Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìgbéyàwó yìí kìí ṣe tuntun, òkè òkun ni Olorì Akinmuda wà àmọ́ àṣà ìbílẹ̀ táà fẹ́ ṣe l'Áàfin rèé - Agbẹnusọ Ooni

  2. Àsírí tú! àwọn obìnrin kan ń yá bàbá ayédèrú fún oyún inú wọn láti lè gba ìwé ìgbé-ìlú ní UK

    Aworan

    Iwadii ti ileeṣẹ BBC se ti fihan pe awọn obinrin kan n ya baba alawọ funfun fun oyun inu wọn lati le gba iwe igbelu ni UK.

    Awọn obinrin wọnyii ni wọn jẹ arinrinajo wa si Ilẹ Gẹẹsi, ti wọn kii se ọmọ bibi ilẹ naa.

    Iwadii naa fihan pe awọn obinrin wọnyii ma n san owo to le ni Poun ẹgbẹrun lọna mẹwaa (£10,000) fun awọn baba ayederu kii ọmọ wọn le jẹ ọmọ bibi Ilẹ Gẹẹsi.

    Ohun ti wọn n se ni ki baba naa yọju lati fi orukọ rẹ si orukọ sabuke iwe ibi( Birth Certificate) ọmọ naa lati jẹ ọmọ onilu, ki iya si gba iwe igbelu pẹlu.

    Wọn tilẹ ni awọn ayederu ọkunrin yii tilẹ n lo oju ẹro ayelujara to fi mọ oju opo ibaraẹnidọrẹ Facebook lati fi tan awọn obinrin miran.

    Wọn ni ikede wọn lori Facebook ni pe , awọn setan lati ran ẹgbẹgbẹrun obinrin lọwọ lati di ọmọ Ilẹ Gẹẹsi.

    Amọ awọn alṣẹ oju opo Facebook ni iru ikede bayii lodi si ofin to de lilo oju opo naa.

    Iwadii BBC naa tun safihan awọn ti wọn n fi pipese ayederu baba yii ṣisẹ ni UK, ti wọn pe ni agent.

    Aworan

    Oniwadii naa ni ọkan ninu awọn onisowo yii to pe orukọ ara rẹ ni Thai ni awọn ko nilẹ nilo Facebook lati polongo ara wọn, o ni ọgbọn ti wọn ma n lo lati fi se ise ayederu yii.

    Laiko ti wọn pade, O mu pade ọmọ ilẹ Gẹẹsi to n jẹ Andrew to si fi iwe igbelu rẹ han an gẹgẹ bi ọmọ bibi ilẹ Gẹẹsi.

    Amọ ileeṣẹ iroyin BBC ko san owo kankan fun ayederu ọkunrin naa, amọ ti wọn ni ọpọlọpọ iru eniyan naa w ani ikawọ wọn ti awọn ti ranlọwọ.

    Ni Ilẹ Gẹẹsi, ohun to lodi si ofin ni lati lo ayederu baba fun ọmọ inu tabi awọn ọmọ miran ti wọn bi abi ti wọn ko bi si Ilẹ Gẹẹsi.

    Agbẹjoro to ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ naa , Harjap Bhangai ni ki ileesẹ to n risi ọrọ igbelu, Home Office ni lẹ Gẹẹsi gbọdọ sewadii finifini ki wọn to fun ẹnikẹni ni iwe igbelu ni UK.

    O ni ọmọ ti wọn ba bi, ti ọkan ninu awọn obi naa kii se ọmọ Ilẹ Gẹẹsi, wọn gbọdọ se ayẹwo ẹjẹ fun wọn lati mọ boya lootọ awọn ni wọn ni ọmọ.

    Ni Ilẹ Gẹẹsi, ko pọn dandan ki wọn se ayẹwo ẹjẹ ki wọn to fun ọmọ ni Sabuke ibi, (Birth certificate) rẹ.

  3. ''INEC kò tíì sanwó iṣẹ́ tí a se lásìkò ìdìbò sípò ààrẹ àti ti gómìnà ní Naijiria''

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Lara awọn oṣiṣẹ ti Ajọ INEC gba lati ba wọn sisẹ lasiko idibo sipo aarẹ ati ti gomina lorilẹede Naijiria ti ni awọn ko I tii gba owo iṣẹ wọn titi ti asiko yii.

    Awọn osisẹ naa to ba BBC sọrọ ni kaakiri orilẹede Naijiria ni awọn osisẹ INEC lasiko idibo ti wọn ko I tii gba owo isẹ wọn wa.

    Ni Osu Keji ati Osu Kẹta, ọdun 2023 ni idibo sipo aarẹ orilẹede Naijiria ati ti awọn gomina ni Naijiria waye ni ọ̀un 2023.

    Lara awọn osisẹ to wa lati ipinlẹ Kano ni o kere tan awọn oṣisẹ ọgọrin to sisẹ lasiko idibo naa ni ko I tii gba owo iṣẹ wọn.

    Wọn ni lara awọn osisẹ to gbiyanju lati mọ oun to n ṣẹlẹ ni wọn sọ fun pe awọn ti nọmba Banki wọn ba bẹrẹ lati ‘0’ ni wọn ko I tii ri owo wọn gba.

    Amọ awọn osisẹ yii ni lara awọn to ni iru nọnba banki yii ti gba owo iṣẹ ti wọn se lasiko eto idibo naa.

    Ninu esi rẹ, adari ajọ INEC ni ilu Kano, Ambassador Abdul Zango ni iwọnba eniyan perete ni wọn ko I tii ri owo wọn gba.

    O ni idi ni pe awọn miran fi nọnba banki mọlẹbi wọn silẹ gẹgẹ bi ibi ti wọn fẹ ki ijọba san owo si.

    Amọ adari Ajọ INEC naa ni ko ni seese nitori wẹrẹ ti wọn ba ti ri pe orukọ wọn ati orukọ to wa lori apo isuna wọn ni banki ko jọra wọn, ni wọn ko ni san owo sibẹ.

    Bakan naa ni Ajọ INEC ni wọn tig be igbimọ kalẹ lati sewadii awọn ti wọn ko I tii san owo wọn yii.

    Nibayii, Ajọ INEC ti kesi ẹnikẹni ti ko ba tii gba owo isẹ to se lasiko idibo naa lati lọ si olu ileeṣẹ INEC to w ani ipinlẹ wọn lati fi orukọ wọn silẹ.

  4. Tinubu se ipàdé idákọ́ńkọ́ pẹ̀lú Rabiu Kwankwaso ni Paris

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Aarẹ ti wọn ṣẹsẹ dibo yan ni Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti sepade pẹlu oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oselu NNPP, Rabiu Kwankwaso ni ilu Paris, ni orilẹede Faranse.

    Iroyin ni awọn mejeeji ni wọn lo ọpọlọpọ wakati lasiko ijiroro wọn ni Paris.

    Osojumikoro ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ fun BBC pe lootọ ni ipade naa waye ni orilẹede Faranse.

    Kwankwaso to jẹ gomina ipinlẹ Kano tẹlẹri, lo gbe ipo kẹrin ninu idibo sipo aarẹ ti ọdun 2023, to si ni idibo to le ni miliọnu kan.

    Bio tilẹ jẹpe ko si iroyin pupọ nipa ipade naa, igbagbọ awọn eniyan ni pe yoo niise pẹlu ijọba tuntun ti wọn yoo burawọle fun ninu osu yii.

    Bola Tinubu to jẹ gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ ri ni awọn eniyan ri gẹgẹ bi onimọ nipa eto oselu, amọ ko I tii fi to awọn eniyan leti bi isejọba rẹ yoo seri.

    Bakan naa ni gbogbo eto n lọ lọwọ fun iburawọle aarẹ ti wọn dibo yan naa ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023.

    Ọjọ Kẹwaa, Osu Karun un ni aarẹ ti wọn dibo yan naa fi lede pe oun lọ si ilẹ Yuroopu fun abẹwo gẹgẹ bi osisẹ ijọba.

  5. Russia ju àdó olóró 18 sí Kyiv tó jẹ́ olú-ìlú orílẹ̀èdè Ukraine

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, State Emergency Service of Ukraine

    Orilẹede Ukraine ni Russia ti ju ado oloro to le ni mejidinlogun si olu ilu orilẹede Ukraine, Kyiv.

    Eyi wa lara igbiyanju orilẹede Russia lati sekọlu si Kyiv ninu ogun to n lọ lọwọ laaarin orilẹede Russia ati Ukraine.

    Ninu esi wọn si ado oloro naa, Ukraine ni gbogbo ado oloro mejidinlogun ti Russia ju si Kyiv ni awọn sọ di ofo nipa lilo ohun ijagun to n gbogun ti ado oloro ni ofurufu, iyẹn ‘’defence missile’’.

    Amọ Russia ni gbogbo ibi ti awọn fẹ ki ado oloro wọn de patapata ni awọn ti ju ado oloro naa si.

    Igba akọkọ kọ niyii ti Moscow n gbiyanju lati lo ikọ ọmọogun ofurufu lati doju ija kọ Ukraine.

    Agogo pajawiri naa ni wọn lo dun ni aagomọkanla-aabo ni ooru Ọjọ Aje, ti awọn eniyan si sa asala fun ẹmi wọn, amọ ti wọn gbe ago pajawiri naa kuro ni lẹyin wakati meji.

    Igba kẹjọ ninu ninu osu karun un, ọdun 2023 ti orilẹede Russia yoo ma ju ado oloro si olu ilu Ukraine, iyẹn Kyiv.

    Awọn araalu ni wọn bẹrẹ si ni gbọ iro ibugbamu ni aarin gbungun ilu naa, ti awọn alasẹ si sọ fun awọn eniyan wi pe awọn ti bẹrẹ lilo ohun ija ti yoo gbogun ti ado oloro naa.

    Ileeṣẹ Ologun ni Ukraine ni gbogbo iha Guusu, ariwa, iwọ oorun ati ila ibẹ ni Russia ti sekọlu si wọn ni igba mejidinlogun.

    Wọn ni kiakia ti wọn ri awọn ado oloro ti Russia ju naa ni wọn sọ ado oloro naa di alailagbara.

  6. Ilé ẹjọ́ dájọ́ ikú fáwọn mẹ́ta fẹ́sùn wí pé wọ́n jí fóònù, bàtà ní Ekiti

  7. Serikin Hausa sọ̀rọ̀ gbá orí àwọn Hausa oníṣòwò bí wọ́n ṣe kọlu ikọ̀ Amotekun ní Ekiti

  8. Aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàrín Fulani àti àwọn ọmọ ìlú Iganna n'ípinlẹ̀ Oyo, òkú sùn!

  9. Ó kéré tán ènìyàn 40,000 ló n kú ní ìjaḿbá ní ọdọọdún ní Naijiria - FRSC

    Ajọ to n risi eto irina ni Naijiria, FRSC ti o keere tan eniyan ẹgbẹrun lọna ogoji lo n ku ninu ijamba ọkọ loju popo ni ọdọọdun ni Niajiria.

    Adari ajọ FRSC naa, Dauda Biu lo sọ bẹẹ ni ilu Abuja lati se ayẹyẹ Ọdun keje ti ajọ iṣokan agbaye, UN gbe eto kalẹ lati da abo bo awọn araalu ni oju popo, ti wọn pe ni United Nations Global Safety week.

    Biu ni awọn akọsilẹ bi awọn eniyan se n ku loju popo naa banilẹru pupọ.

    Bakan naa lo ni awọn ti ko ku ninu iṣẹlẹ ijamba ọkọ nigba miran ma n di alaabọ ara ki wọn to di agbalagba nipasẹ ijamba ọkọ.

    Ninu ọrọ rẹ, o ni ijamba ọkọ lo mu ẹmi awọn eniyan ti iye ọjọ ori wọn w ani aarin ọ̀un marun un si ọdun mọkandinlọgbọn julọ ni Naijiria.

    Ọga Agba Ajọ FRSC naa ni oun to bani ninu jẹ julọ ni pe o seese lati da ọwọ ibi yii duro, ti awọn eniyan ba tẹle ofin irina loju popo.

    O ni o se koko ki awọn eniyan tẹlẹ ofin oju popo , ki wọn bọwọ fun awọn ilana lati da abo bo wọn loju popo, ki wọn si ri pe ọkọ wọn w ani ibamu pẹlu eto irinna ni Naijiria.

    Ajọ FRSC naa wa kesi ijọba lati pese oju ọna to dara fun awọn eniyan ni oju pop, ki wọn si ri pe eto pajawiri to muna doko w ani pẹsẹ fun awọn eniyan ti ijamba ọkọ ba ṣẹlẹ si ni oju popo.

  10. ‘’Ẹnikẹ́ni tó bá gbìyànjú láti da ìbúrawọlé ru, A ó mu balẹ̀’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Ileeṣẹ Ologun ni Naijiria ati Ọga Agba Ọlọpaa, Usban Baba tun ti fi ikilọ lede fun ẹnikẹni to ba n gbiyanju lati da eto iburawọle ru ni Naijiria.

    Usman Baba ka iwe ijiya’’ Riot Act’’ ọhun ni ilu Abuja fun gbogbo awọn to n gbe igbesẹ lati da iburawọle ru.

    Adari ẹka eto iroyin ni ileeṣẹ Ologun ni Naijiria, Ọgagun Tukur Gusau lo tun fi ikilọ ọhun lede fun awọn araalu.

    O ni ileeṣẹ Ologun Naijiria n kilọ fun wọn nitori dida eto iburawọle naa ru, tumọ si didoju eto ijọba tiwantiwa bolẹ ni Naijiria.

    Ileesẹ naa ni awọn yoo sa gbogbo ipa wọn lati ri pe eto ijọba tiwantiwa ko dẹnukọlẹ ni Naijiria, ti wọn si kilọ fun awọn araalu.

    Ninu ọrọ tirẹ, Ọga Agba Ọlọpaa ni awọn yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn oṣiṣẹ eleto aabo to ku ni Naijiria lati jẹki eto aabo to muna doko w ani Naijiria.

    Bakan naa ni Ọga ọlọpaa ni awọn setan lati fi ọwọ ṣinkun ofin mu ẹnikẹni to ba fa wahala ni Naijiria.

    Laipẹ yii ni iroyin gbe pe awọn kan ni ilu Abuja ti gba ileẹjọ lọ lati dawọ iburawọle fun aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan ni Naijiria, Bola Ahmed Tinubu.

    Igbẹjọ naa si ti bẹṛẹ ni ileẹjọ amọ Adajọ Agba, Iyang Ekwo sọ fun awọn to gbe ẹjọ naa wa pe ki wọn lọ sewadii wọn daadaa, ki wọn si tun ri daju pe iru ẹjọ naa ko si ni iwaju ajo to n gbọ ẹsun magomago lasiko idibo.

    Eto iburawọle fun aarẹ tuntun ti wọn dibo yan naa yoo maa waye ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un , ọdun 2023.

  11. ‘’Ẹ kò gbọdọ̀ gba Emefiele láàyè láti kúrò ní Naijiria’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Gomina ipinlẹ Zamfara, Bello Matawalle ti kesi aarẹ Buhari pe wọn ko gbọdọ fun gomina banki apapọ Naijiria, Godwin Emefiele laaye lati kuro ni Naijiria lọ si okeere.

    Eyi ko ṣẹyin iroyin to gbode kan pe aarẹ Buhari ti fun ni họlide lati lọ ka iwe ni oke okun.

    Gomina Matawalle to fi ero rẹ lede ni Ọjọ Aje ni aarẹ Buhari ti fi ero rere rẹ han nipa imura rẹ lati kuro ni ilea arẹ ni kiakia.

    Amọ o rọ aarẹ naa lati mase jẹki ẹnikẹni ba gbogbo iṣẹ rẹ to se silẹ jẹ ki o to lọ.

    Gomina naa ni bio tilẹ jẹpe aarẹ Buhari ti se isẹ rẹ gẹgẹ bi aarẹ, o ni amọ awọn to n baa arẹ naa ṣiṣẹ fẹ ba orukọ rẹ jẹ ninu itan Naijiria.

    ‘’Aarẹ Buhari ati iyawo rẹ ti fi iwa rere han nipa igbiyanju wọn lati kuro ni ilea arẹ ni kiakia.’’

    Mo gboriyin fun aarẹ to gbe igbesẹ alaafia nipa fifi aye silẹ fun gbigbe ipo silẹ ni ọna ti yoo rọrun fun ijọba to n bọ lẹyin.

    Amọ awọn osisẹ ni ijọba rẹ ko hu iwa bẹ̣, wọn n gbe igbesẹ lati mase jẹ ki ijọba to n bọ naa rọrun fun awọn araalu.

    Bakan naa ni gomina naa fikun un pe kani oun ni aarẹ Buhari oun ti oun yoo se ni lati ri pe aarẹ ko buwọlu holide kankan fun awọn osisẹ rẹ Pataki, eleyii ti yoo mu ki aye rọrun fun ijọba tuntun naa ti yoo wọle ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn, Osu Karun un, ọdun 2023.

    Ọpọ eniyan lo bu ẹnu atẹ lu igbesẹ ti gomina banki naa gbe ni asiko ti idibo ku diẹ, eleyii to fa ọwọngogo owo ati ounjẹ fun awọn araalu.

    Emefiele gbe owo naira tuntun sita, eleyii ti ko kari awọn araalu to si kan an nipa fun awọn araalu lati mase na owo atijọ to w ani ọwọ wọn lọna ati gbogun ti iwa jẹgudujẹra.

    Amọ awọn araalu ni igbesẹ naa mu inira ba wọn, ti awọn gomina ipinlẹ kọọkan sig be ijọba apapọ lọ si ileẹjọ lori igbesẹ naa.

  12. Háà, ìbà wùmí kí Bàbá mi dáríjì mí kí ó tó kú – Ọmọ Murphy Afolabi

    Ọmọ gbajugbaja osere Murphy Afolabi, Olamilekan Afolabi ti sọ ẹdun ọkan rẹ lasiko isinku baba rẹ ni Ọjọ Aje.

    Murphy Afolabi to jẹ ẹni ọ̀un mọkandinlaadọta lo padanu ẹmi rẹ ninu ile rẹ ni Ọjọ isinmi , ki o to wọ kaa ilẹ sun ni Ọjọ Aje.

    Iroyin ni nise ni gbajugbaja osere naa subu ninu baluwẹ rẹ , ti o si gba ibẹ dakẹ.

    Awọn mọlẹbi, ara ati ọrẹ lo pejọ si ibi isinku rẹ ni inu ile rẹ ni agbegbe Ikorodu, nipinlẹ Eko lati sedaro rẹ , ki wọn si se ẹyẹ ikẹyin fun.

    Akọbi Murphy Afolabi nigba to n sọrọ ni ibanujẹ ni iku baba oun jẹ fun oun, ti oun si ni ibanujẹ ọkan nitori pe oun ko jẹ ọmọ rere si baba oun, ki o to papoda.

    Bakan naa lo dupẹ lọwọ baba rẹ to ti doloogbe naa fun aduroti rẹ ati atilẹyin rẹ ni gbogbo igba.

    ‘’Mo dupẹ lọwọ Baba mi fun aduroti rẹ ni gbogbo igba, ati gbogbo ohun to ṣe fun mi’’

    ‘’Mo mo pe mi o jẹ ọmọ daradara si baba mi, amọ ko dariji mi’’

    ‘’Osu to kọja ni emi ati baba mi sọrọ, ti wọn si ni ki n mu iyawo ati ọmọ mi wa ki awọn.’’

    ‘’Bi o tilẹ jẹpe mo kuna ni gbogbo ọna gẹgẹ bi ọmọ, ẹ jọwọ ẹ forijimi.’’

    ‘’Adura mi nipe ki Ọlọrun fi ọrun kẹ wọn, ko si tẹ wọn si afẹfẹ rere.’’

    ‘’Osu to kọja ni mo pe wọn, ti wọn si fun mi ni 150,000 Naira fun itọju emi ati ẹbi mi.’’

    Iroyin ni ọmọ mẹta lo gbẹyin gbajugbaja osere to doloogbe naa.

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

  13. Ìbúrawọlé May 29 kò lè yẹ̀ rárá, olóṣèlú tó bá gbéná sórí yóò ... - Ọ̀gá àgbà Ọlọ́pàá lérí

  14. Ọlọ́pàá mú àgúnbánirọ fún ẹ̀sùn ífipábánilòpọ̀ ní Ogun

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Iléeṣé Ọlọ́pàá ni ìpínlẹ Ogun tí kéde pé àwọn tí fi ọwọ ofin mu àgúnbánirọ kan tí wọn fi ẹ̀sùn kan pé ó fi ipá bá ọmọ ogún ọdún kan lọpọ nibẹ.

    Agbẹnusọ Ọlọ́pàá ni Ogun, Abimbola Oyeyemi lọ fi ìdí iṣẹlẹ náà múlẹ̀ ni Abeokuta.

    Abimbola ni obìnrin tí wọn fi ipá bá lọpọ náà ṣàlàyé bí ọrọ ṣe jẹ́.

    Arábìnrin náà ni ọrẹkùnrin ọ̀rẹ́ rẹ ni ẹni tó fi ipá bá lọpọ.

    Ó ní arákùnrin náà wá sí ibi tí òun àti àwọn tí wọn jọ ń ṣíṣe pọ wá, ti o si ni kí òun tẹ́lẹ̀ òun lọ ra ẹ̀bùn fún òun, láti ṣe ayajọ ọjọ ibi rẹ, tí òun sì tẹle lai fún ra.

    Ó ní gẹ́gẹ́ bi ọrẹkunrin ọrẹ òun, òun sì tẹle, àmọ́ lọ́nà lọ tí ni òun fẹ́ yà sí inú ilé ẹ̀kọ́ tí òun ti ń kọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti mú owo.

    Ó ní bí wọn ṣe de iléẹkọ náà lo fi ipa mú òun wọlé sí yara rẹ, tó sì fí ipa bá lopọ.

    Ọlọ́pàá ni afurasi náà jẹwọ pé lóòótọ́ ni òun se bẹẹ, àmọ́ ó tọrọ aforiji pé òun ko mọ òun tó bà lé òun.

    Bákan náà lo fikùn un pé wọn tí gbé obinrin tí wọn fí ipa bá lọpọ náà lọ sí ilé ìwòsàn, fún àyẹ̀wò àti itọju tó péye.

    Ní báyìí, wọn tí gbé ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń rí sì ọrọ ìwà ọ̀daràn fún ẹkúnrẹ́rẹ́ iwadii àti igbesẹ tó kàn.

  15. "Mi ò lè kí Tinubu kú orí irẹ nítorí PDP ti gba iléẹjọ́ lọ"

    Àwòrán

    Oríṣun àwòrán, Others

    Igbakeji alaga ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tẹ́lẹ̀, Bode George tí kéde ìdí tí òun kò leè kí Bola Tinubu kú orí irẹ pé ó jawe olubori nínú idibo sipo Ààrẹ ni Naijiria.

    Bode George ṣàlàyé ìdí náà lásìkò tí àwọn adari ni Ipinle Eko lọ ki ni ile rẹ.

    Àwọn àgbààgbà náà ni wọ́n wá kii nítorí aawo to wá laarin òun àti Ààrẹ tí wọn ṣẹ̀ṣẹ̀ dibo yàn náà.

    Àwọn àgbààgbà náà tí Tajudeen Olusi se adari fún lọ ní àwọn fe ki àlàáfíà jọba laarin awọn Bode George àti Tinubu nítorí aigbọraeniye tó wà láàrin wọn.

    Bákan náà ni wọn ní kí ìjà lè pín, kí Bode George kí Tinubu kú oriire esi idibo náà.

    Àmọ́ ni ìdáhùn rẹ, Bode George ni kò si ọrọ tó lè láàárín òun àti Tinubu.

    Bákan náà lọ ní òun tó dára ní láti jọ ṣíṣe papọ ni ìjọba tó ń bọ̀.

    Àmọ́ Bode George fikùn un pé òun kò ní lè kí Tinubu kú orírẹ nítorí ẹjọ́ tí wá ní iléẹjọ́.

    Ó ní gẹ́gẹ́bí adari nínú ẹgbẹ́ òṣèlú òun, òun kò ní leè kí Tinubu kú orrire báyìí titi ẹjọ́ yóò fi parí ní iléẹjọ́.

  16. ‘’À kọ láti gbé àwọn obìnrin 160 tó há sí Sudan nítorí wọn kò ní ìwé ìgbélú Naijiria’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Ijọba apapọ lorilẹede Naijiria ti ni awọn kọ lati gbe awọn obinrin to le ni ọgọjọ pada wa si Naijiria nitori wọn ko ni iwe igbẹlu ti Naijiria, iyen passport.

    Aadri ajọ to n risi ọrọ pajawiri ni Naijiria, Mustapha Ahmed lo fi eleyii lede ni ilu Abuja lasiko to n sọ ibi ti ọrọ de duro lori kiko awọn ọmọ Naijiria to ha si Sudan kuro nibe nitori ogun to bẹ silẹ nibẹ.

    O ni awọn miran tile ni irandiran wọn lo jẹ ọmọ Naijiria amọ ti wọn bi awọn si Sudan sugbọn ko si aridaju awọn ọrọ naa.

    Ijọba ni ko si aridaju lati fi idi ọrọ naa mulẹ nitori ko si ohun to tọka si pe ọmọ Naijiria ni wọn.

    Ahmed fikun un pe ọpọlọpọ ninu awọn ọmọ ilẹ Sudan lo n gbiyanju lati wọ inu ọkọ to fẹ gbe awọn ọmọ Naijiria.

    Bakan naa lo fikun un pe aye si silẹ fun awọn ọmọ Naijiria to wa ni Sudan lati wa si ile.

    Ijọba Naijiria seleri pe ko si ẹmi ọmọ Naijiria kankan ti yoo lọ si iṣẹlẹ naa.

  17. Ghana: Ẹgbẹ́ alátakò NDC yan John Mahama gẹ́gẹ́ bí olùdíje sípò ààrẹ ní ìdìbò ọdún 2024

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, John Mahama

    Ẹgbẹ alatako lorilẹede Ghana ti yan aarẹ tẹlẹri John Dramani Mahama gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ ni ẹgbẹ oselu National Democratic Congress (NDC).

    Igba kẹrin ni yii ti Mahama yoo maa dije du ipo aarẹ lorilẹede naa, ti ọdun 2012 si jẹ igba akọkọ.

    Aarẹ tẹlẹri naa lo ni ibo ida mejidinlọgọrin ninu idibo abẹle to waye ni Ọjọ Satide.

    Ida kan pere ninu esi idibo naa ni arakunrin Bojo Bonsu to ba fi igagbaga ni.

    Ni idahun si aseyọri naa, John Mahama gba oju ẹrọ ibanidọre rẹ lọ lati dupẹ lọwọ awọn ololufẹ rẹ, ti wọn si ni ni oun ni yoo gbe asia ẹgbẹ naa ni idibo ọdun to n bọ.

    Aarẹ ilẹ Ghana, Nana Akufo-Addo lo fi ẹyin Mahama nalẹ ni lọdun 2020, to si wọle gẹgẹ bi aarẹ orilẹede ọhun.

    Lara awọn ti wọn yoo maa figagbaga ni igbakeji aarẹ orilẹede naa, Dr Mahamudu Bawunia ti awọn eniyan Gbagbo pe o jẹ aayo awọn araalu, to si n dije du ipo ni ẹgbẹ oselu NPP.

    Amọ lati ọdun 2012 ti John Mahama ti n dari ẹgbẹ oselu NDC gẹgẹ bi oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oselu naa, ni o ti bori ninu ẹyọkan, to si kuna ninu meji.

    Lati ọdun to kọja ni eto ọrọ aje orilẹede Ghana ti n koju ipenija ọwọngogo ounjẹ, eleyii to fa ki ọrọ aje naa ma gbooro bi ti tẹlẹ.

  18. Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

  19. ‘’A ti rí òkú ènìyàn 200 nínú àwọn tí pásítọ̀ wọn ní kí wọ́n gba ààwè títí wọn yóò fi rí Jesu’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Kenya ni awọn ti ri oku eniyan mọkanleniigba to ti ku ninu isẹlẹ to waye ni iha Malindi, lorilẹede naa.

    Ileeṣẹ ọlọpaa ni iwadii ti wọn n se lọwọ fihan an pe awọn oku naa niise pẹlu ẹsun ti wọn fi kan pasitọ kan to ni ki awọn ọmọ ijọ rẹ gba aawe titi wọn yoo fi ri Jesu.

    Wọn ni awọn oṣiṣẹ pajawiri lorilẹede naa si n wa awọn eniyan to kopa ninu iṣẹlẹ laabi naa.

    Kọmisọnna ọlọpaa ni agbegbe naa, Rhoda Onyancha to kede iye awọn eniyan tuntun naa, ni eniyan mẹrindinlọgbọn ni wọn ti fi panpẹ mu lori iṣẹlẹ iku awọn eniyan naa.

    Pasitọ naa, Paul Nthenge Mackenzie ni wọn fi ẹsun kan pe o kan ni ipa fun awọn ara ṣọọṣi rẹ pe wọn ko gbọdọ ja aawẹ naa, tabi ki ẹnikẹni kuro ni inu igbo naa ni aaye.

    Ọga Ọlọpaa naa ni awọn oṣiṣẹ pajawiri naa ti n hu oku jade lati bi ọjọ meji lai sinmi, ti wọn yoo si tun pada si ibẹ ni Ọjọ Iṣẹgun.

    Nibayii, Ileẹjọ ti pasẹ ki pasitọ naa wani atimọle fun ọsẹ mẹta titi iwadii naa yoo fi pari lori iṣẹlẹ, ti wọn pe akọle rẹ ni ‘’Shakahola Forest Massacre’’.

    Iwadii ti onimọ nipa ayẹwo oku se ni awọn to ku lo jẹ ebi lo pa wọn ku, amọ o ni o seese ki wọn fun awọn ọmọ to ku naa loru pa, abi ki wọn na wọn titi ti wọn fi ku.

    Bakan naa ni wọn ni wọn yoo awọn ẹya ara awọn miran ninu awọn oku naa.

  20. APC ti fi àwòrán Tinubu àti ti ìgbákejì rẹ̀ tuntun síta

    Ẹgbẹ oselu APC ti fi aworan aarẹ ti araalu dibo yan, Bola Ahmed Tinubu sita pẹlu ti igbakeji rẹ, Kashim Shettima.

    Eyi n waye saaju iburawọle ti yoo waye ni Ọjọ Kọkandinlọgbọn,oṣu Karun un, ọdun 2023.

    Agbẹnusọ fun Bola Tinubu, Bayo Onanuga,lo fi aworan naa lede loju ọpọ Twitter.

    Bakan naa lo fikun un pe ajọ to n risi iburawọle aarẹ ati gbakeji rẹ ti araalu dibo yan buwọlu aworan tuntun naa.

    O ni ọpọ eeyan ni yoo maa lo aworan naa ,ti wọn yoo si maa fi si ọfisi wọn gẹgẹ bi aworan aarẹ ati ti igbakeji rẹ.

    Saaju ni agbẹnusọ aarẹ naa ti kede pe Tinubu rin irinajo lọ si oke okun nitori awọn to fẹ ri fun ipo kan tabi omiran ti pọju bi o se yẹ lọ.

    O ni irinajo naa yoo fun ni anfaani lati gbaradi bi o se yẹ fun iburawọle naa ti yoo waye ni aipẹ.

    Bi ọjọ iburawọle yi ṣe n kan lẹkun dẹdẹẹ, bẹẹ naa ni awọn ikọ kan n pe fun ki wọn ma burawọle fun aarẹ ti ilu dibo yan yi.

    Wọn ni awọn n pe ipe yi notori magomago lasiko idibo naa to gbe aarẹ ti wọn dibo yan naa wọle.

    Aworan tuntun Tinubu ati Shettima

    Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga