Òjòwú ọkùnrin kan dèrò àhámọ́ Kirikiri l'Eko lórí ẹ̀sùn ìṣekúpa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀, Lagos murder: Ọkùnrin kan kó sí gbaga ọlọ́pàá lórí ẹ̀sùn ìṣekúpa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀
Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Samuel Adeniyi ti dero ahamọ lọgba ẹwọn Kirikiri l'Eko lori ẹsun pe o fi nkan fọ ori ọrẹbinrin rẹ lagbegbe Lekki Phase 1.
Adajọ majisreeti Patrick Nwaka ileẹjọ majisreeti to wa lagbegbe Yaba niluu Eko paṣẹ ki wọn ju Adeniyi si ahamọ lori ẹsun ipaniyan oni koko kan.
Olupẹjọ ileeṣẹ ọlọ́pàá, Ọgbẹni Thomas Nurudeen sọ fun ileẹjọ pe ọjọ kẹwaa oṣu kẹjọ ni iṣẹlẹ yii waye ni nọmba 33, Audu Ekpa, Lekki Phase 1.
Olupẹjọ ṣalaye pe afurasi naa ni ọrẹbinrin oun tun n fẹ ẹlọmiiran, ati pe ibalopọ ti awọn ba jọ ni papọ kìí saaba tẹ ẹ lọrun.
A tun gbọ pe lọjọ iṣẹlẹ yii gan an, ọrẹbinrin yii to di oloogbe fi ọmọ to n tọju nibi to ti n ṣe nani silẹ, to sì lọ ba ọkunrin mii,koda irọ ni wọn ni o pa wí pe oun fẹ lọ ra kaadi si foonu ni.
Bakan naa ni a gbọ pe Adeniyi ni lati duro de e fun ọpọ wakati ki o to o de.
Nigba ti o pada de ni Adeniyi beere lọwọ rẹ ohun to jẹ ki o pẹ, bayii ni ọrọ naa di ìja ti Adeniyi si la hama mọ ọrẹbinrin rẹ lori.
Olupẹjọ Nurudeen sọ fun ileẹjọ pe afurasi naa sa lọ lẹsẹkẹsẹ nigba ti wọn gbe ọrẹbinrin rẹ digba digba lọ si ile iwosan nibi ti dokita ti sọ pe ẹlẹmii ti gbaa.
Ileẹjọ kọ lati gba ẹbẹ afurasi Adeniyi.
Adajọ paṣẹ pe ki afurasi naa wa ni ahamọ titi ti igbẹjọ lori ẹjọ yóò fi waye ni ọjọ kẹwaa oṣu kẹwaa ọdun 2023 yii.