Àjọ INEC kéde Muhammadu Buhari bíi ààrẹ fún sáà kejì

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan

  1. Agbofinro mu Galadima ni Abuja, Wọn ti mu Bala Galadima nilu Abuja

    Awọn agbofinro ti fi pakute ofin mu agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo ẹgbẹ oṣelu PDP, Buba Galadima nilu Abuja lọjọ Aiku.

    Ọkan lara mọlẹbi rẹ to ba BBC sọrọ sọ pe awọn oṣiṣẹ ajọ alaabo DSS lo mu u nile rẹ lọsan ọjọ naa lasiko to jade.

    Ṣaaju lọjọ Abamẹta ni agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo ibo fun Muhammadu Buhari, Festus Keyamo pe fun fifi panpẹ ofin mu Galadima, nitori pe ‘o kede oludije PDP gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori lasiko ti wọn ṣi n ṣe akojọpọ esi idibo lọwọ.

    Amọ ṣaa, ajọ DSS ko ti sọ nkankan lori ọrọ naa.

    Bakan naa ni ẹgbẹ oṣelu PDP ti n polongo fun itusilẹ rẹ.

    Buba Galadima wa lara awọn ọmọ ẹgbẹ to fi APC silẹ lati da igun kan ti wọn pe ni R-APC silẹ.

    Bala
    Àkọlé àwòrán, Wọn ti mu Bala Galadima nilu Abuja
  2. Akwa-Ibom tun ti ka ti ijọba ibilẹ Ibeno, Godswill Akpabio ati Udom Emmanuel lo n figa gbaga

    Wọọdu mẹsan

    APC: Buhari: 1011

    PDP: Atiku: 6373

    Apapọ: 7898

    Eyi ti wọn kọ̀: 413

    Omowe Lawrence Usit lo dari ẹ

    ibudo
    Àkọlé àwòrán, Omowe Lawrence Usit lo dari ẹ
  3. Ìpínlẹ̀ Kwara la wà báyìí!, Esi Idibo Aarẹ ni wọn ti n ka ni Kwara bayii

    Eyi lo maa fihan ẹni ti Kwara dibo yàn

  4. Akwa-Ibom ti n ka èsì ìdìbò aarẹ bayii, Ijọba ibilẹ Mbo àti Ibeno ti pari

    Ijọba ibilẹ Mbo - wọọdu mẹsan

    APC: Buhari 5299

    PDP Atiku: 4750

    Apapọ: 10218

    Eyi ti wọn kọ 271

    Ojogbon Effiong Etim Okon àti Asuquo Bassey

    ibudo
    Àkọlé àwòrán, Ijọba ibilẹ Mbo àti Ibeno ti pari
  5. Ipinlẹ Bayelsa ti n gbaradi lati ka awọn esi idibo, Atundi idibo a waye lawọn ibudo kọọkan ni Bayelsa

    Bayelsa ti n ka èsi lati mọ ẹni to maa dari Naijiria

    ibudo
    Àkọlé àwòrán, Atundi idibo a waye lawọn ibudo kọọkan ni Bayelsa
  6. Ipinlẹ Benue ti bẹrẹ si ni ka èsì ìdìbò aarẹ, Benue ti n ka èsi lati mọ ẹni to maa dari Naijiria

    Gbogbo oju wa lara awọn eleto idibo Benue bayii

    ibudo
    Àkọlé àwòrán, Benue ti n ka èsi lati mọ ẹni to maa dari Naijiria
  7. Esi ìdìbò Ibadan ti yoo fihàn bóya Ajimọbi n lọ Abuja tabi bẹẹkọ, Awọn eniyan ti n gbọ esi idibo ti ipinlẹ Oyo

    Ṣe Ajimọbi n lọ abuja tabi bẹẹkọ?

  8. Èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tó gbẹyin ti wọn n duro de lati mọ boya Mimiko yoo wọle tabi bẹẹkọ nipinlẹ Ondo, Wọn ti bẹrẹ bayii ipinlẹ Ondo lati ka esi kan to ku

  9. Wọn ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí ni ka èsì ìdìbò ni Ibadan, Esi idibo yii lo maa fihan boya Ajimọbi n lọ si Abuja padà abi bẹẹkọ

    Ohun gbogbo ti ṣetan bayii ni Ibadan, ẹ tẹti leko

    Oyo
    Àkọlé àwòrán, Esi idibo yii lo maa fihan boya Ajimọbi n lọ si Abuja padà abi bẹẹkọ
  10. INEC ti n ka èsì ìdìbò ìpinlẹ Kano, Ipinlẹ Kano lo ni odiwọn oludibo to pọ julọ ṣikeji si ipinlẹ Eko.

    Ijọba ibilẹ mẹrinlelogoji ni wọn ti dibo ni Kano ti wọn ti n ka lọ bayii.

    kano
    Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Kano lo ni odiwọn oludibo to pọ julọ ṣikeji si ipinlẹ Eko.
  11. Èsì ìdìbò Cross River ti n jáde fún ìdìbò àarẹ Naijiria, Esi Ijọba ibilẹ mejidinlogun ti jade ni Cross River

    Ijoba ibilẹ Akpabuyo to ni ibudo idibo 129.

    APC: Buhari: 4429

    PDP: Atiku: 7776

    SDP: Duke: 88

    Apapọ: 12,637

    Eyi ti wọn ko ka: 1001

    Ojogbon Maurice Asuquo

    alaga
    Àkọlé àwòrán, Esi Ijọba ibilẹ mejidinlogun ti jade ni Cross River
  12. Wo àwọn àwòrán ǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ káàkiri Nàìjíríà báyìí, Èrò àwọn èèyàn n ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó n ṣẹlẹ̀

    Awọn eniyan n retí èsì ìdìbò káàkiri

    Àkọlé fídíò, Èrò àwọn èèyàn n ṣọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ tó n ṣẹlẹ̀
  13. Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ti kéde àtúndì ìbò ní Abia, Bayelsa, Benue, Plataeu àti Zamfara, Bakan naa ni alaga ajọ eleto idibo gba pe lootọ ni awọn kudiẹkudiẹ kan waye lasiko ibo to kọja

    Alaga ajọ eleto idibo lorilẹede yii, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu ti kede faraye pe awọn agbegbe ti ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo ti kun, ni wọn yoo se atundi ibo nibẹ.

    Ọjọgbọn Yakubu kede bẹẹ lasiko ipade akọroyin to se niluAbuja nirọlẹ ọjọ Isinmi.

    Lara awọn ipinlẹ ti Yakubu mẹnuba pe atundi ibo yoo ti waye ni Abia, Bayelsa, Benue, Plateau ati Zamfara.

    Bakan naa ni alaga ajọ eleto idibo gba pe lootọ ni awọn kudiẹkudiẹ kan waye lasiko ibo to kọja nidi amulo awọn ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo, to fi mọ iwa idunkooko mọ ni, rogbodiyan ati jagidijagan.

    Nigba to n kede pe awọn janduku ẹda kan kọlu awọn agunbanirọ to n sisẹ eto idibo nipinlẹ Ọsun, Ọjọgbọn Mahmood koro oju si iru iwa ika yii , to si ni oun ti fi to awọn agbofinro leti.

    O salaye pe akoko ko tii to lati sọ bi awọn osisẹ agbofinro ti pegede si lasiko ibo aarẹ ati tawọn asofin to kọja yii, amọ agbeyẹwo isẹ wọn yoo di ẹyin ibo gomina ati tawọn asofin ipinlẹ.

    Alaga ajọ eleto idibo naa fikun pe akojọpọ esi idibo Ekiti ti pari, ti wọn si ti n gbe bọ ni Abuja, nigba ti wọn yoo bẹrẹ isẹ akojọpọ esi ibo ni olu ileesẹ ajọ eleto idibo ni Abuja to ba di aago mẹfa irọlẹ.

    Ọjọgbọn Mahmood ko sai salaye pe, irọ to jinna sootọ ni pe ajọ eleto idibo ti wọgile awọn eto idibo kan nilu Abuja, nitori ko si ibo kankan ti wọn wọgile nibẹ.

    yakubu
    Àkọlé àwòrán, Ọjọgbọn Yakubu kede bẹẹ lasiko ipade akọroyin to se niluAbuja nirọlẹ ọjọ Isinmi.
  14. Àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ń fara ya lórí pé èsì ìbò ń pẹ́, Awọn ènìyàn ìpinlẹ Ondo n kó ọkan sókè lórí èsì ètò idibo

    Wọn n reti èsì idibo ijọba ibilẹ Mimiko bayii

    Àkọlé fídíò, Election Update 2019: Àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ń fara ya lórí èsì ìbò ń pẹ́
  15. Àwọn èrò ìpínlẹ̀ Ondo n faraya pé èsì ìdìbò ẹkùn aarin gbùngbùn Ondo n pẹ́, Wọn ni awọn ṣi n duro de èsì ijọba ibilẹ iwọ oorun Ondo ti Mimiko n pẹ́ dé

    Wọn ni awọn ṣi n duro de èsì ijọba ibilẹ iwọ oorun Ondo ti Mimiko n pẹ́ dé

    ibudo
    Àkọlé àwòrán, Wọn ni awọn ṣi n duro de èsì ijọba ibilẹ iwọ oorun Ondo ti Mimiko n pẹ́ dé
  16. Èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ méjì ti wọle, o ku mẹ́rin ni Ogun, Aké Centenary Hall ni àwọn èrò ti n dúró de èsì ìbò aṣojuṣofin arin gbungbun Ogun

    Awọn eniyan Abẹokuta n duro de èsì ijọba ibilẹ mẹrin tó kù

    ibudo
    Àkọlé àwòrán, Awọn eniyan Abẹokuta n duro de èsì ijọba ibilẹ mẹrin tó kù
  17. APC àti PDP ló jọ n borí lórí ayélujára, INEC ni yóò pẹ̀tù sááwọ̀

    BBC ṣetán láti kéde ẹni tó ba jáwé olubori láì ṣegbe fẹnikan.

    oludije
    Àkọlé àwòrán, BBC ṣetán láti kéde ẹni tó ba jáwé olubori láì ṣegbe fẹnikan.
  18. Wọ́n ti kéde èsì ìdìbò ijọba ìbílẹ̀ mẹrin ni aarin gbungbun Ondo, Wọn n dúró de èsì Guusu Akurẹ àti Iwọ oorun Ondo

    Esi ijọba ibilẹ meji yii ni yoo fihàn bóyá Mimiko yóò wọlé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́

    olukabo
    Àkọlé àwòrán, Esi ijọba ibilẹ meji yii ni yoo fihàn bóyá Mimiko yóò wọlé tàbí bẹ́ẹ̀kọ́
  19. Wọ́n dá kíka ìdìbò ẹkùn Saraki dúró nitori àwọn aṣojú ẹgbẹ́ oṣelu kòìpé, Kwara n retì èsì ìbò tó kú

    Bayii, wọn ti kéde ti Àsà tán

    oludibo
    Àkọlé àwòrán, Bayii, wọn ti kéde ti Àsà tán
  20. Àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò n ṣe àtòjọ ìbò Ibadan, Wọn n réti bóyá Ajimọbi wọlé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́

    Àwọn ènìyàn Oyo ń wòye bó ṣe n lọ ni Ibadan

    oludibo
    Àkọlé àwòrán, Wọn n réti bóyá Ajimọbi wọlé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́