Wo àwọn nǹkan táwọn olóṣèlú ń pín ṣáájú ìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun tó ń bọ̀

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Bi eto idibo gomina ipinlẹ Osun ti wọle de, gbogbo ọna ni awọn oloṣelu n gba lati rii pe awọn eeyan dibo fun wọn lọjọ idibo.
Oriṣiriiṣi nnkan ni awọn oloṣelu ti n pin fun awọn eeyan ki wọn ba le dibo fun ẹgbẹ oṣelu wọn lọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii.
Oniruuru fọnran ati fọto lo ti lu ori ayelujara pa eyi to n ṣafihan nnkan tawọn oloṣelu n pin fun araalu nipinlẹ Osun ṣaaju eto idibo opin ọsẹ yii.
Ọpọ eeyan lo si ti n sọrọ lori awọn nnkan tawọn oloṣelu n pin lori itakun ayelujara yii.
Wọnyii ni oriṣiiriṣii nnkan tawọn oloṣelu n pin fun araalu ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Osun opin ọsẹ yii:
Burẹdi
Lara nnkan tawọn oloṣelu n pin ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Osun ọjọ Satide ni burẹdi.
Fidio kan to ti lu ori ayelujara pa bayii ṣafihan bi obinrin pupa kan ṣe n fawọn eeyan ni burẹdi.
Burẹdi naa si ni aworan oludije sipo gomina fẹgbẹ oṣelu APC, Bola Oyebamiji, lara.
Bakan naa ni aworan AMBO to jẹ oludije ẹgbẹ APC si tun wa lara ẹwu ti obinrin to n pin burẹdi naa wọ ati fila ti o de pẹlu.
Nibi ti wọn ti n pin burẹdi naa ni wọn ti n fi epe julẹ wi pe ẹnikẹni to ba gba nnkan tawọn n pin ṣugbọn to kọ lati dibo fawọn ko ni i ṣe oriire pẹlu awọn ọmọ rẹ.
Owo
Fidio kan lori ayelujara tun ṣafihan bawọn oloṣelu ṣe n pin owo fawọn eeyan ṣaaju eto idibo gomina ipinlẹ Osun opin ọsẹ yii.
Fọnran naa ṣafihan awọn eeyan kan ti aworan oludije sipo gomina APC, Bola Oyebamiji, wa lara aṣọ ti wọn wọ ati fila ti wọn de pẹlu.
Ni ṣe lawọn eeyan to sẹyin ara wọn lati owo naa.
Awọn to n pin owo yii ko ṣai kilọ fawọn to n gbowo wi pe wọn o gbọdọ ma dido fẹgbẹ awọn lọjọ Satide.
Irẹsi
Nnkan mii ti o tun wọpọ tawọn oloṣelu n pin nipinlẹ Osun ṣaaju eto idibo ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii ni irẹsi.
Obinrin kan to wọ aṣọ ati fila ti aworan oludije ẹgbẹ oṣelu APC AMBO wa lara rẹ lo n pin irẹsi naa.
Ninu ọra ni wọn di irẹsi naa si ti wọn si n fun ẹnikọọkan ni meji meji.
Bi obinrin ọhun ṣe n fun wọn ni irẹsi lo n sọ fun wọn pe ki wọn maa gbagbe lati wa fun ipolongo ibo fun ẹgbẹ APC ni ọjọ keji.
Ẹwẹ, ọpọ eeyan lo ti bu ẹnu ẹtẹ lu awọn nnkan tawọn oloṣelu n pin yii ṣaaju eto idibo ọjọ Abamẹta ọjọ kẹẹdogun oṣu Kẹjọ yii.
Awọn kan tiẹ sọ pe gbigba irẹsi tabi burẹdi ko ni kawọn eeyan to gba awọn nnkan yii dibo fẹgbẹ oṣelu to n pin nnkan.



























