ Tinubu ti fi ontẹ lu lati ti ibode to wọ Niger lati orilẹede Naijiria.

    Adewale naa ni aṣẹ aarẹ Tinubu ni oun wa muṣẹ gẹgẹ bi adari ajọ ECOWAS.

    O ni igbagbọ awọn ni pe wẹrẹ ti nkan ba ti ṣẹnu ire ni Niger awọn yoo da ohun gbogbo pada si ipo to wa tẹlẹ.

    Adari ajọ naa ni awọn yoo si pada ni kete ti awọn Ologun to gbajọba nibẹ ba ti gbọ ọrọ si awọn lẹnu.

    Àwọn àwòrán láti ibodè Naijiria sí Niger tó ti wà ní títìpa rèé…

  12. Tinubu kọ̀wé sílé aṣòfin lórí àwọn ìpinnu ECOWAS fún Niger

  13. Ààrẹ Bazoum késí Amẹríkà fún ìrànlọ́wọ́ lẹ́yìn ìditẹ̀gbàjọba

  14. Mi ò jẹ̀bi ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn mí lórí ìdìbò ọdún 2020 – Donald Trump

    Aarẹ orilẹede Amerika tẹlẹ, Donald Trump ti ni oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an ni ileẹjọ kan ni Washington DC.

    Ẹsun na lo niise pe idibo sipo aarẹ to waye ni ọdun 2020 nibẹ, ti Trump si fi idirẹmi.

    Lasiko igbẹjọ naa ni Trump ti sọrọ ni kukuru, to si fi idi rẹ mulẹ pe oun ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun.

    Lẹyin naa ni Trump salaye fun awọn oniroyin pe awọn ti ko fẹran ẹgbẹ oselu oun,

    Eyi tumọ si pe Donald Trump naa ti kawọ si ẹyin row ̣jọ ni ẹẹmẹta ni aarin osu mẹrin.

    Ileẹjọ naa ti Trump ti gba ẹyin wọle, ko jina si ibi ti rogbodiyan ti bẹ silẹ ni US Capita=ol, ti awọn ololufẹ Trump ti faraya.

    O kere tan awọn eniyan to le ni ẹgbẹrun ni wọn n jẹjọ sise ikọlu si ile aṣofin orilẹede Amerika ni Ọjọ Kẹfa, Osu Kini, ọdun 2021.

    Lara awọn ẹsun ti wọn fi kan an ni pe;

    • O gbimọ lati ja ilẹ Amerika ni ole
    • O gbimọ lati da ipade ijọba orilẹede naa lọwọ
    • Igbiyanju lati da eto ipade ijọba ru.
    • Igbimọpọ tako ifẹ awọn araalu.

    Bakan naa ni adajọ paṣẹ fun lati mase jẹ ki kulẹ kulẹ igbẹjọ naa han sita.

    Trump lo jakulẹ ninu idibo sipo aarẹ ni ọ̀un 2020, to si gbe aarẹ Joe Biden wọle ni orileede naa,

    Nibayii, Trump lo n lewaju ninu awọn oludije sipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu Republican fun idije supo si ipo aarẹ ni ọdun 2024.

  15. Àjọ Ecowas ti bẹ̀rẹ̀ ìjìròrò pẹ̀lú àwọn ìkọ̀ Ológun tó gbajọba ni Niger

    Ajọ Ecowas ti bẹrẹ ijiroro pẹlu ikọ ọmọogun to gbajọba ni Niger lọwọ aarẹ Mohammed Bazoum.

    Eyi n waye lẹyin ti awọn ikọ ti ijọba gbe dide de si ilu Yamai ni orilẹde Niger.

    Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu to jẹ alaga ajọ naa, lo ran ikọ naa ti aarẹ orilẹede Naijiria tẹlẹri, Abdulsalam Abubakar se adari fun.

    Laipẹ yii ni aarẹ Tinubu pẹlu awọn ikọ rẹ gbera lọ si orilẹde Niger lati lọ ba awọn ikọ ọmọogun ni Niger sọrọ lati pẹẹtu si awọn ikọ ọmọgun naa lati jawọ ninu igbesẹ bi wọn se gba ijọba lọwọ aarẹ orilẹede naa.

    Igbesẹ akọkọ niyii ti ajọ Ecowas n gbe lati ri pe alaafia jọba lorilẹede Niger, ki ijọba tiwantiwa si pada sibẹ.

    Ọsẹ to kọja ni Ajọ Ecowas se ipade pajawiri pẹlu awọn asoju orilẹede to wa ninu ajọ naa lati jiroro lori ọna abayọ si bi awọn Ologun se gba ijọba nibẹ.

    Bakan naa ni wọn ti kesi awọn ikọ ọmọogun Niger lati gba alaafia laaye ki alaafia le pada si orilẹede naa.

    Amọ Ajọ Ecowas ni ti wọn ko ba se ohun to tọ, awọn ko ni kọ lati gbe ikọ ọmọogun dide lati koju ija si wọn.

  16. Mọ nípa àwọn obìnrin mẹ́sàn-án tí Tinubu fẹ́ yàn ní Mínísítà

  17. Ganduje di alága tuntun fún APC

  18. Agbára ológun ni a ó lò kẹ́yìn takò ìjọba ológun ní Niger - Ecowas Army

    Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ológun Naijiria, Brigadier General Tukur Gusau, sọ pe àwọn ọgagun ninu àjọ ECOWAS yoo wa ọna abayọ, ti gbogbo igbesẹ oloselu ko ba ṣiṣẹ ni orile-ede Niger lẹyin iditẹgbajọba to waye nibẹ.

    O sọ fun BBC pe igbesẹ ológun ni yoo jẹ igbesẹ to kẹhin.

    Àwọn olori ileeṣẹ alaabo lati lati awọn orile-ede to wa ninu Ecowas n ṣe ipade niluu Abuja, lati Ọjọ́rú si ọjọ Ẹti, lati jiroro lori awọn ọna ti wọn o gba bori ijọba ológun to dojú ijoba Aarẹ Mohamed Bazoum bolẹ̀ ni ọ̀sẹ̀ to kọja.

    Àwọn olori alaabo lati Ghana, Naijiria, Benin, Togo, Sierra Leone, Liberia, Gambia, Cote D'Ivoire, ati Cape Verde, lo n kopa ninu ipade apero naa.

    Sugbọn ṣá, awọn akẹẹgbẹ́ wọn lati Mali, Niger, Guinea Bissau, Burkina Faso, ati Guinea, ko wa fun ipade nitori pe Ecowas ti da wọn duro kuro ninu àjọ naa, nitori iditẹgbajọba to waye ni awọn orile-ede wọn.

    Àwọn olori alaabo naa yoo fi àbọ̀ ohun ti wọn ba fi ẹnu kò lati ṣe to Aarẹ Bola Tinubu létí, lọjọ Ẹti.

    Lẹyin naa ni Aarẹ Tinubu to jẹ alaga Ecowas yoo pinnu lori igbesẹ to kàn lati gbe tako ijọba ologun ti General Abdourahmane Tchiani, to kede ara rẹ ni aarẹ Niger n dari.

  19. Tinubu forúkọ Oyetola, àwọn gómìnà tẹ́lẹ̀ rí mẹ́rin míì ránṣẹ́ sílé aṣòfin fúnpò mínísítà

  20. Ìjọba Senegal fòfin de Tiktok lílò