Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́

Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́
Published

Hmmm

Ki lo n kọ ẹ lominu to fi n mi kanlẹ bayii?

Oni lo pe ọsẹ mẹta tawọn janduku agbebọn ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe lọ l'Ogbomoso

O gbenutan o, mo tiẹ tun gbọ pe ile aṣofin Oyo ti tako aba lati sanwo itusilẹ fawọn janduku naa

Ki nidi abajọ tawọn aṣofin fi sọ bẹẹ?

Alaye wa lori ikanni BBC Yoruba

''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Ẹwẹ, Oloye Sunday Igboho ti sọ pe oun màwọn olóṣèlú tó ṣagbátẹrù ìjinigbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ naa

Ati pe oun yoo darukọ wọn ti wọn o ba jawọ ninu iṣẹ ibi ti wọn n ṣe

Igboho fikun ọrọ rẹ pe oun ṣetan lati wọnu igbo lọ doola awọn akékọọ ti wọn ji gbe naa

Amọ, oun nilo iyọnda lati ọdọ ijọba koun to le ṣe bẹẹ

'''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''''

Pekele pekele, arugbo jẹ gbese ta ni oo san o?

Ki lo ṣẹlẹ?

Igbakeji alaga ijọba ibilẹ Ilememeje l'Ekiti, Grace Ogunleye, lo ma ti dero atimọle

Lẹyin ti iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fidi rẹ mulẹ pe o ji ara rẹ gbe lati gbowo lọwọ ijọba

Ileẹjọ majisireeti l'Ado-Ekiti ti sun igbejọ arabinrin naa siwaju