You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá Kwara nawọ́ gán afurasí ajínigbé mẹ́sàn-án, àkàrà bá tú sépo
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti ni ọwọ awọn ti ba afurasi agbebọn meji ninu igbiyanju wọn lati fopin si ijinigbe ni ipinlẹ naa.
Atẹjade kan ti agbenusọ ileeṣẹ ọlọpaa Kwara Adetoun Ejire-Adeyemi fi lede ṣalaye pe yatọ si awọn afurasi ajinigbe naa, ọwọ ọlọpaa tun tẹ ọkunrin kan ti igbagbọ wa pe o n ṣe agbodegba fun awọn ajinigbe ni ijọba ibilẹ Batuten.
Ikọ to n gbogunti iwa ọdaran lẹka ileeṣẹ ọlọpaa lo lewaju ikọlu naa latari italolobo kan ti wọn ri gba lori awọn afurasi naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọjọ Kẹfa, oṣu Kẹfa ni wọn ṣe ikọlu si ibi kan ti wọn gbọ pe o jẹ ibuba awọn afurasi ajinigbe.
Atẹjade naa ni wọn ba awọn afurasi meji, Bello Mohammed ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Abubakar Mohammed ẹni ọdun mẹẹdọgbọn nibẹ.
"A ri ibọn AK-47 meji, ọta ibọn rẹpẹtẹ, ada meji, daga kan, taya ọkọ meji, foonu atawọn nnkan mii ni ibuba awọn ajinigbe"
Wọn ni gbigbọn ibuba naa yẹbẹyẹbẹ ni wọn fi ṣawari ibọn AK-47 meji, ọta ibọn rẹpẹtẹ, ada meji, daga kan, taya ọkọ meji, foonu atawọn nnkan mii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni igbagbọ wa pe awọn afurasi naa lọwọ ninu ikọlu, ijinigbe atawọn iwa ọdaran mii to n waye ni Baruten atawọn agbegbe rẹ.
Wọn ni nigba ti awọn n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, Abubakar Mohammed jẹwọ pe oun wa lara awọn afurasi to n ṣiṣẹ ibi ni agbegbe naa ati pe ikọlu tawọn ẹṣọ aabo ti ṣe sawọn tẹlẹ lo je ki oun padanu ika mẹta lọwọ oun.
Wọn fi kun pe iwadii awọn lo tun ṣokunfa bi ọwọ ṣe tẹ Umoru Saliu, ẹni ọdun mejidinlọgọta, ni ọjọ Keje, oṣu Kefa.
Saliu ni ileeṣẹ ọlọpaa ni o n pese ibugbe ati ohun irinna fawọn afurasi ọdaran naa lati fi ṣe iṣẹ ibi wọn.
Atẹjade naa ni awọn afurasi naa ko i tii sọ ohunkohun nipa ibi ti olori wọn atawọn yooku wọn wa amọ igbagbọ wa pe wọn ti na papa bora.
Ọwọ ọlọpaa tun tẹ afurasi ajinigbe meje mii
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa tun ni ọwọ ti tẹ awọn awọn afurasi ajinigbe meje kaakiri awọn agbegbe ni ipinlẹ Kwara.
Ejire-Adeyemi ninu atẹjade rẹ ikọ to n gbogunti iwa ijinigbe nigba ti wọn gbọ nipa ijinigbe kan to waye ni agbegbe Agbeyangi ni ilu Ilorin bẹrẹ iwadii ti iwadii wọn si ṣokunfa bi wọn ṣe nawọ gan afurasi kan to n jẹ Surajo Abubakar.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni Surajo Abubakar lo ṣe atọna bi ọwọ ṣe tẹ awọn afurasi mii bii Umar Yabani ti inagijẹ rẹ n jẹ Yabo, ẹni ti wọn pe ni olori awọn ọdaran naa, Isah Sule ati Umar Sani.
Wọn ni iwadii fi han pe awọn afurasi naa lọwọ ninu awọn ijinigbe to n waye ni awọn ijọba ibilẹ Ilorin East, Edu, Ifelodun atawọn ilu to w ani agbegbe rẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa naa ni ọjọ Kẹrin, oṣu Kẹfa ni ajọṣepọ iṣẹ ọlọpaa atawọn aṣọgbo ati fijilante tun so eso rere bi wọn ṣe ri lara awọn ọmọ ẹgbẹ awọn afurasi naa Bello Alhaji Maidabo, Shehu Malami ati Risikuwa Babuga mu ninu igbo kan to w ani ẹba Tsaragi.
Wọn ni oniruuru ohun ija ni wọn ba lọwọ wọn to fi mọ awọn ibọn agbelẹrọ atawọn ọta ibọn lọkan-o-jọkan.
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ naa, Kọmiṣanna ọlọpaa Kwara, Adekimi Ojo juwe aṣeyọri naa bii ifarajin ileeṣẹ ọlọpaa lati le awọn ọdaran kuro ni ipinlẹ naa patapata.
Ojo ni iṣẹ n lọ lọwọ lati ri pe gbogbo awọn ọdaran ti wọn na papa bora naa ni ọwọ tẹ laipẹ, ti wọn si foju wina ofin.
O fi kun iwadii n lọ lọwọ lori awọn afurasi naa ati pe wọn maa koju igbẹjọ ni kete ti iwadii ba ti pari lori wọn.