Líla ọwọ́ sí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ lè jẹ́ kí ẹ̀mí ré gùn - Ìwádìí

Líla ọwọ́ sí àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ rẹ lè jẹ́ kí ẹ̀mí ré gùn - Ìwádìí
Published

O daa lati maa ṣe aanu fun awọn eeyan, o si daa lati maa ṣaanu. Iwe mimọ kan tilẹ sọ pe o san lati fun fun'ni ju ki eeyan maa gba lọ.

Amọ iwadii ijinlẹ ti fidi ọrọ yii mulẹ pe lila ọwọ si awọn ẹbi ati ọrẹ eeyan le jẹ ki ẹmi ẹni to n la ọwọ naa gun.

Iṣẹ iwadii to ti le lọdun mẹwaa lori idunnu agba ti fidi eyii mulẹ pe odinwọn irufẹ ọrẹ tabi ẹbi rere ti eeyan ni le sọ bi inu irufẹ ẹni bẹẹ yoo ṣe maa dun to.

Iwadii Scientific Study of Happiness jẹ ko di mimọ pe awọn to n fi inu kan ṣe ara ati ọrẹ loore kii fi bẹẹ ni aisan ọkan tabi irẹwẹsi yatọ si awọn ti wọn maa n da fi igba gbogbo da wa.

Iwadii ọhun tun fi han pe awọn to ni ọrẹ tabi ẹbi to dara ti wọn si n na ọwọ si awọn eeyan naa lọna ti ko ni pa ara wọn lara maa n dagba lai ni iyọnu to poju.

Wo fidio oke yii fun ẹkunrẹrẹ.