Báwo ni àjọ ICPC tún ṣe ṣàwárí ilé-iṣẹ́ ayédèrú méjì míràn tí Adeyemi Adeniyi dá sílẹ̀?

Adeniyi Adeyemi, oga agba ayederu ilee PFIPC lakooko to kawọn rẹ sẹnu, to si n woye pẹlu ẹrọ gbohungbohun niwaju ẹ

Oríṣun àwòrán, Adeniyi Adeyemi/Others

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ajẹbanu nilẹ Naijiria, ICPC ti sọ pe awọn tun ti ṣawari ileeṣẹ meji miran ti wọn tun fi n lu jibiti labẹ idasilẹ ayederu ileeṣẹ PFIPC ti Adeniyi Adeyemi jẹ alakoso rẹ.

ICPC lo tu aṣiri naa sita lasiko ti alaga wọn, Musa Adamu Aliyu n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Abuja l'Ọjọbọ to kọja.

Aliyu sọ pe lasiko ti awọn n tọpinpin lori bi wọn ṣe da ileeṣẹ PFIPC silẹ, lẹyin aṣẹ Aarẹ Bola Tinubu, ni awọn ṣawari wi pe wọn tun ileeṣẹ meji miran silẹ labẹ iṣakoso ileeṣẹ naa, to si jẹ pe Adeyemi lo n ṣakoso gbogbo rẹ.

"Awọn to n ṣiṣẹ ninu igbimọ PEAC tẹlẹ, ni wọn n lo ọna ayederu ṣe oniruuru ohun ti ko ba ofin mu kaakiri awọn ileeṣẹ ijọba"

Alaga naa sọ pe o di dandan lati jẹ ki awọn eeyan mọ pataki ipade toun ṣe pẹlu aarẹ, ati pe lara iṣẹ ti aarẹ gbe le wọn lọwọ ni oun wa jabọ ibi ti wọn ba iṣẹ iwadii naa de.

O ni awọn oniṣẹ iwadii ni ileeṣẹ awọn fidi rẹ mulẹ pe ijọba apapọ ko figba kankan gba Adeyemi si iṣẹ, ati pe ileeṣẹ PFIPC to n ṣakoso rẹ ko ni atilẹyin ofin kankan, ati pe ko sibikankan labẹ ofin idasilẹ ti ile igbimọ aṣofin agba ti buwọ lu.

Gẹgẹ bi iwadii to ni awọn ṣe, o sọ pe wọn ṣe ayederu iwe igbanisiṣẹ fun Adeyemi ni, ati pe igbimọ oludamọran fun aarẹ lori eto ọrọ aje, PEAC, eyi to ti kogba wọle ni wọn lo lati fi da ileeṣẹ naa silẹ.

Alaga naa sọ siwaju pe awọn to n ṣiṣẹ ninu igbimọ PEAC tẹlẹ naa ni wọn lo ayederu, ti wọn si n ṣe oniruuru awọn ohun ti ko ba ofin mu, ti wọn si n ṣiṣẹ kaakiri awọn ileeṣẹ ijọba.

Nigba to n tọka si awọn ileeṣẹ naa, Aliyu sọ pe awọn ileeṣẹ bii FCT Investment Promotion Agency ati Foreign Investment Promotion Agency, ti wọn jẹ ayederu ni wọn gbe sabẹ iṣakoso PFIPC.

"Wọn da awọn ileeṣẹ wọnyi silẹ nipa ṣiṣe ayederu awọn ohun elo ile igbimọ, to si jẹ pe awọn nnkan naa ni wọn lọ lati fi ṣi apo aṣuwọn lawọn ile ifowopamọ fun iṣẹ jibiti ti ko ba ofin mu," Aliyu ṣalaye.

Kí ló tún ṣẹlẹ̀?

Alaga naa sọ pe Adeyemi ko duro lori igbesẹ, bi ko ṣe pe o tun tẹsiwaju lati yi orukọ ayederu ileeṣẹ ọhun kuro lati Foreign Investment Promotion Council si Foreign Intervention Promotion Council,

O ni eyi jẹ ara erongba lati jẹ ki iwa jibiti rẹ gbooro si, ko si le maa pa ọpọlọpọ owo wọle.

"Iwadii ti a ṣe, a ko ri owo kankan ti wọn buwọlu tabi ko sinu apo aṣuwọn PFIPC/PEAC

A ko si ri ifontẹlu kankan lati ile aṣofin tabi banki apapọ," o fidi rẹ mulẹ.

N jẹ ijiya wa bi fun Adeniyi atawọn osisẹ ijọba to n ti i lẹyin?

Ajọ ICPC sọ pe o yẹ ki ijọba apapọ foju Adeyemi winna ofin, ko si gbe igbesẹ ifiyajẹni fun gbogbo awọn oṣiṣẹ ijọba to lọwọ ninu iwa ibajẹ naa, lati le kọ awọn yooku ti wọn tun n gbero iru rẹ lọjọ iwaju lọgbọn.

Gẹgẹ bi abọ iwadii naa ṣe sọ, awọn alẹnulọrọ nileeṣẹ akọwe ijọba apapọ (OSFG), ileeṣẹ olori awọn oṣiṣẹ ijọba apapọ, ileeṣẹ to n ri sọrọ eto iṣuna ijọba apapọ, ati ajọ NITDA ni wọn jọ lọwọ si idasilẹ naa.

Aliyu wa sọ pe iwadii awọn ko tii pari, ati pe ifaara lasan ni abọ iwadii toun mu lọ fun aarẹ naa, to si ni iwadii n tẹsiwaju.

"Ifaara abọ lasan ni a mu wa yii, iwadii ṣi n lọ lati ṣawari ẹkunrẹrẹ iwa ọdaran siwaju sii, lati le fẹsun iwa ọdaran kan Adeyemi ati awọn alabaṣiṣẹpọ rẹ," Aliyu sọ bẹẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe oun ti ṣalaye ibi ti iwadii de duro fun Aarẹ Tinubu, pẹlu ileri wi pe oun yoo ṣiṣẹ naa lai fi ohunkohun pamọ sabẹ aṣọ lati yanju ohun to ṣẹlẹ yii.