You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Agbébọn pa èèyàn mẹ́ta nílé ẹ̀kọ́, ọlọ́pàá, ológun, fijilanté dènà ìjínigbé, pa agbébọn kan
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi ti ṣalaye nipa ikọlu awọn agbebọn to waye nile ẹkọ Government Secondary School, niluu Iluke, nijọba ibilẹ Kabba/Bunu.
Ọjọru, ọjọ kẹwaa oṣu Kẹfa ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn to to ogoji niye, ya wọ ile ẹkọ naa pẹlu alupupu ti wọn gun wa.
Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kogi, ASP Saliu Oyiza Afusat, ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọru naa, ṣalaye pe awọn agbebọn ọhun pa eeyan mẹta, awọn ikọ alaabo si pa ọkan lara wọn pẹlu, bẹẹ ni wọn ko ri ẹnikẹni gbe wọgbo lọ.
Alaye ileeṣẹ ọlọpaa Kogi lori iṣẹlẹ naa
Gẹgẹ bi Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kogi ṣe fidi ẹ mulẹ, nnkan bii aago mẹwaa aarọ ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa gba ipe, pe awọn ajinigbe ti ya bo ilu Iluke.
"Erongba wọn ni lati ji awọn akẹkọọ atawọn ara agbegbe naa mi-in gbe wọgbo lọ.
"Kia ni ẹka ọlọpaa Kabba 'A' Division ti ṣeto awọn ẹṣọ, pẹlu awọn ọlọpaa to n wọde, awon ologun atawọn fijilante adugbo.
"Wọn jọ koju awọn agbebọn naa, eyi to mu wọn sa wọ awon igbo to wa nitosi lọ.
"Iwadii fi han pe wọn ko ri ẹnikẹni gbe wọgbo lọ. Amọ o ṣeni laaanu pe eeyan mẹta ku lasiko ikọlu naa."
Awọn to di ologbe bi ileeṣẹ ọlọpaa Kogi ṣe kede ni:
Ganiyu Anifowose to jẹ Igbakeji ọga agba nile ẹkọ UBE Secondary/Primary School, Iluke, Ọgbẹni Sunday Jacob Alhassan, ẹni aadọrin ọdun (70 years) ati Sunday Ayele, ọmọ ọdun mẹfa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kogi fi kun un pe ọkan lara awọn agbebọn naa ba ikọlu ọhun lọ, bẹẹ ni awọn ẹṣọ alaabo kan naa fi ara gbọta ibọn, wọn n gba itọju lọwọ.
Lati ri awọn agbebọn to sa wọgbo lọ naa mu, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kogi ti paṣẹ pe kawọn agbofinro maa fọ́ awọn igbo agbegbe naa ka.
Ikọ agbofinro bii ọlọpaa, ologun, fijilante ni wọn ti n fọgbo kiri bayii bi ileeṣẹ ọlọpaa Kogi ṣe wi, wọn si rọ araalu lati fi ọkan balẹ.
Wọn ni ki wọn foju ṣọri, ki wọn si maa fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo pẹlu tita wọn lolobo tootọ, ti yoo ran iṣẹ yii lọwọ.
"Aṣọ ologun ilẹ Naijiria ni awọn agbebọn naa wọ wa"
Ninu atẹjade ti ẹka ileeṣẹ ologun 12 Brigade, ni Kogi fi sita ni tiwọn, wọn ṣalaye pe aṣọ ologun ilẹ wa ni awọn ajinigbe naa wọ wa.
Ọgagun Hassan Abdullahi, Adele Igbakeji Adari ikede nileeṣẹ ologun naa ṣalaye ninu atẹjade to fi sita, pe
"Awọn ajinigbe naa ti to awon akẹkọọ ile ẹkọ alakọọbẹrẹ Iluke si ori ilà, pẹlu ero ati maa gbe wọn wọgbo lọ.
"Lai pẹ rara, ikọ ologun koju wọn, to mu wọn fi ero ijinigbe naa silẹ, ti wọn si sa kuro lagbegbe naa."
O ni agbebọn kan ku ninu ikọlu naa, ọpọ wọn sa lọ.
Kawọn ikọ alaabo too de, ileeṣẹ ologun Kogi sọ pe awọn agbebọn naa ti pa tiṣa kan ati olugbe agbegbe naa kan.
Gẹgẹ bawọn ọlọpaa ṣe rọ araalu lati tete maa ta awọn agbofinro lolobo, bẹẹ naa ni awọn ologun naa parọwa, ti wọn si tun pe fun fifi ojuṣọri araalu, ati ifọkanbalẹ, pe didun ni ọsan yoo pada so.