Wo àwọn agbègbè tí INEC sọ pé ó ṣeéṣe kí wàhálà bẹ́ sílẹ̀ lásìkò ìbò gómìnà Sátidé ní Osun

Aworan eeyan kan to n ṣeto idibo ati aworan awọn janduku lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Bi eto idibo si ipo gomina ṣe n sunmọle ni ipinlẹ Ọṣun ti rukerudo ati wahala ipaniyan ati idaluru n jẹyọ lọtun losi. Lọwọ yii ko din ni iṣẹlẹ jagidijagan mẹtalelaadọrin (73) to ni ṣe pẹlu oṣelu lo ti waye ni ipinlẹ naa.

Gẹgẹbi agbekalẹ ajọ kan to niiṣe pẹlu agbeyẹwo ọrọ abo ṣaaju idibo, Kimpact Development Initiative, (KDI), eeyan mọkandinlọgbọn lo si ti ku nipasẹ awọn ikọlu yii.

Bakan naa ni ajọ eleto idibo Naijiria, INEC pẹlu ti jade lati kede pe awọn ijọba ibilẹ marundinlogun kan wa ninu ọgbọ̀n to wa ni ipinlẹ naa, ti awọn ti n reti pe o ṣeeṣe ki ina wahala jo nibẹ lasiko idibo naa ti yoo waye ni ọjọ karundinlogun oṣu kẹjọ ọdun 2026.

Ajọ INEC si ti ke si awọn ẹṣọ̀ alaabo lati san ṣokoto wọn ko le daindain lati pa ina igbesẹ yoowu lati la idibo ru.

Awọn ijọba ibilẹ ti INEC ni o ṣeeṣe ki wahala ti bẹ silẹ lasiko ibo

Aworan oṣiṣẹ idibo kan to n kọ iwe lori tabili nibi eto idibo kan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn ijọba ibilẹ ti alaga ajọ INEC mẹnuba naa niwọnyii:

  • Atakumosa East
  • Atakumosa West
  • Boripe
  • Ede North
  • Ede South
  • Ife Central
  • Ifedayo
  • Ila
  • Osogbo
  • Ifelodun
  • Oriade