Obi ati Atiku ń gbé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lórí èsì ìbò ààrẹ lọ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ
Ẹgbẹ oselu PDP ati APC ti fesi lori idajọ ti ile ẹjọ Kotẹmilọrun gbe kalẹ lọjọru lori esi ibo aarẹ to kọja lorilẹede Naijiria.
Ile ẹjọ kotẹmilrun naa lo dajọ ni Ọjọru pe aarẹ Bola Tinubu tẹgbẹ oselu APC lo jawe olubori nitootọ ninu ibo aarẹ naa, gẹgẹ bi ajọ INEC ti kede rẹ.
Nibayii Atiku Abubakar, tii se oludije fẹgbẹ oselu PDP ninu ibo aarẹ to kọja ti wa fesi pe oun ko fara mọ idajọ ile ẹjọ kotẹmilọrun naa.
Bakan naa ni akẹẹgbẹ rẹ fẹgbẹ oselu Labour, Peter Obi ti salaye pe idajọ naa ko jẹ itẹwọgba lọdọ oun.
Awọn oludije mejeeji naa, to wọ ẹgbẹ oselu APC ati ajọ eleto idibo INEC lọ sile ẹjọ lori esi ibo naa, ti wa leri leka pe awọn n gba ile ẹjọ to ga julọ ni Naijiria lọ lati yanju ọrọ naa.
Ni klete lẹyin ti ileẹjọ giga naa gbe idajọ rẹ kalẹ lawn oludije mejeeji ọhun sọ ero wọn pe ile ẹjọ to ga julọ ya.
Agbẹjọro fun ikọ Atiku, Oloye Chris Uche, lasiko idajọ ileẹjọ to ga julọ naa wa n rọ ileẹjọ ọhun lati se ẹda iwe idajọ naa fun oun, ki onibara oun le ni ẹtọ lati ta ko o.
O salaye pe Atiku, tii seigbakeji aarẹ tẹlẹ ti pasẹ fun oun pe ki oun tete lọ pe ẹjọ kotẹmilọrun tako idajọ naa nile ẹjọ to ga julọ.
Uche wa n kọminu pe ki lo de ti ile ẹjọ to ga julọ ọhun, to faake kọri lati gba kawọn akọroyin laaye lati gbe bi igbẹjọ se n l lọwọ sita, wa pada gba pe ki wọn ka idajọ wọn bo se n lọ lọwọ.
Bakan naa ni agba amofin Livy Uzoukwu to n lewaju ikọ agbẹjọro fun Peter Obi ati ẹgbẹ oselu Labour naa ti fidi rẹ mulẹ fawọn akọroyin pe onibara oun ti pasẹ pe ki oun gbe ẹjọ naa lọ sile ẹjọ to ga julọ nilẹ wa.