Olùṣọ́ Onadeko ọ̀rẹ́kùnrin Tope Osoba ṣàlàyé nǹkan tó mọ̀ nípa ikú gbajúmọ̀ òṣèré tó lọ àtàwọn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án

Oríṣun àwòrán, Temitope Osoba/Instagram/Temitopa Osoba Fans/TikTok
Ọrẹkunrin gbajumọ oṣere ori itage, Temitope Osoba, to jade laye; Wolii Itunu Onadeko ti ṣalaye bi oṣere naa ṣe dagbere faye.
Wolii Onadeko ṣalaye ninu ifọrọwerọ ti o ṣe pẹlu Celestial Reality Check lopin ọsẹ to kọja wi pe ni agọ ọlọpaa kan ni Ikorodu nipinlẹ Eko ni o ku si.
Onadeko sọrọ yii lẹyin ti ọpọ eeyan ti fẹsun kan an lori ayelujara wi pe oun lo lu u ti ẹmi fi bọ lẹnu rẹ.
Awọn kan tiẹ sọ pe ọrẹkunrin Tope ni o fun un ni majele jẹ ti o si gba ibẹ ku.
Amọ, Wolii Onadeko ṣalaye wi pe ẹnikan lo pe oun lori foonu lọganjọ oru wi pe Tope ti ku.
''Ẹni ti mi o mọ ri rara lo pe mi ni nnkan bi ago mejila oru wi pe Tope ti ku si agọ ọlọpaa kan ni Ikorodu.
Onadeko to jẹ Oluṣọ ile ijọsin CCC Onibuore Cathedral, Bogije, Ibeju-Lekki niluu Eko sọ pe oun ko tiẹ mọ agọ ọlọpaa ti o ku si gan an ni Ikorodu.
Oluṣọ Onadeko ṣalaye pe Arabinrin Kehinde Osoba ti oun naa ni ile ijọsin ni Tope lọ ri ki o to ku.
''Tope sọ fun mi pe oun fẹ lọ ri Arabinrin Kehinde, koda, o ni ki a jọ lọ sibẹ.
Ṣugbọn mo sọ fun un wi pe iṣẹ ijọ ko le jẹ ki n ri aye lati tẹle e lọ sibẹ.
Ẹni to maa n ṣe irun ti Tope maa n sun sọdọ rẹ ni wọn jọ lọ sọdọ Arabinrin Kehinde Osoba.
Amọ, mo n ba a sọrọ ni gbogbo asiko naa, koda, o tun kọ ''Ogo Tuntun'' soju opo ayelujara rẹ lasiko naa.
Lẹyin naa ni mo gbọ wi pe Tope ti ku si agọ ọlọpaa.
Bo tilẹ jẹ pe mi o mọ agọ ọlọpaa ti o ku si, lẹsẹ kẹsẹ ni mo lọ si agọ ọlọpaa to sun mọ mi lati fi ọrọ naa to wọn leti,'' Onadeko lo ṣalaye bẹẹ.
Onadeko sọ pe iyalẹnu lo jẹ foun wi pe ọpọ eeyan n sọ lori ayelujara wi pe arun jẹjẹrẹ ọyan ti o mu un tẹlẹ lo pa a, nigba ti awọn mii sọ pe ẹbi oun lo fiya jẹ ẹ to fi ku.
Wolii ijọ CCC naa sọ pe lootọ ni o ti ni arun jẹjẹrẹ ọyan tẹlẹ, amọ, ki i ṣe arun naa lo ṣekupa a.
''Nigba ti mo kọkọ pade Tope, o sọ fun mi pe oun fẹ ṣiṣẹ abẹ lori arun jẹjẹrẹ ọyan lẹyin ti mo ṣe eto aabo fun un''
Onadeko ṣalaye siwaju si i pe ''nigba ti mo kọkọ pade Tope, o sọ fun mi pe oun fẹ ṣiṣẹ abẹ lori arun jẹjẹrẹ ọyan lẹyin ti mo ṣe eto aabo fun un.''
Oluṣo Onadeko tun ṣalaye wi pe irọ to jinna si ootọ niroyin kan tawọn eeyan n gbe kiri wi pe oun lo ọgbọn miliọnu tawọn eeyan da fun un lati tọju ara rẹ kọ ṣọọṣi.
O ni akanti Tope ni wọn fi gbogbo owo ti o ri ranṣẹ si, kii ṣe akanti oun.
Onadeko ni oun mọ pe awọn eeyan fun un lowo to fi mọ Oloye Mike Adenuga to fun un ni iwe sọwe dowo.
Ṣugbọn Oluṣọ loun ko fọwọ kan owo naa rara.
Wolii Onadeko ni nnkan bi ọdun meji sẹyin loun pade Tope, nigba ti ile ijọsin CCC Bogije si ti wa fun bii ogun ọdun bayii.
Laarin ọsẹ to kọja ni iroyin jade wi pe Tope dagbere faye lẹni ogoji ọdun.


























