Esi ibo aarẹ ni Abia

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP
Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan


"Àyò mi, olówó orí mi, ìwúrí àti ìdùnnú ńlá lo ń jẹ fún mi lọjọkọjọ"
Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ látẹnu Toyin, ìyàwó Bukọla Saraki sí ọkọ rẹ̀ lẹ́yìn tó pàdánù ìdìbò sílé aṣòfin àgbà.

Oríṣun àwòrán, Toyin Saraki
Gomina Abiọla Ajimọbi to fidirẹmi ninu idibo sile aṣofin agba lẹkun idibo gusu ipinlẹ Ọyọ, ti ki oludije fẹgbẹ PDP, Kọla Balogun to bori ku oriire.
Ninu atẹjade kan ti amugbalẹgbẹ fun gomina Ajimọbi lori ọrọ ibanisọrọ, Bọlaji Tunji fi sita, Gomina Ajimọbi ni lootọ oun padanu ijoko aṣofin agba naa, sibẹ ijafafa ẹgbẹ oṣelu APC ninu awọn esi idibo yoku ko lee jẹ ki inu oun bajẹ.
Gomina Ajimọbi ni, oun tẹwọgba esi idibo naa, oun si tun ki gbogbo awọn oludije ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa to jawe olubori ku oriire.

Oríṣun àwòrán, Abiola Ajimọbi
Ẹgbẹ oṣelu alatako PDP ti sọ pe, ohun ko ni gba awọn esi idibo aarẹ ti ajọ eleto idibo INEC ti n kede rẹ.
Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọmọọba Uche Secondus ni awọn esi ibo ti ajọ INEC n kede ko tọna rara.Ọmọọba Secondus sọrọ yii nibi ipade awọn oniroyin to waye niluu Abuja lọjọ Aje.
Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ APC, Aarẹ Muhammadu Buhari lo yege nipinlẹ Ekiti, Oṣun, Kogi, Nasarawa ati Kwara gẹgẹ bi esi ti ajọ INEC kede.
Ṣugbọn Atiku Abubakar to jẹ oludije fẹgbẹ alako PDP lo jawe olubori lolu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

Oríṣun àwòrán, @OfficialPDPNig




Oludari ajọ eleto idibo nipinlẹ Akwa Ibom, Mike Igini ti kede pe oun ko ti fi esi ibo sile asofin agba lẹkun Ikot Ekpene sita rara.

Oludije gomina fun ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Eko, Jimi Agbaje, ti fi aake kọri pe oun ko ni tẹwọgba esi ibo ti wọn ti tọwọ bọ loju.
Agbaje ni wahala ati idunkoko mọni ẹgbẹ oselu APC ti pọ lapọju lawọn agbegbe ti ẹgbẹ PDP fidi mulẹ si bii Oshodi ati Ọjọ.
O ni ẹrọ to n yẹ kaadi idibo wo ko sisẹ daada lawn agbegbe kan eyi to lọwọ magomago ninu.

Oríṣun àwòrán, Jimi Agbaje

INEC kede pe ibo ẹkun idibo ila oorun ipinlẹ Kogi ko tii pari.
Alaye Inec ni pe rogbodiyan waye lasiko ibo naa, ti awọn ibo ti wọn ko gba wọle si pọ lapọju.
Amọ sa, akojọpọ esi ibo aarẹ ni ipinlẹ Kogi ti pari, ti wọn si ti n gbe lọ si Abuja.



Ẹkun idibo aarin gbungbun Adamawa.
Aishatu Dahiru Ahmed (Binani) APC - 188, 526
PDP - 96, 530
ADC - 36, 030
Aishatu Dahiru ni obinrin akọkọ ti yoo dibo wọle sile asofin agba lẹkun ariwa orilẹede yii ninu ibo ọdun 2019.

Olori ọmọ ẹgbẹ oselu to pọ julọ nile asofin tawọn asoju, Femi Gbajabiamila lo jawe olubori ninu ibo sile asoju sofin ni ẹkun idibo Surulere Kinni nipinlẹ Eko.
Gbajabiamila to n soju ẹgbẹ APC lo gbo ewuro si oju Michael Adewara ti ẹgbẹ oselu PDP.
Igba yii ni igba karun un ti Gbajabiamila a lọ

Oríṣun àwòrán, Femi Gbajabiamila