Àjọ INEC kéde Muhammadu Buhari bíi ààrẹ fún sáà kejì

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan

  1. Mimiko (ZLP) kò ni lọ ṣoju Ondo nilu Abuja, Ayọ Akinyelurẹ ni yoo ṣoju Ondo bí Mimiko ṣe padanu ni aarin gbungbun Ondo

    Gomina ana ti ipinlẹ Ondo, Ogbeni Iroko Mimiko ti padanu.

    Nigba ti Senetọ Ayọ Akinyelurẹ ti ẹgbẹ PDP jawe olubori ni aarin gbungbun Ondo

    inec
    Àkọlé àwòrán, Gomina ana ti ipinlẹ Ondo, Ogbeni Iroko Mimiko ti padanu.
    inec
    Àkọlé àwòrán, Gomina ana ti ipinlẹ Ondo, Ogbeni Iroko Mimiko ti padanu.
  2. Benue ṣi n reti èsi ijọba ibilẹ mẹrindinlogun sii, Ajọ INEC n reti èsì ijọba ibilẹ merindinlogun ni Benue

    Bẹẹ gbogbo ariyanjiyan awọn ẹgbẹ PDP ṣi n tẹsiwaju ni Benue

    inec
    Àkọlé àwòrán, Ajọ INEC n reti èsì ijọba ibilẹ merindinlogun ni Benue
  3. Cross River lọ sinmi di ọjọ Aje ki ikede èsì idibo to tẹsiwaju, Ajọ INEC pe fun isinmi ni Cross River ki wọn to kede esi ijọba ibilẹ mejila to ku

    Àwọn oṣiṣẹ INEc tó n kéde ìbò ni Cross River kógbá wọlé, wọn ni o di ọjọ ajé ki wọn to tẹsiwaju pẹ̀lú èsì ijọba ibilẹ mejila tó kù

    inec
    Àkọlé àwòrán, Ajọ INEC pe fun isinmi ni Cross River ki wọn to kede esi ijọba ibilẹ mejila to ku
  4. Èsì ìdìbò aarẹ tún jáde ni ìpínlẹ̀ Delta, Ijọba ibilẹ mẹta mii tun ti jáde nipinlẹ Delta

    Ijọba ibilẹ Aniochia

    APC: Buhari: 3674

    PDP:Atiku: 12996

    Gbogbo ibo: 17052

    Ibo ti wọn wọgile: 874

    Josephine Oby Nwachoka lo dari eto idibo naa.

    Ijọba Ibilẹ Patani

    APC: Buhari: 4789

    PDP: Atiku: 17028

    Gbogbo ibo: 22003

    Ibo ti wọn wọgile: 582

    Theophilus Ehime lo ṣoju INEC ninu ikede

    Ijọba Ibilẹ Ariwa Oshimili

    APC: Buhari: 1960

    PDP: Atiku: 19700

    Gbogbo ibo: 24933

    Ibo ti wọn wọgile: 2941

    Omowe Joan Eze lo dari eto idibo naa

    inec
    Àkọlé àwòrán, Ijọba ibilẹ mẹta mii tun ti jáde nipinlẹ Delta
  5. Wọn ti n ka èsì ìdìbò ti yoo fihan bóyá Mimiko lo maa lọ Abuja, Esi idibo yii lo maa jẹ ki a mọ ẹni ti yoo sọju ẹkun aarin gbungbun Ondo

    Esi idibo yii ni wọn ti n duro de lataarọ nipinlẹ Ondo.

    Ohun ni yoo foju ẹni to n lọ ṣoju aarin gbungbun Ondo nilu Abuja hande

  6. Wọn ti n ka èsì ètò idibo nipinlẹ̀ Anambra, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo tan iná ti èsì idibo nipinlẹ Anambra

    Gbogbo awọn ero fẹ mọ ẹni ti yoo jawe olubori ninu idibo ọhun

    inec
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ eleto idibo tan iná ti èsì idibo nipinlẹ Anambra
  7. BBC Yoruba ti wa nibudo ikede ti ipinlẹ Eko, Gbogbo bo ṣe n lọ nipinlẹ Eko ni yii

    Ipinlẹ eko lo ni odiwọn kaadi oludibo to pọ ju ninu idibo Naijiria tọdun 2019

  8. INEC ṣetán lati kéde Oloriẹgbẹ to n lọ ṣoju aarin gbungbun Kwara l'Abuja, Saraki kò nile ṣoju awọn èèyan Kwara mọ

    Oju tuntun yoo rọpo Bukọla Saraki ni Abuja

  9. Saraki kò ṣe ǹkankan si Kwara- Adedoyin (Accord), Ayọ Adedoyin ṣalaye fun BBC pé Kwara ko mọ ipa pé olori ile aṣofin agba Abuja jẹ ọmọ Kwara

    Oludije fun ipo gomina ni Kwara labẹ ẹgbẹ oṣelu Accord Party ni awọn eniyan Kwara kò mọ ipa Saraki lara wọn

  10. Ibrahim Oloriẹgbẹ ni yoo rọpo Bukọla Saraki ni Abuja, Saraki kò lè padà sí Abuja mọ; Oloríẹgbẹ́ ló n lọ ṣoju aarin gbungbun Kwara

    Ajọ INEC ti kede esi idibo fun ipo aṣojuṣofin ni aarin gbungbun Kwara

    PDP: Saraki Bukóla: 30075

    APC: Ibrahim Oloriẹgbẹ: 51531

    saraki
    Àkọlé àwòrán, Saraki kò lè padà sí Abuja mọ; Oloríẹgbẹ́ ló n lọ ṣoju aarin gbungbun Kwara
    saraki

    Oríṣun àwòrán, others

    Àkọlé àwòrán, Saraki kò lè padà sí Abuja mọ; Oloríẹgbẹ́ ló n lọ ṣoju aarin gbungbun Kwara
    saraki

    Oríṣun àwòrán, others

    Àkọlé àwòrán, Saraki kò lè padà sí Abuja mọ; Oloríẹgbẹ́ ló n lọ ṣoju aarin gbungbun Kwara
  11. Ibi ti wọn ti maa kede esi idibo ipinlẹ Edo niyii, Ipinlẹ Edo ti pese ohun gbogbo silẹ de ikede

    Ipinlẹ Edo ti palẹmọ tan lati bẹrẹ ikede ti esi ba ti wọle tan

    edo
    Àkọlé àwòrán, Ipinlẹ Edo ti pese ohun gbogbo silẹ de ikede
  12. Gbọngan yii ni ohun gbogbo yoo ti dópin ni Asaba, nipinlẹ Delta, Ibi yii ni wọn a ti kede nipinlẹ Delta

    Ohun gbogbo ti sẹtan nibudo ikede Delta nilu Asaba

    asaba
    Àkọlé àwòrán, Ohun gbogbo ti sẹtan nibudo ikede Delta nilu Asaba
  13. Eto ti bẹ̀rẹ̀ nibudo ikéde ni ipinlẹ̀ Rivers, Ohun gbogbo ti setán nipinlẹ Rivers

    Ki àwọn eniyan maa reti èsì idibo ipinlẹ Rivers lo ku

    inec
    Àkọlé àwòrán, Ohun gbogbo ti setán nipinlẹ Rivers
  14. INEC ti n kéde èsì ìdìbò tó gbéyin ni aarin gbungbun Kwara, Sé Saraki yóò lọ Abuja tabi kò ni padà?

    Esi ti INEC n ka lọwọ yii lo maa jẹ ki gbogbo eniyan mọ boya Saraki a pada si Abuja tabi bẹẹkọ

  15. INEC: Wọn pa òṣiṣẹ ajọ elétò ìdìbò ni Rivers ati Ọṣun, INEC nikan ló lè kéde èsì ìdìbò tootọ

    Ojọgbọn Mahmood Yakubu to n tukọ ajọ eleto idibo Naijiria , INEC ti ni wọn yoo ṣe atundi ibo nipinlẹ Abia, Bayelsa, Benue, Sokoto, Zamfara, Imo, Eko, Plateau, FCT Abuja, ati Rivers ni awọn agbegbe ti ẹ\ro to n ka kaadi ko ti ṣiṣẹ bi o ti yẹ

    inec
    Àkọlé àwòrán, INEC: a kó ni pẹ́ kéde èsì ìdìbò bi o ba ṣe n wọle lọla
  16. Ortom: Mo n wa aṣoju PDP ni Benue lati ana!, O ni aarọ Satide ni awọn agbofinro wa gbee nile rẹ ni Benue

    Gomina Samuel Ortom ti Benue ṣalaye fun BBC pe lati ana loun ti n wa Omowe Cletus Tyoka to jẹ aṣoju ẹgbẹ PDP niìnlẹ Benue.

    O ni lana ni awọn agbofinro wa mu u nile rẹ pẹlu ẹsun pe o kó àwọn janduku jọ ti wọn si di eto idibo lọwọ ni Benue.

    ortom
    Àkọlé àwòrán, Ijọba Benue n wa Omowe Cletus Tyoka to jẹ aṣoju ẹgbẹ PDP niìnlẹ Benue.
  17. INEC Abuja: Eré gbogbo di aago mọ́kànlá ọ̀la, ọjọ́ Ajé, Ojọgbọn Mahmood Yakubu, ti ni ọla loun maa bẹrẹ sini kede èsì apapọ

    Gbongan nla International Conference Center ni Garki nilu Abuja, (ICC) ni gbogbo eto ti to.

    Ojọgbọn Mahmood Yakubu ni oun yoo bẹrẹ si ni kede èsì idibo apapọ laago mọkanla aarọ ọla, ọjọ Aje

    icc

    Oríṣun àwòrán, b

    Àkọlé àwòrán, Ojọgbọn Mahmood Yakubu ni oun yoo bẹrẹ si ni kede èsì idibo apapọ laago mọkanla aarọ ọla, ọjọ Aje
  18. Oko ni Buhari ti lo òní bó ṣe n retí èsì ìdìbò aarẹ, Lẹyin idibo, Buhari lọ si oko rẹ ni Daura

    Aarẹ Buhari lọ si oko rẹ

  19. Gomina Benue bínú lọ sọ́dọ̀ INEC, Samuel Ortom ni wọn ti ji apoti ibo Gboko gbe

    David Mark ati Gomina Ortom atawọn eekan ninu ẹgbẹ PDP mii ti binu lọ si ile ajọ INEC ni Makurdi.

    Wọn ni awọn ọmọ ogun kan lo ṣa dede ja esi idibo ẹkun Gboko gba ti wọn gbee lọ

    benue
    Àkọlé àwòrán, Wọn ni awọn ọmọ ogun kan lo ṣa dede ja esi idibo ẹkun Gboko gba ti wọn gbee lọ
  20. A tún ti pada si Kwara fún kika èsì ìdìbò Senetọ, Gbogbo bi wọn ṣe n kaa ni yii

    Kwara n kede èsì ìdìbò síi