Ọkùnrin kan dáná sun ìyàwó rẹ̀, táwọn ọlọ́kadà sì dáná sun afurasí olè kan l‘Eko

Published

Ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Akpos, lo ti dana sun iyawo rẹ, ti orukọ rẹ jẹ Risikat, nile wọn to wa ni agbegbe Ayide Osolo Ijanikin nipinlẹ Eko.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni Akpos fẹsẹ fẹ kete to ṣekupa iyawo rẹ lẹyin ti ariyanjiyan waye laarin wọn, eyi to bi ninu, to si lọ gbe epo bẹntiro, to si dana sun Risikat .

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa,  Benjamin Hundeyin ni kete ti Akpos dana sun iyawo rẹ, to si gbe oku rẹ silẹ, lo ba salọ.

Hundeyin ni awọn olugbe agbegbe to kẹfin isẹlẹ naa lo gbe oku Risikat lọ si ile iwosan fun itọju.

Amọ, lẹyin o rẹyin, obinrin naa papa jade laye.

“Wọn gbe isẹlẹ yii wa si agọ ileeṣẹ ọlọpaa to wa ijanikin pe, Obinrin kan, ti orukọ rẹ jẹ, Risikat, ẹni ọdun mejidinlaadọta ni ariyanjiyan pẹlu ọkọ rẹ, eyi to bi ọkọ rẹ ninu, to si dana sun.

“Ina naa ba ara arabinrin naa jẹ, ti awọn olugbe agbegbe naa si sure gbe obinrin lọ si ile wosan.

Sugbọn o pada jade laye. Gbogbo igbiyanju wa lati mu ọkọ obinrin naa si lo ja si pabo.

Ninu iroyin miiran:

Awọn ọlọkada dana sun ọkunrin kan ti wọn fura si pe o ji ọkada gbe l‘Eko

Awọn ẹgbẹ ọlọkada lọjọbo ṣe ikọlu si awọn ọkunrin kan ti wọn furasi pe o n gbiyanju lati ji ọkada ni agbegbe Egan ni igando, nipinlẹ Eko.

Afurasi ọhun lo ṣe ikọlu si arakunrin kan to n gbe ọkada rẹ jade, ti wọn si ṣe e leṣe gidi gan.

Kete tawọn ẹlẹkada yoku gbọ nipa isẹlẹ yii, ni wọn ṣe awari awọn afurasi adijunjale ọhun, ti wọn si dana sun ọkan lara wọn.

Hundeyin, tii se agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, ni awọn ti gbe oku naa lọ si ile igbokupamọ si.

Agbẹnusọ ọlọpaa ni, ni kete tawọn de sibi isẹlẹ naa, gbogbo awọn to sisẹ naa ti fẹsẹ fẹ.