Ṣé lóòótọ́ làwọn jàndùkú agbébọn fẹ́ gba inú igbó tó wà lẹ́yìn ọgbà fásítì kan wọ ìlú Eko? Ohun tí a mọ̀ rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ sii ṣe atunṣe eto aabo nile ẹkọ giga fasiti Pan-Atlantic University (PAU) to wa lagbegbe Ibeju-Lekki niluu Eko, lẹyin ti fidio kan to ṣafihan eeyan meji to faṣọ boju nibi ti wọn ti n bọ lati inu igbo to wa lẹgbẹẹ ile ẹkọ naa.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Tijani Fatai, funra rẹ ṣabẹwo si ọgba ile ẹkọ naa lanaa Ọjọru lati mọ nnkan to n ṣẹlẹ nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Abimbola Adebisi, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe Kọmiṣọna ọlọpaa ṣepade pọ pẹlu awọn alaṣẹ fasiti PAU nibi ti wọn ti jọ jiroro lori eto aabo nile ẹkọ giga naa.

Nibi ipade naa ni CP Fatai ti gba awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga naa ni imọran lati ri i pe eto aabo fẹsẹ mulẹ si i lọgba fasiti naa.

Bakan naa ni ọga ọlọpaa tun gbawọn alaṣẹ ile ẹkọ ọhun ni imọran lori ohun ti wọn le ṣe ti yoo mu ki eto mulẹ si i.

Ọga ọlọpaa ipinlẹ Eko tun rọ awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga PAU lati ṣọra fawọn to le gbabode fawọn ọdaran.

O fikun ọrọ rẹ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ti n fi baalu ẹlikopita wa ibikibi tawọn ọdaran le sa pamọ si nipinlẹ Eko.

''A ti bẹrẹ sii lo ẹrọ drone lati fi maa ṣe iwadii ati lati maa dẹkun iwa ọdaran ni agbegbe Ibeju-Lekki.''

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Eko wa fi dawọn alaṣẹ ile ẹkọ fasiti PAU, awọn oṣiṣẹ, awọn akẹkọọ atawọn obi loju wi pe awọn agbofinro ko ni kaarẹ nipa pipese eto aabo to mọyan lori fun wọn.

O tun rọ awọn olugbe ilu Eko lati maa sọ fun ọlọpaa ti wọn ba kẹẹfin ẹnikẹni ti o ba mu ifura dani.

''Gbogbo eto ti n lọ deedee pada ninu ọgba fasiti PAU''

Ẹwẹ, awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga fasiti PAU ti rọ awọn akẹkọọ, awọn oṣiṣẹ ati gbogbo eeyan wi pe ki wọn ma foya wi pe ko si ewu.

Ile ẹkọ naa fi ọrọ yii lede loju opo X rẹ.

Igbimọ alaṣẹ ile ẹkọ giga naa sọ pe gbogbo eto ti n lọ pada bo ṣe yẹ ko lọ bayii, to fi mọ idanwo to n lọ lọwọ.

Igbimọ naa ṣalaye pe awọn ẹṣọ eleto aabo ile ẹkọ naa bẹrẹ iṣẹ ni kiakia lẹyin ti iroyin kan jade wi pe awọn kan ri eeyan meji to da aṣọ boju ti irisi wọn dabi tawọn janduku agbebọn.

Wọn ni awọn ẹṣọ eleto aabo ti wa lojufo lati igba naa.

Awọn alaṣẹ ile ẹkọ giga fasiti PAU ko ṣai dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ eleto aabo atawọn olugbe agbegbe Ibeju-Lekki fun ipa ti wọn ko lẹyin ti iroyin naa jade lori ayelujara.