Kókó tó yẹ kí o mọ̀ nípa Aṣíwájú Munirudeen Bola Oyebamiji (AMBO), ọmọ ẹgbẹ́ APC tó ń dupò gómìnà Osun

Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji (AMBO), oludije sipo gomina Osun ninu ẹgbẹ APC. O de fila alawọ ewe, wọ aṣọ funfun. Awọn eeyan duro lẹyin rẹ bo ṣe n sọrọ si ẹrọ gbohungbohun to mu dani, bẹẹ lo n rẹrin-in musẹ pẹlu.

Oríṣun àwòrán, Bola Oyebamiji/Facebook

Àkọlé àwòrán, Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji (AMBO)
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọkan gboogi ninu awon oludije sipo gomina ipinlẹ Osun ni Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji ti ọpọ eeyan mọ si AMBO.

Awọn lẹta akọkọ ninu orukọ rẹ lo di AMBO ti aye mọ ọn si.

AMBO to n dijẹ labẹ asia ẹgbẹ APC ni olori alatako ti Gomina Ademola Adeleke to wa nipo naa lọwọ n koju.

Ta a ni AMBO?

Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji (AMBO)

Oríṣun àwòrán, Bola Oyebamiji/Facebook

  • Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 1965 ni wọn bi Munirudeen Bola Oyemabiji niluu Ikire, ijọba ibilẹ Irewole, nipinlẹ Osun.
  • O lọ sile ẹkọ alakọọbẹrẹ A.D.C , Oke-Ada, Ikire, laaarin ọdun 1971 si 1977.
  • AMBO lọ sile ẹkọ girama Ayedaade, Ikire, laaarin ọdun 1978 si 1982.
  • Ile ẹkọ Gbogboniṣe ilu Ibadan, nipinlẹ Oyo lo ti kẹkọọ nipa ifowopamọ ati Iṣuna (Banking and Finance). O ṣetan ni 1987.
  • AMBO kẹkọọ ninu Iṣakoso Awujọ (Public Administration), fun ipele keji ti a mọ si Masters. Yunifasiti ilu Eko (LASU) lo ti gba a ni 1997.
  • O gba ti okoowo (Business Administration) ni Yunifasiti Ado Ekiti ni 2004.
  • Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ Chartered Institute of Bankers of Nigeria (CIBN) si ni Asiwaju Munirudeen Bola Oyebamiji pẹlu.

Awọn iṣẹ ti AMBO ti ṣe ṣaaju

Gẹgẹ bi oludije lẹgbẹ APC yii ṣe ti fi ibẹrẹ aye rẹ jẹ oṣiṣẹ lẹka ifowopamọ ati okoowo, AMBO ṣiṣẹ lawọn banki bii:

Wema Bank, Trans International Bank, Spring Bank ati Enterprise Bank.

O gba igbega lawọn ẹka idari banki, o si gun awọn akasọ to gbe e de abala iṣakoso.

Ọdun 2012 lo di Adari Osun State Investment Company Limited (ti wọn n pe ni OSICOL nigba yẹn), nibi to ti ri si idokowo l'Osun.

O ṣe kọmiṣanna eto iṣuna lẹẹmeji l'Osun

Oyebamiji ṣe kọmiṣanna eto iṣuna labẹ akoso Rauf Aregbesola ati Gboyega Oyetola lasiko ti wọn jẹ gomina ipinlẹ Osun.

AMBO tun ṣe Oludamọran pataki fun Gboyega Oyetola to wa fun ọrọ omi okun nigba naa.

O dari ajọ NIWA, iyẹn National Inland Waterways Authority, ko too kọwe fipo naa silẹ loṣu Kẹwaa ọdun 2025 lati dupo gomina ni 2026.

Ileri kan pataki ti AMBO n ṣe fawọn eeyan Osun bi wọn ba dibo fun un ni pe oun yoo lo imọ ati jije akọṣẹmọṣẹ fi tun ọrọ aje ipinlẹ Osun ṣe.

O loun yoo pese iṣẹ fawọn ọdọ, bẹẹ ni ọrọ aje ipinlẹ Osun yoo ru gọgọ si i bi wọn ba fibo yan oun sipo gomina.

Baale ile ni AMBO, iyawo rẹ ni Dokita oniṣegun oyinbo; Sekinah Bola-Oyebamiji, wọn si bi awọn ọmọ.