You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo àwọn èèkàn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti fún ìdìbó ọdún 2026
Opin ọsẹ yii, to jẹ ọjọ Abamẹta, ogunjọ, oṣu Kẹfa ọdun 2026 ti a wa yii ni eto idibo sipo gomina ipinlẹ Ekiti yoo waye.
Oniruru ẹgbẹ oṣelu lo n kopa ninu eto idibo naa amọ awọn ẹgbẹ oṣelu ọhun gbajumọ ju ara wọn lọ.
Lara awọn to n dije ni Biodun Oyebaniji ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Oluwole Oluyede ninu ẹgbẹ oṣelu PDP ati Oluwadare Bejide ninu ẹgbẹ oṣelu ADC.
Fun gbogbo awọn oloṣelu mẹtẹta yii, oniruru ileri ni wọn ti ṣe faraalu ti wọn ba de ori alefa.
Pupọ awọn ileri naa jẹ ohun ti yoo ṣe awọn eeyan ipinlẹ Ekiti lanfani ti wọn ba le mu ileri wọn ṣe.
Wayi o, awọn ileri naa jọ ara wọn bo tilẹ jẹ pe ẹgbẹ oṣelu wọn yatọ sira.
Tẹ ori aworan ọkọọkan ninu awọn eeyan wọnyii lati mọ ohun to wọn ni lọkan fun awọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ekiti ti wọn ba gori alefa.