You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ilé ẹjọ́ ní kí INEC yọ orúkọ ẹgbẹ́ òṣèlú Atiku, Oriyomi àti ẹgbẹ́ mẹ́ta mii kúrò nínú àkọsílẹ àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú
Ile ẹjọ giga apapọ niluu Abuja ti paṣẹ fun ajọ eleto idibo INEC pe ko yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu ADC, Accord ati ẹgbẹ oṣelu mẹta mii.
Awọn ẹgbẹ oṣelu mẹta toku ni ẹgbẹ APP, ẹgbẹ oṣelu AA, ati ẹgbẹ ZLP.
Adajọ Peter Lifu lo paṣẹ naa nile ẹjọ giga apapọ l'Abuja lọjọ Aje ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹfa yii.
Ṣaaju ni igbimọ awọn aṣofin tẹlẹri ti beere pe ki ile ẹjọ sọ boya ajọ eleto idibo INEC lagbara labẹ ofin lati yọ awọn ẹgbẹ oṣelu to ba kuna lati ṣe nnkan ti abala 225A iwe ofin orilẹede Naijiria sọ, eyi to wa ni ibamu pẹlu atunṣe ofin eto idibo Naijiria ti ọdun 2022.
Igbimo awọn aṣofin tẹlẹri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un yii ti kuna lati maa tẹsiwaju gẹgẹ bii ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.
Lara awọn nnkan amuyẹ tawọn aṣofin naa sọ pe awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa kuna lati ni, ni ida 25% ibo nipinlẹ kan lasiko eto idibo aarẹ to kọja.
Amuyẹ mii ni pe awọn ẹgbẹ oṣelu yii gbọdọ ni aṣoju kan ti araalu dibo yan yala ni ijọba ibilẹ tabi ipinlẹ tabi nile aṣofin agba l'Abuja.
Awọn olupẹjọ naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin yoku fidirẹmi ninu ibo gbogbogbo ọdun 2023 ati ninu atundi ibo to waye debi wi pe wọn ko ni aṣoju kankan ti araalu dibo yan.
Awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ pe bi ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii ṣe wa lara awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹ dije ninu eto idibo to n bọ lodi sofin orilẹede Naijiria ati ofin eto idibo.
Lẹyin naa ni wọn rọ ile ẹjọ pe ki o yọ orukọ awọn ẹgbẹ marun un naa kuro ninu awọn ẹgbẹ oṣelu ti yoo kopa ninu eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Bakan naa tun ni awọn olupẹjọ tun rọ ile ẹjọ lati fofin de awọn ẹgbẹ oṣelu marun un naa wi pe wọn o gbọdọ kopa ninu ipolongo ibo ati eto idibo ọdun 2027 to n bọ.
Wọn tun rọ ile ẹjọ wi pe ko paṣẹ fun ajọ INEC pe ko gbọdọ ni ibaṣepọ kankan pelu awọn ẹgbẹ naa mọ.
Idajọ yii yoo ṣakoba fun Igbakeji Aarẹ Naijiria tẹlẹ, Atiku Abubakar, to fẹ dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ADC ninu eto idibo ọdun 2027.
''Awọn aṣoju to wa lode ni fẹ ki ADC kopa ninu ibo 2027''
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu ADC to jẹ ẹgbẹ Atiku Abubakar ti sọ pe ile ẹjọ fẹ lo ara rẹ lati ṣakoba fun ijọba awaarawa pẹlu idajọ ti ileẹjọ apapo l'Abuja gbe jade.
Ẹgbẹ naa sọ pe idajọ ti Adajọ Peter Lifu gbe kalẹ buru jai, o si le da rogbodiyan silẹ lagbo oṣelu.
Ẹgbẹ ADC sọ ninu atẹjade to fi sita pe idajọ ile ẹjọ giga apapọ naa tako iwe ofin Naijiria.
Lori ọrọ ti awọn aṣofin tẹlẹ ri naa sọ fun ile ẹjọ wi pe ẹgbẹ oṣelu ADC atawọn mẹrin mii, ADC sọ pe ajọ INEC funra rẹ fontẹ lu ẹgbẹ ADC loṣu Karun un to kọja.
Ẹgbẹ ADC ni kii ṣe ajọ kan lo maa sọ pe ki INEC yọ orukọ awọn ẹgbẹ oṣelu kan kuro ninu akọsilẹ ẹgbẹ oṣelu.
Wọn ni ọrọ ofin lọrọ naa, eyi ti INEC funra rẹ gan an ko ri ẹsun kankan ka si ẹgbẹ naa lẹsẹ.
ADC ni nnkan to yani lẹnu ni wi pe adajọ Lifu mọ wi pe ẹjọ kan wa nile ẹjọ kotẹmilọrun tẹlẹ eyi ti ko tii ni iyanju ki o to gbe idajọ tiẹ kalẹ.
Ẹgbẹ oṣelu Atiku ni ọrọ naa ti lọwọ oṣelu ninu, wọn ni aṣoju ẹgbẹ APC lo wa nidii ọrọ naa.
Ninu ọrọ tiẹ, oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu Accord nipinlẹ Oyo, Oriyomi Hamzat, ti sọ pe ile ẹjọ kotẹmilọrun ni ọrọ idajọ ileẹjọ giga apapọ l'Abuja to ni ki wọn yọ orukọ ẹgbẹ oṣelu naa kuro ninu akọsilẹ INEC ti le ni iyanju.
Oriyomi ni ile ẹjọ ko le da nnkan tawọn araalu n fẹ duro.
Oriyomi sọ pe ẹjọ naa wa ni ile ẹjọ kotẹmilọrun tẹlẹ, ati pe awọn n reti nnkan idajọ ile kotẹmilọrun lori ọrọ naa.