Àjọ NiMet kéde ìpínlẹ̀ 19 tó ṣeéṣe kí omiyalé tún kọlù ní Naijiria

Awọ araalu lasiko omiyale

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ajọ to n ri si ọrọ oju ọjọ ni Naijiria, Nigerian Meteorological Agency (NiMet) ti sọ asọtẹlẹ pe ojo ati oniruru ara yo san kaakiri Naijiria, ti omiyale yoo si ṣelẹ lawọn agbegbe kan.

Gẹgẹ bi ajọ naa ṣe kede louj po X rẹ, awọn ojo yoo ṣu lawọn ipinlẹ kan ni ariwa Naijiria laarọ oni Ọjọru, nigba ti ojo yoo rọ lawọn ipinlẹ kan bii Adamawa, Taraba, Bauchi, Gombe, Jigawa, Kaduna ati Kano.

Nigba ti yoo ba fi di ọsan si irọlẹ, ara pẹlu ojo yoo kọlu awọn ipinlẹ mii bii Kaduna, Katsina, Kano, Kebbi, Zamfara, Sokoto, Yobe, Bauchi, Borno, Adamawa ati Taraba.

Ni aringbubgu iha ariwa Naijiria, NiMet sọ pe ọrọ naa yoo kan awọn ibi kan ni Nasarawa, Benue, Kogi ati Abuja.

Yoo si tun tẹsiwaju titi di ọsan si irọlẹ.

Ni iha gusu, wọn ni o ṣeeṣe ki ojo rọ ni ipinlẹ Ondo atawọn ipinlẹ mii ni ilẹ Igbo.

To ba di ọsan, ojo diẹ yoo rọ ni Cross River ati ipinlẹ Akwa Ibom.

NiMet tun kilọ pe yatọ si iji ti yoo maa fẹ, mọnamọna yo maa kọ, bẹẹ ni kurukuru tun ṣeeṣe ko bo oju ọjọ mọlẹ.

Ajọ ọhun wa fi akoko naa kilọ fun awọn awakọ ki wọn ṣọra fun ere asapajude lasiko ojo ọhun.

Wọn ni "Awọn awakọ gbọdọ ṣọra lasiko ojo, wọn si tun gbọdọ yago fun wiwa ọkọ ninu agbara omi atawọn ibi ti omi ba ya si.

Lẹyin naa ni wọn ke si awọn ileeṣẹ ọkọ ofurufu ki wọn kan si awọn nipa bi oju ọjọ yoo ṣe ri ki wọn to gbe baalu wọn soju ofurufu.