Ọ̀pọ̀ òǹwòye ìbò l;ó wo bí ìbò ṣe lọ

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP
Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan


Awọn ohun elo idibo wọn yi lo ṣẹku lẹyin idibo to waye ni ijọba ibilẹ Owerri Municipal nipinlẹ Imo.



Ko din ni eeyan mẹta to jẹ Ọlọrun nipe ni agọ idibo kan lagbegbe Amukpe nilu Sapẹlẹ, nipinlẹ Delta lasiko eto idibo to waye lana.
Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ salaye pe, awọn eeyan to jẹ alaisi yii ni ẹmi wọn bọ lati ọwọ awọn afurasi janduku oloselu.
Wọn salaye siwaju pe, awọn janduku naa ni wọn ya wa si agọ idibo, ti wọn si n yinbọn mọ awọn oludibo.
Loju ẹsẹ ni eeyan meji ku, ti ikẹta si gbẹmi mi ni kete to de ile iwosan.
Awọn ọlọja nilu Kano ko jafira lẹyin ti gbedeke irina lasiko idibo wa si opin.
Lawọn ọja ti akọroyin wa de,niṣe ni karakata n lọ lai si idiwọ kankan.



Kọmisana kan labẹ ajọ eleto idibo eyi to wa fun eto ilanilọyẹ awọn oludibo, Festus Okoye ni, iroyin ti de eti ajọ Inec lori bi wọn se n ji apoti idibo gbe ni agbegbe Akokotoro ati Bonny nipinlẹ Rivers, Eko ati ni Anambra.
O ni awọn n duro de abọ nipa isẹlẹ ọhun lati ọdọ awọn kọmisana fun ajọ eleto idibo lawọn ipinlẹ.
Okoye ni o seese ki ajọ INEC sun ibo siwaju lawọn ipinlẹ yii.

Awọn olori orilẹede Naijiria tẹlẹri, Oluṣẹgun Obasanjọ, Goodluck Jonathan ati ajagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar ti dunnu si bi idibo aarẹ ati tile aṣofin agba ṣe lọ.
Obasanjọ ni ẹnikan naa ni yoo bori ninu idije nigba ti ẹlomiran yoo fidi rẹmi.
Ninu ọrọ tiẹ, ajagun fẹyinti Abdulsalami Abubakar, rọ awọn oludije lati jẹ ki ifẹ orilẹede Naijiria wa lọkan wọn ṣaaju ohun kohun miran.
Aarẹ ana miran Goodluck Jonathan, to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP naa rọ awọn oludije lati fọwọ wọnu ti esi idibo ba jade.
Eto idibo ti n lọ lọwọ bayii ni agọ idibo mẹrin ni ipinlẹ Plateau.
Eyi waye nitori bi wọn se sun ibo aarẹ ati tawọn asofin agba siwaju di oni ni agọ mẹrin naa.
Gẹgẹ bi Osaretin Imahireogbo, tii se olori ẹka to wa fun ilanilọyẹ awọn oludibo fun ajọ INEC se wi, bi awọn ohun eelo idibo se falẹ, ki wọn to ko wọn de awọn agọ idibo yii, lo sokunfa bi wọn se sun ibo siwaju ni awọn agọ idibo naa.



Agbẹnusọ ile iṣẹ ọlọpaa nilu Kano Abdullhi Haruna ti sọ fun BBC pe awọn n wa arakunrin kan ti wọn lo ji apoti ibo gbe ni ijọba ibilẹ Takai.
O ni awọn ni ireti wi pe ọwọ yoo tẹ ọdaran naa lọjọ aiku nitori pe awọn oludibo to wa ni agọ idibo to ti ji apoti gbe ni awọn mọ ọkunrin naa daada.
O tẹsiwaju pe lasiko ti oṣiṣẹ Inec fẹ gbe apoti ibo naa si inu ọkọ lo ja gba to si gbe salọ

Oríṣun àwòrán, Eniola Badmos


Awọn osisẹ eleto idibo to le ni igba n sun lọwọ ni ileesẹ ajọ INEC to wa nilu Ijẹbu-Jẹsa nigba tawọn janduku oloselu dojukọ wọn.
A gbọ pe ko si ọlọpa tabi agbofinro kankan larọwọto eyi to mu kawọn janduku oloselu ọhun ri aye pa itu ọwọ wọn.
Iroyin naa ni awọn agunbanirọ meji to tun jẹ osisẹ eleto idibo nibẹ, ni ọta ibọn ba.