Ohun gbogbo ti ṣetán ni ibùdó ìkéde ní ìjọba ìbílẹ̀ Aríwá Ibadan, Wọn n réti bóyá Ajimọbi wọlé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́
Wọn n réti bóyá Ajimọbi wọlé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́

Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP
Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan
Wọn n réti bóyá Ajimọbi wọlé tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́

Ajọ to n se akoso awọn ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ lorileede Naijiria NBC ti tun ranwa leti nipa kikede esi ibo.
Ọrọ yi ṣe koko pẹlu bi iroyin ofege ti ṣe gbode lasiko ibo gbogbogbo Naijiria yi.

Esi ijọba ibilẹ mẹta lo n da ikede boya Sẹnẹtọ Bukola Saraki yoo wole tabi ko ni wole duro.
Awọn ijọba ibilẹ mẹta naa ni Ilorin East, Ilorin South ati Ilorin West.
Laaye ibi ti ikede esi ibo ti n lọ lọwọ,akọroyin wa Yemisi Oyedepo jabọ pe awọn aṣoju ẹgbẹ ati oṣiṣẹ Inec to dari ibo naa ko si ni ikalẹ
Esi ibo ti ijọba ibilẹ Asa nikan ni wọn yi ti kede.

Wọn ní àwọn fẹ́ gbọ bóyá Mimiko n wọlé padà ni ẹkùn Ondo

APC: 77, 621
PDP: 53,741

Ajọ Inec ti bẹrẹ si ni kede Esi ibo aarin gbungbun Kwara fun ipo asoju ile asofin agba .
Ijọba ibilẹ akọkọ ti wọn ti ka esi rẹ fun awọn ẹgbẹ oṣelu meji to n lewaju ni
Ijọba ibilẹ Asa
Apapọ ibo 28,815.
APC - 15,932 PDP - 11,252

Ipinlẹ Ogun n wòye de èsì ìdìbò

Ohun gbogbo ti to sílẹ̀ ni Abeokuta báyìí



Àwọn jàǹdùkú yabo ibudo idibo ni Ọkọta nipinlẹ Eko



Ijọba ibilẹ kan pere ninu mẹrinlelọgoji ni o ti fi esi ibowọn ranṣẹ́ si wa.
Igbe ti alukoro ajọ eleto Inec nipinlẹ Kano n pa re.
Garba Lawal ni ''bi a ti ṣe n ba yin ṣọrọ yi, ijọba ibilẹ maarun un wa lọna nibi ti wọn ni awọn ṣi n gbe ibo naa bọ.Nilẹ oni to mọ yi,ijọba ibilẹ kan pere ni a yi ri''



Ni ipinlẹ Benue, awọn osisẹ ajọ eleto idibo ti n da awọn ohun eelo idibo pada si olu ileesẹ ajọ Inec ni Makurdi
Idibo ti n tẹsiwaju ni ijọba ibilẹ ariwa Umuahia lawọn agọ idibo ti ko laanfaani ati dibo lana.
Oniroyin wa Ikechukwu Kalu jabọ pe ni wọọdu 3 U22 ati U21 idibo ti n lọ ni irọwọrọsẹ.




Ikọ iroyin BBC se alabapade awọn eeyan kan to n fi iyan tura lẹyin ti wọn di ibo wọn tan nilu Ekiti.
Mama oniyan naa, to n ri taje se lasiko ibo, ni awọn eeyan n ya wọ isọ rẹ lati mu iyan jẹ.
Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu ANN, Fela Durotoye ti bẹnu atẹ lu iroyin bi awọn eeyan ti n padanu ẹmi wọn ti awọn kan si nṣeeṣe ninu eto idibo aarẹ ati tile aṣofin agba kaakiri orilẹede Naijiria.
Durotoye ni ọpọ idile ni wọn ti wa ninu ibanujẹ bayiii nitori pe awọn eeyan wọn dibo ti wọn ko si pada wale.
O ni ninu irora ni iru awọn idilẹ bẹẹ wa bayii.

Oríṣun àwòrán, Fela Durotoye

