Ìjọba Equatorial Guinea kọ̀wé fipò sílẹ̀ lẹ́yìn tó kùnà láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ijọba orilẹede Equatorial Guinea ti kọwe fipo silẹ lẹyin ti o kuna lati mu ileri rẹ ṣẹ.

Igbakeji Aarẹ orilẹede naa, Teodoro Nguema Obiang Mangue, lo fi idi ọrọ yii mulẹ.

Obiang to tun jẹ ọmọ Aarẹ Teodoro Obiang Nguema Mbasogo sọ pe Olootu ijọba orilẹede naa ti kede wi pe gbogbo ọmọ igbimọ ijọba lo ti fipo wọn silẹ tori bii ida 10% ileri ti wọn ṣe ni wọn le muṣẹ.

Ọmọ aarẹ ko ṣalaye awọn ileri ti ijọba naa ṣe ni pato, amọ, atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu to wa ni ijọba fi sita sọ pe aarẹ orilẹede naa ti ṣakiyesi pe iwa ibajẹ ti gbilẹ si, ati pe ijọba ti kuna lati ri pe ọrọ aje Equatorial Guinea ko duro lori kan.

Aarẹ Obiang ni aarẹ orilẹede ti o tii pẹju lori aleefa lagbaaye lẹyin to bẹrẹ si ni ṣejọba Equatorial Guinea lọdun 1979.

Oniruuru ipo lawọn ẹbi Obiang dimu ninu ijọba orilẹede naa.

Ọdun 2024 ni aarẹ yan igbimọ ijọba to kọwe fipo silẹ sipo, ti o si kede Manuel Osa Nsue Nsua gẹgẹ bi Olootu Ijọba.

Igbakeji aarẹ sọ lọjọ Iṣẹgun wi pe bi igbimọ ijọba ṣe kọwe fipo silẹ wa ni ibamu pẹlu alakalẹ wi pe ẹni to ba di ipo adari mu gbọdọ mu ileri rẹ ṣẹ.

O ni awọn iṣẹ ti jọba ṣe ko to nnkan ti wọn ṣeleri lati ṣe.

Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDGE to wa ni ijọba ti sọ pe igbimọ ijọba to kọwe fipo ko ṣe nnkan iwuri to ṣe e mu yangan.

Ni bayii, aarẹ gbọdọ yan ijọba tuntun.

Ẹgbẹ PDGE tun sọ pe ijọba to n lọ na owo ilu ni inakuna, wọn si kuna lati ṣe awọn akanṣẹ iṣẹ idagbasoke lawujọ.

Aarẹ tun sọ pe igbimọ ijọba to kọwe fipo silẹ kuna lati ṣe agbekalẹ ti yoo mu eto ọgbin gbooro si i.

Epo rọbi ni o pọju ninu nnkan alumọni ti Equatorial Guinea fi n ṣe ọrọ aje.

Ọpọ ọmọ orilẹede naa ni iṣẹ ati oṣi n baa finra, bo tilẹ jẹ pe wọn ni epo rọbi lọpọ yanturu ti wọn fi n ṣe ọrọ aje.