Ghana àti South Africa tọwọ́bọ àdéhùn láti máa wọ orílẹ̀ èdè arawọn láì lo físà
Orilẹ-ede Ghana ati South Africa ti tọwọbọ adehun pe awọnọmọ orilẹ-ede mejeji le maa wọ orilẹ ede arawọn lai gba iwe iwọlu ti a mọ si “visa”.
Ohun ti eyi tumọ si ni pe iwe irinna nikan ni awọn ọmọ orilẹ ede mejeeji yii nilo lati wọ orilẹ arawọn lati lo aadọrun-un ọjọ.
Atẹjade kan ti Minisita to n risi ọrọ ilẹ okere ni orilẹ-ede Ghana fi lede ni lati ọjọ Kiini, osu Kọkanla, ọdun 2023 ni ilana tuntun yoo bẹrẹ.
Lẹyin ti aadọrun-un ọjọ ba pe ti ẹni to rinrinajo yii ṣi fẹ maa wa ninu awọn orilẹ ede yii, onitọhun yoo ṣẹṣẹ gba iwe aṣẹ lati tunbọ wa ninu orilẹ ede naa.
Atẹjade kan lati ile iṣẹ South Africa to wa ni Ghana ni ti kii ba ṣe inu ọdun kan ni gbogbo awọn aadọrun-un ọjọ yii bọ si, onitọhun ko ni gba iwe igbelu.
Ṣaaju asiko yii, awọn ọmọ orilẹ-ede Ghana ati South Africa maa n nilo fisa lati wọ orílé ede arawọn.
Awọn ọmọ Ghana ko ni anfani pe ti wọn ba de South Africa ki wọn to gba fisa gẹgẹ bo ṣe wa fun awọn orilẹ ede kan tẹlẹ amọ ti anfani naa ti wa fun wọn bayii.
Gbigba fisa lọ si South Africa lati Ghana maa n gba ọpọlọpọ ọsẹ tabi oṣu nitori awọn eniyan maa n pọ nibẹ.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Ernest Apraku ṣalaye pe o gba oun to oṣu meji lẹyin ti oun kọwe lati gba fisa lọ si orilẹ-ede South Africa fun isinmi.
O fi kun pe pẹlu igbesẹ tuntun yii, o maa din gbogbo iṣoro ati ọpọlọpọ wahala lati gba fisa ku fun awọn ọmọ orilẹ-ede naa.
Ninu oṣu Kẹsan-an ọdun yii, adẹrininpoṣonu kan ni Ghana, OB Amponsah kò ribi kopa nibi ayẹyẹ awada kan ni South Africa ti awọn akẹgbẹ rẹ n ṣe.
O kọ sori ayelujara nigba naa pe oun ko ribi kopa nibi ayẹyẹ naa pẹlu gbogbo wahala ti oun ṣe lati ri iṣẹ naa gba latari bi oun ko ṣe ri fisa gba.
Lẹyin ti wọn kede igbesẹ tuntun yii, o ni aarẹ orilẹ ede awọn ṣe dada pẹlu ohun ti wọn ṣe yii.