You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
"Adedibu ò kú o, a sì ń rí Baálẹ̀ Molete"
Ọkan lara awọn iyawo oloogbe Alhaji Lamidi Adedibu, ogbontarigi oloṣelu niluu Ibadan, Alhaja Modinat Abosede Adedibu ti sọ pe Adedibu o ku tori nigba kugba toun ba ti wo ọmọ ti oun bi lọjọ ti ọkọ oun jade laye loun maa n ranti Baale Molete.
Ọrọ yii jade nigba ti Alhaja Modinat n sọrọ nibi ayẹyẹ iranti ọdun mejidinlogun ti Oloye Lamidi Ariyibi Adedibu jade laye.
''Oju ọkọ mi ni mo fi maa n wo ọmọ abigbẹyin mi nitori pe ọjọ ti ọkọ mi jade laye ti awọn eniyan n sukun lọwọ ni mo bi ọmọ naa.''
Alhaja Abosede Adedibu sọ pe oun dupẹ pupọ lọwọ Ọlọrun pe lati igba ti ọkọ oun ti di oloogbe, gbogbo awọn ọmọ rẹ ninu oṣelu ko jẹ ki oju ti oun.
O ni gbogbo igba toun ba pe wọn ni wọn maa n jẹ oun.
Alhaja Abosede ni ''ohun ti mo wa fẹ lasiko yii ni pe ninu ile baba Adedibu ni mo ti fẹ ki gomina jade ninu eto idibo gbogbogbo to n bọ lọdun 2027.''
Nigba ti o n se waasi nibi ijokoo naa, Sheikh Taofeek Akeugbagold sọ pataki igbe-aye Oloye Lamidi Adedibu.
Sheikh Akeugbagold sọ pe bi awọn oloselu ba le ma huwa bi ti Adedibu, ipinlẹ Ọyọ ko ba ti tẹsiwaju ju bi o se wa yii lọ.
Akeugbagold ni Oloye Adedibu le jẹ eeyan lile, sugbọn eniyan to nífẹẹ omolakeji ni ti o si fẹ idagbasoke fun gbogbo awọn eniyan ti wọn wa ni ayika rẹ papa julọ awọn ọmọ Ibadan.
Onimọ nipa ẹsin Islam naa jẹ ko di mimọ pe gbogbo ipo ti oun di mu lonii wa lati ipasẹ Oloye Adedibu, o si gbadura pe ki Ọlọrun dẹ ilẹ fun oloogbe naa.
Imaamu agba ilẹ Ibadan, Sheikh Abdul-Ganiyu Agbotọmọkekere ti aafa agba ilẹ Ibadan ṣoju fun nibi eto naa ṣe adura fun gbogbo awọn iyawo, awọn ọmọ oloogbe ati gbogbo awọn afenifere ti wọn wa ni bi eto naa.
Lara awọn eeyan pataki ti wọn peju pesẹ ṣibi eto naa ni Sijuade Adedibu, Sẹnẹtọ tẹlẹ ri, Kola Balogun, ati Saka Balogun.
Awọn mii to tun wa nibi eto ọhun ni Oloye Oyelese, Hazem Gbolarumi to fi mọ Alhaji Morafa.
Ṣaaju ni awọn oloselu ti wọn tara baba Adedibu dide ti fi ẹsẹ rin lati agbegbe Bodija titi wọn fi de Molete nile oloogbe lati bi ọla fun baba.