Okorocha bori ibo sile aṣofin agba
Gómìnà Rochas Okorocha ti ìpínlẹ̀ Imo ni yóò máa ṣoju ẹkùn ìdìbò rẹ̀ nílé aṣòfin àgbà báyìí.
Okorocha APC = 97, 762
Jones Onyereri PDP = 63, 117
Osita Izunaso APGA = 30, 932

Oríṣun àwòrán, Rochas Okorocha
Alága àjọ INEC, ọ̀jọ̀gbọ́n Mahmood yakubu ní Buhari ti APC borí Atiku Abubakar ti PDP
Adedayo Owolabi and Olubusola Afolayan
Gómìnà Rochas Okorocha ti ìpínlẹ̀ Imo ni yóò máa ṣoju ẹkùn ìdìbò rẹ̀ nílé aṣòfin àgbà báyìí.
Okorocha APC = 97, 762
Jones Onyereri PDP = 63, 117
Osita Izunaso APGA = 30, 932

Oríṣun àwòrán, Rochas Okorocha

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Abiola Ajimọbi ti fidi rẹmi ninu ibo sile asofin agba lẹkun idibo Guusu Ọyọ.
Ọmọwe Kọla Balogun tẹgbẹ oselu PDP lo gbo ewuro soju Gomina Ajimọbi.
PDP: 105,716
APC: 92, 218

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Oloriegbe
Odu ni akọṣẹmọṣe oniṣegun oyinbo Ibrahim Oloriegbe, ti o si ti n gbiyanju lati di asoju agba lọjọ to ti pẹ ni Kwara.
Awọn mejeeji ti kọkọ koju ara wọn lọdun 2011 nigba ti Saraki bẹrẹ irinajo rẹ gẹgẹ bi asofin agba. Aburo Bukola Saraki, Sẹnẹto Gbemi Saraki lo ṣẹṣẹ pari saa rẹ gẹgẹ bi Senẹtọ ti awọn mejeeji sijọ du ipo naa.
Labẹ asia ẹgbẹ ACN ni Oloriẹgbẹ́ ti dupo amọ Saraki to wa ni PDP nigba naa fẹyin rẹ janlẹ.
Laarin ọdun 1999 si 2003, Ibrahim Oloriegbe jẹ olori awọn ọmọ ẹgbẹ to pọju lọ nile asofin ipinlẹ Kwara.
O tun joye alaga igbimọ ile to n mojuto ọrọ ilera ati eyi to n ri si ọrọ ijọba ibilẹ.
Lẹyin to pari nile asofin ko ti di ipo oṣelu kankan mu mọ lati igba naa.
Oludije fun ipo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party, YPP, Kingsley Moghalu ti dupẹ lọwọ gbogbo awọn toṣatilẹyin fun ipinnu rẹ lati dupo aarẹ orilẹede Naijiria.
Bakan naa lo ba awọn mọlẹbi to padanu eeyan wọn nitori awọn rogbodiyan oṣelu to waye.
Ẹwẹ, o ba awọn agunbanirọ kẹdun fun ‘awọn nkan ti ko tọ ọ ti oju wọn ri lasiko ti wọn nṣiṣẹ amojuto idibo.
O le ni ibo ẹgbẹrun lọna mọkanlelogun ti ajọ INEC wọgile ladugbo Surulere nikan nipinlẹ Eko.
Nigba to n ka esi ibo aarẹ ti wọn di lọjọ Satide nijọba ibilẹ Surulere, asoju ajọ Inec to se akoso ibo nibẹ salaye pe, rogbodiyan to waye ati bi wọn se n ji apoti ibo gbe, lo jẹ ki iye ibo ti wọn wọgile fi pọ to bẹẹ.
Lẹyin o rẹyin, ni wọn kede ibo aarẹ lati mọ iye ibo ti Atiku Abubakar tẹgbẹ oselu PDP ati Muhammadu Buhari ti ẹgbẹ APC ni.
PDP: 31,603
APC: 30,621
Ibo ti wọn gba wọle: 65784
Ibo ti wọn danu: 4904
Apapọ iye ibo ti wọn di: 70688

Shina Peller , tii se gbajugbaja amuludun kan nilu Eko, ti wọle sile asoju-sofin lẹkun idibo Isẹyin/Itẹsiwaju/Iwajọ̀wa nipinlẹ Ọyọ.
Sina Peller si lo fi ẹyin Najeemdeen Oyedeji tẹgbẹ oselu PDP janlẹ ninu ibo naa.
APC: 44,088
PDP: 31,336
ADC: 12,309

Oríṣun àwòrán, Sina Peller
Oludije fun ipo sẹnetọ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Teslim Fọlarin ti jawe olubori lati ṣoju ẹkùn idibo aarin gbungbun Ọyọ nile aṣofin agba Naijiria.
Fọlarin bori ni ijọba ibilẹ mẹfa ninu mọkanla to wa ni ẹkun idibo naa.
Fọlarin to ti fi igba kan jẹ sẹnetọ, ni ibo ẹgbẹrun mọkanlelaadọrun le ọgọrin, nigba ti alatako rẹ gbooki, Oyebisi Ilaka ti ẹgbẹ oṣelu PDP ni iboẹgbẹrun mẹtalelọgọrin ati ẹgbẹta.
APC: 91,080
PDP: 83,600


Oríṣun àwòrán, Abdulfatai Buhari
Sẹnetọ́ to n soju ẹkun idibo ariwa ipinlẹ Ọyọ, (Oyo North), Abdulfatai Buhari ti moke ninu ibo sile asofin agba fun igba keji .
Buhari, to n soju ẹgbẹ oselu APC lo fagba han Mulikat Adeọla Akande latinu ẹgbẹ oselu PDP.
Bi ibo naa se lọ ree:
APC:107,703
PDP:89,365.
Asofin to n soju ẹkun idibo Kogi, Sẹnetọ Dino Melaye tun ti jawe olubori lati pada sile asofin agba.
Melaye to n soju ẹkun idibo Iwọ oorun Kogi, latinu ẹgbẹ oselu PDP, lo fi ẹyin alatako rẹ latinu ẹgbẹ oselu APC, Smart Adeyẹmi janlẹ ninu ibo naa.
Bi ibo naa se lọ ree:
APC: 76,902
PDP: 85,395

Oríṣun àwòrán, Dino Melaye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gomina tẹlẹ ni ipinlẹ Abia, Orji Uzor Kalu ti jawe olubori ninu ibo sile asofin agba nipinlẹ Abia.
Kalu, to n dije labẹ ẹgbẹ oselu APC fun ẹkun idibo ariwa ipinlẹ́ Abia, (Abia North) lo fi ẹyin alatako rẹ gboogi, Mao Ohuabunwa janlẹ.
Bi ibo naa se lọ ree:
APC: 30,580
PDP: 21,940

Ajibọla ni agbẹjọrọ agba fun ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ nigba ti Olaoluwa jẹ alaga ẹgbẹ oṣelu People's Democratic Party fun ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ.
PDP: Olaoluwa: 106 779
APC: Ajibola: 132 821


Ibrahim Dankwabo: PDP: 88016
Saidu Akali: APC: 152 546

Oríṣun àwòrán, @Ibrahim
Amosun Ibikunle ni o n pada si ile igbimọ aṣojuṣofin agba ni abuja lẹyin ọdun mẹjọ to fi ṣe gomina ipinlẹ Ogun
APC: Amosun: 88110
ADC: Titi Oseni: 37101
Ojogbon Ayinde Idris Akanbi lo dari eto idibo

Oríṣun àwòrán, @Amosun

Oríṣun àwòrán, @Amosun
Awọn ajọ eleto idibo, awọn Onwoye idibo, awọn agbofinro ati awọn akọroyin lai yọ awọn aṣoju ẹgbẹ oṣelu kọọkan ṣi n ba iṣẹ lọ ni Makurdi to jẹ olu ilu Benue

Ìpínlẹ̀ Ogun la kalẹ̀ sí báyìí, níbi tí wọ́n ti ń kéde èsì ìbò ẹkùn ìdìbò Ogun Central, èyí tí Gómìnà Ibikunle Amosun jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Olùdíjé.
Wọn sun ikede naa siwaju ki won le ri awọn esi to ku gba sii.

Wọn n wa aṣoju ajọ eleto idibo nipinlẹ Rivers.
Glen Ukomadu lo ṣoju INEC nijọba ibilẹ Asari Tori ni wọn ko ri mọ ni kete ti wọn ko lọ ṣatunse si esi to gbe wa.
Awọn Esi to ti jade
Ijoba ibilẹ Omuma:
APC: Buhari: 2494
PDP: Atiku: 15322
Ijoba ibilẹ Ogba-Egbema-Ndoni One
APC:Buhari: 10996
PDP: Atiku: 28536
Ijọba ibilẹ Eleme
APC:Buhari: 2412
PDP: Atiku: 8464
Wọn ti wọgile idibo ibudo idibo mẹwaa ni wọọdu kesan an ati ni ibudo idibo merindinlogun ni wọọdu mii ni Rivers.
